____________________
Sirọ̄tun mustaƙīm “ọ̀nà tààrà” jẹyọ ní àyè 33 nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ó sì dúró fún ìwọ̀nyí: (1) Jíjìnnà sí ẹbọ ṣíṣe, jíjìnnà sí ìwà ìbàjẹ́, ṣíṣe rere àti lílo òfin Allāhu; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:151-153. (2) Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:51&101. (3) Ẹ̀sìn kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ṣe; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:83-90. (4) Ẹ̀sìn ’Islām; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:125-126. Nítorí náà, kò sí àyè kan nínú al-Ƙur’ān tí ọ̀nà tààrà ti dúró fún ẹ̀sìn kristiẹniti tàbí yẹhudi.
Nígbà tí mùsùlùmí bá sì ń ṣàdúà ní gbogbo ìgbà pé “ihdina-ssirọ̄tọl-mustaƙīm” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wà rinlẹ̀ lójú ọ̀nà tààrà.” Ìyẹn ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām, ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà, àdúà ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ sínú ẹ̀sìn ’Islām títí dọjọ́ ikú ni àdúà náà dúró fún. Àti pé, āyah 7 ti yanjú ọ̀rọ̀ náà pé, kì í ṣe ọ̀nà yẹhudi nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìbínú lọ́dọ̀ Allāhu. Kì í sì ṣe ọ̀nà kristiẹniti nítorí pé, wọ́n ti di olùṣìnà. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7: 23.
Kíyè sí i! Ìdí tí àdúà yìí sì fi pàtàkì púpọ̀ ni pé, tí ènìyàn bá ṣe ẹ̀sìn ’Islām, kò lè jèrè rẹ̀ àyàfi kí ó kú sínú rẹ̀ nítorí sūrah Āli-‘Imrọ̄n; 3:102. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọsọs; 28:56.
____________________
Àwọn wo gan-an ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún, tí àwa mùsùlùmí ń tọ ojú-ọ̀nà wọn? Ẹ ka sūrah Mọryam;19:58.