ترجمة سورة إبراهيم

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة إبراهيم باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí),
Allāhu, Ẹni tí Ó ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ègbé ni fún àwọn aláìgbàgbọ́ níbi ìyà líle.
Àwọn t’ó ń fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju tọ̀run, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́; àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà.
A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀1 nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.2
____________________
1 “Èdè ìjọ rẹ̀” nínú āyah yìí dúró fún “èdè abínibí rẹ̀” tàbí “èdè ìlú tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán an níṣẹ́ sí”. Èyí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà nítorí ìdí pàtàkì méjì. Ìdí àkọ́kọ́: Èdè abínibí Ànábì kọ̀ọ̀kan àti Òjíṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn níṣẹ́. Ìdí kejì: Ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) ni Ọlọ́hun rán níṣẹ́ sí àwọn elédè abínibí rẹ̀ nìkan àyàfi Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo elédè rẹ̀ àti elédè mìíràn ni Allāhu rán Ànábì wa nìkan níṣẹ́ sí. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà ẹ̀wẹ̀, Allāhu kò fi èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè abínibí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rán an níṣẹ́. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kò tìtorí àwọn elédè mìíràn t’ó wà láyìíká rẹ̀ fi èdè mìíràn kún èdè abínibí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú ìmísí Rẹ̀. Èdè abínibí rẹ̀ náà sì ni èdè Lárúbáwá. Dípò kí Allāhu tún lo èdè mìíràn fún ìmísí Rẹ̀ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àwọn ògbifọ̀ ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń lo nígbàkígbà tí iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ bá kan elédè mìíràn. Lẹ́yìn àlàyé yìí, àwọn n̄ǹkan mẹ́ta wọ̀nyí gbọ́dọ̀ yé wa dáradára. Àkọ́kọ́: Èyíkéyìí èdè tí ẹnikẹ́ni bá túmọ̀ al-Ƙur’ān sí, kò lè ṣe dọ́gba sí al-Ƙur’ān. Kò sì lè rọ́pò rẹ̀. Nítorí náà, tí àléébù kan tàbí òmíràn bá jẹyọ nínú iṣẹ́ atúmọ̀ èdè al-Ƙur’ān, kò kó àlèébú kan kan bá al-Ƙur’ān rárá tí àtúnṣe bá padà dé bá ìtúmọ̀-òdì náà nítorí pé ọ̀rọ̀ tí Allāhu sọ gẹ́lẹ́ sì wà nínú tákàǹdá tí kò yinjẹ. Kò sì túmọ̀ sí pé al-Ƙur’ān ti pé méjì lórí igbá. Ìkejì: Àwọn tírà sánmọ̀ mìíràn bíi Zabūr, Taorāt àti ’Injīl ti wọ ipò aláìsí nítorí pé kò sí ẹyọ kan nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí èdè ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ (èdè ìfihàn rẹ̀) kò tí ì dòkú. Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn akọ̀tàn nìkan l’ó kù wọ́n kù. Ìkẹta: Olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah tako bí ó ṣe jẹ́ pé èdè abínibí nìkan ni Allāhu fi máa ń bá ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sọ̀rọ̀. Mirza Ghulam Ahmad, ìyẹn olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah, parọ́ ńlá mọ́ Allāhu pé Allāhu fi èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè abínibí òun rán òun níṣẹ́ sáyé. Àpapọ̀ àwọn èdè náà sì jẹ́ mẹ́fà; èdè Gẹ̀ẹ́sì, Punjabi, Hébérù, Paṣian, Lárúbáwá àti Urudu. Èdè Urudu nìkan sì ni èdè abínibí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òpùrọ́ pọ́nńbélé t’ó pe ara rẹ̀ ní Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun sí gbogbo ayé ni ọ̀gbẹni náà, ó tún ti ṣàì gbàgbọ́ nínú āyah yìí “A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀“. Kò sì wulẹ̀ tún sí ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí mímọ́ ti Allāhu mọ́ fún ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ikú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àfi àwọn onímìísí èṣù bíi ti mirza Ghulam Ahmad, àwọn onisūfīy àti àwọn ẹlẹ́mìí-gbígbé. Allāhu là wá lọ́wọ́ gbogbo àwọn asòòkùn-sẹ́sìn.
2 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:12.
A kúkú fi àwọn āyah Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ pé: “Mú ìjọ rẹ kúrò láti inú àwọn òkùnkùn bọ́ sínú ìmólẹ̀. Kí o sì rán wọn létí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu (lórí wọn).” Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé ẹ rántí ìkẹ́ Allāhu lórí yín nígbà tí Ó gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín; wọ́n ń dúnńbú àwọn ọmọkùnrin yín, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa Ẹlẹ́dàá yín sọ ọ́ di mímọ̀ (fun yín pé): "Dájúdájú tí ẹ bá dúpẹ́, Èmi yóò ṣàlékún fun yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣàìmoore, dájúdájú ìyà Mi mà le."
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Tí ẹ bá ṣàìmoore, ẹ̀yin àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́."
Ṣé ìró àwọn t’ó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n ti ọwọ́ wọn bọ ẹnu wọn (ní ti ìbínú), wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí."
Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: “Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan.” Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan tayọ abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.”
Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Kí ni ó máa ṣe wá tí a ò níí gbáralé Allāhu, Ó kúkú ti fi àwọn ọ̀nà wa mọ̀ wá. Dájúdájú a máa ṣe sùúrù lórí ohun tí ẹ bá fi kó ìnira bá wa. Allāhu sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn Òjíṣẹ́ wọn pé: “Dájúdájú àwa yóò le yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa tàbí kí ẹ kúkú padà sínú ẹ̀sìn wa.” Nígbà náà, Olúwa wọn fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn pé: “Dájúdájú A máa pa àwọn alábòsí run.
Dájúdájú A sì máa fun yín ní ibùgbé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn. ” Ìyẹn wà fún ẹni tí ó bá páyà ìdúró (níwájú) Mi, tí ó tún páyà ìlérí Mi.
Wọ́n sì tọrọ àrànṣe (Allāhu lórí ìjọ wọn). Gbogbo aláfojúdi, olóríkunkun sì pàdánù.
Iná Jahanamọ ń bẹ lẹ́yìn (ìparun) rẹ̀; A ó sì máa fún un ní omi àwọyúnwẹ̀jẹ̀ mu.
Ó máa sáré mu ún díẹ̀díẹ̀, kò sì níí fẹ́ẹ̀ lè gbé e mì. (Ìnira) ikú yó sì máa yọ sí i ní gbogbo àyè, síbẹ̀ kò níí kú. Ìyà t’ó nípọn tún wà fún un lẹ́yìn rẹ̀.
Àfiwé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn: àwọn iṣẹ́ wọn dà bí eérú tí atẹ́gùn fẹ́ dànù pátápátá ní ọjọ́ ìjì atẹ́gùn. Wọn kò ní agbára kan lórí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ìyẹn ni ìṣìnà t’ó jìnnà.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo? Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.
Ìyẹn kò sì lè dá Allāhu lágara.
Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.”
Èṣù yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: “Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fun yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fun yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fun yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè ràn yín lọ́wọ́ (níbi ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè ràn mí lọ́wọ́ (níbi ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú.” Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.
Wọ́n sì máa mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni ‘àlàáfíà’.
Ṣé o ò rí bí Allāhu ti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ dáadáa pẹ̀lú igi dáadáa, tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí ẹka rẹ̀ sì wà nínú sánmọ̀,
tó sì ń so èso (jíjẹ) rẹ̀ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀? Allāhu ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àkàwé nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Àkàwé ọ̀rọ̀ tí kò dára sì dà bí igi tí kò dára, tí wọ́n fà tu láti òkè lórí ilẹ̀, tí kò sì ní àyè kan lórí ilẹ̀.
Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ó sì máa ṣi àwọn alábòsí lọ́nà. Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
Ṣé o ò rí àwọn t’ó yí ìdẹ̀ra Allāhu padà sí àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì mú ìjọ wọn gúnlẹ̀ sí ilé ìparun?
Iná Jahanamọ ni wọn yóò gúnlẹ̀ sí; ibùgbé náà sì burú.
Wọ́n sọ (àwọn kan di) akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò nínú ẹ̀sìn Rẹ̀. Sọ pé: “Ẹ máa gbádùn ǹsó, nítorí pé dájúdájú àbọ̀ yín ni Iná.”
Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò níí sí títà-rírà kan àti yíyan ọ̀rẹ́ kan nínú rẹ̀.
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì fi ń mú àwọn èso jáde; (ó jẹ́) arísìkí fun yín. Ó sì rọ ọkọ̀ ojú-omi fun yín kí ó lè rìn lójú omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Ó tún rọ àwọn odò fun yín.
Ó rọ òòrùn àti òṣùpá fun yín, tí méjèèjì ń rìn láì sinmi. Ó tún rọ òru àti ọ̀sán fun yín.
Àti pé Ó ń fun yín nínú gbogbo n̄ǹkan tí ẹ tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀. Tí ẹ bá ṣe òǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú ènìyàn ni alábòsí aláìmoore.
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà.
Olúwa mi, dájúdájú àwọn òrìṣà ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn sọnù. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi, dájúdájú òun ni ẹni mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa mi, dájúdájú Ìwọ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́.
Olúwa wa, dájúdájú èmi wá ibùgbé fún àrọ́mọdọ́mọ mi sí ilẹ̀ àfonífojì, ilẹ̀ tí kò ní èso, nítòsí Ilé Rẹ Ọlọ́wọ̀. Olúwa wa, nítorí kí wọ́n lè kírun ni. Nítorí náà, jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn fà sọ́dọ̀ wọn. Kí O sì pèsè àwọn èso fún wọn nítorí kí wọ́n lè dúpẹ́ (fún Ọ).
Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O mọ ohun tí à ń fi pamọ́ àti ohun tí à ń ṣe àfihàn rẹ̀. Kò sì sí kiní kan nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀ t’ó pamọ́ fún Allāhu.
Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún mi ní ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ nígbà tí mo ti darúgbó. Dájúdájú, Olúwa mi ni Olùgbọ́ àdúà.
Olúwa mi, ṣe èmi àti nínú àrọ́mọdọ́mọ mi ni olùkírun. Olúwa wa, kí O sì gba àdúà mi.
Olúwa mi, ṣàforíjìn fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọjọ́ tí ìṣírò-iṣẹ́ yóò ṣẹlẹ̀."
Má ṣe lérò pé Allāhu gbàgbé n̄ǹkan tí àwọn alábòsí ń ṣe níṣẹ́. Ó kàn ń lọ́ wọn lára dí ọjọ́ kan tí àwọn ojú yóò yọ síta ràngàndàn.
Wọn yóò má sáré (lọ síbi àkójọ fún ìṣírò-iṣẹ́), wọn yóò gbé orí wọn sókè, ìpéǹpéjú wọn kò sì níí padà sọ́dọ̀ wọn, àwọn ọkàn wọn yó sì pa sófo pátápátá (fún ìbẹ̀rù).
Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, àwọn t’ó ṣàbòsí yó sì wí pé: “Olúwa wa, lọ́ wa lára fún àsìkò díẹ̀ sí i, a máa jẹ́pè Rẹ, a sì máa tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́.” Ṣé ẹ̀yin kò ti búra ṣíwájú pé ẹ̀yin kò níí kúrò nílé ayé ni?
Ẹ sì gbé nínú ibùgbé àwọn t’ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Ó sì hàn si yín bí A ti ṣe pẹ̀lú wọn. A tún fun yín ni àwọn àkàwé.
Wọ́n kúkú ti dá ète wọn, ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ète wọn wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé (pẹ̀lú) ète wọn àpáta fẹ́ẹ̀ lè yẹ̀ lulẹ̀.
Nítorí náà, má ṣe lérò pé Allāhu yóò yapa àdéhùn Rẹ̀ tí Ó ṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
Ní ọjọ́ tí A máa yí ilẹ̀ ayé padà sì n̄ǹkan mìíràn. (A máa yí) àwọn sánmọ̀ náà (padà. Àwọn ẹ̀dá) sì máa jáde (síwájú) Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
O sì máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí wọn yóò so wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn sínú sẹ́kẹ́sẹkẹ̀.
Òjé Iná ni àwọn èwù wọn. Iná yó sì bo ojú wọn mọ́lẹ̀ bámúbámú
nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Èyí ni iṣẹ́-jíjẹ́ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè fi ṣe ìkìlọ̀, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé (Allāhu) Òun nìkan ni Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí, Ọ̀kan ṣoṣo, àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí.
Icon