ترجمة سورة الفرقان

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الفرقان باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá.
(Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n.
(Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Wọn kò sì lè dá kiní kan. A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé.
Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.”
Sọ pé: "Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, t’ó ń jẹun, t’ó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?
Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”
Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.
Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore t’ó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan.
Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná t’ó ń jò sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́.
Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀).
Nígbà tí Wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè t’ó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀.
(A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”
Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn.
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”
(Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí wọn kò lè gbé ìyà Iná kúrò fun yín, wọn kò sì lè ràn yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà t’ó tóbi tọ́ wò.”
A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran.
Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa, tàbí kí á rí Olúwa wa (sójú nílé ayé)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ànà ní ìtayọ-ẹnu àlà t’ó tóbi.
(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n yóò rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”
Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku àfẹ́dànù.
Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi.
Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun. A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà.
Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́.
(Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: "Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà.
Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò.
Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú Èṣù ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn."
Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi dájúdájú àwọn ènìyàn mi tí pa al-Ƙur’ān yìí tì.”
Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀.
Wọn kò níí mú àpẹẹrẹ kan wá fún ọ (bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé t’ó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀).
Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ.
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un.
A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá.
(Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí.
(Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (t’ó ń bẹ) láààrin wọn.
Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpèjúwe (nípa àwọn t’ó tako òdodo). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá.
Àti pé dájúdájú wọ́n kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde.
Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́!?
Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà.
Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)?
Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Wọ́n wulẹ̀ ṣìnà jùlọ.
Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn.
Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́).
Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fun yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fun yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu).
Òun sì ni Ẹni t’’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀
nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu.
Dájúdájú A ti pín omi yìí láààrin wọn nítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore.
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.
____________________
Āyah yìí ti fi rinlẹ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìlú ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti gbé Òjíṣẹ́ dìde. Bí àpẹẹrẹ, kò sí Òjíṣẹ́ Allāhu t’ó jẹ́ Yorùbá, Haúsá tàbí Ibò. Àmọ́ ní ti sūrah Fātir; 35:24 kò sí ìjọ kan tí Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ si. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, “ummah” dúró fún àpapọ̀ ìjọ ènìyàn fún àkókò Òjíṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Òjíṣẹ́ Allāhu fún àpapọ̀ ìjọ ènìyàn, yálà funfun tàbí dúdú, láti àsìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti gbé e dìde ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀ títí di òpin ayé.
Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun t’ó tóbi.
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) t’ó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ t’ó móró. Ó fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti kó ìnira bá ẹ̀dá).
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.
____________________
Ìṣẹ̀dá ènìyàn wáyé nípasẹ̀ oríṣi ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkíní; nípasẹ̀ erùpẹ̀. Èyí sì ni Allähu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá bàbá wa àkọ́kọ́, Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń ki ìṣẹ̀dá wa mọ́ erùpẹ̀ nítorí ti Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkejì; nípasẹ̀ ẹfọ́nhà. Èyí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá ìyá wa àkọ́kọ́, Hawā’ (r.ah). Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń kí ìṣẹ̀dá àwọn obìnrin mọ́ àwa ọkùnrin, nítorí ti Hawā’ ni (rọdiyallāhu 'anhā). Ìkẹta; nípasẹ̀ omi àtọ̀. Èyí si ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá èmi àti ẹ̀yin. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń ki ìṣẹ̀dá wa mọ́ omi nítorí ti èmi àti ẹ̀yin ni. Ìkẹrin; nípasẹ̀ atẹ́gùn ẹ̀mí àti gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀. Èyí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe ẹ̀dá ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kíyè sí i! Àti ìkíní àti ìkejì àti ìkẹta, kò sí ènìyàn kan tí kò ní atẹ́gùn ẹ̀mí lára ṣíwájú kí ó tó di abẹ̀mí. Ṣebí atẹ́gùn ẹ̀mí tí Allāhu ṣẹ̀ṣẹ̀ fi rán mọlāika Jibril ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni Allāhu fúnra Rẹ̀ fẹ́ sínú ọbọrọgidi Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa àti olùgbàlà. Báwo ni Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) yó ṣe wá jẹ́ olúwa àti olùgbàlà! Kò sì sí ènìyàn kan tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ni sọ gbólóhùn “kunfayakūn” fún, ṣíwájú kí ó tó máa bẹ.
Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún Èṣù) láti tako Olúwa rẹ̀.
A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.
Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”
____________________
Ìyẹn ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan tí ó ń gba owó-ọ̀yà lọ́wọ́ ìjọ rẹ̀ lórí iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an níṣẹ́ sí wọn, iṣẹ́ olóore ni fún ẹnikẹ́ni láti máa fún Òjíṣẹ́ tí Allāhu rán sí wọn lọ́rẹ. Ọrẹ sì yàtọ̀ owó-ọ̀yà.
Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Un. Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan t’ó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn.
Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀.
Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un).
Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn t’ó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ìdúró-kírun fún Olúwa wọn.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun.
Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró.
Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.
(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀.
A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ.
Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni.
(Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.
____________________
Ìyẹn ni pé, àwọn ẹrúsìn Allāhu ń pọ́nra wọn lé nípa àìjókòó pọ̀ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ. Wọ́n sì ń pọ́nra wọn lé nípa yíyẹra fún ìjókòó tí àwọn aláìmọ̀kan bá ti ń ṣe ìbàjẹ̀ nínú rẹ̀.
(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”
Àwọn wọ̀nyẹn, ipò gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀.
Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró.
Sọ pé: "Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín. Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fun yín)."
Icon