ترجمة معاني سورة النازعات باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

آية رقم 1
Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́.
آية رقم 2
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
آية رقم 3
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀.
آية رقم 4
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà.
آية رقم 5
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé.
آية رقم 6
Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe.
آية رقم 7
Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e.
آية رقم 8
Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
آية رقم 9
Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
آية رقم 10
Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
آية رقم 11
Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán?"
آية رقم 12
Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́.)"
آية رقم 14
Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
آية رقم 15
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
آية رقم 16
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
آية رقم 17
Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà.
آية رقم 18
Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
آية رقم 19
Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀)."
آية رقم 20
Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án.
آية رقم 21
(Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀.
آية رقم 22
Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
آية رقم 23
Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
آية رقم 24
Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ."
آية رقم 25
Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).
____________________
Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ náà nìyí, Fir‘aon wí pé: "Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi!" Sūrah al-Ƙọsọs; 28:38
آية رقم 26
Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu).
آية رقم 27
Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
آية رقم 28
Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé.
آية رقم 29
Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
آية رقم 30
Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:29.
آية رقم 31
Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
آية رقم 32
Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
آية رقم 33
Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
آية رقم 34
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
آية رقم 35
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
آية رقم 36
Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran.
آية رقم 37
Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà,
آية رقم 38
tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
آية رقم 39
dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
آية رقم 41
dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
آية رقم 42
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?"
آية رقم 43
Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná?
آية رقم 44
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
آية رقم 45
Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀.
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé).
تقدم القراءة