ﰡ
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé: “Fífi sūrah yìí sọrí Mọryam, ìyá Jésù Kristi àti fífi sūrah kẹta, ìyẹn sūrah āli ‘Imrọ̄n, sọrí mọ̀lẹ́bí Mọryam ti fi hàn kedere pé, kò sí irú Mọryam nínú àwọn ẹ̀dá nítorí pé, kò tún sí sūrah kan kan mọ́ nínú al-Ƙur’ān tí Allāhu fi sọrí obìnrin mìíràn.” Wọ́n tún fi kún un pé, “Ṣebí kò sí sūrah tí wọ́n fi sọrí ìyá Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí ìyàwó rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀.”
Èsì: Kí ni ìbátan orúkọ Mọryam, ìyá Jésù pẹ̀lú ìjọ́sìn fún Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo? Kò sí. Ọlọ́hun t’ó dá Mọryam, ìyá ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Ọlọ́hun kò ṣe Mọryam ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀.
Dípò kí òye àwọn kristiẹni lọ síbi pé, tí kò bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ òdodo pọ́nńbélé t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam, ìyá Jésù. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam, ìyá ‘Īsā nínú Bíbélì, níbi tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Josẹfu gbẹ́nàgbẹ́nà, ẹni tí wọ́n kà kún ọkọ rẹ̀?
Tí ó bá jẹ́ pé fífi orúkọ sọrí sūrah kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé bá sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, kì í kúkú ṣe Mọryam nìkan ni ẹ̀dá tí wọ́n fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kò sì pọn dandan láti rí orúkọ obìnrin mìíràn yàtọ̀ sí Mọryam nínú al-Ƙur’ān. Ṣebí ẹ̀dá ni Mọryam, ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́, kò sí sūrah ‘Īsā. Níwọ̀n ìgbà tí kò sì sūrah ‘Īsā, tí kò sì tàbùkù Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ náà ni kò tàbùkù obìnrin kan kan tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú fi òdidi sūrah kan sọrí gbogbo àwọn obìnrin, ìyẹn “sūrah an-Nisā’”. Tún wò ó, kò sì sí sūrah àwọn ọkùnrin. Ǹjẹ́ èyí yọ àwọn ọkùnrin kúrò nípò tí Allāhu fi ṣe àjùlọ fún wa lórí àwọn obìnrin bí? Rárá.
Ẹ jẹ́ kí á bi àwọn kristiẹni léèrè ìbéèrè pé, ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam, ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ kristiẹniti di ojúlówó ẹ̀sìn Ọlọ́hun, nígbà tí àwọn méjèèjì gan-an kò dá kristiẹniti mọ̀ lójú ayé wọn?
Tí ó bá jẹ́ pé nítorí pé wọ́n fi sūrah kan sọrí Mọryam, ìyá ‘Īsā lágbára tayọ “fífẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́hun”, kí ni àwọn kristiẹni máa sọ nípa àwọn sūrah wọ̀nyí:
Sūrah al-Baƙọrah – sūrah 2, sūrah tí wọ́n fi sọrí màálù tí ìjọ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pa láti fi jí òkú dìde?
Sūrah an-Nahl – sūrah 16, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn kòkòrò oyin?
Sūrah an-Naml – sūrah 27, sūrah tí wọ́n fi sọrí kòkòrò àwúrèbe (èèrà)?
Sūrah al-’Ankabūt – sūrah 29, sūrah tí wọ́n fi sọrí aláǹtakùn?
Sūrah al-Fīl – sūrah 105, sūrah tí wọ́n fi sọrí àwọn erin tí ìjọ Abraha gùn wá ja Kaabah lógun, àmọ́ tí Allāhu pa wọ́n rẹ́?
Ṣé sūrah Màálù sọ màálù di bùrọ̀dá ni tàbí súrah erin sọ erin di bàbá? Ṣé sūrah kòkòrò òyin sọ kòkòrò oyin di òrìṣà ni tàbí sūrah aláǹtakùn sọ aláǹtakùn di ọmọ ọlọ́hun ni? Rárá o!
Kókó ọ̀rọ̀ wa ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò pe Mọryam ní orúkọ kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tayọ olódodo. Bákan náà, ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn, àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀, kò sọ ọmọ Mọryam di olúwà àti olùgbàlà. Ìyá àti bàbá Ànábì ’Ibrọ̄him ńkọ́? Kò sí ẹni t’ó tàbùkù Ànábì ’Ibrọ̄hīm lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ànábì Mūsā ńkọ́? Kò sí ẹni t’ó tàbùkù Ànábì Mūsā lórí ẹ̀sùn pé, wọn kò dárúkọ ìyá àti bàbá rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé tàbí pé wọn kò fi sūrah kan sọrí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Tí wọ́n bá dárúkọ wọn nínú rẹ̀ ńkọ́ tàbí tí wọ́n bá fi orúkọ wọn sọrí àwọn sūrah kan nínú rẹ̀ ńkọ́, kí ni ìwọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú bí a ṣe fẹ́ jọ́sìn fún Allāhu? Bí a ṣe rí sūrah āli ‘Imrọ̄n, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam, a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ, tí Allāhu fi sọrí ẹbí Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di ọmọ Ọlọ́hun. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ ẹnikẹ́ni di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣíṣa ẹ̀dá kan lẹ́ṣà kò sì sí lọ́wọ́ ẹ̀dá. Allāhu l’Ó ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà.
Kíyè sí i, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fi orúkọ ẹ̀dá kan sọrí sūrah kan tàbí Ó dárúkọ ẹ̀dá kan nínú al-Ƙur’ān, n̄ǹkan mẹ́ta kan gbọ́dọ̀ yé wa nípa rẹ̀ dáadáa.
Ìkíní: Kò gbọ́dọ̀ sí ẹ̀sùn fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí dídárúkọ àti àìdárúkọ ẹnì kan nínú al-Ƙur’ān rẹ̀. Bí Ó ṣe fẹ́ l’Ó ṣe.
Ìkejì: Òdodo tí kò ṣe é jà níyàn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa ẹ̀dá tí orúkọ rẹ̀ wà nínú al-Ƙur’ān nítorí pé, òdodo lọ̀rọ̀ Ọlọ́hun.
Ìkẹta: Ẹ̀kọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́ kọ́ wa lára ẹ̀dá Rẹ̀ náà ni orí ire tiwa nínú rẹ̀, kì í ṣe pé kí ẹnì kan wá lò ó lódì láti fi tako Ọlọ́hun.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:45.
____________________
Ìyẹn ni pé, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù Allāhu, ìbẹ̀rù Allāhu kò níí jẹ́ kí o ṣe aburú tí mò ń ṣọ́ra fún lọ́dọ̀ rẹ.
____________________
Àwọn kristiẹni ń sọ pé Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni al-Ƙur’ān pè ní “ẹni mímọ́” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah yìí. Èsì ní ṣókí ni pé, ní òdodo ẹni mímọ́ ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe òun nìkan ni ẹni mímọ́. Āayah 13 nínú sūrah yìí kan náà pe Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹni mímọ́. Bákan náà, ọmọ tí àsọọ́lẹ̀ wáyé lórí rẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 17:81, ẹni mímọ́ ni al-Ƙur’ān pe òun náà. Báwo ni jíjẹ́ ẹni mímọ́ Jésù ṣe máa sọ ọ́ di olúwa àti olùgbàlà nígbà tí jíjẹ́ ẹni mímọ́ àwọn méjèèjì wọ̀nyẹn kò sọ wọ́n di bẹ́ẹ̀. Sì kíyè sì i, gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nínú al-Ƙur’ān ni ẹni mímọ́. Àti pé ìdà kejì ẹni mímọ́ ni ẹni àìmọ́. Báwo ni Ọlọ́hun ṣe máa fi iṣẹ́ mímọ́ rán ẹni àìmọ́? Kò lè ṣẹlẹ̀. Ṣíwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, ìsọdorúkọ olùṣe fún “ẹni mímọ́” ni “zakiyyun”, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ fún “mímọ́” ni “zakāt”. Ìgbà tí ìròyìn bá bùáyà tán lára ẹni tí a fẹ́ pọ́n ní àpọ́npo, dípò kí Lárúbáwá lo ìsọdorúkọ olùṣe fún irú ẹni náà, ìsọdorúkọ àfòyemọ̀ ni wọ́n máa lò. Ìyẹn ni pé, jíjẹ́ ẹni mímọ́ t’ó lágbára gan-an ni ìlò èdè tí aL-Ƙur’ān lò fún Ànábì Yahyā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọmọ alásọọ́lẹ̀ náà. Àfijọ èyí nínú ìlò èdè Yorùbá, bí àpẹẹrẹ, ni ìyàtọ̀ t’ó wà láààrin kí á pe ẹni kan ní olówó àti owó. Nígbà tí owó olówó kan bá ń pe àwọn olówó ńláńlá ránṣẹ́, l’a máa pe ẹni náà pé “Owó ni lágbájá.” Ta wá ni ó mọ́ jùlọ láààrin “zakiyyu” t’ó túmọ̀ sí “ẹni mímọ́” àti “zakāt” t’ó túmọ̀ sí “mímọ́”? Kò wa tán bí!
____________________
Ẹrú Allāhu ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ àwọn kristiẹni kò gbàgbọ́ pé ẹrú Allāhu ni. Wọ́n ní, “ọmọ Ọlọ́hun ni.” Kódà àwọn náà sọra wọn di ọmọ Ọlọ́hun. Kí ni ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò sí ọ̀rọ̀ mìíràn fún ìdàkejì ẹrú bí kò ṣe “ọmọ”. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “Bí ẹrú bá pẹ́ títí ẹrú á dọmọ”. Dọmọ ta ni? Ẹrú a dọmọ bàbá rẹ̀ nítorí pé, “ọ̀nà ló jìn, ẹrú ní baba”. Kí wá ni ọ̀rọ̀ mìíràn fún “ọmọ”? Ọmọ ni ẹni tí kò sí lóko-ẹrú. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ mìíràn fún ọmọ àti òbí tí kò sí lóko ẹrú ni “olómìnira”.
Ní ọ̀dọ̀ àwa mùsùlùmí, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” nìyí: “Ẹ̀dá tí ó ń tẹ̀lé ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun, ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn, ó ti sọra rẹ̀ di ẹrú rẹ̀, láì la wíwà ní oko-ẹrú lọ bíi ti ẹrú àfowórà tàbí ẹrú ogun. Èyí fi hàn pé, ẹrú ẹ̀dá yàtọ̀ sí ẹrú Ọlọ́hun.
Àwọn òǹkọ-bíbèlí mọ̀ọ́mọ̀ yọ “ẹrú Ọlọ́hun” kúrò nínú bíbélì òde-òní. Wọ́n sì fi “ọmọ Ọlọ́hun” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe lè sin òkú àbòsí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò níí yọ sílẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi rí ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun” kà nínú ìwé Róòmù 7:25 báyìí pé: “So then, with my mind I am a slave to the law of God, but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀mí mi, ẹrú ni mi sí òfin Ọlọ́hun, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹran ara mi, ẹrú ni mi sí òfin ẹ̀ṣẹ̀. (New Revised Standard Version àti New International Version) Ìyẹn ni pé, tí ìwọ bá tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin Ọlọ́hun. Tí ìwọ bá sì tẹ̀lé òfin ẹ̀ṣẹ̀, ẹrú ni ìwọ lábẹ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Jésù Kristi ti tẹ̀lé òfin Ọlọ́hun, ẹrú Ọlọ́hun ni Jésù Kristi. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé Jésù Kristi kò lo òfin àti ìlànà Ọlọ́hun? Rárá. Tàbí ẹnu àwọn kristiẹni gbà á láti sọ pé òfin ẹ̀ṣẹ̀ ni Jésù Kristi tẹ̀lé? Rárá. Kò kúkú sí ìkẹta, lẹ́yìn òfin Ọlọ́hun, òfin èṣù ló tún kù. Jésù Kristi kò sì lo òfin Èṣù rí nínú ayé rẹ̀.
Àwa mùsùlùmí kú orí ire. Ọpẹ́ sì ni fún Ọlọ́hun t’ó jẹ́ kí á dá bàbá wa mọ̀ lọ́tọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́hun. Bákan náà, ẹ̀rù kò bà wá láti pe ara wa ní ẹrú Ọlọ́hun níbikíbi nítorí pé, pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn, ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn, Olùgba-ìrònúpìwàdà sì ni Allāhu.
____________________
Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ kò bá lo ìgbọ́rọ̀ wọn fún gbígbọ́ òdodo, tí wọn kò sì lo ìríran wọn fún rírí òdodo ní ilé ayé yìí, wọn yóò fi ìgbọ́rọ̀ wọn gbọ́ òdodo ketekete, wọn yó sì fi ìríran wọn rí òdodo kedere pẹ̀lú àbámọ̀ ní ọ̀run nítorí pé, Ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ náà.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Hūd; 11:71.
____________________
Nígbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni t’Ó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ “ọ̀pọ̀” náà ń dúró fún iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń dá ṣe pẹ̀lú gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀” tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa yan àwọn mọlāika Rẹ̀ láti ṣe. Ní ti āyah 68 àti 69, àwọn mọlāika ni Allāhu máa pàṣẹ iṣẹ́ wọ̀nyẹn fún lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwọn mọlāika náà sì ni ẹ̀ṣọ́ Ina. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah at-Tahrim; 66:6 àti sūrah al-Mudaththir; 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd; 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98-100. “Warada” tún túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, àmọ́ kò wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:23. Ìtúmọ̀ méjèèjì wọ̀nyí ti fi hàn kedere pé kò sí ẹ̀dá tí kò níí dé ibi tí Iná wà lọ́jọ́ Àjíǹde. Àmọ́ àwọn kan máa “débẹ̀ wọbẹ̀”, àwọn kan sì máa “débẹ̀ láì wọbẹ̀”. Ìdí tí gbogbo ẹ̀dá máa fi dé ibi tí Iná wà ni pé, ojú ọ̀nà tí a máa tọ̀ dé ibi tí Ọgbà Ìdẹ̀ra wà ni Iná wà. Ìsàlẹ̀ lọ́wọ́ iwájú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni Allāhu fi àyè Iná sí. Kódà, ọ̀nà tí a máa tọ̀ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sì jẹ́ afárá tẹ́ẹ́rẹ́ yíyọ̀ lórí Iná. Igun mẹ́ta sì ni àwọn ènìyàn àti àlùjọ̀nnú máa pín sí lórí ìrìn wọn lórí afárá Iná. Igun kìíní ni àwọn Ànábì, àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) àti àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná láì níí jábọ́ sínú Iná títí wọ́n fi máa gúnlẹ̀ sínú ilé ìgbàlà wọn, Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Kí Allāhu fi àánú Rẹ̀ ta wá lọ́rẹ àrìnyè náà.). Igun yìí ni Allāhu ti ṣe àforíjìn fún pátápátá lórí àṣìṣe wọn. Ṣebí kò sí bí a ó ṣe rìn tí orí kò níí mì lọ̀rọ̀ ẹ̀dá nílé ayé. Allāhu sì ni Aláforíjìn ẹ̀dá. Igun kìíní yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa wọn nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:101-102 àti sūrah az-Zumọr; 39:61. Igun kejì ni àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, t’ó máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́ sínú Iná. Igun yìí ni wọ́n ní àwọn àṣìṣe kan lọ́rùn, àmọ́ tí Allāhu kò forí rẹ̀ jìn wọ́n. Sebí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú ti sọ pé kí ẹni tí ó bá ń dá ẹṣẹ̀, tí kò tọrọ àforíjìn tàbí ronú pìwàdà lórí rẹ̀ títí ó fi kú má ṣe fọkàn balẹ̀ pé Òun kúkú máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fìyà ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:116. Igun kejì yìí l’ó máa padà jáde kúrò nínú Iná lásìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́, yálà nípasẹ̀ ìṣìpẹ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí nípasẹ̀ àánú àti ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta ni igun gbogbo ẹni tí ó kú sórí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹbọ tàbí ìṣojúméjì pẹ̀lú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Igun kẹta yìí náà máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́, àmọ́ wọn kò níí jáde kúrò nínú rẹ̀ títí láéláé nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣíjú àánú wò wọ́n rárá. Nítorí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí Iná kò níí jó nítorí gbólóhùn “wa ’in minkum ’illā wāriduhā”, ẹni náà ti sọ̀rọ̀ àìmọ̀kan t’ó gbópọn lẹnu nítorí pé, ó ti fi ìtúmọ̀ “warada” mọ sórí “ó débẹ̀ wọbẹ̀” nìkan, ó sì kọ̀yìn sí ìtúmọ̀ “warada” t’ó túmọ̀ sí “ó débẹ̀ kò wọbẹ̀”. Irú ẹni náà sì súnmọ́ kí ó jẹ́ kristiẹni, olùṣìnà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó bá sọ pé kò sí igun kan kan tí ó máa padà jáde kúrò nínú Iná. Kò sí ẹni tí ó máa sọ bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí ó máa wà nínú Iná gbére, irú ẹni náà ti sọ ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah t’ó ń fi Iná gbere rinlẹ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ẹni náà súnmọ́ k’ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah.
Lẹ́yìn náà, yálà igun tí ó máa rin àrìnyè lórí afárá Iná tàbí igun tí ó máa rin àrìnjábọ́ sínú Inȧ, igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé, àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé, kò sí ẹ̀dá kan t’ó máa fẹ́ fínnú fíndọ̀ gba orí afárá Iná kọjá. Dándan sì ni fún gbogbo wọn láti gba orí rẹ̀ kọjá bọ́ sí àyè wọn. Àwọn mọlāika wọ̀nyẹn ni àwọn mọlāika agbèrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àwọn mọlāika agbèrò Iná. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún fi rinlẹ̀ nínú sūrah az-Zumọr; 39:71-73.