ترجمة سورة الأعراف

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الأعراف باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

’Alif lām mīm sọ̄d.
Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí iyèméjì wà nínú ọkàn rẹ nípa rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ẹ tẹ̀lé ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn wòlíì (èṣù) lẹ́yìn Rẹ̀. Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́! Ìyà Wa dé bá wọn ní òru tàbí nígbà tí wọ́n ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.
Igbe ẹnu wọn kò jẹ́ kiní kan nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn ju pé wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."
Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́).
Dájúdájú A óò ròyìn (iṣẹ́ ọwọ́ wọn) fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀. Àwa kò ṣàì wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀).
Òdodo ni òṣùwọ̀n Ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣ’ẹ̀mí ara wọn lófò nítorí pé wọ́n ń ṣàbòsí sí àwọn āyah Wa.
Dájúdájú A fun yín ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. A sì ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu fún yín lórí rẹ̀. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá.
Dájúdájú A da yín, lẹ́yìn náà A ya àwòrán yín, lẹ́yìn náà A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam." Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, tí kò sí nínú àwọn olùforíkanlẹ̀.
(Allāhu) sọ pé: "Kí ni ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí i nígbà tí Mo pa á láṣẹ fún ọ." (Èṣù) wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; iná ni O fi dá èmi, O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀."
(Allāhu) sọ pé: "Sọ̀kalẹ̀ kúrò níbí nítorí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ láti ṣègbéraga níbí. Nítorí náà, jáde dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ."
. (Èṣù) wí pé: "Lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé àwọn ènìyàn dìde."
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn tí A óò lọ́ lára."
(Èṣù) wí pé: "Fún wí pé O ti fi mí sínú anù, èmi yóò jókòó dè wọ́n ní ọ̀nà tààrà Rẹ.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi yóò wá bá wọn láti iwájú wọn, láti ẹ̀yìn wọn, láti ọ̀tún wọn àti òsì wọn. Ìwọ kò sì níí rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní olùdúpẹ́ (fún Ọ)."
(Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò níbí (kí o sì di) alábùkù, ẹni-àlédànù. Dájúdájú ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú Èmi yóò fi gbogbo yín kún inú iná Jahanamọ."
Ādam, kí ìwọ àti ìyàwó rẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Nítorí náà, ẹ máa jẹ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí nítorí kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.
Èṣù sì kó ròyíròyí bá àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ohun tí A fi pamọ́ nínú ìhòhò ara wọn hàn wọ́n. Ó sì wí pé: "Olúwa ẹ̀yin méjèèjì kò kọ igi yìí fun yín bí kò ṣe pé kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di mọlāika tàbí kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di olùṣegbére."
Ó sì búra fún àwọn méjèèjì pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn fún ẹ̀yin méjèèjì."
Ó sì tan àwọn méjèèjì jẹ. Nígbà tí àwọn méjèèjì tọ́ igi náà wò, ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bora wọn. Olúwa àwọn méjèèjì sì pè wọ́n pé: "Ǹjẹ́ Èmi kò ti kọ igi náà fun ẹ̀yin méjèèjì? (Ṣé) Èmi kò sì ti sọ fún ẹ̀yin méjèèjì pé ọ̀tá pọ́nńbélé ni Èṣù jẹ́ fun yín?"
Àwọn méjèèjì sọ pé: "Olúwa wa, a ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí wa. Tí O ò bá foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa, dájúdájú a máa wà nínú àwọn ẹni òfò."
____________________
Láti āyah 19 sí 24 nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó ṣẹlẹ̀ sí bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) nípa bí àwọn méjèèjì ṣe jẹ èso igi tí Allāhu kọ̀ fún wọn láti jẹ. Ó tún wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:35-39 àti sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn okùnfà ìṣìnà fún gbogbo àwọn kristiẹni pátápátá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ìgbàgbọ́ wọn fi forí sánpọ́n láti ìpìlẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú ṣàdédé pe àwọn kristiẹni ní olùṣìnà nínú sūrah al-Fātihah, Allāhu kò sì ṣàdédé kọ̀ fún àwa mùsùlùmí láti mú wọn ní ọ̀rẹ́, yálà ọ̀rẹ́ àyò tàbí ọ̀rẹ́ lásán, tí kì í bá ṣe pé ìgbàgbọ́ wọn dúró sórí àwọn ìṣìnà gban̄kọgban̄kọ méje kan.
Ìkíní; àwọn kristiẹni di olùṣìnà bẹ̀rẹ̀ láti ara sísọ pé gbogbo àwọn ọmọ Ànábì Ādam jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam jẹ láti ọjọ́ ìbí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Ìkejì; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé wọ́n kan Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mọ́ igi àgbélébùú. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé “wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ àgbélébùú…” Ìkẹta; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé ìgbàlà wà nínú ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú àti pé ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam tí wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ ègún èso tí òun àti ìyàwó rẹ̀ jẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n tún ṣe gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú ti pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rẹ́ fún gbogbo àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí igi àgbélébùú. Allāhu sì sọ pé ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmìíràn mọ́ tirẹ̀. Ìkẹrin; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún nítorí pé, wọ́n gbà pé ìkíní kejì wọn nìkan ni kò ní ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àti pé wọ́n tún gbàgbọ́ pé, ìkíní kejì wọn ni kò dá ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rí. Allāhu sì sọ pé kò sí ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Òun. Ìkarùn-ún; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ọmọ Ọlọ́hun. Allāhu sì sọ pé Òun kò bímọ, Òun kò sì fi ẹnì kan kan ṣọmọ. Ìkẹfà: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣàì gbàgbọ́ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí wọ́n sì ń fi ẹnu àbùkù t’ó lágbára kàn òun pẹ̀lú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ mìíràn tí Allāhu rán níṣẹ́ sáyé. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé àwọn t’ó ń ṣẹ̀yàmẹ̀yà láààrin àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ ni ojúlówó aláìgbàgbọ́. Ìkeje: àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tọwọ́bọ tírà tí Allāhu fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti tírà tí Allāhu fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lójú, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí oríṣiríṣi tírà méjèèjì náà fi pọ̀ lórí igbá, tí wọn kò sì yé yí wọn padà sí ìfẹ́-inú wọn lórúkọ “àtúnṣe” látìgbàdégbà. Allāhu sì sọ pé ègbé ni fún àwọn t’ó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun.
Wàyí nípa ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam àti Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ, kókó mẹ́fà wọ̀nyí ni òdodo nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kókó kìíní: bàbá ńlá wa Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá ńlá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ èso igi náà. Jíjẹ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn àwọn méjèèjì nìkan, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àwọn ọmọ wọn kan kan. Kókó kejì: àwọn méjèèjì tọrọ àforíjìn lórí àṣìṣe náà, Allāhu sì foríjìn àwọn méjèèjì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:37 àti sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:19-23. Kókó kẹta: Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó ṣọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:120-123. Kókó kẹrin: ìsọ̀kalẹ̀ àwọn méjèèjì sórí ilẹ̀ ayé yìí wá sí ìmúṣẹ nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Allāhu pé Òun fẹ́ dá àrólé kan sórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:30. Kókó karùn-ún: kò sí ẹnì kan kan t’ó jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ náà láti ara àwọn méjèèjì nítorí pé, Allāhu ti forí jìn àwọn méjèèjì pátápátá. Kókó kẹfà: àdámọ́ tí Allāhu dámọ́ ìṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ṣoṣo ni àwọn ọmọ rẹ̀ jogún pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nítorí pé, Allāhu ti fi àdámọ́ ìtẹ̀lé-àṣẹ àti ìyapa àṣẹ sínú ìṣẹ̀dá wa láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdámọ́ méjèèjì náà sì ti wà lára Ànábì Ādam láti ọjọ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti ṣíwájú ọjọ́ èso t’ó jẹ́. Nítorí náà, tí a bá tẹ̀lé àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá yapa àṣẹ Allāhu, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn ìyapa àṣẹ Rẹ̀, tí a sì tọrọ àforínjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti lè tẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tí a bá sì lo ìkápá tí Allāhu fún wa láti tẹ̀lé ìfẹ́-inú wa, a fi jọ Ànábì Ādam ni ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ tí a bá kùnà láti ronú pìwàdà lórí ìyapa àṣẹ Allāhu, tí a ò sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, kì í ṣe Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’a fi jọ. Nítorí náà, ìyàtọ̀ wà láààrin sísọ pé a jogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti sísọ pé a jogún àwọn àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ní ti jíjẹ ogún ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ru ẹlòmíìràn rinlẹ̀. Àbòsì ńlá sì nìyẹn. Allāhu kì í sì ṣe Ọba alábòsí. Ní ti jíjẹ ogún àdámọ́ ìyapa àṣẹ àti ìtọrọ-àforíjìn láti ara Ànábì Ādam, ìyẹn ń fi dídi ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ru ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn. Déédé àti dọ́gba sì nìyẹn. Allāhu sì ni Ọba Onídéédé.
Síwájú sí i, lára ohun t’ó ń ṣàfi hàn ìṣìnà àwọn kristiẹni lórí èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, tí wọ́n sì sọ gbogbo ọmọ rẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ èso nípasẹ̀ rẹ̀, òhun ni pé, àwọn ìjọ tí Allāhu parẹ́ ṣíwájú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ṣé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ādam àti ìyàwó rẹ̀ jẹ ni tàbí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn dá lẹ́ṣẹ̀? Allāhu kò pa ìjọ kan run rí bí kò ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọwọ́ wọn. Bákan náà, àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò ì bàlágà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan lọ́rùn wọn títí wọ́n fi máa bàlágà. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá nígbà náà nìkan lẹ́ṣẹ̀ tí ó máa wà lọ́rùn wọn. Nítorí náà, kò sí ègún kan kan lórí àwọn ọmọ Ànábì Ādam nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ. Bákan náà, kò sí ẹni tí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tara tirẹ̀ rí nínú gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, kódà t’ó fi mọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, ọmọ ènìyàn ni, kì í ṣe ọmọ Ọlọ́hun. Àrọ́mọdọ́mọ Ànábì Ādam ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), kò ṣàì jogún àwọn àdámọ́ lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé al-Ƙur’ān kò sí fún kíka ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ lọ́rùn - ṣebí ẹni ẹ̀ṣà jùlọ ni gbogbo wọn, - ọ̀wọ́ ohun tí Allāhu bá sọ fún wa nípa wọn nìkan l’ó kúkú kàn wá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ wọn. Tí a ò bá rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan nípa ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú al-Ƙur’ān, kò túmọ̀ sí pé òun náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kan kan rí. Ṣebí a ò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nínú al-Ƙur’ān nípa àwọn Ànábì mìíràn, gẹ́gẹ́ bí Ànábì Lūt, Ànábì Sọ̄lih, Ànábì Ṣu‘aeb, Ànábì Ya‘ƙūb, Ànábì ’Ishāƙ, Ànábì ’Ismọ‘īl, Ànábì Yahyā, Ànábì Yūṣa‘u àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ (aleehim salām). Bákan náà, èyí kò túmọ̀ sí pé wọn kò jogún àwọn àdámọ́ òkè wọ̀nyẹn lára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), bẹ́ẹ̀ sì ni pé, àìrí ẹ̀ṣẹ̀ kan kan kà nípa wọn kò sọ wọ́n di olúwa àti olùgbàlà. Kíyè sí i, ẹ̀dá Ọlọ́hun kúkú ni àwọn mọlā’ika, àmọ́ kò sí àdámọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá nínú ìṣẹ̀dá tiwọn. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ìyẹn kò sọ ẹnikẹ́ni nínú wọn di olúwa àti olùgbàlà, yálà mọlāika Jibrīl, ẹni tí àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹ̀mí Mímọ́” tàbí mọlāika mìíràn. Nítorí náà, olùtàbùkù Ànábì Ādam ni ẹni tí ó bá ń sọ pé àwa ọmọ rẹ̀ jogún ègún èso t’ó jẹ lára rẹ̀. Irú ẹni náà kì í ṣọmọ rere. W-Allāhu ’a‘lam.
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín ní orí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).”
(Allāhu) sọ pé: “Lórí ilẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣẹ̀mí, lórí rẹ̀ ni ẹ̀yin yóò máa kú sí, A ó sì mu yín jáde láti inú rẹ̀.”
Ọmọ (Ànábì) Ādam, dájúdájú A ti sọ aṣọ kalẹ̀ fun yín, tí ó máa bo ìhòhò yín àti ohun àmúṣọrọ̀. Aṣọ ìbẹ̀rù Allāhu, ìyẹn l’ó sì lóore jùlọ. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìfòòró ba yín gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yọ àwọn òbí yín méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó gba aṣọ kúrò lára àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ìhòhò wọn hàn wọ́n. Dájúdájú ó ń ri yín; òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (ń ri yín) ní àyè tí ẹ̀yin kò ti rí wọn. Dájúdájú Àwa fi Èṣù ṣe ọ̀rẹ́ fún àwọn tí kò gbàgbọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sì ṣe ìbàjẹ́ kan, wọ́n á wí pé: "A bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ni. Allāhu l’Ó sì pa á láṣẹ fún wa." Sọ pé: "Dájúdájú Allāhu kì í p’àṣẹ ìbàjẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?"
Sọ pé: “Olúwa mi p’àṣẹ ṣíṣe déédé. Kí ẹ sì dojú yín kọ (Allāhu) ní gbogbo mọ́sálásí. Ẹ pè É (kí ẹ jẹ́) olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe da yín (tí ẹ fi di alààyè), ẹ máa padà (di alààyè lẹ́yìn ikú yín).”
Apá kan ni Ó fi mọ̀nà, apa kan sì ni ìṣìnà kò lé lórí. (Nítorí pé) dájúdájú wọ́n mú àwọn èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ wọ (aṣọ) ọ̀ṣọ́ yín nígbàkígbà tí ẹ bá ń lọ sí mọ́sálásí. Ẹ jẹ, ẹ mu, kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.
Sọ pé: “Ta l’ó ṣe ọ̀ṣọ́ Allāhu, tí Ó mú jáde fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan dáadáa nínú arísìkí ní èèwọ̀?” Sọ pé: “Ó wà fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú ìṣẹ̀mí ayé. Tiwọn nìkan sì ni l’Ọ́jọ́ Àjíǹde." Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀.”
Sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi ṣe ní èèwọ̀ ni àwọn ìwà ìbàjẹ́ – èyí t’ó fojú hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ –, ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀tẹ̀ ṣíṣe láì lẹ́tọ̀ọ́, bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ – èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún – àti ṣíṣe àfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu."
Àkókò kan ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan; nígbà tí àkókò wọn bá sì dé, wọn kó lè sún un síwájú di àkókò kan, wọn kò sì lè fà á sẹ́yìn.
Ọmọ (Ànábì) Ādam, nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ nínú yín bá wá ba yín, tí wọn yóò máa ka àwọn āyah Mi fun yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Mi), tí ó sì ṣàtúnṣe, kò níí sí ìbẹ̀rù kan fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn t’ó bá sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: "Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?" Wọn yóò wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́." Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.”
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ wọlé ti àwọn ìjọ t’ó ti ré kọjá lọ ṣíwájú yín nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn (tí wọ́n ti wà) nínú Iná." Ìgbàkígbà tí ìjọ kan bá wọ (inú Iná), wọn yóò máa ṣẹ́bi fún àwọn ìjọ rẹ̀ (t’ó ti wà níbẹ̀ ṣíwájú wọn), títí di ìgbà tí gbogbo wọn yóò fi pàdé ara wọn nínú Iná. (Ìgbà yìí ni) àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn yóò wí fún àwọn ẹni ìṣáájú wọn pé: "Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ṣì wá lọ́nà. Nítorí náà, fún wọn ni ìlọ́po ìyà méjì nínú Iná." (Allāhu) sọ pé: "Ìkọ̀ọ̀kan (yín) l’ó ní ìlọ́po ìyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀."
Àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn yó sí wí fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn pé: "Kò sí àjùlọ kan fun yín lórí wa. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Dájúdájú àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, Wọn kò níí ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ fún wọn. Wọn kò sì níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra títí ràkúnmí yóò wọ inú ihò abẹ́rẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
Ìtẹ́ wà fún wọn nínú iná Jahanamọ. Òrùlé sì wà fún wọn ní òkè wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.
Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ lódodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere - A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀ - àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
A ó sì mú inúnibíni kúrò nínú ọkàn wọn. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fi wá mọ̀nà yìí. Àwa ìbá tí mọ̀nà, tí kì í bá ṣe pé Allāhu tọ́ wa sí ọ̀nà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá.” Wọ́n sì máa pè wọ́n pé: “Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò pe àwọn èrò inú Iná pé: "A ti rí ohun tí Olúwa wa ṣe àdéhùn rẹ̀ fún wa ní òdodo. Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà rí ohun tí Olúwa yín ṣe àdéhùn (rẹ̀ fun yín) ní òdodo?" Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Olùpèpè kan yó sì pèpè láààrin wọn pé: "Kí ibi dandan Allāhu máa bẹ lórí àwọn alábòsí."
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì tún ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Gàgá yóò wà láààrin èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná. Àwọn ènìyàn kan máa wà lórí ògiri (gàgá náà), wọn yó sì dá ẹnì kọ̀ọ̀kan (ìjọ méjèèjì) mọ̀ pẹ̀lú àmì wọn. Wọn yóò pe àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Kí àlàáfíà máa bẹ fun yín.” Wọn kò ì wọ (inú) rẹ̀, wọ́n sì ti ń jẹ̀rankàn (rẹ̀).
Nígbà tí wọ́n bá yíjú wọn sí ọ̀gangan àwọn èrò inú Iná, wọn yóò sọ pé: “Olúwa wa, má fi wá sọ́dọ̀ àwọn ìjọ alábòsí.”
Àwọn èrò orí ògiri (gàgá náà), yóò pe àwọn ènìyàn kan tí wọ́n mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn, wọn yó sì sọ pé: “Ohun tí ẹ kójọ nílé ayé àti ṣíṣe ìgbéraga yín sí ìgbàgbọ́ òdodo kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ mọ́ (báyìí)”
(Allāhu) yóò sọ fún èrò inú Iná pé: “Ṣé àwọn (èrò orí ògiri) wọ̀nyí ni ẹ̀yin ń búra pé Allāhu kò níí ṣíjú àánú wò? (Nítorí náà, ẹ̀yin èrò orí ògiri) ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò níí sí ìbẹ̀rù kan fun yín. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.”
Èrò inú Iná yóò pe èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Ẹ fún wa nínú omi tàbí nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín.” Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe méjèèjì ní èèwọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
Àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di ìranù àti eré ṣíṣe, ìṣẹ̀mí ayé sì kó ẹ̀tàn bá wọn, ní òní ni A óò gbàgbé wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ wọn ti òní yìí àti (bí) wọ́n ṣe ń tako àwọn āyah Wa.
A kúkú ti mú tírà kan wá bá wọn, tí A ṣàlàyé rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá dé, àwọn t’ó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́.
Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
____________________
Ìyẹn ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé tí kò dáwọ́ dúró láààrin òru àti ọ̀sán lójoojúmọ́ tí ìkíni fi wà nípò ohun t’ó ń wá ìkejì rẹ̀.
Ẹ pe Olúwa yín pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ohùn jẹ́ẹ́jẹ́. Dájúdájú (Allāhu) kò fẹ́ràn àwọn alákọyọ.
Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ẹ pe Allāhu pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìrètí. Dájúdájú àánú Allāhu súnmọ́ àwọn olùṣe-rere.
Òun ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn (t’ó jẹ́) ìró ìdùnnú ṣíwájú àánú Rẹ̀, títí (atẹ́gùn náà) yóò fi gbé ẹ̀ṣújò t’ó wúwo, tí A sì máa wọ́ ọ lọ sí òkú ilẹ̀. Nígbà náà, A máa fi sọ omi kalẹ̀. A sì máa mú oríṣiríṣi èso jáde. Báyẹn ni A ó ṣe mú àwọn òkú jáde nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
(Ilẹ̀) ìlú t’ó dára, àwọn irúgbìn rẹ̀ yóò jáde pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Èyí tí kò sì dára, (irúgbìn rẹ̀) kò níí jáde àfi (díẹ̀) pẹ̀lú ìnira. Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà fún ìjọ t’ó ń dúpẹ́.
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú mò ń bẹ̀rù ìyà Ọjọ́ Ńlá fun yín."
Àwọn àgbààgbà nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: "Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí ìṣìnà kan lọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
. Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mò ń fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Àti pé ohun tí ẹ ò mọ̀ ni èmi mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu.
Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín; nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí A lè kẹ yín?"
Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ t’ó fọ́jú (sí òdodo).
A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ará ‘Ād, arákùnrin wọn, Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"
Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú agọ̀. Àti pé dájúdájú à ń rò pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.”
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí agọ̀ kan lára mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Èmi sì ni onímọ̀ràn rere, olùfọkàntán fun yín.
Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín, nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín? Ẹ rántí nígbà tí (Allāhu) fi yín ṣe àrólé lẹ́yìn ìjọ (Ànábì) Nūh. Ó tún ṣe àlékún agbára fun yín nínú ìṣẹ̀dá (yín). Nítorí náà, ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, nítorí kí ẹ lè jèrè."
Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
Ó sọ pé: “Ìyà àti ìbínú kúkú ti sọ̀kalẹ̀ sórí yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un? – Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”
Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ìran Thamūd, arákùnrin wọn, Sọ̄lih. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín.
Ẹ tún rántí nígbà tí (Allāhu) ṣe yín ní àrólé lẹ́yìn àwọn ara ‘Ād. Ó sì fun yín ní ilé ìgbé lórí ilẹ̀; ẹ̀ ń kọ́ ilé ńláńlá sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àpáta. Ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, kí ẹ sì má ṣe rìn lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.
Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín, (ìyẹn) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú wọn, pé: "Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé dájúdájú Sọ̄lih ni Òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán an níṣẹ́.”
Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ẹ̀yin gbàgbọ́.”
Nítorí náà, wọ́n gún abo ràkúnmí náà pa. Wọ́n sì tàpá sí àṣẹ Olúwa wọn. Wọ́n sì wí pé: “Sọ̄lih, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.”
Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
Nígbà náà, (Sọ̄lih) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ràn àwọn onímọ̀ràn rere.”
(Rántí Ànábì) Lūt, nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ óò máa ṣe ìbàjẹ́ ni tí kò sí ẹnì kan nínú àwọn ẹ̀dá t’ó ṣe irú rẹ̀ rí?
Dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) ń lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) dípò àwọn obìnrin! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni yín."
Kí sì ni ó jẹ́ èsì ìjọ rẹ̀ bí kò ṣe pé, wọ́n wí pé: “Ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ìlú yín, dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn kan t’ó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”
Nígbà náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.
A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Wo bí ìkángun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí!
(A tún rán ẹnì kan) sí àwọn ará Mọdyan, arákùnrin wọn, Ṣu‘aeb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Ẹ má ṣe lúgọ sí gbogbo ọ̀nà láti máa dẹ́rùba àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbagbọ́ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ k’ó wọ́. Ẹ rántí o, nígbà tí ẹ kéré (lóǹkà), Allāhu sọ yín di púpọ̀. Ẹ sì wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí.
Tí ó bá jẹ́ pé igun kan nínú yín gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́, tí igun kan kò sì gbàgbọ́, nígbà náà ẹ ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ láààrin wa. Òun sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.
Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú a máa lé ìwọ Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ jáde kúrò nínú ìlú wa tàbí ẹ gbọ́dọ̀ padà sínú ẹ̀sìn wa.” (Ṣu‘aeb) sọ pé: "Ṣé (ẹ máa dá wa padà sínú ìbọ̀rìṣà) t’ó sì jẹ́ pé ẹ̀mí wa kọ̀ ọ́?"
Dájúdájú a ti dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tí a bá fi lè padà sínú ẹ̀sìn yín lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti yọ wá kúrò nínú rẹ̀. Àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti padà sínú rẹ̀ àfi tí Allāhu, Olúwa wa bá fẹ́. Olúwa wa gbòòrò tayọ gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú ìmọ̀. Allāhu l’a gbáralé. Olúwa wa, ṣe ìdájọ́ láààrin àwa àti ìjọ wa pẹ̀lú òdodo, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́."
Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé Ṣu‘aeb, nígbà náà ẹ̀yin ti di ẹni òfò nìyẹn.”
Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
____________________
Oríṣi ìyà méjì wọ̀nyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi jẹ ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām); ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì (sūrah Hūd; 11:94) àti ẹ̀ṣújò iná (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:189).
Àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ sì dà bí ẹni tí kò gbé nínú ìlú wọn rí; àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
Nítorí náà, (Ṣu‘aeb) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Báwo ni èmi yóò ṣe tún máa banújẹ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”
A ò rán Ànábì kan sí ìlú kan láì jẹ́ pé A fi ìpọ́njú àti ìnira kan àwọn ará ìlú náà nítorí kí wọ́n lè rawọ́-rasẹ̀ (sí Allāhu).
Lẹ́yìn náà, A fi (ohun) rere rọ́pò aburú (fún wọn) títí wọ́n fi pọ̀ (lóǹkà àti lọ́rọ̀). Wọ́n sì wí pé: “Ọwọ́ ìnira àti ìdẹ̀ra kúkú ti kan àwọn bàbá wa rí.” Nítorí náà, A gbá wọn mú lójijì, wọn kò sì fura.
____________________
Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ, wọn kò gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ l’ó kó ìparun bá àwọn bàbá wọn. Èrò-ọkàn wọn ni pé, bí ọ̀rọ̀ ilé ayé ṣe rí ni pé, ènìyàn máa jìyà, ó sì máa jọrọ̀. Èrò-ọkàn wọn yìí mú wọn won̄koko mọ́ ìbọ̀rìṣà. Àwọn náà sì di ẹni ìparun bíi tàwọn bàbá wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ará ìlú náà gbàgbọ́ lódodo ni, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), A ìbá ṣínà àwọn ìbùkún fún wọn láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n pe òdodo nírọ́. Nígbà náà, A mú wọn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní alẹ́ ni, nígbà tí wọ́n bá ń sùn lọ́wọ́?
Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní ìyálẹ̀ta ni, nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré lọ́wọ́?
Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu ni? Kò mà sí ẹni t’ó máa fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu àfi ìjọ olófò.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Ṣé kò hàn sí àwọn t’ó jogún ilẹ̀ lẹ́yìn àwọn onílẹ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ ni), Àwa ìbá fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn mú wọn, Àwa ìbá sì fi èdídí bo ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́rọ̀ (mọ́).
Àwọn ìlú wọ̀nyí ni À ń fún ọ ní ìró nínú ìròyìn wọn. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yánjú wá bá wọn. (Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ náà,) wọn kò kúkú níí gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ t’ó ṣíwájú wọn) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́.
____________________
Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ṣíwájú ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó tẹ̀lé wọn ṣe. Irú kan-ùn ni gbogbo wọn. Ìdí sì nìyí tí ìkọ̀ọ̀kan ìjọ aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn ṣe parun. Ẹ tún wo sūrah Yūnus; 10:74.
Àwa kò rí pípé àdéhùn ní ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Àti pé ńṣe ni A rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní òbìlẹ̀jẹ́.
Lẹ́yìn náà, A gbé (Ànábì) Mūsā dìde lẹ́yìn wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àbòsí sí àwọn àmì náà. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí.
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Fir‘aon, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Dandan ni fún mi pé èmi kò níí ṣàfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo. Mo sì kúkú ti mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá mi lọ."
(Fir‘aon) wí pé: “Tí o bá jẹ́ ẹni t’ó mú àmì kan wá, mú un jáde tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
Nígbà náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.
Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ, ó sì di funfun (gbòlà) fún àwọn olùwòran.
Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.
Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni." (Fir‘aon wí pé: ) “Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:34.
Wọ́n sì wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú,
(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."
Àwọn òpìdán sì dé wá bá Fir‘aon. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú ẹ̀san gbọ́dọ̀ wà fún wa tí àwa bá jẹ́ olùborí.”
Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
(Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, o máa (kọ́kọ́) ju ọ̀pá sílẹ̀ ni, tàbí àwa ni a máa (kọ́kọ́) jù ú sílẹ̀.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, wọ́n fi pidán lójú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì ṣẹ̀rùbà wọ́n. Wọ́n wá pẹ̀lú idán ńlá.
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
Nítorí náà, òdodo dé. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì bàjẹ́.
Nítorí náà, A borí wọn níbẹ̀ yẹn. Wọ́n sì darí wálé ní ẹni yẹpẹrẹ.
Iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wólẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,
Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn."
Fir‘aon wí pé: “Ẹ ti gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú èyí ni ète kan tí ẹ ti hun nínú ìlú nítorí kí ẹ lè kó àwọn ará ìlú jáde kúrò nínú rẹ̀. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa sì ni a máa fàbọ̀ sí.
Àti pé o ò tako kiní kan lára wa láti fìyà jẹ wá bí kò ṣe nítorí pé a gba àwọn àmì Olúwa wa gbọ́ nígbà tí ó dé bá wa. Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu. Kí O sì pa wá sípò mùsùlùmí."
Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Ṣé ìwọ yóò fi Mūsā àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti nítorí kí ó lè pa ìwọ àti àwọn òrìṣà rẹ tì?" (Fir‘aon) wí pé: "A óò máa pa àwọn ọmọkùnrin wọn ni. A ó sì máa dá àwọn ọmọbìnrin wọn sí. Dájúdájú àwa ni alágbára lórí wọn."
(Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ fi Allāhu wá ìrànlọ́wọ́, kí ẹ sì ṣe sùúrù. Dájúdájú ti Allāhu ni ilẹ̀. Ó sì ń jogún rẹ̀ fún ẹni t’Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ìgbẹ̀yìn (rere) sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)."
Wọ́n sọ pé: “Wọ́n ni wá láraṣíwájú kí o tó wá bá wa àti lẹ́yìn tí o dé bá wa.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò pa àwọn ọ̀tá yín run. Ó sì máa fi yín rọ́pò (wọn) lórí ilẹ̀. Nígbà náà, (Allāhu) yó sì wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.”
Dájúdájú A gbá ènìyàn Fir‘aon mú pẹ̀lú ọ̀dá òjò àti àdínkù t’ó bá àwọn èso nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Nígbà tí ohun rere bá dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Tiwa ni èyí.” Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á ṣàfitì aburú náà sọ́dọ̀ (Ànábì) Mūsā àti ẹni t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Kíyè sí i, àmì aburú wọn kúkú wà (nínú kádàrá wọn) lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.
Wọ́n sì wí pé: “Ohunkóhun tí o bá mú wá fún wa ní àmì láti fi pidán fún wa, àwa kò níí gbà ọ́ gbọ́.”
Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn, t’ó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.”
Nígbà tí A gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.
Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.
A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fojú tínrín. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ, t’ó dára sì kò lé àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run.
A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄‘īl la agbami odò já. Nígbà náà, wọ́n kọjá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró ti àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì wí pé: “Mūsā, ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan.” (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni ìjọ aláìmọ̀kan.
____________________
Nínú ẹ̀rí t’ó ń fi rinlẹ̀ pé iṣẹ́-ìyanu kì í sábà mú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn di onígbàgbọ́ òdodo ni āyah yìí wa. Ǹjẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì ìyanu tí àwọn ọmọ ’Isrọ’īl ti f’ojú ara wọn rí bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí wọ́n ti ń bọ̀ títí dé ibi tí wọ́n dé yìí, ṣé ó tún yẹ kí wọ́n máa bèèrè fún òrìṣà kan kan? Ṣé òrìṣà l’ó ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ bọ̀ ni tàbí Allāhu Alágbára? Nítorí náà, àwọn aláìmoore àti aláìníkan-ánṣe l’ó máa ń wá iṣẹ́ ìyanu kiri. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ti tó fún ẹni t’ó níkan-ánṣe. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10 :96-97.
Dájúdájú àwọn wọ̀nyí máa parun lórí ohun tí wọ́n ń ṣe (yìí). Irọ́ sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé kí èmi tún ba yín wá ọlọ́hun kan tí ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni? Òun l’Ó sì ṣe àjùlọ oore fun yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).
(Ẹ rántí) nígbà tí A là yín lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, wọ́n ń pa àwọn ọmọkùnrin yín tààrà, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín."
Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀ (yóò fi bá a sọ̀rọ̀ sì máa) parí ní òru ogójì. (Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀, Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un, Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó tají, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi.)
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.
(Allāhu) sọ pé: "Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi. Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́."
A sì kọ gbogbo n̄ǹkan fún un sínú àwọn wàláà. (Ó jẹ́) wáàsí àti àlàyé ọ̀rọ̀ fún gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣàmúlò rẹ̀ dáradára. Kí o sì pa ìjọ rẹ láṣẹ pé kí wọ́n ṣàmúlò n̄ǹkan dáadáa t’ó ń bẹ nínú rẹ̀. Èmi yóò fi ilé àwọn arúfin hàn yín.
____________________
Ilé àwọn arúfin nínú āyah yìí lè jẹ́ ìlú àwọn ìjọ tí wọ́n ti parẹ́ ṣíwájú, èyí tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl yóò padà gbà kọjá lórí ìrìn-àjò wọn, ìyẹn bí ìlú àwọn ìjọ Ànábì Nūh, ìran ‘Ād àti ìran Thamūd. Kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lè mọ ìkángun àwọn arúfin. Bákàn náà, ilé àwọn arúfin nínú āyah yìí lè jẹ́ àbọ̀ àwọn arúfin ní ọ̀run. Èyí sì ni Iná.
Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn t’ó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn àmì Mi. Tí wọ́n bá sì rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé wọ́n pe àwọn àmì Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.
Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan ni bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́?
Àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā, lẹ́yìn rẹ̀ (nígbà tí ó fi lọ bá Allāhu sọ̀rọ̀), wọ́n mú nínú ọ̀ṣọ́ wọn (láti fi ṣe) ère ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi, ó sì ń dún (bíi màálù). Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú kò lè bá wọn sọ̀rọ̀ ni, kò sì lè fi ọ̀nà mọ̀ wọ́n? Wọ́n sì sọ ọ́ di àkúnlẹ̀bọ. Wọ́n sì jẹ́ alábòsí.
Nígbà tí ó di àbámọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ tán, wọ́n sì rí i pé àwọn ti ṣìnà, wọ́n wí pé: “Tí Olúwa wa kò bá ṣàánú wa, kí Ó sì foríjìn wá, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn ẹni òfò.”
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sì padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ fi rólé dè mí lẹ́yìn mi burú. Ṣé ẹ ti kánjú pa àṣẹ Olúwa yín tì ni?" Ó sì ju àwọn wàláà sílẹ̀, ó gbá orí arákùnrin rẹ̀ mú, ó sì ń wọ́ ọ mọ́ra. (Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi ò, dájúdájú àwọn ènìyàn ni wọ́n fojú tínrín mi, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ pa mí. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ̀ mí. Má sì ṣe mú mi mọ́ ìjọ alábòsí.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, foríjin èmi àti arákùnrin mi. Kí O sì fi wá sínú ìkẹ́ Rẹ. Ìwọ sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
Dájúdájú àwọn t’ó sọ (ère) ọmọ màálù di àkúnlẹ̀bọ, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àti ìyẹpẹrẹ yóò bá wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn aládapa irọ́ ní ẹ̀san.
Àwọn t’ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ aburú, lẹ́yìn náà tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú lẹ́yìn èyí Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Nígbà tí ìbínú (Ànábì) Mūsā sì wálẹ̀, ó mú àwọn wàláà náà. Ìmọ̀nà àti àánú ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù Olúwa wọn.
(Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn.
Kí O sì kọ àkọsílẹ̀ rere fún wa ní ayé yìí àti ní ọ̀run. Dájúdájú àwa ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìyà Mi, Mo ń fi jẹ ẹni tí Mo bá fẹ́. Àti pé ìkẹ́ Mi gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ. Èmi yó sì kọ (ìkẹ́ Mi) mọ́ àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Mi), tí wọ́n sì ń yọ Zakāh àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn āyah Wa.”
Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn; àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.
____________________
"Àjàgà ọrùn wọn ni èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbékọ́ ọrùn ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n wí pé “Dídì ni ọwọ́ Allāhu wà” gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’dah; 5:64." (Tọbariy)
Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni t’Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà."
Ó wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà. Wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
____________________
Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83-85.
A sì pín wọn sí ìran méjìlá ní ìjọ-ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé: “Fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣíji bò wọ́n. A sọ (ohun mímu) mọ́nnù àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì sọ pé: ‘Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.’ Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba. A máa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.”
Àwọn t’ó ṣàbòsí kúkú yí ọ̀rọ̀ náà padà sí òmíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. A sì sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ń ṣe àbòsí.
Bi wọ́n léèrè nípa ìlú t’ó wà ní ẹ̀bádò, nígbà tí wọ́n kọjá ẹnu-àlà nípa ọjọ́ Sabt, nígbà tí ẹja wọn ń wá bá wọn ní ọjọ́ Sabt wọn, wọ́n sì máa léfòó sí ojú odò, ọjọ́ tí kì í bá sì ṣe ọjọ́ Sabt wọn, wọn kò níí wá bá wọn. Báyẹn ni A ṣe ń dán wọn wò nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Ọjọ́ Sabt ni ọjọ́ ìsinmi fún ìjọ náà.
(Rántí) nígbà tí ìjọ kan nínú wọn wí pé: “Nítorí kí ni ẹ fí ń ṣe wáàsí fún ìjọ kan tí Allāhu máa parẹ́ tàbí tí Ó máa jẹ níyà líle?” Wọ́n sọ pé: “(Kí ó lè jẹ́) àwáwí lọ́dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu) ni.”
Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn t’ó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà t’ó le jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
Nígbà tí wọ́n tayọ ẹnu-àlà níbi ohun tí A kọ̀ fún wọn, A sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni ìgbéjìnnà sí ìkẹ́.”
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ ọ́ di mímọ̀ pé dájúdájú Òun yóò gbé ẹni tí ó máa fi ìyà burúkú jẹ wọ́n dìde sí wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
A pín wọn lórí ilẹ̀ sí ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn; wọ́n jogún Tírà (Taorāt àti ’Injīl), wọ́n sì ń gba (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore ilé ayé yìí (láti kọ ìkọkúkọ sínú rẹ̀), wọ́n sì ń wí pé: “Wọn yóò foríjìn wá.” Tí (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore irú rẹ̀ bá tún wá bá wọn, wọ́n máa gbà á. Ṣé A kò ti bá wọn ṣe àdéhùn nínú Tírà pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo? Wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀! Ilé ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Àwọn t’ó ń mú Tírà lò dáradára, tí wọ́n ń kírun, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san àwọn t’ó ń ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ wọn) ráre.
____________________
Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83-85
(Rántí) nígbà tí A gbé àpáta ga sókè orí wọn, ó sì dà bí ibòji. Wọ́n sì lérò pé ó máa wó lu àwọn mọ́lẹ̀, (A sì sọ fún wọn pé): “Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáadáa, kí ẹ sì máa rántí ohun t’ó ń bẹ nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).”
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam, Ó fa àrọ́mọdọ́mọ wọn jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Rárá – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí."
Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn t’ó ń tẹ̀lé irọ́ ṣe ni?”
Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Wa, nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Ka ìròyìn ẹni tí A fún ní àwọn āyah Wa fún wọn, tí ó yọra rẹ̀ sílẹ̀ níbi àwọn āyah náà. Nítorí náà, Èṣù tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó sì wà nínú àwọn olùṣìnà.
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
Ìjọ tí ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, wọ́n burú ní àfiwé. Ara wọn sì ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì ṣì lọ́nà, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra.
Ti Allāhu ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn t’ó ń yẹ̀ kúrò níbi àwọn orúkọ Rẹ̀ tì. A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Ẹní tí ó ń yẹ̀ kúrò nínú àwọn orúkọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ẹni tí ó ń fi àwọn orúkọ òrìṣà, orúkọ àlùjànnú tàbí raohāniyah, orúkọ Jésù Kristi, orúkọ àwọn ṣeeu àti orúkọ àwọn mọlāika ṣàdúà dípò àwọn orúkọ Allāhu. Ẹní tí ó ń yẹ̀ kúrò nínú àwọn orúkọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún ni ẹni tí ó ń fi àwọn orúkọ t’ó lòdì sí ‘aƙidah ’Islām pe Allāhu tàbí ròyìn Rẹ̀. Ẹni tí ó bá ṣe ìwọ̀nyẹn ti di ẹlẹbọ ńlá. Ní òdodo ni pé, àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn t’ó ga jùlọ wà fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). A ò sì lè mọ gbogbo wọn tán nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi àwọn kan pamọ́ fún wa. Àmọ́ àkójá rẹ̀ ni pé, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ pé Allāhu, kò sì gbọ́dọ̀ ròyìn Allāhu àyàfi pẹ̀lú àwọn orúkọ kan àti àwọn ìròyìn kan tí Allāhu fi pe ara Rẹ̀, tí Ó sì fi ròyìn ara Rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti èyí tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pè É tàbí tí ó fi ròyìn Rẹ̀ (subhānahu wa ta'ālā).
Ó wà nínú àwọn tí A dá, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà, wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò níí mọ̀.
Èmi yóò lọ́ wọn lára. Dájúdájú ète Mi lágbára.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Ṣé wọn kò ronú jinlẹ̀ ni? Kò sí wèrè kan kan lára ẹni wọn (ìyẹn, Ànábì s.a.w.). Ta sì ni bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.
Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?
____________________
Gbólóhùn yìí "Nígbà náà, “hadīth wo” ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?" àti irú rẹ̀ t’ó wà nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:6, àwọn kan lérò pé ó ń túmọ̀ sí pé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì kan kan, áḿbọ̀sìbọ́sí pé a óò máa fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.
Èsì: Wọ́n ti dojú ìtúmọ̀ āyah náà rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ pátápátá. Ní àkọ́kọ́ ná, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ t’ó wà nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ba‘dahu” (lẹ́yìn rẹ̀) ń dúró fún n̄ǹkan méjì. Ìkíní: Ó dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”. Ìkejì: Ó ń dúró fún al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Tí ó bá dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde, kò lè wúlò fún wọn mọ́, kò sì lè rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ mọ́ nítorí pé, kò sí ìronúpìwàdà mọ́ tí ikú bá ti dé bá ẹ̀dá, kò sì sí ìronúpìwàdà mọ́ fún ẹ̀dá lọ́jọ́ Àjíǹde.” Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah yìí àti nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 nítorí pé, ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ikú ni gbólóhùn t’ó ṣíwájú nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Bákan náà, ọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó pe ọjọ́ Àjíǹde nírọ́ l’ó ṣíwájú gbólóhùn náà nínú sūrah al-Mursalāt.
Tí ó bá sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ náà ń dúró fún al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn t’ó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé, bí ènìyàn kò bá gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ òdodo al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ irọ́ oríṣiríṣi l’ó máa kù ú kù tí ó máa gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Nítorí náà, “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí pé kí á má gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹnikẹ́ni kò wulẹ̀ lè gbọ́ àgbọ́yé al-Ƙur’ān àfi pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Tí ẹnì kan bá sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, onítọ̀ún ti wọ ipò kèfèrí títí ó máa fi ronú pìwàdà.
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un. (Allāhu) yó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé ìgbà wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn Àkókò rẹ̀ àfi Òun. Ó ṣòro (láti mọ̀) fún àwọn ará sánmọ̀ àti ará ilẹ̀. Kò níí dé ba yín àfi lójijì.” Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè bí ẹni pé ìwọ nímọ̀ nípa rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.”
Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.”
(Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó da yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Ó sì dá aya fún un láti ara rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ̀gbádùn ìgbépọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí ọkọ súnmọ́ ìyàwó rẹ̀, tí ó sì ru ẹrù (àtọ̀) fífúyẹ́. Ó sì rù ú kiri. Nígbà tí ó sì diwọ́ disẹ̀ sínú tán, àwọn méjèèjì pe Allāhu Olúwa wọn pé: “Tí O bá fún wa ni ọmọ rere (t’ó pé ní ẹ̀dá), dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”
Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
____________________
Ta ni ọkọ àti ìyàwó nínú āyah yìí? Kí sì ni ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn? Àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pín sí méjì lórí ìbéèrè àkọ́kọ́. Igun kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām fi rinlẹ̀ pé Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) ni àwọn ọkọ àti ìyàwó tí āyah náà ń tọ́ka sí ní ìbámu sí āyah 189 t’ó síwájú. Igun kejì sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé āyah 189 t’ó síwájú ń tọ́ka sí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā), àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn ni āyah 190 ń tọ́ka sí. Wọ́n ní ìdí nìyí tí ọ̀rọ̀-ìṣe t’ó parí āyah 190 fi wá pẹ̀lú ẹ̀hun ọ̀pọ̀, èyí tí ó ń fi hàn pé tọkọ tìyàwó yẹn kò mọ ní ènìyàn méjì pèrè. Wọ́n fi kún un pé, ìbá jẹ́ pé Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa, Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí ni, ẹ̀hun èjì tí ó máa dúró fún ọ̀wọ́ àwọn méjèèjì nìkan ni kò bá parí āyah náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú āyah 189 t’ó ṣíwájú.
Ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn ni sísọ ọmọ náà ni orúkọ tí ó fi àìmoore hàn sí Allāhu. Bí àpẹẹrẹ, kí Allāhu fún ènìyàn lọ́mọ, kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams, ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh, ‘abdur-Rahmọ̄n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wàyí, wọ́n ṣe àfitì ìtàn kan sí ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu). Ìtàn náà wà nínú àwọn tírà tafsīr kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibn Kathīr ka ìtàn náà mọ́ ara ìtàn irọ́ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl. Àmọ́ ìtàn tí ẹnu kùn yìí kúkú ni àwọn tí wọ́n gbà pé Ànábì Ādam (alaehi sọlāt wa salām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallahu anhā) ni tọkọ tìyàwó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí rí mú lò láti fi túmọ̀ āyah náà. Kókó ìtàn náà ni pé, nígbà tí ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) lóyún, Èṣù wá ba á ní àwòrán ènìyàn, ó sì sọ fún un pé, “Tí kò bá fẹ́ bí àwòrán ẹranko lọ́mọ tàbí tí kò bá fẹ́ kí ọmọ náà kú ní òpóǹló, kí ó sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”. Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) kò dá a lóhùn, kò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Ó bí ọmọ. Ọmọ náà sì kú. Ó tún ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà kejì. Àmọ́ nígbà tí ó lóyún ìkẹta, kò fẹ́ kí ó kú. Wọ́n sì sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”! Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pè ní ẹbọ nítorí pé, wọ́n tẹ̀lé àṣẹ t’ó yapa sí àṣẹ Allāhu pé wọn kò gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Èṣù. Kì í ṣe pé wọ́n gbé ẹbọ fún Èṣù láti fi wá ààbò fún ọmọ náà. Láti ìgbà náà l’ó ti di èèwọ̀ pọ́nńbélé nínú ìlànà ìsọmọlórúkọ láti ṣe àfitì “ẹrú” sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn lẹ́yìn Allāhu. Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí bí àwọn méjèèjì ṣe tẹ̀lé àṣẹ Èṣù níbi sísọ ọmọ wọn ní orúkọ tí Èṣù mú wá fún wọn, kì í ṣe pé wọ́n bímọ tán wọ́n wá ń bọ Èṣù bí àwọn kan ṣe máa ń bọ ìbejì. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì tẹ́wọ́ gba ìronùpìwàdà wọn.
Tí àwọn kristiẹni bá wá tàbùkù Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) nípa èyí, ṣebí Jésù tẹ̀lé àṣẹ Èṣù ni Èṣù fi rí òun náà mú lọ káàkiri láti dán olúwa wọn wò! Jésù Kristi kúkú tẹ̀lé àṣẹ Èsù nínú àwọn bíbélì, àmọ́ kò forí balẹ̀ fún Èṣù rárá. Ìyẹn wà nínú ìwé Luku 4: 1-13. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni kò lè ṣàṣìṣe.
Ṣé wọn yóò sọ n̄ǹkan tí kò lè dá n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ Rẹ̀, A sì ṣẹ̀dá wọn ni?
Àwọn òrìṣà kò lè ṣe àrànṣe kan fún àwọn abọ̀rìṣà. Àti pé àwọn òrìṣà gan-an kò lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n.
Tí ẹ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, wọn kò níí tẹ̀lé yín. Bákan náà ni fun yín; ẹ pè wọ́n tàbí ẹ̀yin dákẹ́ ẹnu (fún wọn).
Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹrú bí irú yin ni wọ́n. Nítorí náà, ẹ pè wọ́n wò, kí wọ́n da yín lóhùn tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Ṣé wọ́n ní ẹsẹ̀ tí wọ́n lè fi rìn ni? Tàbí ṣé wọ́n ní ọwọ́ tí wọ́n lè fi gbá n̄ǹkan mú? Tàbí ṣé wọ́n ní ojú tí wọ́n lè fi ríran? Tàbí ṣé wọ́n ní etí tí wọ́n lè fi gbọ́rọ̀? Sọ pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín, lẹ́yìn náà kí ẹ déte sí mi, kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára.
Dájúdájú Alátìlẹ́yìn mi ni Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà náà kalẹ̀. Àti pé Òun l’Ó ń ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn ẹni rere.
Àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe àrànṣe fun yín. Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n.
Tí ẹ bá sì pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, wọn kò níí gbọ́. Ò ń rí wọn pé wọ́n ń wò ọ́ ni, (ṣùgbọ́n) wọn kò ríran.
Ṣàmójúkúrò, pàṣẹ ohun rere, kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìmọ̀kan.
Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èṣù, sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ní Olùgbọ́, Onímọ̀.
Dájúdájú àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu), nígbà tí ròyíròyí kan bá ṣẹlẹ̀ sí wọn láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí wọ́n bá rántí (Allāhu), nígbà náà ojú wọn yó sì ríran (rí òdodo).
(Àmọ́ ní ti) àwọn ọmọ ìyá (Èṣù), ńṣe ni àwọn Èṣù yóò máa kún wọn lọ́wọ́ nínú ìṣìnà. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dáràn mọ níwọ̀n.
Nígbà tí o ò bá mú àmì wá bá wọn, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kò ṣe ṣe àdáhun rẹ̀?” Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi ni mò ń tẹ̀lé. (al-Ƙur’ān) yìí sì ni àwọn ẹ̀rí t’ó dájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ sì ni fún àwọn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Nígbà tí wọ́n ba ń ke al-Ƙur’ān, ẹ tẹ́tí sí i, kí ẹ sì dákẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín.
Ṣe ìrántí Olúwa Rẹ nínú ẹ̀mí rẹ pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ìbẹ̀rù (Allāhu), kò sì níí jẹ́ ọ̀rọ̀ ariwo, ní òwúrọ̀ àti àṣálẹ́. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn olùgbàgbéra (nípa ìrántí Allāhu).
Dájúdájú àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, wọn kì í jọra wọn lójú láti jọ́sìn fún Un. Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ fún Un.
Icon