ترجمة معاني سورة الشمس باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

آية رقم 1
(Allāhu) búra pẹ̀lú òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀.
آية رقم 2
Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn).
آية رقم 3
Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru.
آية رقم 4
Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀.
آية رقم 5
Ó tún búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n ?
____________________
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Ẹni tí Ó mọ àwọn sánmọ̀. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
آية رقم 6
Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀.
آية رقم 7
Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba.
آية رقم 8
Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
آية رقم 9
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.
آية رقم 10
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
آية رقم 11
Ìjọ Thamūd pe òdodo nírọ́ nípa ìtayọ ẹnu-àlà wọn.
آية رقم 12
(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
آية رقم 13
Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀)."
آية رقم 14
Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
آية رقم 15
(Ẹni t’ó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.
تقدم القراءة