ترجمة سورة التحريم

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة التحريم باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fun yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Òfin ìtánràn ìbúra wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:89.
Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni t’ó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i). Ànábì sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: "O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí."). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: "Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?" (Ànábì) sọ pé: "Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà."
____________________
Méjì ni ọ̀rọ̀ àṣírí náà. Ìkíní: bíbúra tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi Allāhu búra pé òun kò níí fẹ́ ẹrúbìnrin rẹ̀ kan, Mọ̄riyah Ƙibtiyyah (kí Allāhu yọ́nú sí i), ẹni t’ó bí ’Ibrọ̄hīm fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìkejì: sísọ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé Abu Bakr Siddīƙ ni àrólé àkọ́kọ́, ‘Umọr ọmọ Kattọ̄b sì ni àrólé kejì (kí Allāhu yọ́nú sí wọn). Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì náà pamọ́ sí ọwọ́ Hafsọh. Àmọ́, Hafsọh fi tó ‘Ā’iṣah létí (kí Allāhu yọ́nú sí wọn).
Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (tún wà fún un).
Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ, àwọn olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ ní adélébọ̀ àti wúńdíá.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika t’ó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn.
Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní ìronúpìwàdà òdodo. Ó ṣeé ṣe pé Olúwa yín máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fun yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí Allāhu kò níí dójú ti Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọn yóò sọ pé: "Olúwa wa, pé ìmọ́lẹ̀ wa fún wa, kí O sì foríjìn wá. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan."
Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Ibùgbé wọn sì ni iná Jahanamọ. Ìkángun náà sì burú.
Allāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: "Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná)."
Allāhu tún fi ìyàwó Fir‘aon ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó gbàgbọ́. Nígbà tí ó sọ pé: "Olúwa mi, kọ́ ilé kan fún mi lọ́dọ̀ Rẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Là mí lọ́wọ́ Fir‘aon àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Kí O sì là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí."
Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu.
Icon