ترجمة سورة الرعد

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الرعد باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

’Alif lām mīm rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́.
Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín.
Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ àti àwọn odò. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) t’ó wà nítòsí ara wọn àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù t’ó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fi omi ẹyọ kan wọn. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi jíjẹ. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè.
____________________
Bíi ilẹ̀ yanrìn nítòsí ilẹ̀ amọ̀, ilẹ́ yangí nítòsí ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ yangí, ilẹ̀ t’ó lọ́ràá nítòsí ilẹ̀ t’ó sá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn àpẹ̀ẹrẹ ìyà kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.
Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan l’ó sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀.
(Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga.
Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán.
Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni t’ó lè dá a padà. Kò sì sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.
Òun ni Ẹni t’ó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fun yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò t’ó ṣú dẹ̀dẹ̀.
Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un, àwọn mọlāika ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná àrá níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. Ó sì le níbi gbígbá-ẹ̀dá-mú.
TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Gọ̄fir;40:50.
Allāhu ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.
____________________
Àwọn sūfī (Tijāniyyah) ṣi āyah yìí àti tinú sūrah an-Nahl; 16:49 tú lábẹ́ àdìsọ́kàn wọn tí wọ́n ń pè ní “‘Ilmu bātiniy” – “Ìmọ̀ Awo-inú”. Àwọn sūfī (Tijāniyyah) sọ pé, pẹ̀lú àwọn āyah méjèèjì wọ̀nyẹn, “gbogbo olùjọ́sìn tàbí olùforíkanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu lójú-ìta, kò jọ́sìn kò sì forí kanlẹ̀ fún kiní kan àfi Allāhu (ta‘ālā) nítorí pé Òun l’Ó wà nínú àwọn aṣọ wọ̀nyẹn.” Irọ́ ńlá nìyí. Mímọ́ sì ni fún Allāhu tayọ ìsọkúsọ wọn yẹn. Āyah onípọ́n-na ni āyah méjèèjì wọ̀nyẹn. Pọ́n-na inú wọn ni pé, kò sí ẹni tí kì í forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Èyí ni àwọn sūfī ṣe àfikún rẹ̀ pé, “Kódà kí ó forí kanlẹ̀ fún òrìṣà, Allāhu nínú àwòrán òrìṣà l’ó ń forí kanlẹ̀ fún!” Kíyè sí i, ìgbàkígbà tí a bá rí āyah onípọ́n-na, āyah aláìnípọ́n-na ni a máa fi yanjú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi èyí rinlẹ̀ nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7. Nítorí náà, sūrah al-Hajj;22:18 àti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98 ti yọ pọ́n-na tí ó jẹyọ nínú āyah méjèèjì náà. Ní ti sūrah al-Hajj;22:18, òhun fi rinlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Ní ti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98, òhun sì fi rinlẹ̀ pé àwọn t’ó ń forí kanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, àti àwọn àti òrìṣà wọn l’ó máa wọ inú Iná nítorí pé, wọn kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu, wọn kò sì jọ́sìn fún Un. Èyí ti túmọ̀ sí pé, sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 kò kan olùforíkanlẹ̀ àti olùjọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, gbólóhùn “wọ́n fẹ́” dúró fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo; “wọ́n kọ̀” sì dúró fún àwọn munāfiki. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Rūm; 30:26.
Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe òdodo àti irọ́ wá. Ní ti ìfòfó, ó máa bá pàǹtí lọ. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe wá.
Ohun rere wà fún àwọn t’ó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú.
____________________
Aburú ìṣírò-iṣẹ́ ni kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá lé e lọ́wọ́ àti kí Allāhu má ṣàforíjìn fún un nítorí pé ẹ̀dá náà kú sórí ẹbọ ṣíṣe tàbí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu àfọkànṣe.
Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀)? Àwọn onílàákàyè l’ó ń lo ìrántí.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere ti aburú lọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún.
Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ̀, (àwọn) àti ẹni t’ó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
(Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fun yín nítorí ìfaradà yín.” Àtubọ̀tán Ilé náà sì dára.
Àwọn t’ó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn.
Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí sọ́dọ̀ Rẹ̀.”
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:152.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn.
Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, (èyí tí) àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn, nítorí kí o lè máa kà fún wọn n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú Ƙur’ān, wọ́n fi mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn), tàbí wọ́n fi gélè (láti yanu), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn t’ó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn.
Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) ẹ tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ̀yin yóò pa) irọ́ funfun báláú ni? Wọ́n kúkú ti ṣe ète ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sì níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un.
Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.
Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó sì máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ t’ó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí Wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”
Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.1 Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ l’ó ní àkọsílẹ̀.
____________________
1 Kíyè sí i, àwọn kan ń sọ pé gbólóhùn yìí “Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.” ń tọ́ka sí pé “Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó, ó sì ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Nítorí náà, ó ti kú. Kò sì níí padà wá sáyé mọ́.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ fífi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Àti pé, ìrònú wọn nípa gbólóhùn náà jẹ́ ìrònú ọpọlọ lásán, kò sì sí ìtọ́sọ́nà nínú rẹ̀ nítorí àwọn ìdí pàtàkì márùn-ún wọ̀nyí: Ìdí àkọ́kọ́; Kò kọ́kọ́ sí tírà tafsīr àwọn onisunnah t’ó sọ pé gbólóhùn náà dúró fún pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ ìyàwó tàbí pé ó ti bímọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah l’ó ń fá ìtúmọ̀ gbólóhùn náà síbẹ̀. Ìdí kejì: Gbólóhùn náà dúró sórí àdámọ́ tí Allāhu fi sára gbogbo ọmọ Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kì í ṣe àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nìkan ni wọn yóò máa fẹ́ ìyàwó tàbí bímọ. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ṣe gbogbo ẹ̀dá t’ó wá sáyé l’ó rí ìyàwó fẹ́? Tàbí ṣe gbogbo ẹni t’ó sì rí ìyàwó fẹ́ l’ó rí ọmọ bí? Ìdí kẹta; Kì í ṣe nítorí ìfirinlẹ̀ pé kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun tí kò fẹ́ ìyàwó rí tàbí tí kò bímọ rí ni Allāhu fi mú ọ̀rọ̀ náà wá nítorí pé, ó wà nínú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ tí kò fẹ́ ìyàwó, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa bímọ. Àpẹẹrẹ ni Ànábì Yahya ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú sūrah āli-’Imrọ̄n 3:39. Ìdí kẹrin; Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbólóhùn náà fọ èsì fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni. Àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó ń sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní òdodo ni kò yẹ kó jẹ́ òjíṣẹ́ abara tí ó máa fẹ́ ìyàwó, kò sì yẹ fún un láti máa bímọ.”, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe mú ọ̀rọ̀ wọn wá nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:94. Ìdí karùn-ún: Ìbá jẹ́ pé āyah náà jẹmọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ni, ìbá tí sí hadīth kan kan t’ó máa fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Hadīth lórí ìpadàbọ̀ rẹ̀ kò sì mọ ní ẹyọ kan. Nítorí náà, ṣé àwọn t’ó ń lo gbólóhùn náà fún àìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé mọ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ ni tàbí wọ́n kàn jẹ́ asòòkùn-sẹ́sìn ni?! 2 “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà. Kíyè sí i, “àmì kan” láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tún lè jẹ́ “iṣẹ́ ìyanu” tàbí “ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”.
Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà.
____________________
Kí ni n̄ǹkan tí Allāhu ń parẹ́?. Ki sì ni n̄ǹkan tí Ó ń mú ṣẹ? Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan náà. Àgbọ́yé kìíní tí ó tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ ni pé, āyah náà jẹ́ àlàyé fún āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀. Ìdí ni pé, āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀ ń tọ́ka sí bí ó ṣe jẹ́ pé ọjọ́ ìyà, tí ó jẹ́ “àmì kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā)”, èyí tí ó máa kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ti ṣe wà nínú àkọsílẹ̀. Āyah 39 yìí wá ń sọ pé ní ọjọ́kọ́jọ́ tí ìyà náà bá ń dé sí àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́rùn, ó ń bẹ nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó máa bá ìyà náà lọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tí ìyà náà yóò dá sí títí dí ọjọ́ mìíràn. Àti ẹni tí ó máa bá ìyà lọ àtí ẹni tí ọjọ́ ìyà rẹ̀ yóò sún ṣíwájú, gbogbo rẹ̀ ni ó kúkú ti wà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ, tí í ṣe àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá bá ìyà lọ ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá ru ìyà náà là títí di ọjọ́ mìíràn ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Lẹ́yìn àgbọ́yé yìí ní ọ̀rọ̀ kan àwọn àgbọ́yé tí ó dá āyah náà tú lọ́tọ̀, láì sopọ̀ mọ́ āyah 38.
Àgbọ́yé kejì: Inú àkọsílẹ̀ méjì ni kádàrá ẹ̀dá wà. Àkọsílẹ̀ kan wà lọ́dọ̀ àwọn mọlāika. Àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika ni àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń gbé fún wọn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní ọdọọdún nínú Òru Abiyì (Laelatul-Ƙọdr). Ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ sí kádàrá ẹ̀dá nínú àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika nípa ki ohun titun tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá kan. Bákàn náà, àwọn àlámòrí kan lè wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín. Àkọsílẹ̀ kejì ni àkọsílẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àkọsílẹ̀ yìí l’ó kó gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá sínú tán pátápátá, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ẹ̀dá kò tí ì máa jẹ́ ẹ̀dá títí dé ìkángun ẹ̀dá nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra tàbí nínú Iná. Nínú àkọsílẹ̀ yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ń yọ àkọsílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn mọlāika Rẹ̀. Nítorí náà, ohun titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ohun tí ó bá wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Àmọ́ àti ohun titun àti èyí tí kò titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika, ìkíní kejì l’ó wà bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ.
Àgbọ́yé kẹta: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, kí ọkùnrin kan ti máa tẹ̀lé àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìyapa àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìṣìnà àìgbàgbọ́. Onítọ̀ún ni ẹni tí Allāhu pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìmọ̀nà. Irúfẹ́ ẹni yìí l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí Allāhu fí orúkọ rẹ̀ rinlẹ̀ sínú ìmọ̀nà ni kí ọkùnrin kan ti máa yapa àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìmọ̀nà ’Islām. Onítọ̀ún l’ó wà ní abẹ́ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé kẹrin: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn mọlāika yóò máa kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀dá sílẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nígbà tí ó bá dí ọjọ́ Àlàmísì, wọn yóò yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo jẹ; mo mu; mo sùn; mo jí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ”. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’” Wọn yó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yòókù tí ó la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀dá. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé karùn-ún: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn āyah kan ń bẹ lásìkò tí al-Ƙur’ān ń sọ̀kalẹ̀ lọ́wọ́ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu yóò pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ sì l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn āyah kan sì ń bẹ tí Allāhu kò níí pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ l’ó sì wà ní abẹ́ “wa yuthbit”.
Àgbọ́yé kẹfà: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yóò máa ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan fún ẹ̀dá. Èyí sì ni "yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’". Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yó sì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan mú ẹ̀dá. Èyí sì ni "wa yuthbit".
Gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí wà nínú tafsīr at-Tọbarīy. Nítorí náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí yíyí kádàrá ẹ̀dá padà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Ó sì kúkú ti rinlẹ̀ nínú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé: “ A ti gbé gègé sókè kúrò lórí kíkọ kádàrá. Àwọn àkọsílẹ̀ sì ti gbẹ.” Ìyẹn nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Èyí sì l’ó ko gbogbo kádàrá ẹ̀dá sínú pátápátá àti gbogbo àwọn tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.). Fún ìdí èyí àdúà tí ẹ̀dá yóò ṣe àti ọ̀nà tí àdúà náà yó fi gbà, méjèèjì ti wà nínú kádàrá ẹ̀dá tí ó wà nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àti pé kò sí ẹ̀dá t’ó nímọ̀ èwo nínú àwọn oore ayé àti tọ̀run l’ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà. Èyí jẹ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ní abala kan. Ó tún jẹ́ ọlá fún àdúà ṣíṣe lábala kan nítorí pé oore àdúà ọ̀tọ̀, oore ẹ̀bùn Ọlọ́hun ọ̀tọ̀. Nítorí náà, gbogbo gbígbà àdúà wà ní abẹ́ àkọsílẹ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti kọ lé ẹ̀dá lórí nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa.
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá. Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Icon