ترجمة معاني سورة الملك
باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
Ìbùkún ni fún Ẹni tí ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.
Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?
Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.
Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ t’ó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n.
Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.
Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí ó sì máa ru sókè.
Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínú. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: "Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?"
Wọn yóò wí pé: "Rárá, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà t’ó tóbi."
Wọ́n tún wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná jíjò."
Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná t’ó ń jò fòfò.
Dájúdájú àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi ń bẹ fún wọn.
Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.
Ṣé (Allāhu) kò mọ ẹni t’Ó dá ni? Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.
Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.
Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.
____________________
Ta ni Ẹni náà tí Ó wà ní òkè sánmọ̀ bí kò ṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìdí nìyí tí a fi sọ síwájú pé, pàápàá bíbẹ Allāhu kò sí ní ibì kan kan bí kò ṣe ní òkè sánmọ̀. Kíyè sí i! Kalmọh “fī” nínú āyah yìí kò túmọ̀ sí “ní inú” bí kò ṣe “ní òkè” nítorí pé, Allāhu kò fi inú sánmọ̀ ṣe ibùjókòó bí kò ṣe òkè sánmọ̀. Bákan náà, kalmọh “samọ̄’u” jẹ́ ẹyọ nínú āyah yìí, àmọ́ ó ń dúró fún sánmọ̀ keje tàbí àpapọ̀ sánmọ̀ méjèèje.
Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo nírọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.
Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fun yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.
Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fun yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.
Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni t’ó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?
Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fun yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀."
Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí."
Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"
Sọ pé: "Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni."
Nígbà tí wọ́n bá rí i t’ó súnmọ́, ojú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè."
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?
Sọ pé: "Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé."
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú wá ba yín?"