ترجمة سورة الأنبياء

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الأنبياء باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ìṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo).
Kò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ pẹ̀lú eré ṣíṣe.
Wọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: "Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran?"
Ó sọ pé: “Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ t’ó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”
Rárá, wọ́n tún wí pé: “Àwọn àlá tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ́pọ̀ mọ́ra wọn ni (al-Ƙur’ān.” Wọ́n tún wí pé): “Rárá, ó hun ún ni.” (Wọ́n tún wí pé): “Rárá, eléwì ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Kò sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)?
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yūsuf: 12:109 àti sūrah an-Nahl; 16:43.
A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.
A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kò níí jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).
____________________
Àwọn t’ó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú sọ pé, “Āyah yìí àti āyah 34 níwájú tako àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé. Nítorí náà, Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú”.
Èsì: Kíyè sí i! Gbígbé tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lọ sínú sánmọ̀ kò túmọ̀ sí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò níí kú. Rárá o, ó máa kú lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ nítorí pé, abara ni, kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu, Ọlọ́hun nìkan ni kò níí kú láéláé. Yàtọ̀ sí āyah “ƙọbla maotih” nínú sūrah an-Nisā’; 4:159, àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti fi rinlẹ̀ pé, ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹ̀yìn ìgbà tí ó bá t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, ìyẹn ní òpin ayé. Ohun tí ó kàn jẹ́ ìṣòro fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ṣíwájú àsìkò yìí ni pé, bí wọ́n bá sọ pé kò sí āyah tààrà kan lórí àìtíìkú rẹ̀ àti ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀ lópin ayé, kò sí ìmọ̀ t’ó yè kooro fún wọn lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Nítorí pé, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀kọ́ t’ó yè kooro lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), wọn ìbá mọ̀ pé dájúdájú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní òmìnira láti sọ ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ní òdíwọ̀n ìgbà tí hadīth bẹ́ẹ̀ bá sì ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa hadīth, ẹnu aláìmọ̀kan tàbí aláààbọ̀ ẹ̀kọ́ kan kan kò sì gbà á láti tako irúfẹ́ àwọn hadīth náà. Bí ó bá dán an wò pẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti bàjẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4: 115.
Bí àpẹẹrẹ, al-Ƙur’ān fi rinlẹ̀ pé, àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80, sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń dá sálámọ̀ padà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá sálámọ̀ sí i nídìí sàréè rẹ̀. Kódà hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ tún wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, ní gbogbo ọjọ́ Jímọ̀, àwọn mọlāika ń gbé ìtọrọ-ìkẹ́ àti ìtọrọ-ìbùkún fún Ànábì wa Muhammad sí etí ìgbọ́ rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀ láti ibikíbi nílé ayé tí wọ́n bá ti ń tọrọ rẹ̀ fún un (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
Hadīth kìíní: Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Hadīth kejì: Láti ọ̀dọ̀ ’Aos ọmọ ’Aos (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé, “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín t’ó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú rẹ̀, Wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú rẹ̀, ìfọn àkọ́kọ́ sínú ìwo máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Ikú gbogbo ẹ̀dá sì máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ asọlātu fún mi nínú rẹ̀ nítorí pé, wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn asọlātu yín sí ọ̀dọ̀ mi.” ’Aos sọ pé, àwọn Sọhābah wí pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, báwo ni wọ́n ṣe máa kó àwọn asọlātu wa wá bá ọ, ó ó má ti derùpẹ̀!?” Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ('azza wa jall.) ṣe ẹran ara àwọn Ànábì ní èèwọ̀ fún ilẹ̀.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb fọdli yaomil-Jum‘ah walaelatil-Jum‘ah. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà ní àlàáfíà”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Àpẹẹrẹ mìíràn ni àwọn hadīth tààrà t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ènìyàn hóró kan ṣoṣo tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pè ní “Mọsīhu-ddajjāl”. Ẹni yìí má yọjú sáyé lópin ayé. Ó sì máa fòòró ayé ní ìfòòró kan tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.
Àmọ́ tòhun ti bí “Mọsīhu-ddajjāl” ṣe jẹ́ ẹyọ kan nínú àwọn àmì ńlá fún òpin ayé, kò sí āyah kan tààrà lórí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan l’ó jẹ́ kí á mọ̀ pé ènìyàn kan ń bọ̀ lópin ayé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mọsīhu-ddajjāl.
Èyí sì ni ìgbàgbọ́ àti àdìsọ́kàn àwa mùsùlùmí, tòhun ti bí kò ṣe sí āyah t’ó gbè é lẹ́sẹ̀ tààrà nínú al-Ƙur’ān. Nígbà tí gbogbo àwa mùsùlùmí ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn irúfẹ́ àwọn hadīth òkè wọ̀nyẹn, ní ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó tayọ òye wa, àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde, nígbà náà ta ni ẹni tí ó máa lórí láyà tako àwọn hadīth Bukọ̄riy àti hadith Muslim t’ó wá lórí àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé? Ẹnikẹ́ni tí ó bá takò ó ti tako Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ọ̀kan nìyí nínú àwọn hadīth náà.
Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Báwo ni ẹ̀yin máa wà nígbà tí Ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá sọ̀kalẹ̀ sáààrin yín, tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn t’ó gba hadīth yìí wá sọ pé, “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thanb sì fèsì pé, “Ó máa fi tírà Olúwa yín (tabāraka wa ta'ālā) àti sunnah Ànábì yín (sollalāhu 'alayhi wa sallam) darí yín.” Ni ìtúmọ̀ rẹ̀. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “imām” dúró fún nínú hadīth yìí, gẹ́gẹ́ bí “imām” ṣé dúró fún “tírà” nínú sūrah Hūd; 11:17, sūrah al-’Ahƙọ̄f; 46:12 àti sūrah Yāsīn, 36:12.
Lẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà run.
Dájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fun yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
Mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn.
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (t’ó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un.
Ẹ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fun yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè.
Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
Igbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀.
Àwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.
Tí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré).
Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fun yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́).
TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Àti pé wọ́n kò kọ́lẹ.
Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; kò sì rẹ̀ wọ́n.
Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni?
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
Wọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn).
Tàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa.” (Al-Ƙur’ān) yìí ni ìrántí nípa àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi àti ìrántí nípa àwọn t’ó ṣíwájú mi. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”
Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un – Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n.
Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀.
(Allāhu) mọ ohun t’ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t’ó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀.
Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.
Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò rí i pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀ pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni?
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, sūrah Fussilat; 41:11 tako sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.
Èsì: Kò sí ìtakora kan kan nínú āyah méjèèjì. Àlàyé rẹ̀ nìyí, ìtúmọ̀ “rọtƙ” ni “ìlẹ̀pọ̀, lílẹ̀-papọ̀”, ìtúmọ̀ “fatƙ” sì ni “ẹ̀là, lílà, yíyà”. Ní ìpìlẹ̀ ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò fi ojú kan kan sára ìkíní kejì tí n̄ǹkan kan lè gba jáde síta. Lẹ́yìn náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) la ojú sánmọ̀ nítorí kí omi òjò lè máa tinú rẹ̀ jáde sí orí ilẹ̀. Allāhu sì tún la ojú ilẹ̀ nítorí kí irúgbìn lè máa tinú rẹ̀ jáde. Tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bá ṣe èyí fún ìkíní kejì ni, òjò ìbá tí rí ọ̀nà jáde nínú sánmọ̀, irúgbìn ilẹ̀ náà ìbá tí rí ọ̀nà wù jáde nínú ilẹ̀. Ìdí nìyí tí gbólóhùn “A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti ara omi” fi parí āyah yẹn. Kíyè sí i, kalmọh ìlẹ̀pọ̀ tí Allāhu lò fún sánmọ̀ àti ilẹ̀, kò túmọ̀ sí pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’ó lẹ̀ papọ̀ mọ́ra wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wí bẹ́ẹ̀. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wà. Ìdí sì nìyí tí ó fi jẹ́ pé, ìkíní kejì wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa àṣẹ fún láti máa mú ohun tí ó wà nínú wọn jáde. Èyí sì ni ó mú ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ wá ní “èjì”, dípò “ẹyọ”, fún sánmọ̀ àti ilẹ̀ nítorí pé, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìkíní kejì wọn wà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èyí sì l’ó jẹyọ nínú sūrah Fussilat; 41:11. Nítorí náà, kò sí ìtakora nínú àwọn āyah náà. W-Allāhu ’a‘lam.
A sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀.
A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀.
Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto t’ó ń tọ̀.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah kẹjọ.
A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí?
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan l’ó máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fun yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: “Ṣé èyí ni ẹni t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?” Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé.
Wọ́n fi ìkánjú ṣe ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú.
Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni ìlérí yìí yóò ṣẹ ná, tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú).
Ṣùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A ò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn.
Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí àwọn t’ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.
Sọ pé: "Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?" Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọkẹ́-ayé.
Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan t’ó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.
Bẹ́ẹ̀ ni, A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni olùborí ni?
Sọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fun yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.”
Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”
A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò.
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
____________________
Ọ̀rọ̀-ìpínyà, ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí nínú āyah yìí dúró fún àwọn ìròyìn t’ó wà lára tírà kan ṣoṣo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Tírà náà ni at-Taorāt. Lẹ́yìn náà, ìwọ̀nyẹn ni àwọn ìròyìn t’ó máa ń wà lára ìkọ̀ọ̀kan tírà tí Allāhu máa ń sọ̀kalẹ̀ fún àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w.). Kíyè sí i, gbogbo tírà t’ó ṣíwájú ti parí iṣẹ́ wọn. Ní àsìkò yìí, tírà ìkẹ́yìn nìkan l’ó ku gbogbo ayé kù. Ìyẹn sì ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Kódà bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá padà sọ̀kalẹ̀ lópin ayé, kò níí tẹ̀lé tírà kan yàtọ̀ sí al-Ƙur’ān gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 8.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà.
Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni?
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.
(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì lọ́rùn ṣe jẹ́ ná?”
Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.”
Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
Wọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà lára àwọn ẹlẹ́fẹ̀.”
Ó sọ pé: "Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ."
Ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a.
Wọ́n wí pé: “Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí.”
Wọ́n wí pé: “A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní ’Ibrọ̄hīm.”
Wọ́n wí pé: “Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí.”
Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ l’o ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?”
Ó sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí l’ó ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:78.
Nígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí.”
Lẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): “Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀.”
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira ba yín lẹ́yìn Allāhu?
Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"
Wọ́n wí pé: “Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe.”
A sọ pé: “Iná, di tútù àti àlàáfíà lára ’Ibrọ̄hīm.”
Wọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ.
A sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá.
A ta á ní ọrẹ ọmọ, ’Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere.
A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa.
(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́.
A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere.
(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú (yín). A sì dá a lóhùn. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá.
A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá.
(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn.
A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀.
A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fun yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fun yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí?
A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Nínú àwọn èṣù, àwọn t’ó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.
(Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú."
A sì jẹ́ ìpè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).
(Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.
A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.
(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alábòsí."
____________________
Kíyè sí i, ohun tí Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kà kún àbòsí nínú àdúà rẹ̀ yìí kì í ṣe ìjàǹbá nítorí pé, kò sí Ànábì t’ó jẹ́ oníjàǹbá. Àmọ́ ohun tí ó ṣe ni pé, ó kánjú kúrò láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n tọrọ ìyà, tí ìyà náà sì fẹ́ sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí. Nítorí kí ìyà má baà kó òun náà sínú l’ó fi kánjú yẹra fún wọn. Ó sì yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tí ó yẹ jùlọ fún un ni pé, kí ó gba àṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ṣebí Allāhu t’ó rán an níṣẹ́, Ó ń gbọ́ ọ. Ó sì ń rí i.
A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.
(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọffāt; 37:125.
A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.
(Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.
____________________
Kíyè sí i! Ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá, kò túmọ̀ sí pé ìkíní kejì wọn jẹ́ olúwa àti olùgbàlà. Àmọ́ kí ẹ̀dá lè wòye sí agbára Allāhu pé, Ó máa ń ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀dá bí Ó bá ṣe fẹ́. Tí ẹnì kan bá wá tìtorí ìyẹn sọ ẹ̀dá kan di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, Ọba Oníṣẹ́-ìyanu, onítọ̀ún ti sọnù jìnnà. Bákan náà, ẹ tún wo irú gbólóhùn yìí “àmì fún gbogbo ẹ̀dá” nínú sūrah al-’Ankabūt; 29:15.
Dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.
(Àwọn yẹhudi àti nasara), wọ́n sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa.
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un.
Èèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé).
(Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya’jūj àti Ma’jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga.
Àdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): “Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni.”
Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀.
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀.
Iná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn).
Dájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná.
Wọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́.
Ìpáyà t’ó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): “Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.”
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.
Àti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul-Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (Ọgbà Ìdẹ̀ra), àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀.
____________________
Ìtúmọ̀ yìí wà ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:74.
Dájúdájú ohun t’ó tó mú ni gúnlẹ̀ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ti wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ olùjọ́sìn (fún Mi).
A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.
Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?”
Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: "Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dì jọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà.
Dájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
Èmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fun yín títí di ìgbà díẹ̀."
Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Olùrànlọ́wọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀).”
Icon