ﰡ
Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà (ṣẹlẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu ní olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.
Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A ò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni." Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn.
Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fun yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ-tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fun yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ ní olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun t’ó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: "Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná."
Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (t’ó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, t’ó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, t’ó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí.
Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò. Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn láì la ìṣírò lọ."
Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu ní ti olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.
Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)."
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.
Sọ pé: "Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi."
Sọ pé: "Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún (mo máa jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn mi fún Un.
Nítorí náà, kí ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn lófò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé."
Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi."
Àwọn tí wọ́n yàgò fún àwọn òrìṣà láti jọ́sìn fún un, wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.
Àwọn t’ó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí t’ó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.
Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni t’ó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?
Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà bọ́ sínú àwọn òpópónà odò nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.
Ǹjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn ’Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
Allāhu l’Ó sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un.
Ǹjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: "Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò."
Àwọn t’ó ṣíwájú wọn pe òdodo nírọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
Allāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
A sì ti ṣe gbogbo àkàwé fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú (l’A sọ̀kalẹ̀) nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan t’ó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń fà á kiri (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan t’ó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú.
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín.
Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó parọ́ mọ́ Allāhu, t’ó tún pe òdodo nírọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
Ẹni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) àti (àwọn) ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere
nítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.
Ṣé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san?
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?" Sọ pé: "Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé."
Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ
ẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."
Dájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.
Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.
Tàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: "(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) t’ó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè!"
Sọ pé: "Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí."
Nígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú.
Sọ pé: "Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l’O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí."
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu;
Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po.
Nígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: "Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
____________________
Ìyẹn ni pé, òun mọ̀ ọ́n ṣe ni tòun fi gún. Dípò kí ó moore sí Allāhu, kí ó dúpẹ́ fún Un, kí ó sì mọ̀ pé Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá Rẹ̀.
Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
Aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́.
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà t’ó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.
Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura.
Nítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: "Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn t’ó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́."
Tàbí kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)."
Tàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere."
Rárá o! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é nírọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.
____________________
Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (58 àti 59) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:99-100.
Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn t’ó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni?
Allāhu yóò gba àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ àpótí-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
Sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l’ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan?
Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ (pé) "Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò."
Rárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un).
Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún ikú. Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.
Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A ó sì ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú òdodo. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọn yó sì da àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahnamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fun yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fun yín?" Wọ́n wí pé: "Rárá (wọ́n wá bá wa)." Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.
A óò sọ pé: "Ẹ wọ ẹnu ọ̀nà iná Jahnamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn olùṣègbéraga sì burú.
Àti pé A óò kó àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Ẹ̀yin ṣe iṣẹ́ t’ó dára. Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére (nínú rẹ̀)."
____________________
Àwọn kristiẹni tún lérò pé āyah wọ̀nyí, āyah 71 títí dé āyah 73, tako sūrah Mọryam; 19:71. Èsì rẹ̀ ti wà nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 71 yẹn nínú sūrah Mọryam.
Wọ́n á sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára."
O máa sì rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní ẹ̀gbẹ́ Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."