(Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
____________________
Ẹ́ẹ́rìnlé láàádọ́fà sūrah (114) ni àpapọ̀ sūrah tí ó wà nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." sì ni ohun tí wọ́n fi ṣe òpínyà láààrin sūrah kan àti òmíràn. Ó tún lè dá dúró lọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah àkọ́kọ́ nínú sūrah al-Fātihah. Bákan náà, ó jẹ́ awẹ́ āyah gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú sūrah an-Naml; 27:30. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín-sūrah ní gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." dúró fún jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, wọn kò fi pín sūrah at-Taobah sọ́tọ̀ nítorí pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò pa á láṣẹ fún àwọn Sọhābah láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣíwájú kí ó tó jáde kúrò láyé. Kò sì lẹ́tọ̀ó fún àwọn Sọhābah (r.ahm) láti ṣe àfikún ohunkóhun sí àkọsílẹ̀ al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé yálà lójú ayé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí lẹ́yìn ikú rẹ̀. Báyìí sì ni ó ṣe di sunnah pé sūrah at-Taobah kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ìpín-sūrah, èyí tí a mọ̀ sí gbólóhùn "Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm." Kíyè sí i, kò sí orí-ọ̀rọ̀ kan t’ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú "Ní orúkọ Ọlọ́hun." nínú Bíbélì. Bíbélì ayé òde-òní ìbá jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, àwọn orí-ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ìbá máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun tí wọ́n sọ pé Òun l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀! Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ọba t’ó fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ohun ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Nítorí náà, (ẹ̀yin ọ̀ṣẹbọ) ẹ rìn (kiri) lórí ilẹ fún oṣù mẹ́rin. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin kò lè móríbọ́ (nínú ìyà) Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu yóò dójú ti àwọn aláìgbàgbọ́.
Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńlá ni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fun yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ ò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
____________________
Àgékúrú fún “Hajj Ńlá” ni “Hajj”. Ìdà kejì Hajj Ńlá ni Hajj Kékeré. Hajj Kékeré ni a tún mọ̀ sí ‘Umrah. Ìyapa-ẹnu wà lórí ọjọ́ tí a lè pè ní ọjọ́ Hajj Ńlá. Ìdí ni pé, ọjọ́ Hajj Ńlá lè jẹ́ ọjọ́ ‘Arafah tàbí ọjọ́ ìgúnran tàbí àpapọ̀ ọjọ́ tí iṣẹ́ Hajj bẹ̀rẹ̀ mọ́ ọjọ́ tí ó máa parí.
Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Nítorí náà, nígbà tí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ bá lọ tán , ẹ pa àwọn ọ̀ṣẹbọ níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Ẹ mú wọn, ẹ ṣéde mọ́ wọn, kí ẹ sì ba dè wọ́n ní gbogbo ibùba. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, ẹ yàgò fún wọn lójú ọ̀nà. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ nìwọ̀nyí: oṣù kìíní (Muharram), oṣù keje (Rajab), oṣù kọkànlá (Thul-ƙọ‘dah) àti oṣù kejìlá (Thul-hijjah).
Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, mú u dé àyè ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò nímọ̀.
Báwo ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́dọ̀ Allāhu àti lọ́dọ̀ Òjísẹ́ Rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nítòsí Mọ́sálásí Haram? Nítorí náà, tí wọ́n bá dúró déédé pẹ̀lú yín, ẹ dúró déédé pẹ̀lú wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn kan fún onígbàgbọ́ òdodo kan. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùtayọ ẹnu-àlà.
Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n. À ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún ìjọ t’ó nímọ̀.
Tí wọ́n bá rú ìbúra wọn lẹ́yìn àdéhùn wọn, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìdara sí ẹ̀sìn yín, nígbà náà ẹ ja àwọn olórí aláìgbàgbọ́ lógun - dájúdájú ìbúra wọn kò ní ìtúmọ̀ kan sí wọn – kí wọ́n lè jáwọ́ (níbi aburú).
Ṣé ẹ ò níí gbógun ti ìjọ kan t’o rú ìbúra wọn, tí wọ́n sì gbèrò láti lé Òjíṣẹ́ kúrò (nínú ìlú); àwọn sì ni wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tì yín ní ìgbà àkọ́kọ́? Ṣé ẹ̀ ń páyà wọn ni? Allāhu l’Ó ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí pé kí ẹ páyà Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn kristiẹni máa ń sọ̀rọ̀ àtakò burúkú sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn “Jihād”, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìlànà ẹ̀sìn ’Islām. Bí àwọn kristiẹni kan ṣe ka jihād kún ìfipámúni-ṣẹ̀sìn-’Islām, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kristiẹni mìíràn ka jihād kún ọ̀nà ìdigunjalè l’órúkọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Nínú ọ̀rọ̀ burúkú àwọn kristiẹni mìíràn lórí ọ̀rọ̀ jihād ni pé, wọ́n ti ìpasẹ̀ jihād sọ àwa mùsùlùmí di mùjẹ̀mùjẹ̀ bí àwọn Boko Harām. Ó kéré parí, dípò kí àwọn kristiẹni ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwọn kan tí wọ́n ń pè ni “ajàjàgbara” tàbí “ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn”, “alákatakítí-ẹ̀sìn ’Islām” ni orúkọ abunikù mìíràn tí àwọn kristiẹni tún fún wa nítorí ọ̀rọ̀ Jihād. Àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wọ̀nyí tí àwọn kristiẹni ń sọ sí àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād burú gan-an tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ t’ó fi jẹ́ pé, tí ẹnì kan bá kọ́kọ́ ka èyíkéyìí ìwé àtakò wọn sí ẹ̀sìn ’Islām tí wọ́n tẹ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ jihad, kò níí rí dáadáa kan kan lára Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwa mùsùlùmí àti ’Islām gan-an fúnra rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àtakò burúkú àwọn kristiẹni wọ̀nyí sì ni ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń gbìn sínú ọkàn àwọn èwe wẹẹrẹ bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ilé-ìwé alákọ̀ọ́-bẹ̀rẹ̀ pé “’Islām bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú idà lọ́wọ́ ọ̀tún, Kurāni lọ́wọ́ òsì!”
Àwọn kristiẹni, wọn a tún máa fi kún un pé, “Ìsọ̀rí mẹ́ta péré ni Allāhu àti Muhammad pín gbogbo ayé sí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kìíní ni àwọn mùsùlùmí t’ó lè pa àwọn ènìyàn bí àwọn pààyàn-pààyàn, t’ó sì lè gba àwọn dúkìá àwọn ènìyàn lọ́wọ́ wọn bí ìgárá-ọlọ́ṣà; àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo t’ó máa wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kejì ni àwọn mùsùlùmí tí wọn kò fẹ́ kí ẹ̀mí ènìyàn kan kan tọwọ́ àwọn bọ́, tí wọ́n sì ka fífi ogun jíjà gba dúkìá àwọn ènìyàn kún ìwà ọ̀daràn pọ́nńbélé; àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu wọn pè ní munāfiki, alágàbàǹgebè t’ó máa wà nínú àjà ìṣàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kẹta ni gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn ‘Islām; àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn ọ̀ṣẹbọ.” Ní àkótán, àwọn kristiẹni, wọn a tún máa sọ pé. “Âlàáfíà ni Jésù Kristi mú wá sáyé ni kò fi jagun ẹ̀sìn. Àmọ́ ìparun ni Muhammad mú wá sáyé l’ó fi kógun ja gbogbo ayé!” Ìwọ̀nyẹn ni díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àtakò tí àwọn kristiẹni máa ń sọ lásọtúnsọ sí àwa mùsùlùmí.
Kódà, nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọn máa ń tọ́ka sí àwọn āyah kọ̀ọ̀kan àti àwọn hadīth kọ̀ọ̀kan t’ó ń pa àwa mùsùlùmí òdodo láṣẹ ogun jíjà sójú ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ka ẹyọ kan tàbí òmíràn nínú àwọn ìwé àwọn kristiẹni lórí àwa mùsùlùmí kò níí ṣàì rí irúfẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ tí mo mú wá ṣíwájú wọ̀nyẹn nínú wọn. Ní pàápàá jùlọ, àwọn oníròyìn lórí ẹ̀rọ rédíò àti tẹlifísọ̀n àti àwọn ìwé ìròyìn gbogbo kò là nínú sísọ àwọn ọ̀rọ̀ abunikù bẹ́ẹ̀ sí àwa mùsùlùmí.
Mo ṣetán báyìí láti mú àlàyé díẹ̀ ní ṣókíṣókí wá lórí ọ̀rọ̀ jihād. Ní àkọ́kọ́ ná, bóyá ni ẹnì kan fi lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ogun jíjà fún ẹ̀sìn ‘Islām yé tí onítọ̀ún kò bá ní ìmọ̀ òdodo pọ́nńbélé nípa ìtàn ìgbésí ayé Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti ìtàn àwọn ẹ̀dá ẹlẹ̀sìn t’ó wà lásìkò rẹ̀. Ìdí èyí ni pé, kódà tí ẹnì kan bá ń tọ́ka sí āyah ogun tàbí hadīth ogun, ó gbọ́dọ̀ yé onítọ̀ún – tí kò bá níí ṣàbòsí sórí ara rẹ̀ - pé ọ̀rọ̀ l’ó ń ṣíwájú ogun, ọ̀rọ̀ l’ó ń kẹ́yìn ogun.
Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bẹ̀rẹ̀ ’Islām rẹ̀ nínú ìlú Mọkkah láààrin kìkìdá ọ̀ṣẹbọ. Àwọn ará ìlú Mọkkah, lásìkò náà, ni ọmọ-ojúmọ́-kan òòṣà kan. Àwọn ọ̀ṣẹbọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ ìnira t’ó lágbára kan Ànábì àti àwọn ènìyàn díẹ̀ t’ó ti gbà fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ṣíwájú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ìyẹn ogójì ọdún àkọ́kọ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ ẹni rere, olódodo, olùfọkàntán, oníwà-ìrẹ̀lẹ̀, akínkanjú ènìyàn àti ọmọlúàbí láààrin ìlú Mọkkah. Kò sì sí ẹnì kan nígbà náà t’ó ń f’ẹnu àbùkù kàn án. Kódà gbogbo ará ìlú wọn l’ó mọ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sí olódodo àti olùfọkàntán.
Àmọ́ níkété t’ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ọlọ́hun nínú ìlú, àwọn ará ìlú sọ ọ́ di “wèrè, òpìdán, akéwì” fún wí pé ìpèpè rẹ̀ lòdì sí ìbọ̀rìṣà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi kọjú oro sí òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ lu èyí tí ó ṣe é lù lálùbami nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì pa èyí tí ó ṣe é pa nínú wọn ní ìpakúpa. Bí àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe ń pa àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pa àwọn obìnrin. Àwọn ọmọ wẹẹrẹ gan-an kò móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ lásìkò náà. Kò sì sí ìgbà kan tí àwọn ọ̀ṣẹbọ bá pitú ọwọ́ wọn han àwọn mùsùlùmí lásìkò náà, àfi kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fún wọn ní àrọwà sùúrù mu. Ó sì tún máa jẹ́ kí ó yé wọn pé, irú ìyà mìíràn tí òun kò mọ̀ tún lè tọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ wá lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ sá, kí àwọn mùsùlùmí má ṣe tìtorí ìnira àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ẹ̀sìn Ọlọ́hun sílẹ̀. Èyí l’ó jẹyọ nínú sürah al-‘Ahƙọ̄f; 46:9.
Ní òdodo kàkà kí àwọn ọ̀ṣẹbọ yìí fi àwọn mùsùlùmí lọ́rùn sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n tún le mọ́ wọn sí i. Nígbà tí ìnira yìí sì ń lọ síbi ìfojú-egbò-rìn, láì dáràn kan tayọ pípe “Allāhu ni Ọlọ́hun àti Olúwa”, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí kan pé kí wọ́n fi ìlú bàbá wọn sílẹ̀, kí wọ́n gbé ẹ̀sìn wọn sá fún àwọn ọ̀ṣẹbọ, kí wọ́n lọ forí pamọ́ sínú ìlú mìíràn. Èyí l’ó ṣòkùnfà bí àwọn kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lọ ṣàtìpó nílẹ̀ Habaṣah (Ethopia). Èyí sì ni ohun tí a mọ̀ sí Hijrah àkọ́kọ́ t’ó wáyé nínú ìjọ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìkọ̀ kìíní lọ. Ìkọ̀ kejì náà lọ.
Ilẹ̀ Habaṣah wà lábẹ́ ọba Kristiẹni kan lásìkò náà. Orúkọ ọba náà ni ‘’Ashamọh bun al-Hurr an-Najāṣīy (rọdiyallāhu 'anhu). Àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah kúkú tọpasẹ̀ àwọn mùsùlùmí dé inú ìlú náà. Wọ́n sì lọ ṣe tánàdí àwọn mùsùlùmí lọ́dọ̀ ọba náà. Wọ́n fi ẹ̀sùn gban̄kọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kan àwọn mùsùlùmí. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ fún ọba pé, “ẹrú àwọn t’ó sá mọ́ àwọn lọ́wọ́ ni àwọn mùsùlùmí náà. Wọ́n ní àwọn mùsùlùmí náà kò ní ìtẹríba fún àwọn àgbà. Paríparí rẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ pé àwọn mùsùlùmí ń sọ àìdáa sí ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀.” Orí ọba náà gbóná wá. Lójú ẹsẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ kó gbogbo àwọn mùsùlùmí náà wá ṣíwájú òun. Èsì tí àwọn mùsùlùmí fọ̀ sí àwọn ẹ̀sùn náà ni pé, “àwọn kì í kúnlẹ̀ tàbí dọ̀bálẹ̀ fún ẹnikẹ́ni àfi Allāhu. Ìkíni “àlàáfíà fún ọ” ni ìkíni tàwọn. Àwọn kì í ṣe ẹrú t’ó sá mọ́ olówó rẹ̀ lọ́wọ́, àmọ́ nítorí pé àwọn kọ̀ láti máa bá wọn bọ̀rìṣà lọ l’ó mú àwọn ọ̀ṣẹbọ t’ó ń darí ìlú gbógun líle ti àwọn. Wọ́n pa nínú àwọn nípakúpa nígbà tí lílù àlùbami àti lílẹ̀lókò kò ran àwọn mọ́. Níwọ̀n ìgbà tí àyè mìíràn sì wà láyé l’àwọn fi sá wá síbí. Nípa ti ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá rẹ̀, kò sí ẹni t’ó fẹnu àbùkù kàn wọ́n rí nínú àwọn.” Agbẹnusọ wọn, Ja‘far (rọdiyallāhu 'anhu) sì ké sūrah Mọryam fún wọn nínú ààfin ọba. Orí ọba wú nígbà tí ó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òdodo tí al-Ƙur’ān ń sọ nípa ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ìyá rẹ̀. Èyí tí ń ṣe àfihàn pé “wòlíì náà tí à ń retí ti dé”. Ọba náà kò ṣe méní, kò ṣe méjì, ó gbàfà fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì fínnúfíndọ̀ gba ’Islām. Ó sì ṣe ẹ̀sìn ’Islām d’ọjọ́ ikú rẹ̀ (rọdiyallāhu 'anhu). Ọba wá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àdéhùn àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí nínú ìlú rẹ̀. Ojú ti àwọn ọ̀ṣẹbọ náà. Wọ́n sì dárí padà wá sínú ìlú Mọkkah láti tẹ̀ síwájú nínú ìfìnira kan àwọn mùsùlùmí t’ó ṣẹ́kù nínú ìlú wọn. Ọba yìí àti irú rẹ̀ mìíràn nínú àwọn èèkàn èèkàn kristiẹni t’ó gba ẹ̀sìn ’Islām sínú ayé wọn wọ́ọ́rọ́wọ́ ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí nínú àwọn súrah kan bíi tinú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:82-85.
Síwájú sí i, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah tún ń fínná mọ́ àwọn mùsùlùmí ìlú Mọkkah ju ti àtẹ̀yìnwá lọ t’ó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣèpàdé lórí bí wọ́n ṣe máa pa Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ní alẹ́ ọjọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah gbéra láti gbẹ̀mí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Allāhu tú àṣírí èròkérò wọn fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì pa á láṣẹ láti sá kúrò nínú ìlú bàbá rẹ̀ fún wọn. Allāhu pa òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣàtìpó sínú ìlú Mọdīnah. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀ṣẹbọ tọpasẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Abu-Bakr as-Siddīƙ (rọdiyallāhu 'anhu) lórí ìrìn-àjò wọn sí ìlú Mọdināh, Allāhu kó àwọn méjèèjì yọ nínú ṣùtá àwọn t’ó tọpasẹ̀ wọn. Èyí mú kí àwọn ọ̀ṣẹbọ fàbọ̀ sórí àwọn t’ó kù lẹ́yìn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dènà dè wọ́n bí ìgbà tí ẹkùn bá ń dènà de ẹranko. Àwọn tí ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ba bà nínú àwọn mùsùlùmí, yálà kí ó padà sínú ìlú Mọkkah fún ìdíyàjẹ t’ó kọjá àfaradà tàbí tí ó bá kọ̀ kí wọ́n pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sójú ọ̀nà.
Àyà kò tún ko àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah láti lé àwọn mùsùlùmí kan wọnú ìlú Modīnah. Nígbà tí ọwọ́ wọn bá sì tẹ̀ wọ́n níbẹ̀, Wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìlú Mọkkah pẹ̀lú ìjìyà t’ó dópin. Lásìkò yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí náà láti jàjà gbára fún ẹ̀mí ara wọn, láti gba àwọn ìyàwó wọn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àti àwọn tí kò rọ́nà jáde kúrò nínú ìlú Mọkkah. Kí wọ́n lè dáàbò bo ẹ̀sìn wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Hajj; 22: 39-41 àti sūrah an-Nisā’; 4:75. Gbogbo ìwọ̀nyí l’ó kúkú bi āyah ogun ẹ̀sìn, èyí tí àwọn kristiẹni ń tọ́ka sí lódì lódì báyìí.
Āyah àti hadīth tí wọ́n sì tún ń tọ́ka sí lórí jíja àwọn kristiẹni àti àwọn yẹhudi lógun kò ṣàdédé wáyé bí kò ṣe nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí àwọn ìjọ méjèèjì hù níwà sí àwọn mùsùlùmí nínú ìlú Mọdinah Onímọ̀ọ́lẹ́. Ìdí ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bá ìjọ yẹhudi àti kristiẹni nínú ìlú Mọdīnah gẹ́gẹ́ bí àrè, wọn kì í ṣe ọmọ-onílùú rárá nítorí pé àwọn ìdílé ’Aos àti ìdílé Kazraj l’ó ni ìlú wọn, ìlú Mọdīnah.
Níkété tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gúnlẹ̀ sínú ìlú Mọdīnah ni àwọn ìdílé méjèèjì wọ̀nyí fa àkóṣo àti ìjọba ìlú Mọdīnah lé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ láì bèèrè fún un nítorí pé kò fẹ́ẹ̀ ṣẹ́ku ẹnì kan kan tí kò gba ’Islām wọ́ọ́rọ́wọ́. Ìgbàláàyè tí àwọn ọmọ ìlú Mọdīnah ṣe fún Ànábì wa yìí l’ó kúkú sọ àwọn náà di “al-’Ansọ̄r” –alárànṣe-ẹ̀sìn. Àti pé orúkọ ìlú Mọdīnah yí padà kúrò ní Yẹthrib, ó sì di Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn t’ó wá ṣàtìpó sínú ìlú náà ṣe ń jẹ́ “al-Muhājirūn” – atorí-ẹ̀sìn-gbélùú-ẹni-jùsílẹ̀ -. Nígbà tí àṣẹ ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ dé ọwọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ó di alásẹ gbogbogbò fún ìlú Mọdīnah láti ọdún àkọ́kọ́ t’ó ti wọ inú ìlú náà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lé àwọn yẹhudi àti àwọn kristiẹni kúrò nínú ìlú Mọdīnah àti ìgbéríko rẹ̀. Kódà àwọn ìjọ yẹhudi ní abúlé tiwọn tí wọ́n mọ odi yíra wọn ká pẹ̀lú rẹ̀. Lábẹ́ “ààbò-ara-ẹni lààbò ìlú” l’ó mú kí àdéhùn ojú-lalákàn fi í ṣọ́rí wáyé láààriin ìjọ mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi t’ó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àmọ́ ńṣe ni àwọn yẹhudi wọ̀nyí lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah. Wọ́n sì fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ àwọn mùsùlùmí níṣu. Èyí lóbí àwọn āyah àti hadīth tí wọ́n ń tọ́ka sí lónìí lódì lódì lórí gbígbé ogun tí àwọn ahlul-kitāb.
Ìṣẹ́gun ńlá àti àrànṣe t’ó lágbára lórí àwọn ọ̀tá ’Islām àkọ́kọ́ tí Allāhu fi kó Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ṣùtá àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb, òhun ni à ń pè ní jihād. Ní ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ èkù-idà rárá títí Allāhu fi gbé e lọ sínú sánmọ̀. Òun náà ìbá kúkú jagun nítorí pé, àwọn yẹhudi kò fi òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ láì gbógun tì wọ́n. Àmọ́, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò wọ ipò aláṣẹ ìlú, áḿbọ̀sìbọ̀sí pé ó máa ní ọmọ ogun t’ó lè kó jagun ẹ̀sìn. Àti pé mélòó gan-an ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ t’ó fi máa dira ogun? Gbígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbà fún Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ọlọ́hun fi jogún ìjọba ìlú fún un l’ó fi rí ogun àjàyè jà lórí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām. Tàbí ṣe a rí ìjọba kan láyé tí kò ní ọmọ ogun ni? Ìjọba ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìjọba àlàáfíà sì ni pẹ̀lú nítorí pé, nípasẹ̀ ogun ẹ̀sìn ni àlàáfíà fi jọba lérékùsù Lárúbáwá. Ìkọjá-ẹnu-àlà àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb l’ó sì bí jihad nítorí pé, ìwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pèpè sẹ́sìn.
Àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn kò sì yé tayọ ẹnu-àlà sí àwa mùsùlùmí títí di àsìkò yìí. Ṣebí ọ̀rọ̀-ẹnu ni àwa mùsùlùmí sì fi ń yanjú rẹ̀ lọ́wọ́ lásìkò tiwa yìí. Ó sàn fún àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà wọ̀nyẹn kí wọ́n jẹ́ kí ó mọ bẹ́ẹ̀. Kò sí ìfipámúni-ṣẹ̀sìn ’Islām nítorí pé àwọn āyah kan, bíi sūrah Yūnus; 10:99-100, ti fi rinlẹ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni Allāhu máa ṣe ní mùsùlùmí. Àmọ́ Allāhu kọ kí ẹlẹ̀sìn máa fi ìníra kan ẹlẹ̀sìn mìíràn. Nítorí náà, òkìkí tí àwọn kristiẹni ń fún àwa mùsùlùmí kò lè yọ jihād kúrò nínú ẹ̀sìn ’Islām. Tí wọn kò bá fẹ́ ká ṣe jihād lórí àwọn kí wọ́n so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́.
Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn.
Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti ṣe àmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná.
Ẹni tí ó máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì ń kírun, t’ó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà.
Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun t’ó dọ́gba sí ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:100.
Olúwa wọn ń fún wọn ní ìró ìdùnnú nípa ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí ìdẹ̀ra gbére wà fún wọn nínú rẹ̀.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹ̀san ńlá wà.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
____________________
Nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:23-24, sūrah Luƙmọ̄n; 31:14-15 àti sūrah al-’Ankabūt; 29:8, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa ọmọ láṣẹ láti ṣe rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì, kódà kí àwọn méjèèjì jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí ọ̀ṣẹbọ. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láààrin ṣíṣe rere sí òbí àti títẹ̀lé àṣẹ òbí lórí ohun t’ó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìdí nìyí tí àwọn sūrah at-Taobah; 9:23 àti sūrah al-Mujādilah; 58:22 fi ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀lé àṣẹ òbí wọn nígbà tí àṣẹ wọn bá ti jẹmọ́ ìbọ̀rìṣà, àìgbàgbọ́ àti ìyapa àṣẹ Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí ṣíṣe bidah. Nítorí náà, ọmọ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe rere sí òbí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní ẹ̀tọ́ láti kọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá páṣẹ t’ó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún un. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìṣẹ̀yá-ṣẹbàbá.
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn bàbá yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn arákùnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ìbátan yín pẹ̀lú àwọn dúkìá kan tí ẹ ti kó jọ àti òkòwò kan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù pé kí ó má kùtà àti àwọn ibùgbé tí ẹ yọ́nú sí, (tí ìwọ̀nyí) bá wù yín ju Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú jíja ogun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀, ẹ máa retí (ìkángun) nígbà náà títí Allāhu yóò fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Dájúdájú Allāhu ti ṣe àrànṣe fun yín ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ojú ogun àti ní ọjọ́ (ogun) Hunaen, nígbà tí pípọ̀ yín jọ yín lójú, (àmọ́) kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan; ilẹ̀ sì fún mọ yín tòhun ti bí ó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìn dà, ẹ sì ń sá sẹ́yìn.
Lẹ́yìn náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó tún sọ àwọn ọmọ ogun kan kalẹ̀, tí ẹ ò fojú rí wọn. Ó sì jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.
Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́ lẹ́yìn ìyẹn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ Mọ́sálásí Haram lẹ́yìn ọdún wọn yìí. Tí ẹ bá ń bẹ̀rù òṣì, láìpẹ́ Allāhu máa rọ̀ yín lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀, tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ.
Àwọn yẹhudi wí pé: "‘Uzaer ni ọmọ Allāhu." Àwọn nasara sì wí pé: "Mọsīh ni ọmọ Allāhu." Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasara) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Allāhu, Allāhu yó sì kọ̀ (fún wọn) títí Ó fi máa pé ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Rẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (ẹ̀sìn ’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà (nínú nasara), wọ́n kúkú ń fi ọ̀nà èrú jẹ dúkìá àwọn ènìyàn ni, wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àwọn t’ó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, wọn kò sì ná an fún ẹ̀sìn Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Ní ọjọ́ tí A óò máa yọ́ (wúrà àti fàdákà náà) nínú iná Jahanamọ, A ó sì máa fi jó iwájú wọn, ẹ̀gbẹ́ wọn àti ẹ̀yìn wọn. (A sì máa sọ pé): "Èyí ni ohun tí ẹ kó jọ fún ẹ̀mí ara yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ohun tí ẹ kó jọ wò."
Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
____________________
Ìyẹn ni pé, lára ẹ̀sìn àti ìjọ́sìn rẹ̀ ni lílo àwọn oṣù wọ̀nyí nítorí pé, oṣù náà ni à ń lò fún ìjọ́sìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Bí àpẹẹrẹ, à ń kí ìrun Jum‘ah ní ọjọ́ Jum‘ah, à ń gba ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n nínú oṣù Rọmọdọ̄n, a sì ń ṣe iṣẹ́ hajj nínú oṣù Thul-Hijjah.
Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò sì níí jagun nínú rẹ̀) nítorí kí wọ́n lè yọ òǹkà oṣù tí Allāhu ṣe ní ọ̀wọ̀ síra wọn. Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí A bá sọ fun yín pé kí ẹ jáde (láti jagun) lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀.
Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.1 Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa."2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ ò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun l’ó sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
1Olùbárìn rẹ̀ ni ’Abū-Bakr as-Siddīƙ (rọdiyallāhu 'anhu). 2 “Allāhu wà pẹ̀lú wa” Ìyẹn ni pé, “Allāhu mọ̀ pé àwa méjèèjì wà nínú ọ̀gbun yìí, Ó ń gbọ́ wa, Ó ń rí wa. Nítorí náà, Ó máa kó wa yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyí tí wọ́n ń lépa wa.” Gbólóhùn yìí jọ sūrah Tọ̄hā; 20:46. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Ẹ tú jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú okun àti ìrọ́jú. Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.
Tí ó bá jẹ́ pé n̄ǹkan ìgbádùn (ọrọ̀ ogun) àrọ́wótó àti ìrìn-àjò tí kò jìnnà (l’o pè wọ́n sí ni), wọn ìbá tẹ̀lé ọ. Ṣùgbọ́n ìrìn-àjò ogun Tabūk jìnnà lójú wọn. Wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a lágbára ni, àwa ìbá jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú yín.” – Wọ́n sì ń kó ìparun bá ẹ̀mí ara wọn (nípa ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu.) – Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọn.
Allāhu ti ṣàmójúkúrò fún ọ. Kí ló mú ọ yọ̀ǹda fún wọn (pé kí wọ́n dúró sílé? Ìwọ ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀) títí ọ̀rọ̀ àwọn t’ó sòdodo yóò fi hàn sí ọ kedere. Ìwọ yó sì mọ àwọn òpùrọ́.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kò níí tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ láti má fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, dípò lílọ sí ojú-ogun) ni àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ọkan wọn sì ń ṣeyèméjì. Nítorí náà, wọ́n ń dààmú kiri níbi ìṣeyè-méjì wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: "Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé."
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n jáde pẹ̀lú yín, wọn kò níí kun yín àfi pẹ̀lú ìbàjẹ́. Wọn yó sì sáré máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láààrin yín, tí wọn yóò máa ko yín sínú ìyọnu. Àti pé wọ́n ní olùgbọ́rọ̀ fún wọn láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Wọ́n kúkú ti dá ìyọnu sílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì dojú àwọn ọ̀rọ̀ rú fún ọ títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì fojú hàn kedere; ẹ̀mí wọn sì kọ̀ ọ́.
Ó wà nínú wọn, ẹni tí ń wí pé: “Yọ̀ǹda fún mi (kí n̄g jókòó sílé); má ṣe kó mi sínú àdánwò.” Inú àdánwò (sísá fógun ẹ̀sìn) má ni wọ́n ti ṣubú sí yìí. Dájúdájú iná Jahanamọ yó sì kúkú yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
Tí dáadáa bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí àìda bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)” Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú.
Sọ pé: “Kò sí ohun kan t’ó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa.” Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń retí kiní kan pẹ̀lú wa ni bí kò ṣe ọ̀kan nínú dáadáa méjì (ikú ogun tàbí ìṣẹ́gun)? Àwa náà ń retí pẹ̀lú yín pé kí Allāhu mú ìyà kan wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tàbí láti ọwọ́ wa. Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú àwa náà wà pẹ̀lú yín tí à ń retí."
Sọ pé: "Ẹ fínnú-fíndọ̀ náwó ni tàbí pẹ̀lú tipátipá, A ò níí gbà á lọ́wọ́ yín (nítorí pé) dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́."
Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kọ̀ ọ́.
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́.
Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan t’ó ń bẹ̀rù.
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré.
Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń dá ọ lẹ́bi níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú.
Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: "Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ) , dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí."
____________________
N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ìbámu sí āyah 58 tí ó ṣíwájú rẹ̀ àti āyah 60 tí ó tẹ̀lé e. Kì í ṣe pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó ń pín oore ayé tàbí oore àjùlọ fún àwọn ẹ̀dá.
Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām, àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn t’ó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
“Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó t’ó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀.
Àwọn t’ó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni." Sọ pé: "Elétí-ọfẹ rere ni fun yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gbà àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”
Wọ́n ń fi Allāhu búra fun yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ l’ó sì yẹ kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Ṣé wọn kò mọ̀ pé ẹnikẹ́ni t’ó bá ń tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un ni? Olùṣegbére sì ni nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni àbùkù ńlá.
Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bẹ̀rù pé kí Á má ṣe sọ sūrah kan kalẹ̀ nípa wọn, tí ó máa fún wọn ní ìró ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Sọ pé: "Ẹ máa ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Dájúdájú Allāhu yóò ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù."
Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: "Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni." Sọ pé: "Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́?"
Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn. Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Kò sí ìgbàgbé nínú ìròyìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Àmọ́ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo orúkọ iṣẹ́ aburú wọn fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Allāhu sì ti ṣe àdéhùn iná Jahanamọ fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin àti àwọn aláìgbàgbọ́. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀. Iná máa tó wọn. Allāhu sì ti ṣẹ́bi lé wọn. Ìyà gbére sì wà fún wọn.
(Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò.
Ṣé ìròyìn àwọn t’ó ṣíwájú wọn kò tì í dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí.
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Allāhu ṣe àdéhùn àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó tún ṣe àdéhùn) àwọn ibùgbé t’ó dára nínú àwọn ọgbà ìdẹ̀ra ‘Adni (fún wọn). Ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó sì tóbi jùlọ (fún wọn). Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.
Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.
Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò tako kiní kan bí kò ṣe nítorí pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì kọ̀yìn (si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Ó wà nínú wọn, ẹni t’ó bá Allāhu ṣe àdéhùn pé: "Tí Ó bá fún wa nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, dájúdájú a óò máa tọrẹ, dájúdájú a ó sì wà nínú àwọn ẹni ire."
Àmọ́ nígbà tí Ó fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, wọ́n ṣahun sí I. Wọ́n pẹ̀yìn dà, wọ́n sì ń gbúnrí (láti náwó fẹ́sìn).
Nítorí náà, ahun wọn mú ọ̀rọ̀ wọn kángun sí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ọkàn wọn títí di ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Allāhu nítorí pé wọ́n yẹ àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe àti nítorí pé wọ́n ń parọ́.
Ṣé wọn kò mọ̀ pé Allāhu mọ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ wọn, àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀?
Àwọn t’ó ń bú àwọn olùtọrẹ-àánú nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lórí ọrẹ títa àti àwọn tí kò rí n̄ǹkan kan tayọ ìwọ̀n agbára wọn, wọ́n sì ń fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́, Allāhu fi àwọn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn – kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin – Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Pẹ̀lú gbólóhùn yìí, àwọn kò-gbédè-ó-gbékèé nínú àwọn kristiẹni lérò pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí Allāhu sì foríjìn wá. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ ohun tí ń bẹ nínú āyah yìí ni pé, kò sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn aláìgbàgbọ́ àti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹni yòówù ó bá wọn tọrọ àforíjìn. Nípa ti òkú àwọn aláìgbàgbọ́, ẹ wo āyah 84 níwájú. Nípa ti òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, ẹ wo sūrah al-Munāfiƙūn; 63:6. Bákan náà, nípa ti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹ wo sūrah an-Nisā’; 4:48 àti 116 àti sūrah at-Taobah; 9:113. Bákàn náà, bíbá tí Allāhu ni kí àwọn mùsùlùmí lọ bá Ànábí (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti lè bá wọn tọrọ àforíjìn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Sūrah an-Nisā’; 4:64, ìyẹn náà ti wá sópin nípasẹ̀ ikú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ọ̀wọ́ ìgbà tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń bẹ nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú nìkan ni ó lè bá ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì máa foríjìn ín. Àmọ́, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀. Ó sì di Ọjọ́ Àjíǹde kí Ànábì wa tó lè bá wa ṣ’ìpẹ̀ àṣegbà níwájú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nítorí náà, ìṣẹbọ sí Allāhu ni fún ẹnikẹ́ni láti lọ bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ìdí sàréè rẹ̀ fún títọrọ n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn dunnú sí jíjókòó sínú ilé wọn lẹ́yìn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n sì kórira láti fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n tún wí pé: “Ẹ má lọ jagun nínú ooru gbígbóná.” Sọ pé: “Iná Jahanamọ le jùlọ ní gbígbóná, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀.”
Nítorí náà, kí wọ́n rẹ́rìn-ín díẹ̀, kí wọ́n sì sunkún púpọ̀; (ó jẹ́) ẹ̀san (fún) ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Tí Allāhu bá mú ọ délé bá igun kan nínú wọn, tí wọ́n bá wá ń gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ fún jíjáde fún ogun ẹ̀sìn, sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀yin kò lè jáde fún ogun ẹ̀sìn mọ́ pẹ̀lú mi. Ẹ̀yin kò sì lè ja ọ̀tá kan lógun mọ́ pẹ̀lú mi, nítorí pé ẹ ti yọ́nú sí ìjókòó sílé ní ìgbà àkọ́kọ́. Nítorí náà, ẹ jókòó sílé ti àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn.”
Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́.
Má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. (Ó sì fẹ́ kí) ẹ̀mí bọ́ lára wọn, nígbà tí wọ́n bá wà nípò aláìgbàgbọ́.
Nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀ pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí wọ́n sí jagun pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (nígbà náà ni) àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn yóò máa tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n á sì wí pé: “Fi wá sílẹ̀ kí á wà pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.”
Wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. A ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò níí gbọ́ àgbọ́yé.
Ṣùgbọ́n Òjíṣẹ́ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn oore ń bẹ fún wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Allāhu ti pèsè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Àwọn aláwàáwí nínú àwọn Lárúbáwá oko wá (bá ọ) nítorí kí wọ́n lè yọ̀ǹda (ìjókòó sílé) fún wọn. Àwọn t’ó sì pe ọ̀rọ̀ Allāhu àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ nírọ́ náà jókòó sílé. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ ba àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìsàn àti àwọn tí kò rí ohun tí wọn máa ná ní owó (láti fi jagun ẹ̀sìn) nígbà tí wọ́n bá ti ní òtítọ́ sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kò sí ìbáwí kan fún àwọn olótìítọ́-inú sẹ́. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Kò tún sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ pé kí o fún àwọn ní n̄ǹkan tí àwọn yóò gùn (lọ sójú ogun), tí o sì sọ pé, “N̄g ò rí n̄ǹkan tí mo lè fun yín gùn (lọ sójú ogun), wọ́n máa padà pẹ̀lú ojú wọn tí yóò máa damije ní ti ìbànújẹ́ pé wọn kò rí n̄ǹkan tí wọ́n máa ná (lọ sójú ogun ẹ̀sìn).
Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, tí) wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò sì mọ̀.
Wọ́n yóò mú àwáwí wá fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín. Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Āyah yìí jọ āyah 105 níwájú nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.
Wọ́n yóò máa fi Allāhu búra fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn, nítorí kí ẹ lè pa wọ́n tì. Nítorí náà, ẹ pa wọ́n tì; dájúdájú ẹ̀gbin ni wọ́n. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé wọn. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n yóò máa búra fun yín nítorí kí ẹ lè yọ́nú sí wọn. Tí ẹ bá yọ́nú sí wọn, dájúdájú Allāhu kò níí yọ́nú sí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Àwọn Lárúbáwá oko le nínú àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu. Ó sì súnmọ́ pé wọ́n kò mọ àwọn ẹnu-àlà ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Àti pé ó wà nínú àwọn Lárúbáwá oko ẹni tí ó ka ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) sí owó ọ̀ràn. Ó sì ń retí àpadàsí aburú fun yín. Àwọn sì ni àpadàsí aburú yóò dé bá. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) di àwọn ìsúnmọ́ Allāhu àti (gbígba) àdùá (lọ́dọ̀) Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú òhun ni ìsúnmọ́ Allāhu fún wọn. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r pẹlú àwọn t’ó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. O ò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì. Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá.
____________________
Ìyà ẹ̀ẹ̀ mejì dúró fún ìyà tayé àti ìya tinú sàréè.
Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn t’ó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
____________________
Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn t’ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ìbámu sí āyah 102 t’ó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn t’ó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́. Àmọ́ lílo āyah náà fún gbígba owó àdúà yálà níbi ìsìnkú tàbí ní àyè mìíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ń lo āyah náà, kò jẹ mọ́ bẹ́ẹ̀ rárá nínú àwọn tírà Tafsīr.
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run?
Sọ pé: "Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i). Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Āyah yìí jọ āyah 94 nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.
Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná fún àṣẹ Allāhu; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Ìyẹn, àwọn t’ó ṣàì lọ sógun, àmọ́ tí wọn kò mú àwáwí irọ́ wá.
Àwọn t’ó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùba fún àwọn t’ó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣaájú – dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” – Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé. Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ l’o lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn t’ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra.
____________________
Kíyè sí i! Gbólóhùn yìí “Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.” àti āyah 107 l’ó ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwa mùsùlùmí onisunnah láti kírun nínú àwọn mọ́sálásí àwọn mùsùlùmí onibidiah pẹ̀lú májẹ̀mu pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fi mọ́sálásí náà sọrí bidiah wọn. Irú àwọn mọ́sálásí tí èyí kàn ni mọ́sálásí Ahmadiyyah àti Zāwiyah àwọn oníwírìdí Tijāniyah, Ƙọ̄diriyyah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tí ó bá wá jẹ́ pé wọn kò fi mọ́sálásí sọrí bidiah, àmọ́ tí wọ́n fi imām ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah tàbí ẹlẹ́sìn Tijāniyyah tàbí Ƙọ̄diriyyah ṣe imām nínú mọ́sálásí náà, mùsùlùmí lè kírun nínú mọ́sálásí náà kò kàn níí kírun lẹ́yìn imām onibidiah yẹn ni.
Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun t’ó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. (Ó jẹ́) òdodo nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Àwọn olùronúpìwàdà, àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu), àwọn olùdúpẹ́ (fún Allāhu), àwọn aláààwẹ̀, àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun), àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu), àwọn olùpàṣẹ-ohun rere, àwọn olùkọ-ohun burúkú àti àwọn olùṣọ́-ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (wọ̀nyí) ní ìró ìdùnnú (Ọgbà Ìdẹ̀ra).
Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n.
Àti pé àforíjìn tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm tọrọ fún bàbá rẹ̀ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe nítorí àdéhùn t’ó ṣe fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó hàn sí i pé dájúdájú ọ̀tá Allāhu ni (bàbá rẹ̀), ó yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni olùrawọ́rasẹ̀, olùfaradà.
Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú Allāhu l’ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu.
Dájúdájú Allāhu ti gba ìronúpìwàdà Ànábì, àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r, àwọn t’ó tẹ̀lé e ní àkókò ìṣòro lẹ́yìn tí ọkàn ìgun kan nínú wọn fẹ́ẹ̀ yí padà, (àmọ́) lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Òun ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún wọn.
(Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A (so ọ̀rọ̀ wọn rọ̀ nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí sì dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi há mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira tàbí ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn lójú ogun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tàbí wọn kò níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, tàbí ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá àfi kí Á fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí Á kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san t’ó dára jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Gbogbo àwọn mùsùlùmí kò sì gbọdọ̀ dà lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn. Ìbá ṣuwọ̀n kí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan jáde láti wá àgbọ́yé nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn bóyá wọn yó lè ṣọ́ra ṣe.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbógun ti àwọn t’ó súnmọ́ yín nínú àwọn aláìgbàgbọ́; kí wọ́n rí ìlekoko lára yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Nígbà tí A bá sì sọ sūrah kan kalẹ̀, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tí ó máa wí pé: “Ta ni nínú yín ni èyí lé ìgbàgbọ́ (rẹ̀) kún?” Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, (āyah náà) yó sì lé ìgbàgbọ́ (wọn) kún. Wọn yó sì máa dunnú.
Ní ti àwọn tí àìsàn sì wà nínú ọkàn wọn, (āyah náà) yó sì ṣe àlékún ẹ̀gbin sí ẹ̀gbin wọn. Wọn yó sì kú sí ipò aláìgbàgbọ́.
Ṣé wọn kò rí i pé À ń dán wọn wò ní ẹ̀ẹ̀ kan tàbí ẹ̀ẹ̀ méjì ní ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, wọn kò ronú pìwàdà, wọn kò sì lo ìrántí.
Àti pé nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀, apá kan wọn yóò wo apá kan lójú (wọn yó sì wí pé): “Ṣé ẹnì kan ń wò yín bí?” Lẹ́yìn náà, wọ́n máa pẹ̀yìndà. Allāhu sì pa ọkàn wọn dà (sódì) nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ kan tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó ìnira ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore ọ̀run) fun yín; aláàánúàti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo.
Nítorí náà, tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni Olúwa Ìtẹ́ ńlá.