ﰡ
A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.
Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu).
(Ó jẹ́) ìmísí t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.
Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.
TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú
àwọn sánmọ̀, ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun t’ó wà lábẹ́ ilẹ̀.
Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.
Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?
(Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fun yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é "Mūsā,
Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
____________________
Ìdí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi pa á láṣẹ fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Mọs‘ūd (rọdiyallāhu 'anhu) ṣe gbà á wá, ni pé awọ òkúǹbete kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọn kò pa lósè ni wọ́n fi ṣe bàtà náà. Àmọ́ nínú sunnah Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), mùsùlùmí lè wọ bàtà kírun níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti pa awọ rẹ̀ lósè, tí kò sì níí kó ìnira bá ẹnikẹ́ni lórí ìrun, tí kò sì níí kó ìdọ̀tí wọ inú mọ́sálásí. Ọ̀kan nínú ìrun tí èyí lè ti rọrùn jùlọ ni ìrun tí a kí ní orí ilẹ̀ gban̄sasa bí mọ́sálásí eléruku, ìrun ‘Īd méjèèjì, ìrun jannāzah àti ìrun ìwá òjò.
Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí.
Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.
____________________
Láti ọ̀dọ̀ ’Anas bun Mọ̄lik, ó sọ pé. Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Tí ọ̀kan nínú yín bá sùn tayọ (àsìkò) ìrun tàbí ó gbàgbé (ìrun) rẹ̀, kí ó kí i nígbà tí ó bá rántí rẹ̀, nítorí pé Allāhu sọ pé: “Kírun fún ìrántí Mi.”
Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hàn rẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́.
____________________
Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí "’ukfī, ’ikfā’." Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ alójú-lódì. Nítorí náà, bí ó ṣe túmọ̀ sí ṣíṣe àfihàn n̄ǹkan, ó tún ń túmọ̀ sí fífi n̄ǹkan pamọ́.
Nítorí náà, ẹni tí kò gbà á gbọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun.
Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā?"
Ó sọ pé: “Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn.”
(Allāhu) sọ pé: “Jù ú sílẹ̀, Mūsā.”
Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò t’ó ń sáré.
(Allāhu) sọ pé: "Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́.
Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn.
Kí Á lè fi èyí t’ó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́.
Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà."
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi.
Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi.
kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé.
Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi,
Hārūn, arákùnrin mi ni.
Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi
kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀,
kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.
Dájúdájú Ìwọ ń rí wa.”
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā.
Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí.
(Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ
pé: “Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú agbami odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e.” Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi.”
(Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe ẹni tí ó máa gbà á tọ́ (fun yín)?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, kò sì níí banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.
Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi.
Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ, pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ nínú ìrántí Mi.
Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà.
Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi)."
Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-àlà.”
(Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).”
Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà.
Dájúdájú Wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i."
(Fir‘aon) wí pé: “Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà.”
____________________
Ìyẹn ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣẹ̀dá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwòrán àti àdámọ́ t’ó máa ṣe wẹ́kú jíjẹ́ ẹ̀dá rẹ̀, tí ó sì máa yà á sọ́tọ̀ láààrin àwọn ẹ̀dá mìíràn. Nítorí náà, ènìyàn ń jẹ́ ènìyàn lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú ènìyàn, àlùjànnú ń jẹ́ àlùjànnú lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú àlùjànnú, mọlāika ń jẹ́ mọlāika lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú mọlāika, ẹranko ń jẹ́ ẹranko lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú ẹranko, kòkòrò ń jẹ́ kòkòrò lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú kòkòrò, sánmọ̀ ń jẹ́ sánmọ̀ lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú sánmọ̀, ilẹ̀ ń jẹ́ ilẹ̀ lórí àwòrán àti ètò t’ó ṣe wẹ́kú ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà, ènìyàn jọra wọn, àmọ́ ènìyàn kò jọ ẹ̀dá mìíràn. Àlùjànnú jọra wọn, àmọ́ àlùjànnú kò jọ ẹ̀dá mìíràn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tọ́ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan sọ́nà lórí ọ̀nà tí ó máa gba lo ẹ̀yà ara rẹ̀. Tí ẹnì kan bá wá sọ pé Allāhu dá ènìyàn lórí àwòrán Ara Rẹ̀, ó ti sọ ìsọkúsọ. Ẹnì kan kò sì níí sọ bẹ́ẹ̀ àfi aláìgbàgbọ́ nínú bíbẹ Allāhu èyí tí kò jọ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá kan kan.
(Fir‘aon) wí pé: “Kí l’ó mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé.
(Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fun yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fun yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.
Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn."
Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é nírọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀.
Ó wí pé: "Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā?
Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àkókò ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó sì mú) àyè kan t’ó tẹ́jú."
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta.”
Fir‘aon pẹ̀yìn dà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀).
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti ṣòfò.”
Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀.
Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín t’ó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́.
Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè."
(Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀.”
(Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré.
(Ànábì) Mūsā sì pa ẹ̀rù inú ọkàn rẹ̀ mọ́ra.
A sọ pé: "Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè.
Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé."
Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā."
(Fir‘aon) wí pé: "Ṣé ẹ ti gbà á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ."
(Àwọn òpìdán) sọ pé: "Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí t’ó dájú, (a ò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá lẹ́jọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́.
Dájúdájú àwa gba Olúwa wa gbọ́ nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé.
Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (gẹ́gẹ́ bí) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún.
(Ohun ni) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀)."
Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ nínú omi òkun. Má ṣe bẹ̀rù àlébá, má sì ṣe páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”
Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú agbami odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.
Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà.
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ba yín ṣe àdéhùn ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àpáta. A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fun yín.
Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fun yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu àlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).
Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.
Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?
Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà."
(Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?"
Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”
Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, t’ó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: "Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀)."
Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn!
Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fun yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi.”
Wọ́n wí pé: “A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa.”
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà
láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni?"
(Ànábì Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi tàbí orí mi fà mí (mọ́ra). Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi.'"
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?”
(Sāmiriyy) wí pé: “Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, “Má fi ara kàn mí”. Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí Wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú agbami odò.
Ọlọ́hun yin ni Allāhu nìkan, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan.
Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, ojú wọn yó sì dúdú batakun.
Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: "Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá."
Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni-abiyì jùlọ nínú wọn wí pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan.”
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: “Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù tán ráúráú.
Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa.
O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀.
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀.
Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
(Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀.
Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu).
Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn.
Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur’ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.”
Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn.
Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó kọ̀.”
Nítorí náà, A sọ pé: "Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà dààmú (fún ìjẹ-ìmu).
Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀.
Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́."
Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: “Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?”
Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà.
Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà.
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí dààmú.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un nílé ayé. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde.”
(Ó) máa wí pé: “Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!”
(Allāhu) sọ pé: "Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná).
Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé."
Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye.
Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan t’ó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan.
Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ọpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán, kí ó retí (ẹ̀san) tí ó máa yọ́nú sí.
Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn t’ó jẹ́ òdódó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.
Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l’À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu).
Wọ́n wí pé: “Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Ṣé ẹ̀rí t’ó yanjú t’ó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni?
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: "Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù."
Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun).” Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni t’ó mọ̀nà.