ترجمة سورة الأعلى

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الأعلى باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.
____________________
Nínú āyah yìí, mẹ́ta gbòòrò ni ìtọ́sọ́nà náà èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń ṣe fún àwa ènìyàn àti àlùjànnú. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfirinlẹ̀ rẹ̀ sì ń jẹyọ nínú àwọn tírà sánmọ̀ àti nínú ọ̀rọ̀ àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (a.s.w.).
Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn. Ìtọ́sọ́nà yìí kò sì sọ ẹnikẹ́ni di Òjíṣẹ́ Allāhu. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, kò sí ẹ̀san rere kan fún un lórí rẹ̀ ní ọ̀run. Ó kàn wúlò dànù fún ayé ni.
Ẹni tí Ó mú koríko tútù (hù) jáde,
Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ t’ó dúdú.
Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun t’ó pamọ́.
____________________
Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ t’ó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.
Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé awàdà nítorí pé, àwọn ènìyàn t’ó wà níbẹ̀ kò níí kọbi ara sí olùsọ̀rọ̀. Āyah yìí jọ sūrah an-Nisā’; 4:140 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:68.
Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná t’ó tóbi.
Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn rẹ̀) ti jèrè.
Ó tún rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́,
tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.
Icon