ترجمة سورة المائدة

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة المائدة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fun yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fun yín (ní èèwọ̀), láì níí sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbé kalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ oṣù ọ̀wọ̀ di ẹ̀tọ́ (fún ogun ẹ̀sìn), Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn t’ó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-àlà nítorí pé wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-àlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
A ṣe é ní èèwọ̀ fun yín ẹran òkúǹbete, àti ẹ̀jẹ̀, àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀, àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe Allāhu, àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa, àti ẹran tí wọ́n lù pa, àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ kú, àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fun yín láti yẹṣẹ́ wò. Ìwọ̀nyí ni ìbàjẹ́. Lónìí ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sọ̀rètí nù nípa ẹ̀sìn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi. Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fun yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kó sínú ìnira ebi (láti jẹ ẹran èèwọ̀), yàtọ̀ sí olùfínnúfíndọ̀-dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: "Kí ni Wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?" Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fun yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
____________________
Ìyẹn nígbà tí ẹ bá fẹ́ rán ẹranko tàbí ẹyẹ láti dọdẹ àti nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹran tí ó pa fun yín.
Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.1 Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fun yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí ’Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí yàn wọ́n lálè.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
____________________
1 Kíyè sí i, àwọn kan lérò pé gbólóhùn yìí “Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.” kó oúnjẹ ọdún àwọn kristiẹni sínú. Rárá o. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, kò jẹ oúnjẹ ọdún mìíràn yàtọ̀ sí oúnjẹ ọdún ’Islām. Bákan náà, àwọn Sọhābah (r.ahm.), kò sí ẹni t’ó jẹ oúnjẹ ọdún kristiẹni rí nínú wọn. Kò sì sí ẹnì kan nínú àwọn t’ó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, t’ó lo gbólóhùn yìí fún sísọ oúnjẹ ọdún kristiẹni di ẹ̀tọ́. Tí ẹnì kan bá wá ń lo gbólóhùn náà fún jíjẹ oúnjẹ ọdún kristiẹni àti sísọ ọ́ di oúnjẹ ẹ̀tọ́, ó ti gbé gbólóhùn náà ka àyè tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò gbà lérò. Ó sì ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó gbọ́ àgbọ́yé āyah ju Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn Sọhābah rẹ̀ (r.ahm.) pẹ̀lú àwọn aṣíwájú rere fún wa (kí Allāhu kẹ́ gbogbo wọn). Síwájú sí i, àfàìmọ̀ kí ẹni tí ó bá ń ló gbólóhùn náà fún sísọ oúnjẹ ọdún àwọn kristiẹni di ẹ̀tọ́ fún àwa mùsùlùmí má sọra rẹ̀ di kèfèrí nítorí àwọn ewu ńlá t’ó rọ̀ mọ́ ọn. Àwọn ewu ńlá náà nìwọ̀nyí: Gbígbà tí àwọn kristiẹni gbàgbọ́ pé wọ́n kan olúwa àti olùgbàlà àwọn mọ́ igi àgbélébùú, tí ó sì kú sórí igi àgbélébùú náà, tí ó tún jí dìde l’ọ́jọ́ kẹta, l’ó mú wọn dá ọdún Àjíǹde Jésù Kristi sílẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé irọ́ ni wọ́n pa. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì fi òdodo ọ̀rọ̀ rinlẹ̀ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kì í ṣe olúwa àti olùgbàlà (sūrah al-Mọ̄’idah; 5:17 àti 75). Ó tún fi rinlẹ̀ pé wọn kò pa ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), wọn kò sì kàn án mọ igi àgbélébùú (sūrah an-Nisā’; 4:157-158). Àti pé àwọn yẹhidi di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe pète pèrò láti mú ‘Īsā ọmọ Mọryamọ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn mọ́ igi àgbélébùú. Mùsùlùmí yó sì máa jẹ́ mùsùlùmí lórí gbígba ọ̀rọ̀ Allāhu gbọ́ ní òdodo. Tí irú mùsùlùmí yìí bá tún wá bá àwọn kristiẹni dá sí ọdún Àjíǹde Jésù, ó ti fara mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ikú Jésù lórí igi àgbélébùú nìyẹn. Ó sì ti pe Allāhu ní òpùrọ́. Ẹ̀sìn rẹ̀ sì ti bàjẹ́ nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ wo ewu ńlá tí oúnjẹ ọdún Àjíǹde Jésù bí fún mùsùlùmí! Bákan náà, àwọn kristiẹni ń ṣe ọdún kérésìmesì nítorí pé wọ́n gbàgbọ́ pé ọjọ́ yẹn ni wọ́n bí ọmọ Ọlọ́hun sáyé ní àwòrán ènìyàn. Wọ́n sì ń pè é ní Ọlọ́hun ọmọ. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Allāhu sọ pé Òun kò bímọ, Òun kò sì fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé, kò sí ọlọ́hun mẹta lọ́kan. Ọlọ́hun Olúwa àti Olùgbàlà, ẹyọ kan ṣoṣo l’Ó wà. Mùsùlùmí yó sì máa jẹ́ mùsùlùmí lórí gbígba ọ̀rọ̀ Allāhu gbọ́ ní òdodo. Tí irú mùsùlùmí yìí bá tún wá bá àwọn kristiẹni dá sí ọdún ọjọ́ ìbí ọlọ́hun ọmọ, ó ti fara mọ́ ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́hun bímọ, ó sì ti fara mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ọlọ́hun ọmọ. Nípa èyí, irú mùsùlùmí yìí ti pe Allāhu ní òpùrọ́. Ẹ̀sìn rẹ̀ sì ti bàjẹ́ nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ wo ewu ńlá tí oúnjẹ ọdún kérésìmesì bí fún mùsùlùmí! Wòóore: Ìjẹkújẹ wulẹ̀ ni oúnjẹ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Ànábì tiwa gan-an, ìyẹn oúnjẹ mòlídì. Kí wá ni ó máa jẹ́ ìdájọ́ jíjẹ oúnjẹ ọjọ́ ìbí “ọlọ́hun ọmọ” bí kò ṣe èèwọ̀. Bákan náà, àwọn kristiẹni gbàgbọ́ pé oṣù ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ni oṣù January.
Àwọn kristiẹni tún gbàgbọ́ pé oṣù ìparí ọdún ni oṣù December. Wọ́n sì sọ òru ìkẹ́yìn December di òru àìsùn àdúà. Wọ́n tún sọ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù January di ọjọ́ ọdún. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kò sí osù January, February títí dé December ní ọ̀dọ̀ Òun. Allähu (subhānahu wa ta'ālā) sì fi àwọn orúkọ oṣù tiRẹ̀ rinlẹ̀ fún wa. Ó ní orúkọ oṣù ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ni oṣù Muharram. Orúkọ oṣù ìparí ọdún ni oṣù Thul-hijjah. Àti pé ìwádìí fi rinlẹ̀ pé àwọn orúkọ oṣù tí àwọn kristiẹni gbàgbọ́ nínú wọn wọ̀nyẹn kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ àwọn òrìṣà òyìnbó. Bí àpẹẹrẹ, òrìṣà ìbẹ̀rẹ̀ àti ìdáwọ́lé kan tí àwọn òyìnbó abọ̀rìṣà ń pè ní Janus, ni wọ́n fi gbé oṣù àti ọdún January kalẹ̀. Àwọn kristiẹni sì tẹ́wọ́ gbà á lọ́wọ́ wọn. Mùsùlùmí yó sì máa jẹ́ mùsùlùmí lórí gbígba ọ̀rọ̀ Allāhu gbọ́ ní òdodo. Tí irú mùsùlùmí yìí bá tún wá bá àwọn kristiẹni dá sí ọdún January, ó ti fara mọ́ ìgbàgbọ́ nínú January títí dé December. Ó sì ti yọ́nú sí àwọn òrìṣà tí wọ́n fi sọrí àwọn orúkọ oṣù náà. Nípa èyí, irú mùsùlùmí bẹ́ẹ̀ ti pe Allāhu ní òpùrọ́. Ẹ̀sìn rẹ̀ sì ti bàjẹ́ nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ wo ewu ńlá tí oúnjẹ ọdún January bí fún mùsùlùmí! Wòóore, àwa mùsùlùmí tí à ń ṣẹ̀mí ní orílẹ̀ èdè tí kò lo òfin ’Islām, kò ní ìlànà mìíràn fún ṣíṣí òǹkà ọjọ́ fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ wa àfi lílo àwọn orúkọ oṣù àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn. Èyí wà lábẹ́ làlúrí títí di ìgbà tí ìjọba t’ó máa lo òfin ’Islām máa fi dìde ní orílẹ̀ èdè wa. Àmọ́ èèwọ̀ ni fún wa láti dunnú sí lílo àwọn orúkọ oṣù àwọn abọ̀rìṣà náà. Ọ̀kan pàtàkì lára dídunú sí i ni ṣíṣe ọdún rẹ̀ nítorì pé ìdùnnú ní ọdún ṣíṣe. Ará ìjọ́sìn sì ni ọdún ṣíṣe wà pẹ̀lú. Ìjọbà kò sì jẹ ẹnikẹ́ni nípá láti ṣe ọdún kan kan, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ṣíṣe ọdún January máa wọ ipò làlúrí fún àwa mùsùlùmí. Nítorí náà, gbólóhùn yìí “Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.” Kò fi ọ̀nà kan kan sọ oúnjẹ ọdún àwọn kristiẹni di ẹ̀tọ́ fún àwa mùsùlùmi. Àwọn oúnjẹ wọn tí kò jẹmọ́ ìsìn wọn, tàbí ẹran tí kristiẹni kò fi orúkọ Jésù pa nínú àwọn ẹran tí Allāhu ṣe jíjẹ rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún àwa mùsùlùmí nìkan ni gbólóhùn náà ń tọ́ka sí.
2 Kíyè sí i, a rí nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn tí ó gbá ọ̀rọ̀ yìí mú bẹ́ẹ̀ láì ṣíjú wo àwọn āyah mìíràn t’ó rọ̀mọ́ ìgbéyàwó, láì sì ṣíjú wo àwọn ewu ńlá tí kò ṣe é jànìyàn t’ó tún rọ̀ mọ́ ìgbéyàwó. Dandan sì ni fún wa láti lo āyah papọ̀ mọ́ra wọn ní ọ̀nà tí kò fi níí já sí pé mùsùlùmí tẹ̀lé ìtúmọ̀ ojú-ọ̀rọ̀ nìkan ní ìyapa sí ìtúmọ̀ ojú ọ̀rọ̀ mìíràn. Ní àkọ́kọ́ ná, nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:221, Allāhu ṣe é ní èèwọ̀ fún wa láti fẹ́ ọ̀ṣẹbọ àfi tí ó bá fi ẹbọ sílẹ̀. Kí sì ni ẹbọ ní àyè yìí bí kò ṣe jíjọ́sìn fún ẹ̀dá àti pípe ẹ̀dá lẹ́yìn Allāhu. Kí sì ni ẹ̀sìn kristiẹni bí kò ṣe jíjọ́sìn fún Jésù àti pípe Jésù lẹ́yìn Allāhu. Bákan náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa wá láṣẹ pé kí á ṣọ́ ara ilé wa níbi ìyà Iná, ìyẹn nínú sūrah at-Tahrīm; 66:6. Ta sì ni ará ilé wa bí kò ṣe àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ wa. Láti ọ̀dọ̀ ’Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Kò sí ọmọ kan àfi kí wọ́n bí i sórí àdámọ́ ’Islām, àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ ló máa sọ ọ́ di yẹhudi tàbí kristiẹni tàbí abọ̀rìṣà.” (Bukọ̄riy àti Muslim). Nítorí náà, ọ̀rọ̀ t’ó tẹ̀wọ̀n jùlọ, t’ó sì fọkàn balẹ̀ jùlọ ni pé, àwọn obìnrin kristiẹni tàbí yẹhudi t’ó bá gba ’Islām nìkan ni ọ̀rọ̀ yìí jẹmọ́. Ìkìlọ̀ t’ó sì parí āyah yìí gan ti fi hàn pé tí mùsùlùmí bá ti ipasẹ̀ jíjẹ oúnjẹ wọn tàbí ipasẹ̀ fífi wọ́n ṣe ìyàwó di kèfèrí, iṣẹ́ rẹ̀ máa bàjẹ́. Ó sì máa di ẹni òfò. Kí Allāhu kó wa yọ.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ̀ ń bẹ lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín àti àdéhùn Rẹ̀, èyí tí Ó ba yín ṣe, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e.” Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí ti Allāhu ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l’ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Allāhu ṣe àdéhùn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere (pé) àforíjìn àti ẹ̀san ńlá ń bẹ fún wọn.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ní èrò inú iná Jẹhīm.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín; nígbà tí ìjọ kan gbèrò láti nawọ́ ìjà si yín, (Allāhu) sì kó wọn lọ́wọ́ rọ̀ fun yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Àti pé Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Dájúdájú Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì gbé ìjòyè méjìlá dìde nínú wọn. Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Mò ń bẹ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá ń kírun, tí ẹ̀ bá ń yọ Zakāh, tí ẹ bá ń gba àwọn Òjíṣẹ́ Mi gbọ́, tí ẹ bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ẹ bá ń yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára. Dájúdájú Mo máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́. Dájúdájú Mo máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìyẹn nínú yín, ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà.”
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn ni A fi ṣẹ́bi lé wọn. A sì mú ọkàn wọn le koko (nítorí pé) wọ́n ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A fi ṣe ìrántí fún wọn. O ò níí yé rí oníjàǹbá láààrin wọn àfi díẹ̀ nínú wọn. Nítorí náà, ṣe àmójúkúrò fún wọn, kí o sì forí jìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
Àti pé lọ́dọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.”, A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A fi ṣe ìrántí fún wọn. Nítorí náà, A gbin ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti wá ba yín. Ó ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí ẹ fi pamọ́ nínú tírà fun yín. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀. Ìmọ́lẹ̀ àti Tírà t’ó yanjú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Allāhu.
Allāhu ń fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà. (Allāhu) yó sì mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta sì l’ó ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam, àti ìyá rẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àwọn yẹhudi àti nasara wí pé: "Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀." Sọ pé: “Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?” Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fun yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má baà wí pé: “Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó dé bá wa.” Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti dé ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín, nígbà tí Ó fi àwọn Ànábì sáààrin yín, tí Ó ṣe yín ní ọba, tí Ó tún fun yín ní n̄ǹkan tí kò fún ẹnì kan rí ní àgbáyé (lásìkò tiyín).
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọ orí ilẹ̀ mímọ́ tí Allāhu kọ mọ́ yín. Ẹ má se padà sẹ́yìn, nítorí kí ẹ má baà padà di ẹni òfò."
Wọ́n wí pé: "Mūsā, dájúdájú ìjọ ajẹni-nípá wà nínú ìlú náà. Dájúdájú àwa kò sì níí wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi jáde kúrò nínú rẹ̀. Tí wọ́n bá jáde kúrò nínú rẹ̀, àwa máa wọ inú rẹ̀ nígbà náà."
Àwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì - wọ́n sọ pé: "Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
Wọ́n wí pé: "Ìwọ Mūsā, dájúdájú àwa kò níí wọ inú ìlú náà láéláé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá sì wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ìwọ àti Olúwa rẹ lọ. Kí ẹ̀yin méjèèjì jà wọ́n lógun. Dájúdájú ibí yìí ni àwa yóò jókòó sí ná."
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀."
(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọ inú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi máa rìn rìn rìn lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ìtọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). Wọ́n gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, Wọn kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí Wọn kò gba tirẹ̀) wí pé: “Dájúdájú èmi yóò pa ọ́.” (Ìkejì) sì sọ pé: "(Ọrẹ) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà.
Dájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Dájúdájú èmi fẹ́ kí o padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde) pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ (bí ó ṣe pa) mí àti ẹ̀ṣẹ̀ tìrẹ nítorí kí o lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò inú Iná. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí."
Ẹ̀mí rẹ̀ sì gbà fún un láti pa arákùnrin rẹ̀. Ó pa á. Ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ẹni òfò.
Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde. Ó sì ń fi ẹsẹ̀ wa ilẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmi bàjẹ́ o! Mo kágara láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí n̄g sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀.” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.
Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.
Ẹ̀san àwọn t’ó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà ṣíwájú kí ẹ tó lágbára lórí wọn. Nítorí náà, ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wá àtẹ̀gùn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (pẹ̀lú iṣẹ́ rere). Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá jẹ́ tiwọn àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ níbi ìyà Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí gbà á ní ọwọ́ wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Wọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀. Ìyà gbére sì wà fún wọn.
Olè lọ́kùnrin àti olè lóbìnrin, ẹ gé ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó sì jẹ́) ìjìyà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Gígé ọwọ́ olè ní àwọn májẹ̀mu òdíwọ̀n ohun tí olè náà jí, ìbátan ààrin olè náà àti onídúkìá, ibi tí dúkìá náà wà àti ibi tí wọ́n máa gé nínú ọwọ́. Kíyè sí i, gbígbé ìdájọ́ ìjìyà kan dìde lórí ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ wáyé àfi láti ọwọ́ ìjọ́ba ìlú tàbí pẹ̀lú ìyọ̀nda láti ọ̀dọ̀ ìjọba.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà lẹ́yìn àbòsí (ọwọ́) rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.
Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì máa forí jin ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn t’ó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn t’ó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” – tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn t’ó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fun yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fun yín ẹ ṣọ́ra.” Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
____________________
Àwọn yẹhudi rán ara wọn sí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti bi í léèrè nípa ìdájọ́ onísìná tí ó ti ṣe ìgbéyàwó rí. Wọ́n sì sọ fún àwọn tí wọ́n rán wá pé tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní kòbókò àti kíkun ojú onísìná ní dúdú láti fi ṣẹ̀sín níta, kí wọ́n gba ìdájọ́ yẹn. Àmọ́ tí ó bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní ìlẹ̀lókòpa, ẹ ṣọ́ra fún un, kí ẹ má ṣe tẹ̀lé e. Ìyẹn ni àlàyé fún "Tí wọ́n bá fun yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fun yín ẹ ṣọ́ra."
Wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé.
Báwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìn dà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Dájúdájú Àwa sọ Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn t’ó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A ní kí wọ́n ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́.
A sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
A fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Taorāh. A sì fún un ni ’Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀).
Kí àwọn tí A fún ní ’Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Kíyè sí i, bí àwọn tí A fún ní ’Injīl bá lò ó gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀, dandan ni fún wọn láti tẹ̀lé Ànábì àsìkò yìí, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Nítorí pé, àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kúkú wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Johannu 1:19-21, bíbélì sọ pé: (19) Eyi si ni ẹri Johannu, nigba ti awọn Ju ran awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalẹmu wa lati bi i leere pe. Tani iwọ ṣe? (20) O si jẹwọ, ko si sẹ; o si jẹwọ pe. Emi ki i ṣe Kristi naa. (21) Wọn si bi i pe, Tani iwọ ha ṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹẹkọ, Iwọ ni woli naa bi “ẹni tí à ń retí”? O si dahun wipe, Bẹẹkọ. [Complete Jewish Bible àti New Living Translation Bible. Kíyè sí i, àwọn bíbélì yòókú ti yọ “ẹni tí à ń retí” kúrò gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.] Nítorí irú àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ló mú kí Waraƙọh ọmọ Naofal, ẹ̀bí ìyáwó àkọ́fẹ́ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Kọdījah ọmọ Kuwaelid (rọdiyallāhu 'anhā), ṣe gbà pé òun máa tẹ̀lé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nígbàkígbà tí Allāhu bá rán an níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn. Àmọ́ ó kú ṣíwájú àsìkò náà. Síwájú sí i, kàyéfì tí ń bẹ́ lára àwọn yẹ̀húdí àti nàsárá ni pé, wọ́n kò yé retí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Kódà wọ́n máa ń fi bá àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ̀rọ̀ nínú ìwàásù wọn fún wọn. Àmọ́ nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sí ìmúṣẹ, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn l’ó gbúnrí. Wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Ànábì náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ nípa èyí nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:89.
A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn t’ó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fun yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Ṣé ìdájọ́ ìgbà àìmọ̀kan ni wọ́n ń wá ni? Ta ni ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ níbi ìdájọ́ fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú (nípa Rẹ̀)?
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn yẹhudi àti nasara ní ọ̀rẹ́ àyò. Apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, dájúdájú ó ti di ara wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Nítorí náà, o máa rí àwọn tí àárẹ̀ wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa yára lọ sáààrin wọn. Wọn yóò máa wí pé: “À ń bẹ̀rù pé kí àpadàsí ìgbà má baà kàn wá ni.” Ó súnmọ́ kí Allāhu mú ìṣẹ́gun tàbí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Wọn yó sì di alábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n fi pamọ́ sínú ọkàn wọn.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Ṣé àwọn (yẹhudi) wọ̀nyí kọ́ ni àwọn t’ó fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé dájúdájú àwọn ń bẹ pẹ̀lú ẹ̀yin (munāfiki)?" Iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Nítorí náà, wọ́n sì di ẹni òfò.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà níbi ẹ̀sìn rẹ̀ nínú yín, láìpẹ́ Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan wá; Ó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wọn yóò rọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọn yó sì le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Wọn yóò máa jagun ẹ̀sìn fún Allāhu. Wọn kò sì níí bẹ̀rù èébú eléèébú. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbòòrò, Onímọ̀.
Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nìkan ni ọ̀rẹ́ yín, àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, àwọn sì ni olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀rẹ́; dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùborí.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn yín di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe ní ọ̀rẹ́ nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn aláìgbàgbọ́. Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Nígbà tí ẹ bá pèpè síbi ìrun kíkí, wọn yóò sọ ọ́ di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ṣe làákàyè.
Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ǹjẹ́ ẹ tako kiní kan lára wa bí kò ṣe pé a gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú?” Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín ni òbìlẹ̀jẹ́.
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fun yín ní ìró àwọn tí ìyà wọn burú ju ìyẹn lọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu?” (Òun ni) ẹni tí Allāhu ṣẹ́bi lé, tí Ó sì bínú sí, tí Ó sì sọ àwọn kan nínú wọn di ọ̀bọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti abọ̀rìṣà. Àwọn wọ̀nyẹn ni ipò wọn burú jùlọ, àwọn sì ni wọ́n ṣìnà jùlọ.
Nígbà tí wọ́n bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Dájúdájú wọ́n wọlé (tì yín) pẹ̀lú àìgbàgbọ́, wọ́n sì ti jáde pẹ̀lú rẹ̀. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:72.
O máa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń yára kó sínú ẹ̀ṣẹ̀, ìtayọ ẹnu-àlà àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Kí ni kò jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin máa kọ̀ fún wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú! Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Àwọn yẹhudi wí pé: "Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa." A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Àmọ́ ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ ní òdodo, kí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), Àwa ìbá pa àwọn àìda wọn rẹ́ fún wọn, Àwa ìbá sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur’ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn t’ó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú.
____________________
Ọ̀wọ́ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dé bá láyé, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Wọ́n sì gba ’Islām. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Mọ̄’idah; 5:82-86 àti sūrah āl-‘Imrọ̄n; 3:113 àti 115.
Ìwọ Òjíṣẹ́, fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ jíṣẹ́. Tí o ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jíṣẹ́ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (láti ṣe ọ́ ní aburú).
Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn t’ó di yẹhudi, - àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn kristiẹni, - ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, tí ó sì ṣiṣẹ́ rere, kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:62.
A kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan.
Wọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró; wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Mọsīh sì sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí."
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta.” Kò sì sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l’ó máa jẹ àwọn t’ó di kèfèrí nínú wọn.
Nítorí náà, ṣé wọn kò níí ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, kí wọ́n sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Kí ni Mọsīh bí kò ṣe Òjíṣẹ́ kan. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Olódodo sì ni ìyá rẹ̀. Àwọn méjèèjì máa ń jẹ oúnjẹ. Wo bí A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà. Lẹ́yìn náà, wo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
Sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò ní ìkápá ìnira àti àǹfààní kan fun yín? Allāhu, Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”
Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, tí kì í ṣe (ẹ̀sìn) òdodo. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú ìjọ kan t’ó ti ṣìnà ṣíwájú (ìyẹn, àwọn yẹhudi). Wọ́n ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Wọ́n sì ṣìnà kúrò ní ojú ọ̀nà tààrà."
A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí ahọ́n (Ànábì) Dāwūd àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-àlà.
Wọn kì í kọ ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ láààrin ara wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì burú.
O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn t’ó ń ṣọ̀rẹ́ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà.
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Dájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.” Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo).
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: "Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo).
Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa fi wá sínú àwọn ẹni-ire."
Nítorí náà, nítorí ohun tí wọ́n sọ, Allāhu san wọ́n ní ẹ̀san pẹ̀lú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún àwọn olùṣe-rere.
Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
____________________
Al-Ƙur’ān pín ìjọ ƙristiẹni sí igun méjì; igun kìíní ni igun tí àwọn ìròyìn t’ó wà nínú āyah 82 sí 84 nínú sūrah yìí wà lára rẹ̀. Igun yìí ló padà máa ń gba ’Islām ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn. Igun yìí nìkan ló sì máa bá àwa mùsùlùmí wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 85 nínú sūrah yìí. Igun kejì ni igun kristiẹni tí kò ní àwọn ìròyìn wọ̀nyẹn lára. Igun yìí ló máa ń takú sínú ẹ̀sìn kristiẹni títí di ọjọ́ ikú wọn lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ti dé etí ìgbọ́ wọn. Igun yìí ló sì máa wà pẹ̀lú àwọn yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ nínú Iná gbére. Àti pé nígbà tí al-Ƙur’ān bá sọ pé “onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.” Igun méjèèjì yẹn náà l’ó ń sọ nípa wọn. Kíyè sí i, igun kristiẹni t’ó máa wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra kì í ṣe “katoliik” tàbí “ajẹ́rìí” tàbí “àtúnbí” tàbí “sẹ̀lẹ́” tàbí “kérúbù” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bí kò ṣe ẹnikẹ́ni nínú ìjọ kristiẹni tí ó bá ṣe bí ó ṣe wà nínú āyah 82 sí 84 nínú sūrah al-Mọ̄’idah yìí.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe sọ àwọn n̄ǹkan dáadáa tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fun yín di èèwọ̀. Ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn olùtayọ ẹnu-àlà.
Ẹ jẹ n̄ǹkan ẹ̀tọ́ t’ó dára nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fun yín. Àti pé ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀.
Allāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹnikẹ́ni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí, tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ Èṣù ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè.
Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́ Èṣù) ni?
Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu, ẹ tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Kí ẹ sì ṣọ́ra. Nítorí náà, tí ẹ bá gbúnrí, kí ẹ mọ̀ pé iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe àwọn Òjíṣẹ́ Wa.
Kò sí ìbáwí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.
____________________
Mímú ìbẹ̀rù Allāhu àti ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ wá ní àsọtúnsọ nínú āyah yìí ń tọ́ka sí lílékún ní ìbẹ̀rù Allāhu, ìgbàgbọ́ òdodo àti iṣẹ́ rere.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú Allāhu yóò fi kiní kan dan yín wò níbi ẹran-ìgbẹ́ tí ọwọ́ yín àti ọ̀kọ̀ yín bà (nínú aṣọ hurumi) nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni t’ó ń páyà Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ìtánràn rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó jẹ́) ẹran ìtánràn tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí ààrọ̀ ìyẹn ni ààwẹ̀, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun t’ó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ hurumi), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
Wọ́n ṣe odò dídẹ àti jíjẹ oúnjẹ (òkúǹbete) inú rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fun yín. N̄ǹkan ìgbádùn ni fún ẹ̀yin àti àwọn onírìn-àjò. Wọ́n sì ṣe ìgbẹ́ dídẹ ní èèwọ̀ fun yín nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọ́n máa ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Allāhu ṣe Kaaba, Ilé Haram, ní àyè ààbò fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Kò sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ náà bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
Sọ pé: “Ohun burúkú àti ohun dáadáa kò dọ́gba, púpọ̀ ohun burúkú ìbáà jọ ọ́ lójú”. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè, nítorí kí ẹ lè jèrè.”
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe máa bèèrè nípa àwọn n̄ǹkan sá. Tí A bá fi hàn yín, ó máa kó ìpalára ba yín. Tí ẹ bá sì bèèrè nípa (àwọn n̄ǹkan t’ó yẹ láti bèèrè nípa ẹ̀sìn) nígbà tí À ń sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ lọ́wọ́, A máa fi hàn yín. Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
____________________
Ìyẹn ni pé, ìbéèrè tí ẹ bi Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) léèrè tí ó lè yọrí sí kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ n̄ǹkan ní ọ̀ran-anyàn fun yín, ohun tí kì í ṣe ọ̀ran-anyàn tẹ́lẹ̀ nínú ẹ̀sìn, Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀ fun yín. Kò sì níí tipasẹ̀ ìbéèrè yín ṣe àwọn n̄ǹkan náà ní ọ̀ran-anyàn nítorí kí ẹ má baà kó ara yín sínú ìpalára.
Ìjọ kan kúkú ti bèèrè rẹ̀ ṣíwájú yín. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.
Allāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā’ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
____________________
Ìwọ̀nyí ni orúkọ tí àwọn Lárúbáwá fún àwọn ẹran-ọ̀sìn tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì ka àwọn ẹran náà kún ẹran òrìṣà.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà.” Wọ́n á wí pé: “Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?
____________________
Ìyẹn nígbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti kó ẹjọ́ lọ bá a nídìí sàréè rẹ̀. Nítorí náà, ní àsìkò tiwa yìí gbígbé ẹjọ́ lọ sí ilé-ẹjọ́ Ṣẹria ’Islām àti ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ ’Islām tí wọ́n jẹ́ onisunnah lọ̀rọ̀ kàn. Èyí sì ni àgbọ́yé āyah náà. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:64 àti sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:101.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀nà. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Nígbà náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín. Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) "A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀."
Tí wọ́n bá sì rí i pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà), kí àwọn méjì mìíràn nínú àwọn tí àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ ṣe àbósí sí (ìyẹn, ẹbí òkú) rọ́pò wọn. Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: "Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-àlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí."
Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù lẹ́yìn ìbúra tiwọn. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Òfin yìí, òfin fífí àsọọ́lẹ̀ pín ogún fún ẹbí, ó jẹ́ òfin àkọ́kọ́ fún ogún pípín nínú ’Islām. Lẹ́yìn náà ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yanjú ìpín fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ẹbí òkú, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Nisā’; 4: 11-12 àti 176. Nítorí náà, Wọ́n ti pa ìdájọ́ āyah náà rẹ̀.
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó àwọn Òjíṣẹ́ jọ, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni èsì tí wọ́n fun yín?” Wọ́n á sọ pé: “Kò sí ìmọ̀ kan fún wa (nípa rẹ̀). Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.”
(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, ìjìnlẹ̀ òye, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo kó àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ ró, nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
____________________
Nínú āyah alápọ̀n-ọ́nlé yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu kan tí Ó fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe ní àsìkò t’ó fi jíṣẹ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Àwọn iṣẹ́ ìyanu náà nìwọ̀nyí; Ìkíní: Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló. Ìkejì: Ó fi amọ̀ mọ ẹyẹ, ó sì fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, ẹyẹ náà sì fò lọ. Ìkẹta: Ó wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn. Ìkẹrin: Ó mú àwọn òkú jáde ní alààyè láti inú sàréè, ìyẹn ni pé, ó jí òkú dìde. Iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 110 nínú sūrah yìí, sūrah al-Mọ̄’idah. Ìkarùn-ún: Ó sọ ọpọ́n oúnjẹ ńlá kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, wọ́n sì jẹ oúnjẹ àtọ̀runwá nílé ayé. Ìyẹn wà nínú āyah 114, nínú sūrah yìí bákan náà. Iṣẹ́ ìyanu yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi sọ sūrah yìí “al-Mọ̄’idah” lórúkọ. Ìkẹfà: Ó máa ń sọ àṣírí ohun tí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ lóúnjẹ àti èyí tí wọ́n gbé pamọ́ sínú ilé wọn. Ìyẹn wà nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:40. Èyí ni àwọn kristiẹni tún tìràn mọ́ gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọn. Wọ́n sì ń wí pé “Nítorí tí Jésù la’jú afọ́jú, tí ó wo adẹ́tẹ̀ sàn, tí ó fún ẹyẹ amọ̀ àti okú ènìyàn ní ẹ̀mí, nítorí náà, ìyè wà nínú Jésù, òun sì ni olúwa àti olùgbàlà nítorí pé kò tún sí ẹlòmíìràn t’ó ṣe irú rẹ̀ rí, kódà Muhammad.” Èsì: Ní àkọ́kọ́ náà, al-Ƙur’ān kò sọ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi agbára ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára àti ìyọ̀ǹda Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá. Èyí sì ní awẹ́ gbólóhùn “bi’ithnī” t’ó ń jẹyọ nínú āyah náà. Àti pé awẹ́ gbólóhùn “bi’ithnī” yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú wá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:38, sūrah Gọ̄fir; 40:78 àti sūrah al ‘Ani‘ām; 6:34-35. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rí báyìí, ti ta ni ògo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣé, ṣe tirẹ̀ ni tàbí t’Ọlọ́hun? Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá l’Ó ni ògo náà, kì í ṣe ti ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) rárá. Báwo wá ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe lè di olúwa nítorí iṣẹ́ tí Allāhu Ẹlẹ́dàá Rẹ̀ fún un ṣe! Bákan náà, àwọn onígbàgbọ́ òdodo t’ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn àwọn Ànábì (aleehim salām) kì í retí iṣẹ́ ìyanu, wọ́n kì í sì bèèrè fún un ṣíwájú kí wọ́n tó mọ Ọlọ́hun Òdodo ní Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ti tò wọn lórí ìgbàgbọ́ òdodo wọn àti ìjọ́sìn wọn. Àmọ́ nítorí àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn agbọ́mágbà, àwọn ọlọ́kàn-gíga tí wọ́n máa ń gbógun líle ti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ní àsìkò olúkùlùkù wọn ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe máa ń fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní àǹfààní iṣẹ́ ìyanu ṣe. Bí ó tilẹ̀ já sí pé kò sí ẹ̀dá tí ìṣẹ̀dá rẹ̀ kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu Allāhu, àìláròjinlẹ̀ ènìyàn l’ó tún fi ń wá iṣẹ́ ìyanu mìíràn kiri kí ó tó lè mọ Allāhu ní Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Ìdí nìyí tí al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi ń darí wa síbi wíwo àwọn iṣẹ́ ìyanu t’ara wa gan-an, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah ath-Thāriyāt; 51:21. “Nínú ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni?” Lẹ́yìn náà, kò fẹ́ẹ̀ sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu rán níṣẹ́, tí Allāhu kò níí fún un ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ máa jẹmọ́ àsìkò àti irú àwọn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ sí. Ẹ jẹ́ kí a wòye sí àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ: Al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, nínú sūrah Hūd; 11:37-48 àti sūrah al-Mu’minūn; 23: 27-30, ó fi iṣẹ́ ìyanu kíkan ọkọ̀ ojú-omi rinlẹ̀ fún Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́, Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ní àsìkò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kọ́kọ́ pa ilé ayé rẹ́ pẹ̀lú omi ìyanu. Ṣebí ọkọ̀ ojú-omi tí Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn nígbà náà ni Allāhu fi ṣe ìgbàlà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lásìkò náà. Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni ìbá kúkú lẹ́tọ̀ọ́ sí oríkì olùgbàlà aráyé nípasẹ̀ ọ̀kọ̀ ìgbàlà rẹ̀. Àmọ́ a ò lè pè é ní olùgbàlà nítorí pé, pẹ̀lú ìyọ̀ǹda, àṣẹ, ògo àti agbára Allāhu l’ó lò fún kíkan ọkọ̀ ojú-omi ńlá náà àti wíwa ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí èbúté ayọ̀, láì kọ́ ẹ̀kọ́ kíkàn àti wíwà tẹ́lẹ̀, - Allāhu ’akbar. Bákan náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi iṣẹ́ ìyanu méjì rinlẹ̀ fún ẹni tí àwọn kristiẹni mọ̀ sí “Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́”, Ọ̀rẹ́ Àyò Ọlọ́hun “kọlīlu-llāh”, Baba-ńlá àwọn Òjíṣẹ́, Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkíní: Nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:68-69 láti ka ìtàn nípa bí àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe ju Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sínú iná ńlá láti gbẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́ iná náà di ohun tútù àlàáfíà fún Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìkejì: Nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:260 láti ka ìṣẹ̀lẹ̀ kan nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pé, ó pa oríṣi ẹyẹ mẹ́rin, ó gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn, ó sọ wọ́n di lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, ó bù ú díẹ̀díẹ̀, ó sì bò wọ́n mọ́’nú ilẹ̀ ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí pe ẹyẹ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, eegun àti ẹran ara ẹyẹ kọ̀ọ̀kan sì bẹ̀rẹ̀ sí parapọ̀ lójú rẹ̀. Àwọn òkú ẹyẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó ti gún kúnná, tí ó sì ti bò mọ́lẹ̀ sì padà sípò aláàyè, - Allāhu ’akbar. - Ṣé ẹ rí i báyìí pé, Ànábì ’Ibrọ̄hīm náà ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe iṣẹ́ ìyanu. Òun náà jí òkú ẹyẹ dìde? Kódà Ànábì ’Ibrọ̄hīm kò wulẹ̀ mọ ọ̀bọrọgidi kan kan bí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) alámọ̀-ẹyẹ ti ṣe. Àní sẹ́, Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò kúkú ṣẹ̀ṣẹ̀ fátẹ́gùn kan kan sínú àwọn ẹyẹ náà kí wọ́n tó di aláàyè padà. Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn pè wọ́n ní ìkọ̀ọ̀kan, wọ́n sì jẹ́pè rẹ̀. Ti ta ni ògo àti agbára wọ̀nyí bí kò ṣe ti Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Lẹ́yìn náà, Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé fi àwọn iṣẹ́ ìyanu kan ròyìn òun náà. Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń lo ọ̀pá rẹ̀ láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá náà ṣe di ejò, tí ejò náà sì kó gbogbo idán kàbìtì-kàbìtì tí àwọn òpìdán Fir‘aon pa kalẹ̀. Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tún fi ọ̀pá yìí pín agbami odò ńlá sí méjì pẹ̀lú àwọn ojú-ọ̀nà gbòòrò láààrin rẹ̀ fún ìgbàlà àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ ìyà Fir‘aon. Ó sì tún fi pa odò náà dé papọ̀ mọ́ra wọn fún ìparun Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Bákan náà, Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi burè ẹran ara màálù “baƙọrah” jí òkú díde, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:73. Iṣẹ́ ìyanu yìí gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi sọ sūrah yìí ní “al-Baƙọrah” - “màálù”. – Sūrah yìí sì tún ni ọgbà ọ̀rọ̀ t’ó ní ẹsẹ ọ̀rọ̀ t’ó pọ̀ jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbogbo ìwọ̀nyí kò sọ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa àti olùgbàlà, tòhun ti bí ó tún ṣe gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn Fir‘aon. Síwájú sí i, ní ti Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Allāhu fún òun náà ní àwọn iṣẹ́ ìyanu kan ṣe, àmọ́ èyí t’ó ga jùlọ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu náà ni ààbò mímọ́ tí Allāhu fi bo al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Èyí ń jẹ́ iṣẹ́ ìyanu t’ó ga jùlọ nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí: Ìkíní ni pé, gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún àwọn Ànábì t’ó ṣíwájú l’ó ti lọ. Gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu wọn sì ti di ìtàn gẹ́gẹ́ bí àwọn fúnra wọn ti ṣe di ẹni-ìtàn rere. Al-Ƙur’ān nìkan ni kò níí di ìtàn láéláé. Ìkejì: òǹkà díẹ̀díẹ̀ ló kúkú gbà fún àwọn Ànábì oníṣẹ́-ìyanu wọ̀nyẹn. Ṣebí tòhun ti àwọn iṣẹ́ ìyanu ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bíi ènìyàn méjìlá lọmọ-lẹ́yìn rẹ̀ lójú ayé rẹ̀. Ẹ wo ọmọ-lẹ́yìn púpọ̀ tí al-Ƙur’ān mú wá fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lójú ayé rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu wo ni àwọn ènìyàn gbàgbọ́ nínú rẹ̀ tó báyìí? Kò sí. Tí mo bá tún wá mẹ́nu lé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ṣe, ó máa gba ojú-ewé púpọ̀. Àmọ́ èròǹgbà àwọn aláìmọ̀kan ni pé, nígbà tí wọn kò ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kà nínú al-Ƙur’ān, wọ́n ti lérò pé kò rí iṣẹ́ ìyanu kan kan ṣe, irú èyí tí wọ́n ń wá kiri bí ẹni tí ń wá ìwo ẹṣin kiri. Ẹ lọ ka àwọn tírà lórí rẹ̀. Òdidi tírà ni àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ṣe lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bákan náà, nínú sūrah Yūsuf; 12: 26-27 ni a ti ka ìtàn nípa ọmọ òpóǹló tí òun náà sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ nígbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìbàjẹ́ àti ìbani-lórúkọjẹ́ kan Ànábì Yūsuf ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ níbi ẹ̀sùn náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu ọmọ òpóǹló náà. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ló sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló. Wàyí, kókó ọ̀rọ̀ wa ni pé, iṣẹ́ ìyanu kan kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan di olúwa àti olùgbàlà. Èyí sì ni òdodo ọ̀rọ̀ pọ́nńbélé tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rinlẹ̀ nípa àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (aleehim sọlāt wa salām) fún àwọn tí kò bá fẹ́ tara wọn wọ inú Iná gbére l’ọ́jọ́ Àjíǹde. Ẹ kà á nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:79-80.
(Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.”
(Rántí) nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ǹjẹ́ Olúwa rẹ lè sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ láti sánmọ̀?” Ó sọ pé: "Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
Wọ́n sọ pé: “A fẹ́ jẹ nínú rẹ̀, a sì fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, kí á sì lè mọ̀ pé o ti sọ òdodo fún wa. A sì máa wà nínú àwọn olùjẹ́rìí.”
‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Allāhu, Olúwa wa, sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti inú sánmọ̀, kí ó jẹ́ ọdún fún ẹni àkọ́kọ́ wa àti ẹni ìkẹ́yìn wa.1 Kí ó sì jẹ́ àmì kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Pèsè fún wa, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè."2
____________________
1 Ìyẹn ni pé, ọjọ́ náà máa di ọjọ́ ọdún fún ìjọ Ànábì ‘Īsā (alaehi sọlātu wa salām), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò tirẹ̀ ti lọ. 2 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Allāhu sọ pé: “Dájúdájú Èmi yóò sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fun yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn náà nínú yín, dájúdájú Mo máa jẹ ẹ́ níyà kan tí Mi ò fi jẹ ẹnì kan rí nínú gbogbo ẹ̀dá.”
(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: "Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?" Ó sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. N̄g ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.
Èmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín." Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Lórí ìtúmọ̀ “تَوَفَّيْتَنِى فَلَمَّا” (falammọ̄ tawaffaetanī), ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:55.
Tí O bá jẹ wọ́n níyà, dájúdájú ẹrú Rẹ ni wọ́n. Tí O bá sì forí jìn wọ́n, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Allāhu sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ tí òdodo àwọn olódodo yóò ṣe wọ́n ní àǹfààní. Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú wọn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Icon