ترجمة سورة القدر

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة القدر باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Òru Abiyì?
Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù lọ.
Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.
Icon