ترجمة معاني سورة المرسلات
 باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
            .
            
                                    من تأليف: 
                                            أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
                                                            .
                                                
            
                                                                                                            ﰡ
                                                                                        
                    
                                                                                    Allāhu búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ó búra pẹ̀lú àwọn ìjì atẹ́gùn t’ó ń jà.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ó búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń tú èṣújò ká.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ó búra pẹ̀lú àwọn t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́).
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    (Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fun yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́, 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù, 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ, (Àkókò náà ti dé nìyẹn). 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà? 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ṣé A ò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ) 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀). (Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá t’ó dára. 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun t’ó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    (ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fun yín ní omi dídùn mu.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè t’ó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    (Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    A ò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́. 
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
                                                                         
                                                                                                                                        
                    
                                                                                    Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? 
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:185.