ترجمة سورة الإخلاص

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الإخلاص باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.
Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn).
Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.
Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́."
____________________
Ẹ kíyè sí i! Àwọn kan máa ń ké “Ƙul huwa-llāhu” mẹ́ta fún òkú mùsùlùmí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè ké òdidi al-Ƙur’ān fún un. Ìwọ̀nyí kò tọ sunnah rárá. Sūrah al-Haṣr; 59:10 ti fún wa ní àdúà t’ó jẹmọ́ òkú àti alààyè.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun” ni “Olúwa gbogbo ayé àti ọ̀run àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Nínú èdè al-Ƙur’ān, èyí ni a mọ̀ sí “rọbbu-ssamọ̄wāt wal-’ard wa mọ̄ baenahumọ̄”. Ìdí nìyí tí a ò fi túmọ̀ “Allāhu” sí “Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò fẹ́ẹ̀ sí ìtúmọ̀ tí a fọkàn balẹ̀ sí fún ọ̀rọ̀-orúkọ ńlá náà “Allāhu” àfi lílo ọ̀rọ̀-orúkọ kan èyí tí àwọn Yorùbá máa ń lò ní ọjọ́un àná fún “Ọlọ́hun”. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí máa mú àríyànjiyàn lọ́wọ́. Nítorí náà, “Allāhu” ni “Allāhu”.
Icon