ترجمة سورة البقرة

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة البقرة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

’Alif lām mīm.
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām máa ń sọ pé irúfẹ́ àwọn lẹ́tà (háràfí) wọ̀nyí dúró fún àwọn ọ̀rọ̀ kan, ohun tí àwọn onímọ̀ ’Islām faramọ́ jùlọ ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí Ó gbà lérò pẹ̀lú àwọn harafi náà.
Èyí ni Tírà náà, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu);
àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú (ìró) ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn,
____________________
Ìró ìkọ̀kọ̀ ni ohunkóhun tí ’Islām mú wá ní ìró nípa Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), àwọn mọlāika, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, Ọgbà Ìdẹ̀ra, Iná àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́. Ìwọ́nyí ni àwọn ohun tí a ò lè fojú rí ní ilé ayé, àmọ́ tí ó jẹ́ òdodo pọ́nńbélé, tí a gbọ́dọ̀ gbágbọ́, nítorí kí á lè jẹ́ ara àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
àti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
____________________
Ìgbàkígbà tí àwọn kristiẹni bá ka irú āyah yìí nínú al-Ƙur’ān, wọ́n a wí pé: “Al-Ƙur’ān gan-an sọ pé àwa mùsùlùmí gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú bíbélì!” Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu kò dárúkọ bíbélì nínú al-Ƙur’ān. Orúkọ àwọn tírà mímọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú al-Ƙur’ān ni Zabūr, Suhuf, ’Injīl àti Taorāt. Lẹ́yìn náà, ìkọ̀ọ̀kan àwọn tírà wọ̀nyẹn l’ó wà fún ìjọ Ànábì tí Allāhu fún nìkan, kò sì kan ìjọ mìíràn lẹ́yìn wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé ìjọ yẹn nìkan ni Allāhu rán Ànábì tí ọ̀rọ̀ kan sí. Lẹ́yìn náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rinlẹ̀ nínú al-Ƙur’ān pé kò sí ojúlówó àwọn tírà náà mọ́ níta, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:75 & 79, sūrah an-Nisā’; 4:46 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Lóde òní yìí, bíbélì ti lé ní oríṣi ọgbọ̀n! Wàyí, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti rinlẹ̀ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ àwọn tírà kan kalẹ̀ fún àwọn Ànábì kan t’ó ṣíwájú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), mùsùlùmí gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé Allāhu fún àwọn Ànábì kan ní tírà, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé mùsùlùmí yóò sọ tírà náà di ohun tí yóò máa kà áḿbọ̀sìbọ́sí pé yóò tẹ̀lé wọn. Nítorí náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ni tírà ìkẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún gbogbo ẹ̀dá. Kò sí òmíràn mọ́.
Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o ò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́.
Allāhu fi èdídí dí ọkàn wọn àti ìgbọ́rọ̀ wọn. Èbìbò sì bo ìríran wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Wọ́n ń tan Allāhu àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo jẹ. Wọn kò sì lè tan ẹnì kan jẹ bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.
Àrùn kan wà nínú ọkàn wọn, nítorí náà Allāhu ṣe àlékún àrùn fún wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn nítorí pé wọ́n ń parọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Àwa ni alátùn-únṣe.”
Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òbìlẹ̀jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò fura.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ ní òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́.” Wọ́n á wí pé: “Ṣé kí á gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn òmùgọ̀ ṣe gbàgbọ́ ni?” Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òmùgọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì kù wọ́n ku àwọn (ẹni) èṣù wọn, wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwa ń bẹ pẹ̀lú yín, àwa kàn ń ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”
Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
____________________
Kì í ṣe gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ ni ó máa di orúkọ Rẹ̀ àfi èyí tí Allāhu bá fúnra Rẹ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ̀ nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí:
Ìdí àkọ́kọ́: Nínú ìdí tí a ò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn ìṣe kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn ìṣe náà jẹ́ ìṣe t’ó dúró sórí fífi orúkọ ìṣe ẹ̀dá sọ orúkọ ẹ̀san ìṣe náà. Irú rẹ̀ l’ó ṣẹlẹ̀ nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe olùṣeyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ó máa ń ṣe yẹ̀yẹ́) tàbí oníyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ẹ̀dá lè fi ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹnì kan kò sì níí máa ṣe yẹ̀yẹ́ àfi kí ó jẹ́ aláwàdà, oníranù. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe àwàdà, kì í sì ṣe ìranù. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ aláwàdà, oníranù. Nítorí náà, kò sí orúkọ ẹ̀san tí a lè fún ẹni tí ó bá ń fi Allāhu tàbí āyah Rẹ̀ tàbí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san yẹ̀yẹ́ ni ẹ̀san olùṣeyẹ̀yẹ́.
Síwájú sí i, irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’ 4:142. Àwọn munāfiki ni ẹlẹ́tàn, Allāhu kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ẹnì kan kò níí jẹ́ ẹlẹ́tàn àfi kí ó jẹ́ òpùrọ́, olùyapa-àdéhùn. Allāhu kì í ṣe òpùrọ́. Allāhu gan-an ni Òdodo. Bákan náà, Allāhu ni Olùmú-àdéhùn-ṣẹ. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá bá lérò pé òun lè tan Allāhu, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba, ohun tí ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu kò níí jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ẹ̀dẹ. Ìyẹn ni pé, Allāhu yóò máa jẹ́ kí ẹlẹ́tàn náà lérò pé, òjé òun ń jẹ Allāhu ni àṣírí òun kò fi tú síta. Kò sì sí òjé kan kan tí ó lè jẹ Allāhu. Ohun tí ẹlẹ́tàn ń ṣe ni ó rí ní ẹ̀san. Báyìí náà ni ọ̀rọ̀ ṣe rí lórí àwọn āyah tí Allāhu ti fi “mọkr” àti “kaed” (ìyẹn, ète) ròyìn Ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àwọn āyah wọ̀nyí: sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:99, sūrah Yūnus; 10:21, sūrah ar-Ra‘d; 13:42, sūrah at-Tọ̄riƙ; 86:16. Irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ nínú sūrah as-Sajdah; 32:14. Ìyẹn ni pé, ìgbàgbé ni ẹ̀san ìgbàgbé, kì í ṣe pé Allāhu jẹ́ onígbàgbé (ẹni t’ó máa ń gbàgbé n̄ǹkan) tàbí ẹni tí ó yẹ kí ẹ̀dá gbàgbé. Ẹni tí wọ́n bá kọ́ ní ẹ̀kọ́, tí ó sì gbàgbé rẹ̀ tàbí ẹni tí inú rẹ̀ bá bu ni onígbàgbé. Allāhu mọ́, Ó sì ga tayọ ìwọ̀nyẹn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbàgbé Allāhu nílé ayé ni ẹni tí ó pa Allāhu tì, tí kò sì jọ́sìn fún Un. Kí ni ó máa jẹ́ ẹ̀san rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe pé kí Allāhu pa òun náà tì sínú ìyà Iná gbére. Ìyẹn ni pé, Allāhu kò níí fún un ní àǹfààní kan kan láti jáde kúrò nínú Iná. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Allāhu máa ń gbàgbé bí? Rárá o. Ṣebí ohun tí àgbẹ̀ bá gbìn sínú ilẹ̀ l’ó máa ká lérè oko. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní “muṣākalah” ìfiṣẹ́jẹ̀san-anṣẹ́ (ìfi iṣẹ́ jọ ẹ̀san iṣẹ́).
Ìdí kejì: Nínú ìdí tí a ò gbọ́dọ̀ fi sọ gbogbo ìṣe tí Allāhu bá fi ròyìn Ara Rẹ̀ di orúkọ Rẹ̀ ni pé, Allāhu fi àwọn iṣẹ́ kan ròyìn Ara Rẹ̀, tí àwọn iṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́ t’ó dúró sórí fífi gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀ kún iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá nítorí iṣẹ́ náà lè di òhun. Mùsùlùmí kò sì gbọ́dọ̀ sọ irúfẹ́ iṣẹ́ náà di orúkọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Irú rẹ̀ l’ó ṣẹlẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:17. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í fi Ọwọ́ ara Rẹ̀ jùkò. Òkò tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì jù lu àwọn ọ̀tá lójú ogun kì í ṣe òkò tí ó lè gba ẹ̀mí lára ènìyàn. Àmọ́ òkò náà gba ẹ̀mí wọn pẹ̀lú “kunfayakūn” Allāhu. Ṣé a wa lè pe Allāhu ní òǹjùkò bí nítorí pé Ó fi iṣẹ́ òkò jíjù ròyìn Ara Rẹ̀. Rárá.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà. Nítorí náà, òkòwò wọn kò lérè, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
Àpèjúwe wọn dà bí àpèjúwe ẹni tí ó tan iná, ṣùgbọ́n nígbà tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí àyíká rẹ̀ tán, Allāhu mú ìmọ́lẹ̀ wọn lọ, Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àwọn òkùnkùn; wọn kò sì ríran mọ́.
Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; nítorí náà wọn kò níí ṣẹ́rí padà.
Tàbí (àpèjúwe wọn) dà bí òjò ńlá tí ń rọ̀ láti sánmọ̀. Ó mú àwọn òkùnkùn, àrá sísán àti mọ̀nàmọ́ná lọ́wọ́. Wọ́n ń fi ìka wọn sínú etí wọn nítorí igbe àrá sísán fún ìbẹ̀rù ikú. Allāhu sì yí àwọn aláìgbàgbọ́ ká.
Mọ̀nàmọ́ná náà fẹ́ẹ̀ mú ìríran wọn lọ. Nígbàkígbà tí ó bá tan ìmọ́lẹ̀ sí wọn, wọ́n á rìn lọ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì ṣóòòkùn mọ́ wọn, wọ́n á dúró si. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá gba ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná).
____________________
Kalmọh “لَعَلَّ” “la‘lla” ní ìtúmọ̀ mẹ́ta. Ìrètí, nítorí àti ìgbájúmọ́. “Ƙurtubiy”
(Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́).
Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Tí ẹ ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò wulẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Nígbàkígbà tí A bá p’èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: “Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” – Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). – Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Dájúdájú Allāhu kò níí tijú láti fí ohun kan bí ẹ̀fọn tàbí ohun tí ó jù ú lọ ṣàkàwé ọ̀rọ̀. Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò wí pé: “Kí ni ohun tí Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àkàwé yìí?” Allāhu ń fi ṣi lọ́nà. Ó sì ń fi tọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sọ́nà. Kò sì níí fi ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àyàfi àwọn arúfin.
Àwọn t’ó ń yẹ májẹ̀mu Allāhu lẹ́yìn tí májẹ̀mu náà ti fìdí múlẹ̀, wọ́n tún ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Gọ̄fir; 40:11.
Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ fun yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó wà l’ókè sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Àwọn kristiẹni wí pé, “Sūrah al-Baƙọrah; 2:29 tako sūrah an-Nāzi‘āt; 79:27-30 nítorí pé, ìkíní ń sọ pé ilẹ̀ ni Allāhu kọ́kọ́ dá ṣíwájú sánmọ̀, ìkejì sì ń sọ pé sánmọ̀ ni Allāhu kọ́kọ́ dá ṣíwájú ilẹ̀!”
Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí, ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ṣíwájú ìṣẹ̀dá sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah inú sūrah Baƙọrah yẹn ṣe fi rinlẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ni āyah sūrah an-Nāzi‘āt ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sì lo ọ̀rọ̀ t’ó túmọ̀ sí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ nínú āyah t’Ó ti dárúkọ ilẹ̀, ìyẹn āyah 30 nínú sūrah
an-Nāzi‘āt. Kalmọh “dahāhā” ni Allāhu lò níbẹ̀ fún ilẹ̀. Ìtúmọ̀ “dahāhā” sì ni pé “Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ”. Ẹ tún wo sūrah al-Hijr; 15:19. Àlàyé tí àwọn onímọ̀ ’Islām mú wá nípa èyí ni pé, ìṣẹ̀dá ilẹ̀ wáyé fún ọjọ́ méjì. Lẹ́yìn náà, ìṣẹ̀dá gbogbo ohun t’ó máa wà nínú ilẹ̀ ní àwọn igi, àwọn ibúdò, àwọn àpáta, àwọn àlùmọ́nì ilẹ̀, àwọn oúnjẹ ènìyàn, àwọn oúnjẹ àlùjànnú àti àwọn oúnjẹ gbogbo abẹ̀mí wáyé fún ọjọ́ méjì. Lẹ́yìn náà, ìṣẹ̀dá sánmọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹrù inú rẹ̀ ní àwọn ìràwọ̀, òṣùpá, òòrùn àti òjò wáyé fún ọjọ́ méjì. Àpapọ̀ gbogbo ọjọ́ ìṣẹ̀dá wọ̀nyí jẹ́ ọjọ́ mẹ́fà. Àmọ́, ilẹ̀ tòhun ti àwọn ẹrù inú rẹ̀ sì wà roboto títí Allāhu fi parí ìṣẹ̀dá sánmọ̀. Sísọ ilẹ̀ roboto di ilẹ̀ pẹrẹsẹ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀dá sánmọ̀. Ohun tí ó sì fa èyí ni pé, ilẹ̀ bùkátà sí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti ìmọ́lẹ̀ òòrùn nítorí kí àwọn ohun gbogbo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ṣẹ̀dá sínú ilẹ̀ lè máa gbèrú sí i. Báyìí ni Allāhu ṣe tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ fún òṣùpá, ìràwọ̀ àti òòrùn nítorí kí wọ́n lè rí iṣẹ́ ṣe lára ilẹ̀, Ó sì fi àwọn àpáta inú ilẹ̀ ṣe èṣó t’Ó fi kan ilẹ̀ nítorí kí àwọn ibúdò má lè yí ilẹ̀ dànù. Nítorí náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti parí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ ṣíwájú ìṣẹ̀dá sánmọ̀. Àmọ́ Ó sọ ilẹ̀ roboto di ilẹ̀ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìṣẹ̀dá sánmọ̀. Kì í ṣe pé Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ lẹ́yìn sánmọ̀. Àkàwé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dà bíi kíkọ́ ilé àti ṣíṣí ilé. Kò sí oníṣirò tí ó máa ṣí ọjọ́ ìkọ́lé mọ́ ọjọ́ ìṣílé àfi ẹni tí kò bá yanjú nínú ẹ̀kọ́ ìṣírò. Nítorí náà, kò sí ìtakora tóríbẹ́ẹ̀ nínú àwọn āyah náà. W-Allāhu ’a‘lam.
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.” Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa tẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Ọ. A sì ń fi ògo fún Ọ!" Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”
____________________
Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ́ àrólé nítorí pé, ó jẹ́ ẹ̀dá tí yóò máa bímọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ náà yóò máa bímọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mọlāika kò sì lè jẹ́ àrólé nítorí pé, bíbí ọmọ kò sí nínú ìṣẹ̀dá tiwọn.
Allāhu fi àwọn orúkọ náà, gbogbo wọn pátápátá, mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ wọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fun yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.
____________________
’Iblīs ni àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣaetọ̄n. Àwọn kan kà á mọ́ ara àwọn mọlāika. Wọ́n tún lérò pé Ṣaetọ̄n jẹ́ onímọ̀-jùlọ àti olùjọ́sìn-jùlọ láààrin àwọn mọlāika ṣíwájú kí ó tó di ẹni-ẹ̀kọ̀. Àmọ́ sá, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹyọ kan nínú àwọn àlùjànnú ni ’Iblīs, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 18:50. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sì fi ìmọ̀ àti ìjọ́sìn ròyìn Ṣaetọ̄n rí.
A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”
____________________
Nípa èso tí Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jẹ, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Arọ̄f; 7:22.
Àmọ́ Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín lórí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).”
Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
A sọ pé :“Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
____________________
Kíyè sí i, nígbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” dípò “ẹyọ” fún ara Rẹ̀, kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́hun pọ̀ ní òǹkà. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ lè dúró fún ọ̀pọ̀ ní òǹkà tàbí àpọ́nlé. Ibikíbi tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ti lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” nínú al-Ƙur’ān tàbí ọ̀rọ̀-orúkọ “ọ̀pọ̀” tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe “ọ̀pọ̀”, kò túmọ̀ sí Ọlọ́hun púpọ̀ rárá. Àmọ́ Ó ń ṣe àpọ́nlé fún iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ ni. Kí èyí lè dájú pé ìwọ̀nyí kò túmọ̀ sí Ọlọ́hun púpọ̀, ṣebí ìtúmọ̀ ọlọ́hun ni ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún tàbí ẹni tí wọ́n ń bọ, ìdí nìyí t’ó fi jẹ́ pé ibikíbi tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ti sọ̀rọ̀ kan jíjọ́sìn fún Un kì í lo ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ kan àfi “ẹyọ”. Èyí l’ó fi rinlẹ̀ pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí, àmọ́ Ó lè lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ “Àwa” fún ara Rẹ̀ ní ti ìtúmọ̀ àpọ́nlé.
Àwọn t’ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.”
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo ṣe fun yín. Ẹ mú májẹ̀mu Mi ṣẹ, Mo máa mú (ẹ̀san) májẹ̀mu yín ṣẹ. Èmi nìkan ni kí ẹ sì páyà.
____________________
Ibn ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) sọ pé: “Nínú èdè ‘Abrāniyyah (Hébérù), “’Isrọ̄” túmọ̀ sí “ẹrú”, “ ’īl” sì túmọ̀ sí “Allāhu”. Èyí já sí pé, “ẹrú Allāhu” ni ìtúmọ̀ “’Isrọ̄’īl”. (Tọbariy)
Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi l’ówó pọ́ọ́kú.Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.
____________________
Títa āyah Taorāt àti ’Injīl “bíbélì” lówó pọ́ọ́kú ni títi ọwọ́ bọ̀ ọ́ lójú nítorí kí wọ́n lè jáde kúrò lábẹ́ òfin Ọlọ́hun fún ìgbádùn ayé.
Ẹ má da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì má fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo).
Ẹ kírun, ẹ yọ zakāh, kí ẹ sì dáwọ́ tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
Ṣé ẹ̀yin yóò máa pa àwọn ènìyàn l’áṣẹ ohun rere, ẹ sì ń gbàgbé ẹ̀mí ara yín, ẹ̀yin sì ń ké Tírà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!
Ẹ wá oore (Allāhu) pẹ̀lú sùúrù àti ìrun kíkí. Dájúdájú ó lágbára (láti ṣe bẹ́ẹ̀) àyàfi fún àwọn olùpáyà (Allāhu),
____________________
Mẹ́ta ni sùúrù yìí pín sí. Ìkíní: Dídúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn ’Islām. Ìkejì: Ṣíṣe ìfaradà lórí àdánwò àti níní àtẹ̀mọ́ra ìnira. Ìkẹta: Sísá fún ẹ̀ṣẹ̀.
àwọn t’ó mọ̀ pé dájúdájú àwọn yóò pàdé Olúwa wọn, àti pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo fi ṣèdẹ̀ra fun yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fun yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò níí gba ìṣìpẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.1 A ò sì níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.2
____________________
1 Ìyẹn ni pé, lọ́jọ́ Àjíǹde dúkìá kan kan kò níí wúlò fún ìràpadà ẹ̀mí níbi Iná àfi iṣẹ́ rere tí í ṣe ìjọ́sìn fún Allāhu àti ìwà rere t’ó tọ sunnah.
2 Àwọn kristiẹni sọ pé, “Àwọn āyah kan sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ lọ́jọ́ Àjíǹde, àwọn āyah mìíràn sọ pé ìṣìpẹ̀ wà.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn.”
Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí. Àwọn āyah t’ó ń sọ pé kò sí ìṣìpẹ̀ lọ́jọ́ Àjíǹde ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ajáni-ní-tànmọ́ọ̀n fún àwọn yẹhudi àti àwọn kristiẹni tí wọ́n ń fọkàn sí ìṣìpẹ̀ láì ṣe iṣẹ́ tí ó máa mú wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí ìṣìpẹ̀ àti àwọn ọ̀ṣẹbọ tí ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà tiwọn wulẹ̀ dúró sórí bíbọ ẹ̀dá kan nítorí kí ó lè ṣìpẹ̀ wọn lọ́jọ́ Àjíǹde. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:48, 123 àti 254 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:51. Àmọ́ àwọn āyah t’ó ń sọ pé ìṣìpẹ̀ máa wà lọ́jọ́ Àjíǹde ń sọ nípa àwọn májẹ̀mú tí ó wà fún ìṣìpẹ̀, olùṣìpẹ̀ àti olùṣìpẹ̀-fún. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah; 2:255, sūrah Tọ̄hā; 20:109, sūrah Saba’; 34:23, sūrah az-Zukruf; 43:86 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:70. Kíyè sí i, gbígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa gba ìṣìpẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kan fún àwọn kan kò kéré ipò agbára Allāhu, àmọ́ ipò tí ìbániṣàdúà wà ni ìṣìpẹ̀ wà. Nítorí náà, bí ó ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣàdúà, bẹ́ẹ̀ náà l’ó máa ní ẹ̀tọ́ láti bá ẹlòmíìràn ṣìpẹ̀ lọ́jọ́ Àjíǹde. Olùṣìpẹ̀ àkọ́kọ́ fún gbogbo ẹ̀dá sì ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ má ṣe fọkàn sí pé mùsùlùmí kan máa ṣìpẹ̀ rẹ tàbí pé o máa ṣìpẹ̀ mùsùlùmí kan nítorí pé, nínú ohun t’ó pamọ́ fún ẹ̀dá ni ìmọ̀ nípa ta gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa fi ìṣìpẹ̀ pọ́nlé nínú àwa ẹrúsìn Rẹ̀. Àdúà wa ni pé, kí Allāhu fi ìṣìpẹ̀ ṣe àpọ́nlé fún èmi àti ẹ̀yin.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.
(Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami odò sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fun yín, A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.
Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fun yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
(Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.
____________________
Kíyè sí i, al-Furƙọ̄n "ọ̀rọ̀-ìpínyà" (ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) jẹ́ ìròyìn àti àbùdá kan tí ń bẹ lára gbogbo tírà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún gbogbo àwọn Ànábì Rẹ̀ ('alaehim sọlātu wa salām). Kì í ṣe pé ọ̀tọ̀ ni Tírà, ọ̀tọ̀ ni Furƙọ̄n. Ìdí nìyí tí al-Furƙọ̄n fi jẹ́ orúkọ mìíràn fún al-Ƙur’ān.
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn t’ó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fun yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbà ọ́ gbọ́ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkorojú.” Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀.
Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
____________________
Ikú tí wọ́n kú yìí jẹ́ ikú ìbáwí (bí irú ikú tí Allāhu s.w.t. sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah yìí kan náà, nínú āyah 259), kì í ṣe ikú òpin ìṣẹ̀mí tí ń kò lé gbogbo ẹ̀dá lórí n’ílé ayé. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ta wọ́n jí padà s’ílé ayé kí wọ́n lè parí òǹkà àsìkò tí Ó ti bù fún ìṣẹ̀mí ayé wọn. Ẹ̀dá kan kò níí kú ikú òpin ìṣẹ̀mí kí ó tún padà s’ílé ayé mọ́. Nítorí náà, kò sí àkúdàáyà. Ète àwọn àlùjànnú kan ni. Ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 154 nínú sūrah yìí.
A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fun yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnu àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fun yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba. Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.
Àwọn t’ó ṣàbòsí yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé àwọn t’ó ṣàbòsí lórí nítorí pé wọ́n ń rú òfin.
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā tọrọ omi fún ìjọ rẹ̀. A sì sọ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na òkúta.” Orísun omi méjìlá sì ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Ìran kọ̀ọ̀kan sì ti mọ ibùmu wọn. Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu nínú arísìkí Allāhu. Ẹ má balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí ṣe ìfaradà lórí oúnjẹ ẹyọ kan. Nítorí náà, pe Olúwa rẹ fún wa. Kí Ó mú jáde fún wa nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde bí ewébẹ̀ rẹ̀, kùkúḿbà rẹ̀, ọkà bàbà rẹ̀, ẹ̀wà rẹ̀ àti àlùbọ́sà rẹ̀.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò fi èyí tó yẹpẹrẹ pààrọ̀ èyí tí ó dára jùlọ ni? Ẹ sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú (mìíràn). Dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún ń bẹ (níbẹ̀) fun yín.” A sì mú ìyẹpẹrẹ àti òṣì bá wọn. Wọ́n sì padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n sì ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-àlà.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi, nasara àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
____________________
Irú āyah yìí tún wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:69 àti sūrah al- Hajj; 22:17. Àgbọ́yé rẹ̀ sì ni pé, kí àwa mùsùlùmí dúró ṣínṣín nínú ẹ̀sìn ’Islām. Kí á sì mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọ̀nà mìíràn fún àwọn yẹhudi, àwọn kristiẹni, àwọn mọjūs, àwọn sọ̄bi’u àti àwọn ọ̀ṣẹbọ bí kò ṣe ìgbàgbọ́ nínú Allāhu gẹ́gẹ́ bí àwa mùsùlùmí ṣe gbà Á gbọ́ àti ṣíṣe iṣẹ́ rere, tí í ṣe sunnah Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún ìdí pàtàkì mẹ́ta. Ìkíní: Kò sí ẹ̀sìn kan lọ́dọ̀ Allāhu àfi ’Islām (Ẹ wo sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:19, 85 àti sūrah al-Mọ̄’dah; 5:3.) Ìkejì: Kò sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu rán níṣẹ́ rí pẹ̀lú ẹ̀sìn mìíràn àfi ’Islām. (Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:140 àti 213.) Ìkẹta: Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pe ẹ̀sìn àwọn yẹhudi àti nasara ní ẹ̀sìn irọ́. (Ẹ wo sūrah at-Taobah; 9:29.) Bákan náà, láti ọ̀dọ̀ ’Abū Huraerah (rọdiyallāhu 'anhu), láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam), dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu sọ pé: “Èmi fi Ẹni tí ẹ̀mí Muhammad wà ní ọwọ́ Rẹ̀ búra; ẹnì kan nínú ìjọ yìí, yẹhudi tàbí nasara, kò níí gbọ́ nípa mi, lẹ́yìn náà kí ó kú láì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́, àfi kí ó jẹ́ ara èrò inú Iná.” (Muslim).
Ẹ rántí nígbà tí A gba àdéhùn yín, A sì gbé àpáta wá sókè orí yín, (A sì sọ pé): “Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáradára, kí ẹ sì rántí ohun t’ó wà nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín, ẹ̀yin ìbá wà nínú ẹni òfò.
Dájúdájú ẹ mọ àwọn t’ó kọjá ẹnu-àlà nínú yín nípa ọjọ́ Sabt. A sì sọ fún wọn pé: "Ẹ di ọ̀bọ, ẹni-ìgbéjìnnà sí ìkẹ́."
A sì ṣe é ní àríkọ́gbọ́n fún ẹni t’ó ṣojú rẹ̀ àti ẹni t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Ó tún jẹ́) ẹ̀kọ́ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa abo màálù kan.” Wọ́n wí pé: “Ṣé ò ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ni!” Ó sọ pé: "Mò ń sádi Allāhu níbi kí n̄g jẹ́ ara àwọn òpè."
Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, èwo ni.” Ó sọ pé: "Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ ògbólógbòó, kò sì níí jẹ́ gódógbó. Ó máa wà láààrin (méjèèjì) yẹn. Nítorí náà, ẹ ṣe ohun tí Wọ́n ń pa yín láṣẹ."
Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, kí ni àwọ̀ rẹ̀.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù, aláwọ̀ omi-ọsàn ni. Àwọ̀ rẹ̀ yó sì mọ́ fónífóní, tí ó máa dùn-ún wò l’ójú àwọn olùwòran.
Wọ́n wí pé: "Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, èwo ni. Dájúdájú àwọn abo màálù jọra wọn lójú wa. Àti pé dájúdájú, tí Allāhu bá fẹ́, àwa máa mọ̀nà (tí a ó gbà rí i.)"
Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ màálù yẹpẹrẹ tí ń roko. Kò sì níí máa fomi wọ́n oko. Ó máa ní àlàáfíà, kò sì níí ní àbàwọ́n kan lára.” Wọ́n wí pé: “Nísinsìn yìí l’o mú òdodo wá.” Wọ́n sì pa màálù náà. Wọ́n fẹ́ẹ̀ má ṣe é mọ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
____________________
Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Òkú náà sì ta jí. Ó tú àṣírí ẹni tí ó pa á. Ó sì kú padà. Báyìí ni Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jí òkú dìde pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle t’ó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Nínú èdè Lárúbáwá, ìtúmọ̀ “ ’ao” ni “tàbí”. Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, kò sì sí ọ̀rọ̀ tàbí-ṣùgbọ́n t’ó ń bí iyèméjì nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo àwọn ìtúmọ̀ ìjìnlẹ̀ fún“ ’ao”. (Ìkíní) Lárúbáwá ń lo “ ’ao” láti ṣe àfihàn ìwọ̀fún àti ìṣẹ̀ṣà láààrin n̄ǹkan méjì sókè. (Ìkejì) Wọ́n ń lo “ ’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ bá ń ṣiyèméjì nípa ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ. Ìlò yìí kò sì lè ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). (Ìkẹta) Wọ́n ń lo “ ’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ kò ṣiyèméjì nípa ohun tí ó ń sọ, àmọ́ tí kò fẹ́ kí olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ pàtó nípa ọ̀rọ̀ náà. Àpẹẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” t’ó jẹyọ nínú sūrah as-Sọffāt; 37:147. (Ìkẹrin) Wọ́n ń lo “’ao” nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ kò ṣiyèméjì nípa ohun tí ó ń sọ, tí ó sì ti fún olùbásọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àǹfààní láti mọ pàtó àti òkodoro ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí olùbásọ̀rọ̀ ń ṣe ìṣe aláìníkan-ánṣe tàbí aláìgbàgbọ́. Àpẹẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” t’ó jẹyọ nínú sūrah Saba’; 34:24. (Ìkarùn-ún) Wọ́n ń lo “ ’ao” láààrin ọ̀rọ̀ méjì sókè t’ó dúró fún ọ̀kan-ùn. Àpẹẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” t’ó jẹyọ nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:110. (Ìkẹfà) Wọ́n ń lo “wāwu-l-‘atf” fún “ ’ao” t’ó ń túmọ̀ sí “tàbí”. Àpẹẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “wāwu-l-‘atf” t’ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 àti Fātir; 35:1. (Ìkejè) Wọ́n ń lo “ ’ao” fún “bal” - “rárá” - nígbà tí òǹsọ̀rọ̀ bá fẹ́ bàbàrà ọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ ìlò yìí ni ìtúmọ̀ “ ’ao” t’ó jẹyọ nínú sūrah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Ìyẹn ni pé, ọkàn àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ìbá le bí òkúta ṣe le, ìrètí gbígba òdodo gbọ́ ìbá wà fún wọn nítorí pé bí òkúta ṣe le tó, ó ń sán, ó ń fọ́, tí omi àti n̄ǹkan rere mìíràn ń tibẹ̀ jáde. Àmọ́ ọkàn wọn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ńṣe ni ọkàn wọn le tayọ òkúta. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ni Alámọ̀tán nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Ǹjẹ́ ẹ lérò pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fun yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀?
Àti pé ó wà nínú wọn, àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, tí wọn kò nímọ̀ nípa Tírà àfi àwọn ọ̀rọ̀-irọ́. Kí ni wọ́n (ń sọ) bí kò ṣe pé wọ́n ń sàròsọ.
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ Tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ.
Wọ́n sì wí pé: “Iná kò lè fọwọ́ bà wá tayọ ọjọ́ t’ó lóǹkà.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ti rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Allāhu ni?”Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?
Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ‘Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù. Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah at-Taobah; 9:60.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín pé ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i.
____________________
Àdéhùn yìí wáyé láààrin Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn yẹhudi ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Nínú ìwé àdéhùn yìí, àwọn Mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi jọ gbà láti má ṣe gbé ìjà kora wọn. Wọ́n sì jọ gbà láti máa dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ọ̀tá òde. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí āyah 85 ṣe fi rinlẹ̀, àwọn yẹhudi gbàbọ̀dè, wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn Ƙuraeṣi tí wọ́n wá gbé ogun ti àwọn mùsùlùmí ní ìlú Mọdīnah.
Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin wọ̀nyí l’ẹ̀ ń p’ara yín. Ẹ tún ń lé apá kan nínú yín jáde kúrò nínú ilé wọn. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àti àbòsí ṣèrànwọ́ (fún àwọn ọ̀tá) lórí wọn. Tí wọ́n bá sì wá ba yín (tí wọ́n ti di) ẹrú, ẹ̀yin ń rà wọ́n (láti fi’ra yín ṣẹrú). Èèwọ̀ sì fẹ̀ẹ̀kan ni fun yín láti lé wọn jáde. Ṣé ẹ̀yin yóò gba apá kan Tírà gbọ́, ẹ sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan? Nítorí náà, kí ni ẹ̀san fún ẹni tó ṣè yẹn nínú yín bí kò ṣe àbùkù nínú ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọjọ́ Àjíǹde, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìyà tó le jùlọ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì mú àwọn Òjíṣẹ́ wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé lẹ́yìn rẹ̀. A tún fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A tún fún ní agbára nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, Mọlāika Jibrīl). Ṣé gbogbo ìgbà tí Òjíṣẹ́ kan bá wá ba yín pẹ̀lú ohun tí ọkàn yín kò fẹ́ ni ẹ ó máa ṣègbéraga? Ẹ sì pe apá kan (àwọn Ànábì) ní òpùrọ́, ẹ sì ń pa apá kan!
Wọ́n sì wí pé: “Èbìbò bò wá lọ́kàn.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Ṣebí díẹ̀ ni wọ́n ń gbàgbọ́.
Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́.
Aburú ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn nípa bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ní ti ìlara pé Allāhu ń sọ (Tírà) kalẹ̀ nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Wọ́n sì padà pẹ̀lú ìbínú (mìíràn) lórí ìbínú (Allāhu tí ó ti wà lórí wọn tẹ́lẹ̀). Ìyà tí í yẹpẹrẹ (ẹ̀dá) sì ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun t’ó wà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?
Àti pé dájúdájú (Ànábì) Mūsā ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.”
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) "Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀." Wọ́n wí pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (àṣẹ)." Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: "Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé tiyín nìkan ni Ilé Ìkẹyìn tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu, tí kò sì níí jẹ́ ti àwọn ènìyàn (mìíràn), ẹ tọrọ ikú, tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
Wọn kò níí tọrọ ikú láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Dájúdájú o máa rí wọn pé àwọn ni ènìyàn t’ó l’ójú kòkòrò jùlọ nípa ìṣẹ̀mí ayé, (wọ́n tún l’ójú kòkòrò ju) àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ. Ìkọ̀ọ̀kan wọn ń fẹ́ pé tí A bá lè fún òun ní ẹgbẹ̀rún ọdún lò láyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kì í ṣe ohun tí ó máa là á nínú ìyà ni pé kí Á fún un ní ìṣẹ̀mí gígùn lò. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl, (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló mú al-Ƙur’ān wá sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
Nínú àwọn mọlāikah tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa ń fi iṣẹ́ ìmísí rán sí àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni mọlaika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Òun sì ni olórí gbogbo wọn. Mọlaika Jibrīl tún ní àwọn orúkọ mìíràn nínú al-Ƙur’ān. Nínú àwọn orúkọ rẹ̀ ni “ar-Rūh” - Ẹ̀mí - (sūrah al-Mọ‘ārij; 70:4), “rūhul-ƙudus” - Ẹ̀mí Mímọ́ - (sūrah an-Nahl; 16:102) àti “rūhul-’Amīn” - Ẹ̀mí Ìfàyàbalẹ̀, Ẹ̀mí tí kì í jàǹbá iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an. - (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:193). Àmọ́ yàtọ̀ sí pé, mọlāika Jibrīl ń jẹ́ “ar-rūh”, nínú al-Ƙur’ān “rūh” tún lè túmọ̀ sí “ìmísí tàbí al-ƙur’ān (sūrah an-Nahl; 16:2); “rūh” lè túmọ̀ sí “ẹ̀mí” tí a fi ń jẹ́ abẹ̀mí (sūrah al-’Isrọ̄’; 17:85); àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Jibrīl àti Mīkāl, dájúdájú Allāhu ni ọ̀tá fún àwọn aláìgbàgbọ́."
Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ọ. Ẹnì kan kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ àyàfi àwọn arúfin.
Àti pé ṣé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dá májẹ̀mu kan ni apá kan nínú wọn yóò máa jù ú nù? Rárá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni kò gbàgbọ́.
Àti pé nígbà tí Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu dé bá wọn, tí ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú ohun t’ó wà pẹ̀lú wọn, apá kan nínú àwọn tí A fún ní Tírà gbe Tírà Allāhu jù s’ẹ́yìn lẹ́yìn wọn bí ẹni pé wọn kò mọ̀ (pé àsọọ́lẹ̀ nípa Ànábì s.a.w. wà nínú rẹ̀)!
Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán) lásìkò ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì ṣàì gbàgbọ́, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán. Àwa kò sì sọ (idán) kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjì náà. (Àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú wọ̀nyí) Hārūt àti Mọ̄rūt ní (ìlú) Bābil (ni wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn nídán). Wọn kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n wí pé: "Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí." Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn àlùjànnú méjèèjì. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
____________________
“ما” jẹ́ atọ́ka-àyísódì, “و” sì jẹ́ ọ̀rọ̀-àsopọ̀, tí Wọ́n fi so
مَا أُنزِلَ عَلَى ٱلْمَلَكَيْنِ pọ̀ mọ́ كَفَرَ سُلَيْمَٰنُ مَا Okùnfà èyí ni pé, àwọn yẹhudi wí pé: ‘Dájúdájú Allāhu fi idán rán mọlāika Jibrīl àti Mīkā’īl. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀… Hārūt àti Mọ̄rūt sì ni orúkọ àwọn èṣù àlùjànnú tí gbólóhùn: وَلَٰكِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ كَفَرُوا۟ dúró fún. Èyí ni ìtúmọ̀ t’ó dára jùlọ. Ìtúmọ̀ yìí sì tún ni ìtúmọ̀ t’ó ní àlàáfíà jùlọ, tí àwọn onímọ̀ mú wá lórí rẹ̀. Má ṣe ṣíjú wo ìtúmọ̀ mìíràn … bí ìtàn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn ọtí mímu àti ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn mọlāika… Ìpìlẹ̀ àdìsọ́kàn tí a ní sí àwọn mọlāika yó forí sánpọ́n nípa pípe Hārūt àti Mọ̄rūt ní mọlāika. Àwọn mọlāika ni ẹni tí Allāhu ní àfọkàntán sí lórí ìmísí Rẹ̀, tí Ó fi rán wọn. Àwọn sì ni aṣojú Allāhu fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ wo sūrah at-Tahrīm; 66:6 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy.
Síwájú sí i, àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ ‘alā muliki Sulaemọ̄n” kò túmọ̀ sí lórí àga ìjọba Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Rárá o. Kò sí ìgbà kan kan tí èṣù àlùjànnú rọ́nà jẹ gàba rí lórí àga Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé, bí Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ òdodo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán an níṣẹ́ sí wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èṣù àlùjànnú kan ń lọ bá àwọn ènìyàn láti máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ idán láti máa fi tako ìgbàgbọ́ òdodo tí wọ́n ń gbọ́ lọ́dọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Níkété tí ìró aburú yìí détí ìgbọ́ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó páṣẹ láti gba gbogbo àkọsílẹ̀ idán náà lọ́wọ́ wọn. Ó sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn agbọ́mágbà ènìyàn kan pẹ̀lú àwọn èṣù àlùjànnú olóríkunkun padà wá a kàn ní ibi tí Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bò ó mọ́. Wọ́n sì padà síbi lílo idán náà, wọ́n sì tún ń ba Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórúkọ jẹ́ kiri ìlú pé, ohun tí ó fi ṣe ìjọba lórí àwọn nìyẹn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ òdodo àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ni Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi ṣe ìjọba rẹ̀, kì í ṣe idán. Ẹ tún ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Sọ̄d; 38:34. W-Allāhu ’a‘lam.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ẹ̀san tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore jùlọ (fún wọn), tí wọ́n bá mọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má sọ pé “rọ̄‘inā”. (Àmọ́) ẹ sọ pé “unṭḥurnā” , kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́ (ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
____________________
Rọ̄‘inā jẹ́ ọ̀rọ̀ méjì; “rọ̄‘i" àti “nā”. “Nā” jẹ́ ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kíní ọ̀pọ̀ “wa”. “Rọ̄‘i” ní ìtúmọ̀ méjì nínú èdè Lárúbáwá àti èdè Isrā’īl. Bákan náà, “rọ̄‘i" lè jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ nínú èdè méjèèjì. Nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i" ní ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “òmùgọ̀” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ru‘ūnah”, agọ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i" ní ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “kíyè sí, wò,” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ri‘ānah” kíkíyèsí ẹnì kan, mímójútó ẹnì kan. Ìgbàkígbà tí àwọn yẹhudi bá lo “rọ̄‘i" fún àwọn Ànábì wọn, ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ ni wọ́n ń gbà lérò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, tí wọ́n bá sọ fún àwọn Ànábì wọn pé “rọ̄‘inā", ohun tí wọ́n ń gbà lérò ni pé “òmùgọ̀ wa!”. Àmọ́ nígbà tí àwọn Sọhābah (r.ahm.) bá lò “rọ̄‘inā" fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ ni wọ́n ń gbà lérò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn Sọhābah ń sọ pé “kí Ànábì kíyè sí wa”. Nítorí kí àwọn yẹhudi má baà ṣe lérò pé irú wọn ni àwọn Sọhābah ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi kọ lílo ọ̀rọ̀ yẹn fún àwọn Sọhābah (r.ahm.), Ó sì fún wọn ní òmíràn tí ó gbé ìtúmọ̀ àti èròǹgbà rere wọn jáde, tí kò sì jẹmọ́ èdè abunikù. Èyí sì ni “unṭḥurnā”. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwa mùsùlùmí lè mọ̀ pé ìlò èdè wa àti ìṣe wa kò gbọdọ̀ jọ ti àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn ọ̀ṣẹbọ kò fẹ́ kí wọ́n sọ oore kan kan kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Allāhu sì ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
A ò níí fi āyah kan pa āyah kan rẹ́ tàbí kí Á fi sílẹ̀ (bẹ́ẹ̀ ní ohun kíké nìkan), A máa mú èyí t’ó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan?
Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu.
Tàbí ẹ fẹ́ máa bèèrè (ọ̀rọ̀kọrọ̀) lọ́wọ́ Òjíṣẹ́ yín ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe bèèrè (ọ̀rọ̀kọrọ̀) lọ́wọ́ (Ànábì) Mūsā ṣíwájú? Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àìgbàgbọ́ rọ́pò ìgbàgbọ́, dájúdájú ó ti ṣìnà (kúrò) l’ójú ọ̀nà tààrà.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A fún ní Tírà ń fẹ́ láti da yín padà sípò kèfèrí lẹ́yìn tí ẹ ti ní ìgbàgbọ́ òdodo, ní ti kèéta láti inú ẹ̀mí wọn, (àti) lẹ́yìn tí òdodo (’Islām) ti fojú hàn sí wọn. Nítorí náà, ẹ foríjìn wọ́n, kí ẹ ṣàmójú kúrò fún wọn (nípa ìnira tí wọ́n ń fi kàn yín) títí Allāhu yó fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá (láti ja wọ́n lógun). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh; ohunkóhun tí ẹ bá sì tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín ní rere, ẹ máa bá a lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: “Ẹnì kan kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi ẹni tí ó bá jẹ́ yẹhudi tàbí nasara.” Ìyẹn ni ìfẹ́-ọkàn wọn. Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (nínú ’Islām) fún Allāhu, tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (iṣẹ́) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn yẹhudi wí pé: “Àwọn nasara kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn).” Àwọn nasara náà wí pé: “Àwọn yẹhudi kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn.)” Wọ́n sì ń ké Tírà! Báyẹn ni àwọn tí kò nímọ̀ ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Nítorí náà, Allāhu á dájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí.
Àti pé ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà? Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ní ọ̀run, ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn.
____________________
Àwọn onisūfī lérò pé āyah yìí ń ṣe é ní èèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti lé àwọn kúrò nínú mọ́sálásì tàbí láti kọ̀ fún wọn láti ṣe wiridi wọn àti waṭḥīfah wọn nínú mọ́sálásí. Rárá o. Āyah yìí kò gba bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹni tí kò jẹ́ kí àwa mùsùlùmí ṣe ìjọ́sìn t’ó tọ sunnah nínú mọ́sálásí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pè ní alábòsí jùlọ nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹni tí ó kọ aburú àti bidiah ṣíṣe nínú àwọn mọ́sálásí. Ọ̀nà tí àwọn oníwírìdí ń gbà ṣe ìrántí Allāhu kò sì tọ sunnah rárá. Dandan sì ni fún wá láti lé wọn kúrò nínú mọ́sálásí Allāhu. “Zāwiyah” ni wọ́n máa ń kọ́ fún wírìdí bidiah, kì í ṣe mọ́sálásí.
Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí ẹ bá dojú kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ƙiblah Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fi sūrah al-Baƙọrah; 2:144, 149, àti 150 pa ìdájọ́ āyah yìí rẹ́, ìdájọ́ tí ń bẹ nínú āyah náà ṣe é lò fún ẹni tí ó wà ní àyè kan tí kò sì mọ agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú náà láààrin orígun ayé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti ìlú náà. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí kírun rẹ̀ láààrin orígun méjì nínú orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú rẹ̀ tí gbé e títí ó máa fi mọ àmọ̀dájú nípa agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú rẹ̀.
Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.
Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni (Allāhu). Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?” Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná.
Àwọn yẹhudi àti nasara kò níí yọ́nú sí ọ títí o fi máa tẹ̀lé ẹ̀sìn wọn. Sọ pé: “Dájúdajú ìmọ̀nà ti Allāhu ni ìmọ̀nà.” Dájúdajú tí o bá sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn èyí tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀ (’Islām), kò níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu.
Àwọn tí A fún ní Tírà (al-Ƙur’ān), wọ́n ń ké e ní kíké ẹ̀tọ́. Àwọn wọ̀nyẹn gbà á gbọ́ ní òdodo. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni ẹni òfò.
____________________
Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún wí pé, òǹkà àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (‘aleehim sọlāt wa salām) pọ̀ púpọ̀ nínú ìran ọmọ ’Isrọ̄’īl ju àwọn ìran ẹ̀dá yòókù lọ, àmọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl náà ni ìran t’ó ṣàì gbàgbọ́ jùlọ.
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìkẹ́ Mi, èyí tí Mo ṣe fun yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fun yín lórí àwọn
ẹ̀dá (àsìkò yín).
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí gba ààrọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣìpẹ̀ kan kò níí wúlò fún un. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa fi àwọn ọ̀rọ̀ kan dán (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wò. Ó sì parí wọn ní pípé. (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Èmi yó ṣe ọ́ ní aṣíwájú fún àwọn ènìyàn.” (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àti nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi.” (Allāhu) sọ pé: "Àdéhùn Mi (láti sọ ẹnì kan di Òjíṣẹ́) kò níí tẹ àwọn alábòsí lọ́wọ́."
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun).
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì pèsè àwọn èso fún àwọn ará ibẹ̀ (ìyẹn) ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn.” (Allāhu) sọ pé: "Àti ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò fún un ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mo máa taari rẹ̀ sínú ìyà Iná. Ìkángun náà sì burú."
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ismọ̄‘īl gbé àwọn ìpìlẹ̀ Ilé náà dúró. (Wọ́n ṣàdúà pé) "Olúwa wa, gbà á lọ́wọ́ wa, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Olúwa wa, ṣe wá ní mùsùlùmí fún Ọ. Kí O sì ṣe nínú àrọ́mọdọ́mọ wa ní ìjọ mùsùlùmí fún Ọ. Fi ìlànà ẹ̀sìn wa hàn wá. Kí O sì gba ìronúpìwàdà wa. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Olúwa wa, gbé dìde nínú wọn Òjíṣẹ́ kan láààrin wọn, (ẹni tí) ó máa ké àwọn āyah Rẹ fún wọn, tí ó máa kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì máa sọ wọ́n di ẹni mímọ́. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n."
Ta sì ni ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run.
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ mùsùlùmí.” Ó sọ pé: “Mo jẹ́ mùsùlùmí fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. (Ànábì) Ya‘ƙūb náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìkíní kejì sọ pé): "Ẹ̀yin ọmọ mi, dájúdájú Allāhu yan ẹ̀sìn náà fun yín. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí."
Tàbí ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí nígbà tí ikú dé bá (Ànábì) Ya‘ƙūb? Nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ni ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn (ikú) mi?” Wọ́n sọ pé: "Àwa yó máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun rẹ àti Ọlọ́hun àwọn bàbá rẹ, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo. Àwa sì ni mùsùlùmí (tí a juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un."
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ yẹhudi tàbí nasara kí ẹ mọ̀nà.” Sọ pé: "Rárá, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (lẹ̀sìn), olùdúró-déédé, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ."
Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.”
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú irú ohun tí ẹ gbàgbọ́, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, wọ́n ti wà nínú ìyapa (òdodo). Allāhu sì máa tó ọ (níbi aburú) wọn. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(Ẹ dúró ti) aró Allāhu. Ta sì l’ó dára ju Allāhu lọ ní aró! Àwa sì ni olùjọ́sìn fún Un.
____________________
Kíyè sí i, ìtúmọ̀ àkànlò ni wọ́n lò fún “aró” nínú āyah yìí. “Aró” sì dúró fún ẹ̀sìn. Kókó ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, ẹ̀sìn gbọ́dọ̀ hàn lára olùjọ́sìn fún Allāhu gẹ́gẹ́ bí aró ṣe máa ń hàn lára aṣọ tí wọ́n bá pa láró. Nípa èyí, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ ní ìrísí ọkàn àti ìrísí ara t’ó tọ sunnah, tí ó máa mú un yàtọ̀ gédégbé sí ẹlẹ́sìn mìíràn.
Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yó jà wá níyàn nípa Allāhu ni?” Òun sì ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Àwa (mùsùlùmí) sì ni olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.
Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasara.” Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Kókó tí āyah yìí ń fi rinlẹ̀ ni pé, kò sí Ànábì kan tàbí Òjị́ṣẹ́ Allāhu kan t’ó ṣe ẹ̀sìn Yẹ̀húdí tàbí Kristiẹniti tàbí ìbọ̀rìṣà. ’Islām ni ẹ̀sìn tí gbogbo wọn ṣe ('alaehim sọlātu wa salām).
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn òmùgọ̀ nínú àwọn ènìyàn máa wí pé: “Kí ni ó mú wọn yí kúrò níbi Ƙiblah wọn tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).”
Báyẹn ni A ti ṣe yín ní ẹ̀ṣà ìjọ t’ó lóore jùlọ, nítorí kí ẹ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, àti nítorí kí Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín. A kò sì ṣe Ƙiblah tí o wà lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ibùkọjú-kírun bí kò ṣe pé nítorí kí Á lè ṣe àfihàn ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tí ó máa yísẹ̀ padà. Dájúdájú ó lágbára àyàfi fún àwọn tí Allāhu tọ́ sọ́nà. Allāhu kò sì níí fi ìgbàgbọ́ yín ráre. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
A kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, A ó dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Dájúdájú tí o bá fún àwọn tí A fún ní Tírà ní gbogbo āyah, wọn kò níí tẹ̀lé Ƙiblah rẹ. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ tẹ̀lé Ƙiblah wọn. Apá kan wọn kò sì níí tẹ̀lé Ƙiblah apá kan. Dájúdájú tí o bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, dájúdájú nígbà náà ìwọ wà nínú àwọn alábòsí.
Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́; wọ́n sì mọ̀.
Òdodo náà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
Ìkọ̀ọ̀kan (ìjọ ẹlẹ́sìn) l’ó ní ibùkọjúsí t’ó ń kọjú sí. Nítorí náà, ẹ yára gbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere. Ibikíbi tí ẹ bá wà, Allāhu yó mú gbogbo yín wá (ní Ọjọ́ Àjíǹde). Dájúdájú Alágbára ni Allāhu lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram, nítorí pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀, nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fun yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà
____________________
Àwọn āyah wọ̀nyí 144, 149 àti 150 ń pa wá láṣẹ láti dojú kọ agbègbè Kaabah lórí ìrun, ìyẹn sì ni agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí mọ́sálásí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ohun t’ó bí “agbègbè” dípò “ọ̀gangan” Kaabah ni pé, kò lè rọrùn rárá fún àwọn tí kò sí nínú mọ́sálásí Haram Mọkkah láti dojú kọ ọ̀gangan Kaabah láti àyè mìíràn lórí ìrun wọn. Èyí sì yọrí sí àtòyípo Kaabah fún ọ̀wọ́ àwọn t’ó wà nínú mọ́sálásí Kaabah nítorí kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè kọjú sí ọ̀gangan Kaabah. Ní ìdà kejì ẹwẹ̀, gbogbo àwọn olùkírun yòókù ní àyè mìíràn máa tò ní àtògbọọrọ. Wàyí, nípasẹ̀ títò ní àtògbọọrọ yìí, (1) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojú kọ orígun kan nínú àwọn orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé nínú ìlú wọn tàbí (2) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojú kọ ààrin orígun méjì nínú orígun méjì ìpìlẹ̀ nínú àwọn orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé nínú ìlú wọn tàbí (3) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojú kọ ààrin orígun méjì tí orígun kan máa jẹ́ orígun ìpìlẹ̀, tí orígun kejì sì máà jẹ́ orígun-àlà láààrin orígun ìpìlẹ̀ méjì. Àpẹẹrẹ fún (2) ni ƙiblah fún ìlú Mọdinah onímọ̀ọ́lẹ̀ nítorí pé, ní ti ìlú Mọdinah onímọ̀ọ́lẹ̀, láààrin agbègbè ìlà òòrùn (mọṣriƙ) àti ìwọ̀ òòrùn (mọgrib) ìlú Mọdinah ni agbègbè tí Kaabah wà sí wọn. Àpẹẹrẹ fún (3) ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí pé, láààrin ìlà òòrùn (east) àti àríwá-ìlà òòrùn (north-east) ni agbègbè tí Kaabah wà sí wa. Èyí ni àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé sì fi rinlẹ̀.
A máa mọ ọ̀gangan ìlà òòrùn (east) ní ọjọ́ tí òòji òòrùn-kàtàrí bá bọ́ sí abẹ́ ẹsẹ̀ ìdúró ènìyàn. Ẹnu-àlà láààrin àríwá (north) àti ìlà-òòrùn (east) ni a mọ̀ sí àríwá-ìlà òòrùn (north-east). Àríwá-ìlà òòrùn (north-east) sì ni òpin ibùyọ òòrùn ní ẹ̀bá òkè ìlà òòrùn (east). Ní àsìkò tí òòrùn bá ń yọ ní agbègbè àríwá-ìlà òòrùn, tí ènìyàn bá dojú kọ ìlà òòrùn, òòji rẹ̀ máa wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ níkété tí òòrùn bá yẹ̀tàrí. Nígbà tí òpin ẹ̀bá òkè ìlà òòrùn ń jẹ́ àríwá-ìlà òòrùn (north-east), òpin ẹ̀bá ìsàlẹ̀ ìlà òòrùn sì ń jẹ́ gúsù-ìlà òòrùn (south-east). Nítorí náà, lórí ìrun, olùkírun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò níí kọjú sì àríwá (north) tàbí àríwá-ìlà òòrùn (north-east) tàbí ìlà òòrùn (east), áḿbọ̀sìbọ́sí gúsù-ìlà òòrùn (south-east). Agbègbè tí ƙiblah rẹ̀ bọ́ sí nínú ìlú rẹ̀ kò tayọ ààrin ìlà òòrùn (east) àti àríwá-ìlà òòrùn (north-east).
gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan si yín láààrin ara yín, tí ó ń ké àwọn āyah Wa fun yín, tí ó ń sọ yín di ẹni mímọ́, tí ó ń kọ yín ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì ń kọ yín ní ohun tí ẹ ò mọ̀ tẹ́lẹ̀.
Nítorí náà, ẹ rántí Mi, Mo máa rántí yín. Ẹ dúpẹ́ fún Mi, ẹ má ṣàì moore sí Mi.
____________________
“Ìrántí Allāhu” láti ọ̀dọ̀ ẹ̀dá sí Ẹlẹ́dàá ni ìwọ̀nyí: (1) fífi tírà Allāhu ṣe wáàsí àti títẹ́tí gbọ́ ọ (2) kíké tírà Allāhu bí ṣíṣe tilāwatul-Ƙur’ān (3) ṣíṣe gbólóhùn tí orúkọ Allāhu ti jẹyọ bí subhān-Allāh, alhamdu lillāh, Allāhu ’akbar, lā’ilāha ’ill-Allāh (4) ṣíṣe àwọn orígun ọ̀ran-anyàn ẹ̀sìn bí ìrun kíkí (5) ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu àti ìjìnnà sí èèwọ̀ Rẹ̀ (6) fífi orúkọ Allāhu búra (7) rírántí ẹ̀san rere tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ní àdéhùn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (8) rírántí ẹ̀san ìyà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ní ìlérí fún àwọn olùyapa àṣẹ Rẹ̀ àti àwọn aláìgbàgbọ́. Àmọ́ “Ìrántí Allāhu” láti ọ̀dọ̀ Allāhu Ẹlẹ́dàá sí ẹ̀dá ni ìwọ̀nyí:(1) ẹ̀san rere tí Allāhu máa fún ẹ̀dá lórí àwọn n̄ǹkan márùn-ún wọ̀nyẹn (2) sísọ tí Allāhu máa sọ nípa àwọn olùparapọ̀ lórí ìrántí Rẹ̀ fún àwọn mọlā’ika t’ó súnmọ́ Ọn l’ókè sánmọ̀ keje.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ fi sùúrù àti ìrun kíkí tọrọ oore (Allāhu). Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù.
Ẹ má ṣe pe àwọn tí wọ́n ń pa sí ojú-ogun ẹ̀sìn Allāhu ní òkú (ìyà), àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fura.
____________________
A bi ‘Abdullāh léèrè nípa āyah yìí, ‘Abdullāh sọ pé, àwa kúkú bi Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) léèrè nípa èyí, ó sì sọ pé: “Ẹ̀mí àwọn tí wọ́n kú sí ojú ogun ẹ̀sìn ’Islām yóò máa bẹ nínú agbẹ̀du ẹyẹ aláwọ̀ ewéko. Àwọn ẹyẹ náà ní àtùpà tí wọ́n gbékọ́ fún wọn s’ára Ìtẹ́-ọlá ti Allāhu. Àwọn ẹyẹ náà ń jẹ kiri síbi tí wọ́n bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Lẹ́yìn náà, àwọn ẹyẹ náà yóò fara pamọ́ sídìí àwọn àtùpà wọ̀nyí. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣíjú wò wọ́n, Ó sì sọ pé: “Ẹ̀ ń fẹ́ n̄ǹkan bí? Wọ́n sọ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí a tún ń fẹ́? Àwa tí à ń jẹ kiri síbi tí a fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú wọn ní ẹ̀ẹ̀ mẹta. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i pé Wọn kò fi àwọn sílẹ̀ nípa bíbi wọ́n pé kí ni n̄ǹkan tí wọ́n tún ń fẹ́, wọ́n bá sọ pé: "Olúwa, a fẹ́ kí O dá ẹ̀mí wa padà sínú ara wa, kí wọ́n lè tún wa pa ní ẹ̀ẹ̀ kan sí i sí ojú ogun ẹ̀sìn Rẹ." Nígbà tí Allāhu rí i pé wọn kò ní bùkátà kan mọ́ (Allāhu, Onímọ̀ nípa ohun gbogbo sì ti mọ̀ ṣíwájú kí Ó tó bi wọ́n léèrè), Wọ́n fi àwọn ẹ̀yẹ̀ náà sílẹ̀ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Bukọ̄riy; al-Jihād was-saer: 3500). Irúfẹ́ āyah yìí wà ní sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:169. Kókó tí àwọn āyah wọ̀nyí fi rinlẹ̀ sì ti jẹyọ nínú hadīth yẹn, ìyẹn ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dùn-ún gbè níjà t’ó bẹ́ẹ̀ gẹ́ t’ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n bá kú fún Un, àwọn ni wọ́n kú ikú tí ó lápọ̀n-ọ́nlé jùlọ, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọn yóò fi máa bẹ nínú Ọgbà Ìdẹ́rà ní àwòrán ẹyẹ aláwọ̀ ewéko ṣíwájú Ọjọ́ àjíǹde. Àti pé kò sí àǹfààní fún òkú kan kan láti padà sílé ayé mọ́. Nítorí náà, kò sí àkúdàáyà tàbí àṣẹ̀yìnwáyé kan níbikíbi bí kò ṣe ète àlùpàídà tí àwọn èṣù àlùjànnú ń dá. Àwọn èṣù àlùjànnú l’ó ń gbé àwòrán ọmọnìyàn wọ̀ láti fi ba ìgbàgbọ́ wọn jẹ́. Ẹ wo sūrah al-Mu’minūn; 23:99-100 àti sūrah Yāsīn; 36:48-54.
Dájúdájú A ó máa dan yín wò pẹ̀lú kiní kan látara ẹ̀rù, ebi, àdínkù nínú àwọn dúkìá, àwọn ẹ̀mí àti àwọn èso. Kí o sì fún àwọn onísùúrù ní ìró ìdùnnú.
Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.”
Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti ìkẹ́ yó máa bẹ fún láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùmọ̀nà.
Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Amoore, Onímọ̀.
Dájúdájú àwọn t’ó ń daṣọ bo ohun tí A sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú àti ìmọ̀nà, lẹ́yìn tí A ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn sínú Tírà, àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ń ṣẹ́bi lé. Àwọn olùṣẹ́bi sì ń ṣẹ́bi lé wọn.
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni ègún Allāhu, (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) ènìyàn pátápátá ń bẹ lórí wọn.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn. A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, àti àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn lórí omi pẹ̀lú (ríru) ohun t’ó ń ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní omi òjò láti sánmọ̀, tí Ó sì ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ó ti kú, àti (bí) Ó ṣe fọ́n gbogbo ẹranko ká sí orí ilẹ̀, àti ìyípadà atẹ́gùn àti ẹ̀ṣújò tí A tẹ̀ba láààrin sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè.
____________________
Ìyípadà atẹ́gùn túmọ̀ sí pé, atẹ́gùn lè fẹ́ wá láti agbègbè kan, kí ó dáwọ́ dúró, kí ó tún fẹ́ wá láti agbègbè mìíràn. Ìyípadà atẹ́gùn tún túmọ̀ sí pé, atẹ́gùn lè fẹ́ tútù, ó sì lè fẹ́ gbígbóná.
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí
Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàbòsí lè rí ìgbà tí wọ́n máa rí Ìyà náà ni, (wọn ìbá mọ̀ pé) dájúdájú gbogbo agbára ń jẹ́ ti Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
(Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (nínú àìgbàgbọ́) máa yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun t’ó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá.
Àwọn t’ó tẹ̀lé wọn yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ìpadàwáyé lè wà fún wa ni, àwa ìbá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wọn ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa.” Báyẹn ni Allāhu yó ṣe fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n ní (iṣẹ́) òfò fún wọn. Wọn kò sì níí jáde kúrò nínú Iná.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jẹ nínú ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ (t’ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti n̄ǹkan) dáadáa.Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.
____________________
Oúnjẹ ẹ̀tọ́ ni èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ní halāl. Oúnjẹ dáadáa ni èyí tí àwọn èròjà oúnjẹ aṣaralóore pé sí lára.
Ohun tí ó máa pa yín ní àṣẹ rẹ̀ ni (iṣẹ́) aburú, ìbàjẹ́ àti sísọ nípa Allāhu ohun tí ẹ ò nímọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé:
“Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá, A óò máa tẹ̀lé ohun tí a bá l’ọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà?
Àpèjúwe àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ dà bí àpèjúwe ẹni tí ó ń ké pe ohun tí kò lè gbọ́rọ̀ tayọ ìpè àti igbe (asán). Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; wọn kò sì níí ṣe làákàyè.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín, kí ẹ sì dúpẹ́ fún Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fun yín ni òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun tí wọ́n pe orúkọ mìíràn lé lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tí wọ́n bá fi ìnira (ebi) kan, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ìnira ebi ni pé, kí ènìyàn bọ́há sí àyè kan, tí kò ti lè rí òdíwọ̀n ohun jíjẹ tàbí ohun mímu halāl tí ó kéré jùlọ láti fi gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró. Àmọ́ ní ti ìnira àìsàn, mùsùlùmí kò gbọdọ̀ lo n̄ǹkan harām láti fi tọ́jú ara rẹ̀, bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, kódà kó fẹ́ já sí ikú. Harām kì í ṣe okùnfà ìlera. Nítorí náà, ìnira ebi ni làlúrí. Ìnira àìsàn kì í ṣe làlúrí.
Dájúdájú àwọn t’ó ń daṣọ bo ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú Tírà, tí wọ́n sì ń tà á ní owó pọ́ọ́kú, àwọn wọ̀nyẹn kò jẹ kiní kan sínú wọn bí kò ṣe Iná. Allāhu kò sì níí bá wọn sọ̀rọ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà, (wọ́n tún fi) àforíjìn ra ìyà. Báwo ni wọn ṣe máa lè ṣèfaradà fún Iná ná!
Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé dájúdájú Allāhu sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àwọn t’ó sì yapa Tírà náà ti wà nínú ìyapà t’ó jìnnà (sí òdodo).
Kì í ṣe ohun rere ni kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni t’ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì. Tòhun ti ìfẹ́ tí olùṣe-rere ní sí owó, ó tún ń fi owó náà tọrẹ fún àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù, onírìn-àjò (tí agara dá), àwọn atọrọjẹ àti (ìtúsílẹ̀) l’óko ẹrú. (Ẹni rere) yó máa kírun, yó sì máa yọ Zakāh. (Ẹni rere ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn wọn ṣe nígbà tí wọ́n bá ṣe àdéhùn àti àwọn onísùúrù nígbà àìríná-àìrílò, nígbà àìlera àti l’ójú ogun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe (iṣẹ́) òdodo. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùbẹ̀rù (Allāhu).
____________________
Kíyè sí i, Kaabah ni ƙiblah (àdojúkọ) àwa mùsùlùmí lórí ìrun wa, àmọ́ níwọ̀n ìgbà tí a ò bá sí nínú haram Mọkkah, agbègbè yòówù kí àdojúkọ wá bọ́ sí láààrin orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, kì í ṣe ìyẹn ni àdojúkọ wa bí kò ṣe pé ó jẹ́ ọ̀nà tààrà sí Kaabah láti ìlú wa. Àwọn yẹhudi àti kristiẹni ni Allāhu ń júwe àwọn iṣẹ́ rere fún dípò bí wọ́n ṣe sọ ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn nìkan di ògóńgórí iṣẹ́ rere nínú ìlànà wọn.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ẹ̀san gbígbà níbi ìpànìyàn ní ọ̀ran- anyàn fun yín. Olómìnira fún olómìnira, ẹrú fún ẹrú, obìnrin fún obìnrin. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò kiní kan fún láti ọ̀dọ̀ ọmọ ìyá (ẹni tí wọ́n pa, kí ẹni tí ó máa gba owó ẹ̀mí dípò ẹ̀mí) ṣe ohun rere tẹ̀lé (owó tí ó gbà, kí ẹni tí ó máa san’wó ẹ̀mí) san owó náà fún un ní ọ̀nà t’ó dára. Ìyẹn ni ìgbéfúyẹ́ àti àánú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà (òfin) lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.
Ìsẹ̀mí wà fun yín nínú (òfin) ìgbẹ̀san ìpànìyàn, ẹ̀yin onílàákáyè, kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fun yín, nígbà tí ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín, tí ó sì fi dúkìá sílẹ̀, pé kí ó sọ àsọọ́lẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára fún àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí. (Èyí jẹ́) ojúṣe fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá yí i padà lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ ọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yó sì wà lọ́rùn àwọn t’ó ń yí i padà. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá bẹ̀rù àṣìṣe tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó sọ àsọọ́lẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe láààrin (àwọn tí ogún tọ́ sí). Nítorí náà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
(Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn t’ó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.
____________________
Fífi ìnira gba ààwẹ̀ lè jẹ́ nípasẹ̀ ogbó, àmódi ọlọ́jọ́ gbọọrọ, oyún tàbí fífún ọmọ lọ́yàn.
Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀ 1 (tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà 2 fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ìlú rẹ̀ nínú yín nínú oṣù náà, 3 kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fun yín, kò sì fẹ́ ìnira fun yín. Ẹ pé òǹkà (ọjọ́ ààwẹ̀), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un.
____________________
1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106. 2 “ọ̀rọ̀-ìpínyà”: ni ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́. 3 Kíyè sí i, awẹ́ gbólóhùn yìí “famọn ṣẹhida minkum-ṣṣahr fal yẹsumhu” kò túmọ̀ sí “nítorí náà, ẹni tí ó bá rí oṣù, kí ó gba ààwẹ̀” nítorí pé, nínú gírámà èdè Lárúbáwá, kalmọh “aṣ-ṣahrọ” nínú awẹ́ gbólóhùn náà kì í ṣe “mọf‘ūlun bih” (àbọ̀) fún “ṣẹhida” bí kò ṣe “ṭḥọrfu-zzamọ̄n” (ọ̀rọ̀-àpọ́nlé / àrótì fún àsìkò). Bákan náà, kì í ṣe gbogbo ènìyàn l’ó máa ní àǹfààní láti rí ìlétéṣù ní alẹ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù Rọmọdọ̄n. Àti pé Ohun tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n àti ìparí rẹ̀ ni pé “Ẹ gba ààwẹ̀ fún rírí ìlétéṣù. Ẹ tunu fún rírí ìlétéṣù. Tí wọ́n bá fi ẹ̀sújò bò ó lójú fun yín, ẹ parí òǹkà (ọgbọ̀n ọjọ́ fún oṣù Ṣa‘bān àti ọgbọ̀n ọjọ́ fún oṣù Rọmọdọ̄n) Bukọ̄riy àti Muslim.
Bákan náà, ó pọn dandan kí gbogbo ayé gun òkè ‘Arafah ní ọjọ́ kan náà nítorí pé, àyè kan náà ni òkè ‘Arafah wà, ṣùgbọ́n kò pọn dandan kí gbogbo ayé bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ kan náà, kò sì pọn dandan kí gbogbo ayé parí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ kan náà. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé kí òdidi orílẹ̀ èdè kan ṣoṣo tàbí òdidi ìlú kan ṣoṣo bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí parí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Nítorí náà, ní orílẹ̀ èdè wa Nàìjíríà ní àpapọ̀, tí a bá fẹ́ kí ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n wa àti ìparí rẹ̀ máa jẹ́ ọjọ́ kan náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pọn dandan bẹ́ẹ̀ nínú òfin ’Islām, a bùkátà sí n̄ǹkan méjì gbòòrò. Ìkíní: aṣíwájú ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa jẹ́ onisunnah, tí àṣẹ rẹ̀ máa múlẹ̀ dáadáa. Ìkejì: ètò t’ó hàn kedere láti ọ̀dọ̀ àwọn olùwá-oṣù lórí ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ààwẹ̀ t’ó máa dúró lórí sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Láì sí ìkíní kejì, ìtàsé ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n wa kò níí yé máa fi ọjọ́ ẹyọ kan tàbí ọjọ́ méjì tàsé ara wọn. W-Allāhu-l-musta‘ān.
Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà).
Wọ́n ṣe alẹ́ ààwẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fun yín láti súnmọ́ àwọn ìyàwó yín; àwọn ni aṣọ yín, ẹ̀yin sì ni aṣọ wọn. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀ ń tan ara yín jẹ (nípa àìfẹ́ sun oorun ìfẹ́ ní alẹ́ ààwẹ̀). Ó ti gba ìronúpìwàdà yín, O sì ṣe àmójúkúrò fun yín. Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ ó fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) ní àfẹ̀mọ́júmọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́ (nígbà tí òòrùn bá wọ̀). Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn nígbà tí ẹ bá ń kóra ró nínú àwọn mọ́sálásí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀), ẹ má ṣe súnmọ́ ọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Rẹ̀).
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ gbé dúkìá lọ bá àwọn adájọ́ (ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀) nítorí kí ẹ lè fi ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ìpín kan nínú dúkìá àwọn ènìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ìlétéṣù. Sọ pé: “Òhun ni (òǹkà) àkókò fún àwọn ènìyàn àti (òǹkà àkókò fún) iṣẹ́ Hajj. Kì í ṣe iṣẹ́ rere (fun yín) láti gba ẹ̀yìn-ìnkùlé wọnú ilé, ṣùgbọ́n (olùṣe) rere ni ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà wọnú ilé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.
Fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, ẹ pa àwọn t’ó ń jà yín lógun. Kí ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn olùtayọ ẹnu-àlà.
Ẹ pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Kí ẹ sì lé wọn jáde kúrò níbi tí wọ́n ti le yín jáde. Ìfòòró le ju pípa lọ. Ẹ má ṣe bá wọn jà ní Mọ́sálásí Haram àfi ìgbà tí wọ́n bá ba yín jà nínú rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá ba yín jà, ẹ bá wọn jà. Báyẹn ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.
Tí wọ́n bá sì jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ gbógun tì wọ́n títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́. Ẹ̀sìn ’Islām yó sì wà (ní òmìnira) fún Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), kò sí ogun mọ́ àyàfi lórí àwọn alábòsí.
Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-àlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-àlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Ẹ náwó fún ogun ẹ̀sìn Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun (nípa sísá fún ogun ẹ̀sìn). Ẹ ṣe rere. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu. Tí wọ́n bá sì se yín mọ́ ojú ọ̀nà, ẹ fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ fá irun orí yín títí di ìgbà tí ẹran ọrẹ náà yó fi dé àyè rẹ̀. Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí ìnira kan ń bẹ ní orí rẹ̀, ó máa fi ààwẹ̀ tàbí sàráà tàbí ẹran pípa ṣe ìtánràn (fún kíkánjú fá irun orí). Nígbà tí ẹ bá fọkànbalẹ̀ (nínú ewu), ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá t’ó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí A ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò t’ó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè.
Kò sí ìbáwí fun yín (níbi òwò ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ hajj) pé kí ẹ wá oore kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, tí ẹ bá ń darí bọ̀ láti ‘Arafah, ẹ ṣe ìrántí Allāhu ní àyè alápọ̀n-ọ́nlé (Muzdalifah). Ẹ ṣe ìrántí Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ wà nínú àwọn olùṣìnà.
Lẹ́yìn náà, ẹ dà lọ sí ibi tí àwọn ènìyàn bá dà lọ (nínú iṣẹ́ Hajj), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn Allāhu. Dájúdájú, Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Nígbà tí ẹ bá parí ìjọ́sìn (Hajj) yín, ẹ ṣèrántí Allāhu gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń ṣèrántí àwọn baba ńlá yín. Tàbí kí ìrántí náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ayé.” Kò sì níí sí ìpín oore kan fún un ní ọ̀run.
Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni t’ó ń sọ pé: "Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná."
Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni ìpín oore nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ t’ó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un fún ẹni tí ó bá ṣọ́ra (fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
____________________
Èyí ni ọjọ́ kọkànlá, ìkejìlá àti ìkẹtàlá tí àwọn alálàájì máa fi dúró ní Minā.
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ̀ yó máa ṣe ọ́ ní kàyéfì nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, tí yó sì máa fi Allāhu jẹ́rìí sí ohun tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀ (pé kò sí ìjà), oníjà t’ó le jùlọ sì ni.
Nígbà tí ó bá sì yísẹ̀ padà, ó máa ṣiṣẹ́ kiri lórí ilẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀, kí ó sì lè pa n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn run. Allāhu kò sì fẹ́ràn ìbàjẹ́.
Àti pé nígbà tí wọ̀n bá sọ fún un pé: “Bẹ̀rù Allāhu.” Ìgbéraga sì máa mú ún dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, iná Jahanamọ yóò tó o (ní ẹ̀san). Ibùgbé náà sì burú.
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń ta ẹ̀mí ara rẹ̀ láti wá ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀).
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ kó s’ínú ẹ̀sìn ’Islām pátápátá. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ tẹ̀lé ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.
Nítorí náà, tí ẹsẹ̀ yín bá yẹ̀ (kúrò nínú ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe pé kí Allāhu wá bá wọn nínú ibòji ẹ̀ṣújò, àwọn mọlāika náà (sì máa wá, nígbà náà) A ó sì yanjú ọ̀rọ̀ (ìṣírò iṣẹ́ ẹ̀dá)! Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè pé: “Mélòó ni A ti fún wọn nínú āyah t’ó yanjú?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá (fi àìgbàgbọ́) jìrọ̀ ìdẹ̀ra Allāhu lẹ́yìn tí ó dé bá a, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn t’ó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì la ìṣírò lọ.
Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣọ (ẹlẹ́sìn ’Islām nípìlẹ̀). Allāhu sì gbé àwọn Ànábì dìde ní oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa ẹnu sí. Kò sì sí ẹni t’ó yapa ẹnu (sí ’Islām) àfi àwọn tí A fún ní Tírà, lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Nítorí náà, Allāhu tọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sọ́nà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọlọ̀tẹ̀1 yapa ẹnu sí nípa òdodo (’Islām). Allāhu yó máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà.2
____________________
1 Ìyẹn àwọn yẹhudi àti nasara.
2 Ẹ wo sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:19, 67, 80 àti 85.
Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí irúfẹ́ (àdánwò) t’ó kan àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú yín kò tí ì kàn yín? Ìpọ́njú àti àìlera mú wọn. Wọ́n sì rí àmìwò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Òjíṣẹ́ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ fi sọ pé: “Ìgbà wo ni àrànṣe Allāhu máa dé sẹ́?” Kíyè sí i! Dájúdájú àrànṣe Allāhu súnmọ́.
Wọ́n ń bí ọ léèrè pé kí ni àwọn yó máa náwó sí. Sọ pé: "Ohun tí ẹ bá ná nínú ohun rere, kí ó máa jẹ́ ti àwọn òbí méjèèjì, àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe nínú ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀."
A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí, ohun ìkórira sì ni fun yín. Ó sì lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ oore fun yín. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ aburú fún yín. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ogun jíjà nínú oṣù ọ̀wọ̀. Sọ pé: "Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ogun jíjà nínú rẹ̀. Àti pé ṣíṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ṣíṣe àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, dídí àwọn mùsùlùmí lọ́wọ́ láti wọ inú Mọ́sálásí Haram àti lílé àwọn mùsùlùmí jáde kúrò nínú rẹ̀, (ìwọ̀nyí) tún tóbi jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu." Ìfòòró sì burú ju ìpànìyàn lọ. Wọn kò ní yéé gbógun tì yín títí wọn yó fi ṣẹ́ yín lórí kúrò nínú ẹ̀sìn yín, tí wọ́n bá lágbára (ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣẹ́rí kúrònínú ẹ̀sìn rẹ̀, tí ó sì kú sí ipò kèfèrí, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn t’ó gbé ìlú (wọn) jù sílẹ̀ àti àwọn t’ó jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ń retí ìkẹ́ Allāhu. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Wọ́n ń bí ọ léèrè nípa ọtí àti tẹ́tẹ́. Sọ pé: "Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá àti àwọn àǹfààní kan wà nínú méjèèjì fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì sì tóbi ju àǹfààní wọn lọ." Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yó máa ná ní sàráà. Sọ pé: “Ohun tí ó bá ṣẹ́kù lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbọ́ bùkátà inú ilé tán (ni kí ẹ fi ṣe sàráà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fun yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀
____________________
Āyah yìí l’ó kọ́kọ́ sọ̀kalẹ̀ nípa ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́. Lẹ́yìn náà, āyah mìíràn sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’; 4:43. Lẹ́yìn náà, āyah ìkẹ́yìn nípa ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́ sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:90. Àwọn āyah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí kò kúkú takora wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni pé, ọ̀mùtí àsìkò yìí kò lè rí āyah àkọ́kọ́ àti ìkejì tìràn mọ́ láti lè sọ ọtí àti tẹ́tẹ́ di ẹ̀tọ́. Ní àkọ́kọ́ ná, bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fẹ́ l’Ó ṣe mú ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́ wá ní ìmúwá ìpele mẹ́ta. Nínú ìṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ni kí Ó fi ìdájọ́ ìkejì pa ìdájọ́ àkọ́kọ́ rẹ́. Nítorí náà, nínú āyah àkọ́kọ́, Allāhu pé àkíyèsí wa sí ìgbéléwọ̀n láààrin ẹ̀ṣẹ̀ ọtí àti àǹfààní rẹ̀. Nínú āyah ìkejì, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe é ní èèwọ̀ láti máa hunrírà lórí ìrun. Àmọ́ díẹ̀ ènìyàn ló gbọ́ ìdájọ́ náà yé sí pé àkóbá ọpọlọ ni ìhunrírà jẹ́ ní èyíkéyìí àsìkò. Allāhu sì fi āyah ìkẹta ṣe ìhunrírà tàbí mímu ọtí ní èèwọ̀ nínú èyíkéyìí àsìkò, yálà ní àsìkò ìrun kíkí tàbí ní àsìkò mìíràn, yálà ní ọ̀sán tàbí ní òru, yálà ní àsìkò ayọ̀ tàbí ní àsìkò ìbànújẹ́.
nípa ayé àti ọ̀run. Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ọmọ òrukàn. Sọ pé: "Ṣíṣe àtúnṣe dúkìá wọn (láì níí dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín) l’ó dára jùlọ. Tí ẹ bá sì dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín, ọmọ ìyá yín (nínú ẹ̀sìn) kúkú ni wọ́n. Allāhu sì mọ òbìlẹ̀jẹ́ yàtọ̀ sí alátùn-únṣe. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (kí ẹ ya dúkìá wọn sí ọ̀tọ̀ nìkan ni) ìbá kó ìnira ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n."
Ẹ má fi àwọn abọ̀rìṣà lóbìnrin ṣaya títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú ẹrúbìnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lóbìnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lóbìnrin jọ yín lójú. Ẹ má sì fi onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin fún àwọn abọ̀rìṣà lọ́kùnrin títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹrúkùnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lọ́kùnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lọ́kùnrin jọ yín lójú. Àwọn (abọ̀rìṣà) wọ̀nyẹn ń pèpè sínú Iná. Allāhu sì ń pèpè sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìmọ́ra, ẹ súnmọ́ wọn ní àyè tí Allāhu pa láṣẹ fun yín. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra."
Àwọn obìnrin yín, oko ni wọ́n fun yín. Ẹ lọ s’ínú oko yín bí ẹ bá ṣe fẹ́, kí ẹ sì ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ẹ̀mí ara yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ máa pàdé Rẹ̀. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.
Ẹ má ṣe fi Allāhu ṣe ìkẹ́wọ́ fún ìbúra yín pé ẹ ò níí ṣe rere, ẹ ò níí ṣọ́ra (níbi ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ẹ ò sì níí ṣe àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá t’inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
Ìkóraró fún oṣù mẹ́rin wà fún àwọn t’ó búra pé àwọn kò níí súnmọ́ obìnrin wọn. Tí wọ́n bá ṣẹ́rí padà (láààrin ìgbà náà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Tí ọkùnrin bá sọ pé "Mo fi Allāhu búra, èmi kò níí súnmọ́ ìyàwó mi." Òǹkà ọjọ́ tí kò fi níí súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn ìbúra náà kò gbọdọ̀ tayọ oṣù mẹ́rin. Tí oṣù mẹ́rin bá bá a lórí ìpinnu rẹ̀ yìí, wọn yóò pa á láṣẹ pé kí ó padà síbi sísúnmọ́ ìyàwó rẹ̀ tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ìyẹn nígbà tí ó bá kọ̀ jálẹ̀ láti padà síbi sísúnmọ́ ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́rin.
Tí wọ́n bá sì pinnu ìkọ̀sílẹ̀, (kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóra ró fún n̄ǹkan oṣù mẹ́ta. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti fi ohun tí Allāhu ṣ’ẹ̀dá (rẹ̀) s’ínú àpò-ọmọ wọn pamọ́, tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àwọn ọkọ wọn ní ẹ̀tọ́ sí dídá wọn padà l’áààrin (àsìkò) yẹn, tí wọ́n bá gbèrò àtúnṣe. Àwọn ìyàwó ní ẹ̀tọ́ l’ọ́dọ̀ ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí àwọn ọkọ wọn ní l’ọ́dọ̀ wọn lọ́nà t’ó dára. Ipò àjùlọ tún wà fún àwọn ọkùnrin lórí wọn. Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá ń páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (ofin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀) Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
____________________
Ìyẹn ni pé, ìyàwó máa dá sadāƙi rẹ̀ padà fún ọkọ rẹ̀ nígbà tí ó bá jẹ́ pé ìyàwó fúnra rẹ̀ l’ó ní òun kò ṣèyàwó rẹ̀ mọ́.
Nítorí náà, tí ọkọ bá kọ̀ ọ́ (ní ẹ̀ẹ̀ kẹta), obìnrin náà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i mọ́ lẹ́yìn náà títí obìnrin náà yó fi fẹ́ ẹlòmíìràn. Tí ẹni náà bá tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì nígbà náà láti padà sí ọ̀dọ̀ ara wọn, tí àwọn méjèèjì bá ti lérò pé àwọn máa ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ (fún wọn), tí Ó ń ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ t’ó nímọ̀.
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí àsìkò (opó) wọn súnmọ́ kó parí, ẹ lè mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ (ní ìparí opó wọn) pẹ̀lú dáadáa. Ẹ má ṣe mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà ìnira láti lè tayọ ẹnu-àlà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, ó kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín àti ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah Ànábì s.a.w.), tí Ó ń fi ṣe ìṣítí fun yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdáju Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn, nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
____________________
Láti ọ̀dọ̀ Hasan. Ó sọ pé, Mi‘ƙọl ọmọ Yasār sọ fún mi pé, Wọ́n sọ āyah yìí (sūrah al-Baƙọrah 2:232) kalẹ̀ lórí òun. Ó sọ pé: “Mo so yìgì arábìnrin mi kan fún ọkùnrin kan. Lẹ́yìn náà, ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ títí òǹkà ọjọ́ opó rẹ̀ fi parí. À fi bí ó ṣe tún padà wá bá mi láti bá obìnrin náà s’ọ̀rọ̀ ìfẹ́ (kitbah). Mo sì sọ fún un pé, mo fún ọ lóbìnrin fẹ́ láya, mo ṣe é fún ọ ni ìtẹ́ (ìgùn), mo fi pọ́n ọ lé. Lẹ́yìn náà, o kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, o tún wá bá mi pé o fẹ́ bá a s’ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láti fẹ́ ẹ. Rárá, mo fi Allāhu búra, kò níí padà sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ láéláé.” - Ènìyàn gidi sì ni arákúnrin yìí, obìnrin náà sì fẹ́ padà sí ọ̀dọ̀ arákùnrin yìí.- Báyìí ni Allāhu sọ āyah kalẹ̀. Waliyyu (alámòjúútó) obìnrin yìí sọ pé: “Ní báyìí mo máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ Òjíṣẹ́ Allāhu.” Ó sì so yìgì rẹ̀ padà fún un. (al-Bukọ̄riy, kitāb an-Nikāh, bāb mọn ƙọ̄l: Lā nikāh ’illā bi waliy)
Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà t’ó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún. Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà t’ó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn tí ọkọ wọn kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sílẹ̀, wọn yóò kóra ró fún oṣù mẹ́rin àti ọjọ́ mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n bá parí àsìkò (opó) wọn, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí wọ́n bá ṣe fúnra wọn (láti ní ọkọ mìíràn) ní ọ̀nà t’ó dára. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ pẹ́sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí tí ẹ fi pamọ́ sínú ẹ̀mí yín. Allāhu mọ̀ pé dájúdájù ẹ̀yin yó máa rántí wọn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀, àyàfi pé kí ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ má ṣe pinnu ìta kókó yìgì títí àsìkò (opó) máa fi parí. Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Rẹ̀. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, láì tí ì súnmọ́ wọn tàbí láì tí ì sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn ní pàtó. Kí ẹ sì fún wọn ní ẹ̀bùn (ìkọ̀sílẹ̀); kí olùgbòòrò (nínú arísìkí) fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀, kí tálíkà sì fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùṣe-rere.
Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdiwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdiwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò (fún gbogbo rẹ̀, ìyẹn àwọn obìnrin) tàbí tí ẹni tí kókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bá ṣàmójú kúrò (fún gbogbo rẹ̀, ìyẹn àwọn ọkọ). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin. Kí ẹ sì dúró (kírun gẹ́gẹ́ bí) olùtẹríba fún Allāhu, láì níí sọ̀rọ̀ (mìíràn lórí ìrun).
Ṣùgbọ́n tí ẹ bá ń bẹ̀rù (ọ̀tá l’ójú ogun ẹ̀sìn), ẹ kírun yín lórí ìrìn (ẹsẹ̀) tàbí lórí n̄ǹkan ìgùn. Nígbà tí ọkàn yín bá sì balẹ̀, ẹ kírun fún Allāhu gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ (tẹ́lẹ̀) mọ̀ yín.
Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sáyé lọ, kí wọ́n ṣe àsọọ́lẹ̀ ìjẹ-ìmu ọdún kan fún àwọn ìyàwó wọn, láì sì níí lé wọn jáde kúrò nínú ilé wọn. Tí wọ́n bá sì jáde (fúnra wọn lẹ́yìn ìjáde opó), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí wọ́n bá fi’ra wọn ṣe ní dáadáa (láti ní ọkọ mìíràn). Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
N̄ǹkan ìgbádùn ní ọ̀nà t’ó dára tún máa wà fún àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀sílẹ̀. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu.
Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Ṣé o ò rí àwọn t’ó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 56 níwájú.
Ẹ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, kí Allāhu sì ṣe àdìpèlé (ẹ̀san) fún un ní àdìpèlé púpọ̀? Allāhu ń ká ọrọ̀ nílẹ̀, Ó sì ń tẹ́ ẹ sílẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Ṣé o ò rí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n wí fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣe é ṣe pé tí Wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: "Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!" Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Ànábì wọn sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Allāhu ti gbé Tọ̄lūt dìde fun yín ní ọba.” Wọ́n wí pé: “Báwo ni ó ṣe lè jẹ ọba lé wa lórí nígbà tí ó jẹ́ pé àwa ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba jù ú lọ? Kò sì ní owó púpọ̀ lọ́wọ́?” Ó sọ pé: "Dájúdájú Allāhu ṣà á lẹ́ṣà le yín lórí. Ó sì fún un ní àlékún púpọ̀ nínú ìmọ̀ àti okun ara. Allāhu ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ìjọba Rẹ̀. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀."
Ànábì wọn tún sọ fún wọn pé: "Dájúdájú àmì ìjọba rẹ̀ ni pé, àpótí yóò wá ba yín. N̄ǹkan ìfàyàbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti ohun t’ó ṣẹ́kù nínú ohun tí àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā àti ènìyàn (Ànábì) Hārūn fi sílẹ̀ ń bẹ nínú àpótí náà. Àwọn mọlāika máa rù ú wá (ba yín). Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fun yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
Nígbà tí Tọ̄lūt jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu máa fi odò kan dan yín wò. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú rẹ̀, kì í ṣe ẹni mi. Ẹni tí kò bá tọ́ ọ wò dájúdájú òun ni ẹni mi, àyàfi ẹni tí ó bá bu ìwọ̀n ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan mu.” (Ṣùgbọ́n) wọ́n mu nínú rẹ̀ àfi díẹ̀ nínú wọn. Nígbà tí òun àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ sọdá odò náà, wọ́n sọ pé: “Kò sí agbára kan fún wa lónìí tí a lè fi k’ojú Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Àwọn t’ó mọ̀ pé dájúdájú àwọn máa pàdé Allāhu, wọ́n sọ pé: "Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ (ogun) kékeré t’ó ti ṣẹ́gun ìjọ (ogun) púpọ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù."
Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: "Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́."
Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd sì pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó bá fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá.
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Àti pé dájúdájú ìwọ wà lára àwọn Òjíṣẹ́.
Àwọn Òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn, A ṣoore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan. Ó ń bẹ nínú wọn, ẹni tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (tààrà). Ó sì ṣe àgbéga àwọn ipò fún apá kan wọn. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa ẹnu (si ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasara). Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
____________________
Ẹ wo āyah 213 níwájú àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:72–76.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú ohun tí A ṣe ní arísìkí fun yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé. Kò níí sí títà-rírà kan nínú rẹ̀. Kò níí sí olólùfẹ́ kan, kò sì níí sí ìṣìpẹ̀ kan (fún àwọn aláìgbàgbọ́). Àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn sì ni alábòsí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn t’ó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Allāhu ni Alárànṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Ṣé o ò rí ẹni t’ó bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jiyàn nípa Olúwa rẹ̀, nítorí pé Allāhu fún un ní ìjọba? Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” Ó wí pé: “Èmi náà ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Mo sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Dájúdájú Allāhu ń mú òòrùn wá láti ibùyọ. Mú un wa nígbà náà láti ibùwọ̀." Wọ́n sì pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹnu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Tàbí bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí ó ti tú tòrùlé-tòrùlé rẹ̀. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn. Sì tún wo eegun náà bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 56 níwájú.
Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè." (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: "Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n."
Àpèjúwe àwọn t’ó ń ná owó wọn fún ẹ̀sìn Allāhu dà bí àpèjúwe kóró èso kan tí ó hu ṣiri méje jáde, tí ọgọ́rùn-ún kóró sì wà lára ṣiri kọ̀ọ̀kan. Allāhu yó ṣe àdìpèlé fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.
Àwọn t’ó ń ná owó wọn fún ẹ̀sìn Allāhu, tí wọn kò sì fi ìrègún àti ìpalára tẹ̀lé ohun tí wọ́n ná, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbẹ̀rù kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Ọ̀rọ̀ rere àti àforíjìn lóore jùlọ sí sàráà tí ìpalára tẹ̀lé. Allāhu sì ni Ọlọ́rọ̀, Aláfaradà.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi ìrègún àti ìpalára ba àwọn sàráà yín jẹ́, bí ẹni tí ń ná owó rẹ̀ pẹ̀lú ṣekárími, kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àpèjúwe rẹ̀ dà bí àpèjúwe àpáta kan tí erùpẹ̀ ń bẹ lórí rẹ̀. Òjò ńlá rọ̀ sí i, ó sì kó erùpẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ pátápátá. Wọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Àpèjúwe àwọn t’ó ń ná owó wọn láti wá ìyọ́nú Allāhu àti (nítorí) ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wọn, ó dà bí àpèjúwe ọgbà oko t’ó wà lórí ilẹ̀ gíga kan, tí òjò ńlá rọ̀ sí, tí àwọn èso rẹ̀ sì yọ jáde ní ìlọ́po méjì. Tí òjò ńlá kò bá sì rọ̀ sí i, ìrì ń ṣẹ̀ sí i. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
Ǹjẹ́ ẹnì kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí kí òun ní ọgbà oko dàbínù àti àjàrà, tí àwọn odò ń ṣàn ní abẹ́ rẹ̀, tí oríṣiríṣi èso tún wà fún un nínú rẹ̀, kí ogbó dé bá a, ó sì ní àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò lágbara (iṣẹ́ oko ṣíṣe), kí atẹ́gùn líle tí iná ń bẹ nínú rẹ̀ kọlu oko náà, kí ó sì jóná? Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah náà fun yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí ẹ ṣe níṣẹ́ àti nínú àwọn n̄ǹkan tí A mú jáde fun yín láti inú ilẹ̀. Ẹ má ṣe gbèrò láti ná nínú èyí tí kò dára. Ẹ̀yin náà kò níí gbà á àfi kí ẹ dijú gbà a. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Èṣù ń fi òṣì dẹ́rù bà yín, ó sì ń pa yín ní àṣẹ ìbàjẹ́ ṣíṣe. Allāhu sì ń ṣe àdéhùn àforíjìn àti oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fun yín. Allāhu ní Olùgbààyè, Onímọ̀.
Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀, A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè.
Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ìnáwó tàbí (ohunkóhun) tí ẹ bá jẹ́ ní ẹ̀jẹ́, dájúdájú Allāhu mọ̀ ọ́n. Kò sì níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún àwọn alábòsí.
Tí ẹ bá ṣàfi hàn àwọn sàráà, ó kúkú dára. Tí ẹ bá sì fi pamọ́, tí ẹ lọ́ fún àwọn aláìní, ó sì dára jùlọ fun yín. Allāhu sì máa pa àwọn ìwà àìdáa yin rẹ́ fun yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ìmọ̀nà wọn kò sí lọ́rùn rẹ, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ mọ̀nà. Ohunkóhun tí ẹ bá ń ná ní ohun rere, fún ẹ̀mí ara yín ni. Ẹ ò sì níí náwó àfi láti fi wá ojú rere Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ná ní ohun rere, A ó san yín ní ẹ̀san (rẹ̀) ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín.
(Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì nítorí kí wọ́n lè máa jagun) fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́. Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.
____________________
Àwọn aláìní wọ̀nyẹn ni a mọ̀ sí ahlus-suffah. Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-’An‘ām; 6:52 àti sūrah al-Kahf; 18:28.
Àwọn t’ó ń ná owó wọn ní òru àti ní ọ̀sán, ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpayà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn t’ó ń jẹ èlé kò níí dìde (nínú sàréè) àfi bí ẹni tí Èṣù fọwọ́ bà tí ń ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ yó ṣe dìde. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n wí pé: “Òwò ṣíṣe dà bí òwò èlé.” Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀. Ẹnikẹ́ni tí wáàsí bá dé bá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, tí ó sì jáwọ́, tirẹ̀ ni èyí t’ó ṣíwájú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì padà (síbi òwò èlé), àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Allāhu máa run òwò èlé. Ó sì máa bù sí àwọn ọrẹ. Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n kírun, tí wọ́n sì yọ Zakāh, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpayà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì fi ohun t’ó ṣẹ́kù nínú èlé sílẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Tí ẹ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ mọ̀ pé ogun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (ń bọ̀ wá ba yín). Tí ẹ bá sì ronú pìwàdà, tiyín ni ojú-owó yín. Ẹ ò níí ṣàbòsí (sí wọn). Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín.
Tí (onígbèsè) bá jẹ́ ẹni tí ara ń ni, ẹ wò ó níran di àsìkò ìdẹ̀ra. Àti pé kí ẹ fị ṣe sàráà (fún un) lóore jùlọ fun yín, tí ẹ bá mọ̀.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà ní àwìn fún gbèdéke àkókò kan, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Kí akọ̀wé ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láààrin yín ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí akọ̀wé má ṣe kọ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi mọ̀ ọ́n. Nítorí náà. kí ó ṣe àkọsílẹ̀. Kí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ pè é fún un. Kí ó bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Kò má ṣe dín kiní kan kù nínú rẹ̀. Tí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ bá jẹ́ aláìlóye tàbí aláìsàn, tàbí kò lè pè é (fúnra rẹ̀), kí alámòjúútó rẹ̀ bá a pè é ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí ẹ pe ẹlẹ́rìí méjì nínú àwọn ọkùnrin yín láti jẹ́rìí sí i. Tí kò bá sí ọkùnrin méjì, kí ẹ wá ọkùnrin kan àti obìnrin méjì nínú àwọn ẹlẹ́rìí tí ẹ yọ́nú sí; nítorí pé tí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin méjèèjì bá gbàgbé, ọ̀kan yó sì rán ìkejì létí. Kí àwọn ẹlẹ́rìí má ṣe kọ̀ tí wọ́n bá pè wọ́n (láti jẹ́rìí). Ẹ má ṣe káàárẹ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kéré ni tàbí ó tóbi, títí di àsìkò ìsangbèsè rẹ̀. Ìyẹn ni déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì gbé ìjẹ́rìí dúró jùlọ. Ó tún fi súnmọ́ jùlọ pé ẹ̀yin kò fi níí ṣeyèméjì. Àfi tí ó bá jẹ́ kátà-kárà ojú ẹsẹ̀ tí ẹ̀ ń ṣe ní àtọwọ́dọ́wọ́ láààrin ara yín, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín tí ẹ ò bá ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ẹ wá ẹlẹ́rìí sẹ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà (ọjà àwìn). Wọn kò sì níí kó ìnira bá akọ̀wé àti ẹlẹ́rìí. Tí ẹ bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, dájúdájú ìbàjẹ́ l’ẹ ṣe. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Allāhu yó sì máa fi ìmọ̀ mọ̀ yín. Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun t’ó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fun yín (tí ẹ bá ṣe é níṣẹ́). Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”
____________________
Kíyè sí i, ìgbàgbọ́ àwa ọmọlẹ́yìn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú àwọn Tírà àti àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú (ahm.s.w.) tí gbogbo wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn ’Islām, kò túmọ̀ sí títẹ̀lé wọn nínú ìlànà ìjọ́sìn wọn àti ìdájọ́ ṣíṣe ní àsìkò yìí. Ìdí ni pé, nínú oore àjùlọ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni pé, bí àwọn Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé wọ̀nyí bá fi lè wà lórí ilẹ̀ ayé títí di àsìkò Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àti àwọn àti ọmọlẹ́yìn wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀lé Ànábì wa, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tẹ̀lé al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé dípò tírà tiwọn. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:81. Ìdí nìyí tí ó sì fi jẹ́ pé, nígbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá padà sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé, al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé ni tírà tí ó máa tẹ̀lé nínú ìlànà ìjọ́sìn rẹ̀ àti ìdájọ́ ṣíṣe. Irú oore àjùlọ yìí jẹ́ oore ẹ̀ṣà fún Ànábì wa nìkan ṣoṣo (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bí àpẹẹrẹ, ní àsìkò Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti Kidr (rọdiyallāhu 'anhu), ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìlànà ìjọ́sìn àti ìdájọ́ ṣíṣe tí Allāhu fún àwọn méjèèjì. Irú èyí kò lè ṣẹlẹ̀ ní àsìkò ti Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Nítorí náà, tí ẹnikẹ́ni bá ṣe bí Kidr ní àsìkò Ànábì wa, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà ìjọ́sìn àti ìdájọ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí Ànábì wa mú wá, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti di òbìlẹ̀jẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:82.
Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe ní’ṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù t’ó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn t’ó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.
Icon