ﰡ
____________________
Ẹ kíyè sí i! Àwọn kan máa ń ké “Ƙul huwa-llāhu” mẹ́ta fún òkú mùsùlùmí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè ké òdidi al-Ƙur’ān fún un. Ìwọ̀nyí kò tọ sunnah rárá. Sūrah al-Haṣr; 59:10 ti fún wa ní àdúà t’ó jẹmọ́ òkú àti alààyè.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun” ni “Olúwa gbogbo ayé àti ọ̀run àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Nínú èdè al-Ƙur’ān, èyí ni a mọ̀ sí “rọbbu-ssamọ̄wāt wal-’ard wa mọ̄ baenahumọ̄”. Ìdí nìyí tí a ò fi túmọ̀ “Allāhu” sí “Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò fẹ́ẹ̀ sí ìtúmọ̀ tí a fọkàn balẹ̀ sí fún ọ̀rọ̀-orúkọ ńlá náà “Allāhu” àfi lílo ọ̀rọ̀-orúkọ kan èyí tí àwọn Yorùbá máa ń lò ní ọjọ́un àná fún “Ọlọ́hun”. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí máa mú àríyànjiyàn lọ́wọ́. Nítorí náà, “Allāhu” ni “Allāhu”.