ﰡ
____________________
Ìbúra Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ìbúra ẹ̀dá: Nígbà tí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe kan bá jẹ́ kìkìdá òdodo àti àmọ̀dájú, ìbura lórí rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè gba ṣe àfihàn ìdánilójú rẹ̀ fún ẹlòmíìràn nítorí kí ó lè bi iyèméjì àti rújúrújú wó lulẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti dájú pé iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀ ni níti òdodo àti àmọ̀dàjù, ẹ̀tọ́ ni fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) láti fi èyíkéyìí nínú wọn búra. Ṣebí iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu ni gbogbo bíbẹ. Àmọ́, ẹ̀dá kan kò gbọdọ̀ fi ẹ̀dá mìíràn búra nítorí pé, ẹ̀dá kan kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá mìíràn. Allāhu nìkan ni òdodo àti àmọ̀dájú fún ẹ̀dá láti fi búra nítorí pé, fífi Allāhu nìkan ṣoṣo búra ni ẹ̀sìn gbà wá láyè mọ láti fi búra. Bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ (ẹbọ ṣíṣe) sì ni fífi n̄ǹkan mìíràn búra lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
____________________
Ẹ̀tọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.