ترجمة سورة الهمزة

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الهمزة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
ẹni tí ó kó owó jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fẹ́sìn).
Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Hutọmọh?
(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (t’ó ń jò geregere),
èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).
Icon