ﰡ
Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
(Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde).
Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn. Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fun yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn.
Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fun yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko.
____________________
Èyí ni pé, dída ẹran-ọ̀sìn lọ bọ̀, ó jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún olówó rẹ̀ fún wí pé àwọn ènìyàn yóò mọ olówó ẹran-ọ̀sìn sí ẹni tí àṣírí rẹ̀ bò tàbí ọlọ́rọ̀.
Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín t’ó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ ò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
(Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ ò mọ̀.
Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀). Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām).
____________________
Àwọn ọ̀nà wíwọ́ ni ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà, ẹ̀sìn yẹhudi àti ẹ̀sìn nasara.
Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Mímu wà fun yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀. Ẹ sì ń fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn.
(Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fun yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.
Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fun yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè.
Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fun yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń lo ìrántí.
Òun ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - ó sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ – àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn àjùlọ oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀;
àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́).
____________________
Àwọn n̄ǹkan tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dá fún dídá ojú ọ̀nà mọ̀ wọ̀nyí dúró fún ìrínarí ojú ọ̀nà, yálà ní alẹ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tàbí ní ọ̀sán pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti àwọn atọ́ka òpópónà. Nítorí náà, mímọ̀ nípa ìràwọ̀ kò sí fún mímọ ìkọ̀kọ̀ àti ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la. Kò sì wulẹ̀ rọrùn fún ẹnikẹ́ni láti mọ ìkọ̀kọ̀ tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Luƙmọ̄n; 31: 34 àti sūrah an-Naml; 27:65. Síwájú sí i, ẹnikẹ́ni t’ó ń ṣe iṣẹ́ àyẹ̀wò láti sọ nípa ohun tí ó pamọ́ fún ẹ̀dá, ó ti di aláìgbàgbọ́. Bákan náà ni ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ẹnu alábigba, awòràwọ̀, oníyanrìn-títẹ̀, onítẹ̀sùnbáà-wíwò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́ sa, ’Islām kò lòdì sí ṣíṣe àyẹ̀wò àìsàn ara, àìsàn inú ẹ̀jẹ̀, yíya àwòrán egungun àti àwòrán ọlẹ̀ ní ilé ìwòsàn àwọn akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ ti òyìnbó.
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.
Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀.
Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè. Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò gbé wọn dìde.
____________________
Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀rí ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn irú wọn gbogbo lórí ìgbàgbọ́ wọn pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú, kò sì níí padà wá sílé ayé mọ́ ni gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.”. Àwọn wọ̀nyí ń fi rinlẹ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé āyah 20 t’ó ṣíwájú gbólóhùn náà ń sọ nípa ipò tí àwọn n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn sọ di olúwa àti ọlọ́hun wọn lẹ́yìn Allāhu wà, ìyẹn ni pé, wọn kò lè dá ẹ̀dá kan àti pé òkú ni wọ́n, wọ́n ní nígbà náà, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú nítorí pé, òun náà wà lára n̄ǹkan tí àwọn kan sọ di ọlọ́hun, olúwa àti olùgbàlà. Wọ́n fi kún un pé, “Ṣebí Ànábì ‘Īsā náà kò lè dá n̄ǹkan kan.”
Ọ̀rọ̀ wọn yìí jìnnà sí òtítọ́. Àti pé wọ́n ti gbé gbólóhùn náà tayọ ẹnu-àlà. Wọ́n sì ti fi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Èyí t’ó jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ ni pé, gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ohun t’ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà, aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá, kò ì kú. Síwájú sí i, àwọn ènìyàn kan ń jọ́sìn fún òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀. Ṣé wọ́n ti gbọ́ ikú tiwọn náà ni? Kò sí ọ̀kan nínú wọn t’ó tí ì di òkú. Kódà a kúkú rí àwọn ọlọ́hun mìíràn t’ó jẹ́ pé láti ojú-ayé wọn ni àwọn ẹ̀dá kan ti ń jọ́sìn fún wọn lẹ́yìn Allāhu. Àpẹẹrẹ irú wọn ni “Sati Guru Maraj” tí ó sọ ara di ọlọ́hun nínú ìlú Ìbàdàn. Alààyè ni ọ̀gbẹni náà, kò ì tí ì kú, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kú ni l’ọ́jọ́ ti àkókò ikú rẹ̀ bá dé ni.
L’ódodo ni pé àwọn kristiẹni ti sọ Jésù Kristi di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún, àmọ́ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò ì kù. Ó sì wà nípò alààyè nínú sánmọ̀, bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan t’ó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55. Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), hadīth t’ó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ l’à ń rí. Ẹni tí kò ì kú l’ó sì lè padà wá sílé ayé.
Kí wá ni èròǹgbà Allāhu lórí gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),”? Ìtúmọ̀ àkànlò èdè l’ó wà fún gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n),” nínú āyah náà, kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé, nígbà tí kò bá sí ìwúlò kan kan tí a lè rí lára ẹ̀dá, irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ti wà nípò ẹni tí a lè ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú “òkú” nítorí pé òkú ni kò ní àǹfààní kan tí ó lè ṣe fún ara rẹ̀ àti fún àwọn alààyè. Nítorí náà, Allāhu ń fi gbólóhùn “Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.” pe làákàyè gbogbo ẹnikẹ́ni t’o ń jọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ pé kò sí àǹfààní kan kan tí irú olùjọ́sìn náà lè rí lọ́dọ̀ n̄ǹkan t’ó sọ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, gẹ́gẹ́ bí alààyè kò ṣe lè rí àǹfààní kan kan láti ara òkú.
Wàyí níwọ̀n ìgbà tí àwọn kristiẹni náà ti sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kò sí àǹfààní kan tàbí oore kan tí ó lè ṣe fún wọn, wọn ìbáà pariwo orúkọ Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ Jésù nígbà igba. Àpẹẹrẹ àyè mìíràn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti lo kalmọh “òkú” àmọ́ tí kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí “ẹni tí ó ti kú” bí kò ṣe ẹni tí kò lè ṣàǹfààní fún ara rẹ̀ àti fún ẹlòmíìràn ni sūrah al-’Ani‘ām; 6:122.
Bákan náà, Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ère Jésù Kristi àti igi àgbélébùú rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́, tí wọ́n ń jọ́sìn fún, kò lè sọ̀rọ̀, kò lè ríran, kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́.
Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga.
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
(Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú.
____________________
Kíyè sí i! Kò sí ìtakora láààrin āyah yìí àti sūrah an-Najm; 53:38. Āyah àkọ́kọ́ ń sọ nípa ìpín ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa wà fún onísábàbí iṣẹ́-aburú àti onísábàbí ìṣìnà. Ìyẹn ni pé, bí ìyà ṣe wà fún oníṣẹ́-aburú bẹ́ẹ̀ náà ni ìyà wà fún onísábàbí rẹ̀. Ní ti āyah ti sūrah an-Najm, ò ń sọ nípa bí kò ṣe níí sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni láti gbé àpapọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ t’ó wà lọ́rùn rẹ̀ fún ẹlòmíìràn ní Ọjọ́ ẹ̀san. Nítorí náà, àròpọ̀ iṣẹ́ tí ẹ̀dá ṣe àti iṣẹ́ tí ó ṣe sábàbí rẹ̀ l’ó máa wà lọ́rùn rẹ̀. Kò sì níí rí alábàárù-ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-‘ankabūt; 29:12 àti 13.
Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó láti ìpìlẹ̀. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tì torí wọn yapa (Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
(Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Rárá (ẹ ṣiṣẹ́ aburú)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Nítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
Wọ́n sọ fún àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára.
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Àwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fun yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Nítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po.
Àwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé.
Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn t’ó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí?
Tí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, dájúdájú kò níí fi mọ̀nà, kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn.
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Kò rí bẹ́ẹ̀, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. Òdodo sì ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀.
(Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́.
Ọ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.
____________________
Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, àyè méjì péré ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti pe àwọn kan ní “ahlu-ththikr” (ìtúmọ̀ “àwọn oníràn-ántí / àwọn tí A sọ ìrántí kalẹ̀ fún). Àyè kìíní ni sūrah an-Nahl; 16:43. Àyè kejì ni sūrah al-‘Anbiyā’; 21:7. Àwọn sūfī sì ń lérò pé àwọn ni “ahlu-ththikr”. Àti pé àwọn gan-an ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah méjèèjì náà.
Èsì: Ohun tí wọ́n ń sọ yìí kì í ṣe òtítọ́ páàpáà. Èyí tí í ṣe òdodo ọ̀rọ̀ ni pé, àwọn onímọ̀ nípa at-Taorāt àti al-’Injīl ni Allāhu ń tọ́ka sí, kì í ṣe àwọn sūfī. Ìdí ni pé, okùnfà āyah méjèèjì yìí ni pé, Allāhu fi fọ èsì sí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ tí wọ́n ń sọ pé mọlaika ni Allāhu máa ń fi iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rán, kì í ṣe ènìyàn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń pàṣẹ fún pé kí wọ́n lọ bèèrè wò lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa tíra ìṣáájú bóyá ní òdodo ni Allāhu ti fi iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rán mọlāika kan rí sí àwọn ènìyàn, tí yó sì máa gbé láààrin wọn ṣíwájú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àtakò àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyí l’ó tún bí ìsọ̀kalẹ̀ sūrah Yūnus; 10:2. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yūsuf 12:109.
(A fi) àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
Ṣé àwọn t’ó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura?
Tàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́.
Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni? Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́.
Àti pé ṣé wọn kò rí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń padà yọ láti ọ̀tún àti òsì ní olùforíkanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)?
Allāhu sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
Wọ́n ń páyà Olúwa wọn t’Ó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn.
____________________
Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:18 àti sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Allāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”
TiRẹ̀ sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni ẹ̀sìn títí láéláé Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni?
____________________
Ìyẹn ni pé, Allāhu nìkan ṣoso ni gbogbo ẹ̀dá gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún.
Ohunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni kí ẹ máa pè (fún ìdáǹdè.)
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá sì mú ìnira náà kúrò fun yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò mọ̀. Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́.
Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). – Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn!
Nígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò ṣókùnkùn, ó sì máa kún fún ìbànújẹ́.
Ó sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà á ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú!
Ti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé t’ó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di ìgbà kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.”
Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) n̄ǹkan tí wọn kórira lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni.
Mo fi Allāhu búra, dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn lónìí. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
____________________
Ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi Ara Rẹ̀ búra. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Un láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Òun l’Ó ni Ara Rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún ẹ̀dá kan láti fi ara rẹ̀ búra dípò Allāhu, tí Ó ni í.
A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí; ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
Dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fun yín mu nínú n̄ǹkan t’ó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ t’ó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn t’ó ń mu ún.
____________________
Ìyẹn ṣíwájú kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) t’ó ṣe ọtí ní èèwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:90.
Àti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí àti ohun àmú-ṣọrọ̀ t’ó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè.
Olúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: "Mu ilé sínú àpáta, igi àti ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga.
Lẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba." Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn ni fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀.
Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára.
Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, kí wọ́n fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, kí wọ́n sì jọ pín in ní dọ́gbadọ́gba! Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?
____________________
Àkàwé kan nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti pe làákàyè wọn sí ohun tí wọn kò lè gbà, àmọ́ tí wọ́n ń fi lọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Kókó àkàwé náà sì ni pé, ǹjẹ́ ẹnì kan lè gbà fún ẹrú rẹ̀, yálà ẹrú ogun tàbí ẹrú àfowórà, pé kí òun àti ẹrú rẹ̀ jọ pín dúkìá rẹ̀ sí méjì ní dọ́gbadọ́gba. Àwọn dúkìá bí àwọn ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo dúkìá mìíràn, ǹjẹ́ olówó ẹrú lè kò ìlàjì rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ bí? Kò níí ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, pípe ẹ̀dá kan nínú ẹ̀dá Allāhu ní olúwa àti olùgbàlà tí wọn yóò máa jọ́sìn fún, ó ti jọ pé ẹ̀dá náà tí ó jẹ́ ẹrú fún Allāhu ti sọra rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Allāhu níbi dúkìá Rẹ̀, tí í ṣe àwa ẹ̀dá Rẹ̀. Nítorí náà, āyah yìí kò ní ìtúmọ̀ pípín dúkìá ẹni sí méjì fún ẹrú wa. Bákan náà, āyah yìí kò sì ní kí á sọ olówó dí ẹgbẹ́ olòṣì, gẹ́gẹ́ bí ètò ìjọba “communism”. Ohun tí ẹ̀dá kò lè gbà, àmọ́ tí ó ń fi lọ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni àkàwé tí ó jẹyọ nínú āyah náà.
Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fun yín láti ara yín. Ó fun yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, wọn yó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ìdẹ̀ra Allāhu?
Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan).
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn àkàwé náà lélẹ̀ nípa Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí t’ó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà?
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún ẹ̀dá láti fi àkàwé àti àfijọ lélẹ̀ fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gẹ́gẹ́ bí āyah 74 ṣe fi rinlẹ̀ ṣíwájú, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lè fi àkàwé ara Rẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ̀dá nítorí kí ẹ̀dá lè mọ̀ pé Allāhu tóbi jùlọ. Nítorí náà, kíkó ara ẹni sínú wàhálà tí kò lẹ́tọ̀ọ́ ni sísọ ẹ̀dá kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nítorí pé kò sí nínú wọn tí ó lè gbọ́ ìpè, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọn yóò jẹ́ ìpè. Báwo ni oore kan ṣe fẹ́ ti ọ̀dọ̀ wọn wá? Àwọn t’ó ń pè wọ́n kò sì yé wàhálà ẹ̀mí ara wọn lórí ìpè asán? Àmọ́, Allāhu, Ẹni tí Ó ń gbọ́ ìpè ẹ̀dá, Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹ̀dá, Òun ní ìjọ́sìn tọ́ sí. Ó sì ti pa wá ní àṣẹ láti jọ́sìn fún Un. Àṣẹ́ náà ni àṣẹ ẹ̀tọ́. Òun nìkan ṣoṣo sì ni ìpè náà tọ́ sí.
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
Ṣé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni t’ó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu ṣe ibùsinmi fun yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan t’ó fúyẹ́ fun yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn, irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀.
____________________
Ìtàn Sūfiyyah Ní Ṣókí: Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, àyè kan péré ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti lo kalmọh “’aswāf”. “’Aswāf” ni ọ̀pọ̀ “sūf”. Ìtúmọ̀ “sūf” ni “irun àgùtàn”. Bákan náà, lílò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo kalmọh “’aswāf” jẹ́ ṣíṣe ìrègún oore Rẹ̀ lórí wa nípa bí “irun àgùtàn” ṣe jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò tí a fi ń ṣe àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn nínú ìṣẹ̀mí ayé wa. Àmọ́ ohun tí a fẹ́ pe àkíyèsí wa sí ní àyè yìí ni pé, Allāhu kò sọ̀rọ̀ “sūf” gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìjọ́sìn tàbí àdìsọ́kàn ìgbàgbọ́ fún àwa mùsùlùmí. Ohun èlò àti n̄ǹkan ìgbádùn ayé, bíi lílo “sūf” fún híhun aṣọ fún oríṣiríṣi lílò àti fífi ṣòkòwò kátà-kárà nínú ìṣẹ̀mí ayé wa, ni ìwúlò àti àǹfààní tí à ń rí lára “sūf”. Síwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, tí a bá fẹ́ fi ìbátan hàn láààrin n̄ǹkan méjì pẹ̀lú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ìyẹn nígbà tí a bá fẹ́ ṣe àfihàn ohun tí wọ́n lò láti fi ṣe n̄ǹkan kan, tàbí nígbà tí a bá fẹ́ ròyìn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí ó máa ń lò, a kàn máa fi lẹ́tà “yā’un muṣaddadah” kún kalmọh náà, tí “yā’un muṣaddadah” náà sì máa jẹ́ àfòmọ́-ìparí fún kalmọh náà. “Yā’un muṣaddadah” yìí ni à ń pè ní “yā’u-nnisbah” (yā’u ìbátan / yā’u afìbátanhàn) nínú ẹ̀kọ́ mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá. Nítorí náà, nínú èdè Lárúbáwá nígbà tí a bá fẹ́ sọ pé aṣọ kan jẹ́ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun tàbí nígbà tí a bá fẹ́ sọ pé ènìyàn kan máa ń wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun, a kàn máa so àfòmọ́ ìparí “yyun” (èyí tí a pè ní “yā’u-nnisbah”) mọ́ ìparí kalmọh “sūf”, ó sì máa di “صُوفِيٌّ” “sūfiyyun/ sūfiyy” (akọ, ẹyọ), “صُوفِيُّونَ” “sūfiyyūn” (akọ, ọ̀pọ̀), “صُوفِيَّةٌ” “sūfiyyatun / sūfiyyah” (abo, ẹyọ / ọ̀rọ̀-orúkọ tí a ṣẹ̀dá láti ara sūf) “صُوفِيَّاتٌ” “sūfiyyāt” (abo, ọ̀pọ̀). Ìtúmọ̀ gbogbo rẹ̀: “aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun / olùwọṣọ-irun àgùtàn.
Síwájú sí i, nínú àwọn ìran n̄ǹkan tí ẹ̀dá ń lò fún híhun aṣọ, aṣọ èyí tí wọ́n bá fi irun àgùtàn hún máa ń jẹ́ aṣọ t’ó rọjú jùlọ ní rírà. Nítorí èyí, aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ àwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn olówó kì í sì fẹ́ rà á fún wíwọ̀ sọ́rùn nítorí pé, ó jẹ́ aṣọ pọ́ọ́kú-lowóẹ̀, kì í sì jọ̀là lára rárá bí ìran aṣọ mìíràn. Nítorí pé, aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ tálíkà, l’ó mú aṣọ náà di ọ̀gá aṣọ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ráyé sá nínú àwọn ẹni-ìṣaájú.
Ìmúra àwọn ẹni-ìṣaájú gbajúmọ̀ pẹ̀lú wíwọ aṣọ irun àgùtàn láti fi mú ayé bín-íntín tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ t’ó fi jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ́ pe ẹnikẹ́ni nínú wọn ní olùráyésá, “sūfiyy” ni wọ́n á pe irú ẹni náà nítorí pé kò sí olùráyésá kan nínú wọn àfi kí ó dúnní mọ́ wíwọ aṣọ irun àgùtàn tààrà. Ìdí nìyí tí a bá gbọ́ pé wọ́n pe àáfà àgbà kan nínú àwọn aṣíwájú rere fún wa ní “sūfiyy” bí Imām Ṣāfi‘iyy tàbí ẹlòmíìràn, ìráyésá wọn nípa wíwọ aṣọ irun àgùtàn l’ó ń mú wọn jẹ́ bẹ́ẹ̀. Lára sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ni ìráyésá wà. Oríkì ìráyésá nìyí nígbà náà: Ìráyésá ni jíjìnnà sí àwọn n̄ǹkan olówó ńlá àti jíjìnnà sí kíkó ọrọ̀ ilé ayé jọ àti lílo àwọn n̄ǹkan t’ó kéré jùlọ ní òǹkà láti fi gbé ìṣẹ̀mí ayé ẹni ró. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ni aṣíwájú gbogbo àwọn olùráyésá. Dídi olùwọṣọ-irun àgùtàn “sūfiyy lábẹ́ ìráyésá” nígbà náà kò lòdì sí ẹ̀sìn ’Islām nítorí pé jíjẹ́ “sūfiyy” ẹnikẹ́ni nínú wọn kò sọ ọ́ di ẹni tí ó ní ìlànà ẹ̀sìn tàbí àdìsọ́kàn mìíràn t’ó yàtọ̀ sí sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bí ọ̀rọ̀ àwọn sūfiyy “àwọn olùwọṣọ-irun àgùtàn” ṣe wà nìyẹn títí di ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn Hijrah.
Lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn Hijrah ni àwọn kan nínú ìlú Basrọ nílẹ̀ ‘Irāƙ bá sọ orúkọ yìí “صُوفِيَّةٌ” “sūfiyyah” di n̄ǹkan mìíràn mọ́ra wọn lọ́wọ́. Àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn gbé ìtúmọ̀ rẹ̀ kúrò lábẹ́ “wíwọ aṣọ irun àgùtàn” pátápátá, wọ́n sì fún un ní ìtúmọ̀ àgbélẹ̀rọ àti ayédèrú bíi kí wọ́n sọ pé “sūfiyyah” túmọ̀ sí dídi ẹni mímọ́, olùfọkànsìn, ẹni ẹ̀ṣà, wòlíì Ọlọ́hun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Paríparí rẹ̀ ni pé, àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn bá sọ orúkọ náà “sūfiyyah” di ìlànà ẹ̀sìn titun kan, wọ́n sì gbé e jù sábẹ́ ẹ̀sìn ’Islām. Àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí to ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìròrí àwọn ọ̀ṣẹbọ, ìròrí àwọn yẹhudi àti ìròrí àwọn kristiẹni papọ̀ mọ́ra wọn ní ọ̀nà ẹ̀tàn pẹ̀lú yíyí àwọn ìtúmọ̀ āyah al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì lọ́rùn láti fi ṣe àtìlẹ́yìn fún ìlànà titun náà tí wọ́n ronú gbékalẹ̀ lábẹ́ orúkọ “sūfiyyah”. Nígbà tí wọ́n sì fura mọ̀ pé, orúkọ yìí kò kún tó, wọ́n bá tún ṣe ẹ̀dà orúkọ mìíràn láti ara rẹ̀. Orúkọ náà ni “التَّصَوُّفُ” “at-tasọwwuf”. Báyìí ni “sūfiyyah” tàbí “at-tasọwwuf” ṣe di ìjọ́sìn mìíràn ní pẹrẹu láààrin àwọn aláìlẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bọ́há sọ́wọ́ àwọn àáfà onibidia.
Bákan náà, nígbà tí àwọn àáfà onibidia tasọwwuf wọ̀nyí pèrò sọ́kọ̀ bidiah tasọwwuf tán, òǹpèrò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àáfà onibidiah wọ̀nyẹn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀ pèrò dípò lílo orúkọ àgbélẹ̀rọ tí wọ́n dìjọ ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà, ni ayé wọn bá di ìlànà / tọrīkọ “at-tasọwuffu al-kọ̄diriyyah”, “at-tasọwuffu al-kọlwatiyyah” “at-tasọwuffu at-tijāniyyah” “at-tasọwuffu aṣ-Ṣāthiliyyah”, “at-tasọwuffu al-Haṣwatiyyah” àti “at-tasọwuffu an-naƙṣanbadiyyah”. Títí di òní olónìí, wọn kò yé fi orúkọ aṣíwájú wọn pèrò sọ́kọ̀ bidiah tasọwuffu wọn. Èyí l’ó sì ṣokùnfà bí wọ́n tún ṣe ń pe àwọn kan nínú àwọn ìlànà / tọrīkọ wọn ní “at-tasọwuffu an-Niyāsiyyah””, “at-tasọwuffu al-bulāliyyah” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mutasọwiffūn wọ̀nyí náà ni wọ́n mú tíà sísà (bíi firāku, katali) àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, oogun ṣíṣe, idán pípa, lílo àlùjànnú, lílọ nínú ẹ̀mí àti iṣẹ́ jálàbí ṣíṣe (ìyẹn, iṣẹ́ babaláwo) wọ inú ẹ̀sìn ’Islām. Àwọn sì ni wọ́n pọ̀ jùlọ nílẹ̀ aláwọ̀dúdú, pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ Naijiria.
Wò ó, ìlànà tasọwuffu ti lé ní ìgbà ọ̀nà. Ó sì ti di tọ́rọ́-fọ́kánlé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ t’ó fí jẹ́ pé, tí ọkùnrin kan kò bá ti rí iṣẹ́ halāl ṣe ní iṣẹ́ òòjọ́, ó máa di “ṣééù”, tí obìnrin náà kò bá ti rí ọ̀kan-ṣèkan mọ́, òun náà á sọra rẹ̀ di “ṣééhá”. Òṣì, àìríná àti àìrílò ti kó wọn sínú tasọwuffu. Pẹ̀lú ète àwọn àlùjànnú, iná idán àwọ́rò wọn sì ń jò bùlàbùlà. Kíyè sí i, yálà al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò sí ọ̀kan kan nínú méjèèjì t’ó fàyè gba ìlànà mìíràn yàtọ̀ sí sunnah Ànábì nínú ìjọ́sìn mùsùlùmí tàbí ìṣe mùsùlùmí tàbí ìròrí mùsùlùmí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún lérò pé ìlànà àfikún kan tún wà fún mùsùlùmí láti lè súnmọ́ Allāhu tààrà dípò gbígba tító pẹ̀lú sunnah Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), onítọ̀ún ni a ó máa pè ní onibidiah “aládàádáálẹ̀ ìlànà ẹ̀sìn”. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá sì ronú pìwàdà pátápátá kúrò lórí dída sunnah Ànábì pọ̀mọ́ ìlànà àdádáálẹ̀ pẹ̀lú èròǹgbà láti pé lẹ́sìn, Iná ni ẹ̀san rẹ̀ lọ́run ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:115. Àkàwé sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni àpẹẹrẹ omi tí wọ́n rọ kún inú ìgò fìfo. Àkàwé èyíkéyìí ìlànà àdádáálé tí wọ́n bá fi kún sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ni omi mìíràn tí wọ́n tún fẹ́ rọ mọ́ ẹ̀kún igo omi náà. Ìgbàkígbà tí ẹnikẹ́ni bá tún rọ omi mìíràn sínú ẹ̀kún igo omi, ilẹ̀ ni yóò máa dà sí títí láéláé. Omi náà yó sì máa ṣòfò dànù. Ìdí nìyí ti gbogbo ìran tasọwuffu àti àpapọ̀ tasọwuffu fi máa di òfò pọ́nńbélé lọ́jọ́ ìṣírò-iṣẹ́. Àti pé, ọ̀kan pàtàkì nínú bidiah Aṣaetäni ni gbogbo ìran tasọwuffāt pátápátá nítorí pé “sūfiyyah” ti kúrò ní abẹ́ ìráyésá pátápátá, ó sì ti bọ́ sí abẹ́ awo ṣíṣe, awo èṣù. Kí Allāhu bá wa gbé sunnah Ànábì ga. Kí Ó bá wa rẹ bidiah Aṣaetāni nílẹ̀. Kí Ó sì bá wa paná adẹ́bọ rẹ́.
Allāhu ṣe àwọn ibòji fun yín láti ara n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fun yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fun yín t’ó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ t’ó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín. Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí.
____________________
Àpẹẹrẹ aṣọ t’ó ń dáàbò bo ẹ̀dá lójú ogun ni ẹ̀wù irin tí kì í jẹ́ kí ọfà wọlé sínú ara. Àwọn aṣọ ààbò ogun wọ̀nyí kò túmọ̀ sí aṣọ òògùn bíi bàǹtẹ́ òògùn fún ààbò lójú ogun. Irúfẹ́ àwọn aṣọ òògùn wọ̀nyí jẹ́ èèwọ̀ ẹ̀sìn nítorí pé wọn kò là níbi ṣíṣe ẹbọ àti wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ àlùjànnú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lo irúfẹ́ aṣọ òògùn yìí sì ti sọ ara rẹ̀ di ọ̀ṣẹbọ.
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe tìrẹ.
Wọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore.
(Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
Nígbà tí àwọn t’ó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà wọn ní fífúyẹ́, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
Nígbà tí àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”
Wọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ yó sì di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́.
____________________
Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ tí ó máa di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọ̀run ni ìṣìpẹ̀ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà wọn.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́.
(Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan, ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.
Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Kí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan lọ. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fun yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú Wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fun yín.
Ẹ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.
Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san àwọn t’ó ṣe sùúrù lẹ́san wọn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.
Nígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
Dájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
Ẹni t’ó lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn t’ó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn t’ó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu.
Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun t’Ó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.
Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní ti òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí.
A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan l’ó ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń yẹ̀ sí (tí wọ́n ń tọ́ka sí pé ó ń kọ́ ọ) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí.
Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu l’ó ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn sì ni òpùrọ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí àìgbàgbọ́ bá tẹ́ lọ́rùn, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni afọ́núfọ́ra.
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́).
(Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé láti du orí ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n.
Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, t’ó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fun yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ t’ó yàtọ́ sí “Allāhu”. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fi ìnira ebi kan, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.
Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run).
Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn t’ó di yẹhudi. A ò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
____________________
Ìyẹn nínú sūrah an-Nisā’; 4:160-161.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe lẹ́yìn rẹ̀ dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Ó máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
A ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere.
Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn t’ó yapa ẹnu nípa rẹ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí.
____________________
Yíyapa-ẹnu tí àwọn yẹhudi yapa ẹnu sí ṣíṣe àgbéga fún ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n sì fi ọjọ́ Sabt dípò rẹ̀, l’ó ṣokùnfà bí ọjọ́ náà ṣe di dandan fún ọ̀wọ́ wọn nìkan láti ṣe àgbéga rẹ̀. Nítorí náà, ọpẹ́ ni fún Allāhu tí kò ṣe ìjọ́ mùsùlùmí ní olùyapa sí ṣíṣe àgbéga ọjọ́ Jímọ̀, ọjọ́ t’ó lóore jùlọ nínú ọ̀ṣẹ̀.
Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì s.a.w.) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí).
Tí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, ó mà sì lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù.
Ṣe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète.
Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn t’ó ń ṣe rere.