ﰡ
(Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe é ní òfin. A sì sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì.
____________________
Ọgọ́rùn-ún kòbókò àti ẹ̀wọ̀n ọdún kan tàbí lílé kúrò nínú ìlú fún ọdún kan ni ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ‘akdu-nnikāh pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Àmọ́ lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà fún onísìná tí ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí. Ẹ̀dá ìbá mọ ìjìyà wọ̀nyí lọ́ràn, ìbá jìnnà sí àgbèrè ṣíṣe. Ìwọ arákùnrin àti arábìnrin mi, bí ọ̀ràn sìná bá fúyẹ́ ni, ìbá tí la ìjìyà lọ bí kò ṣe títọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ronú pìwàdà lónìí, má sì ṣe tìràn mọ́ àìsí Ṣẹria lórílẹ̀ èdè wa. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan sọ pé āyah wo l’ó ní kí á lẹ onísìná t’ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí lókò pa? Kì í ṣe āyah nìkan ni mùsùlùmí ń tẹ̀lé nínú Ṣẹria àti ohun gbogbo t’ó rọ̀mọ́ ẹ̀sìn rẹ̀. Hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó ṣe é lófin fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé, lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbé dìde lórí àwọn kan tí wọ́n jẹ́wọ́ ọ̀ràn sìná lásìkò rẹ̀. Bí ó sì ṣe wà nìyẹn nínú òfin Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìdájọ́ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) náà mú wá nìyẹn. Kò sì sí āyah kan t’ó lòdì sí èyí. Mùsùlùmí t’ó bá sì yapa Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí èyí ti sọnù jìnnà.
Síwájú sí i, tí ọkùnrin kan bá ṣe zinā pẹ̀lú obìnrin abilékọ kan, tí ó bá di oyún, tí ọkọ rẹ̀ kò sì mọ̀, tí ìyàwó rẹ̀ kò sì jẹ́wọ́, ọkọ l’ó ni ọmọ tí ó bá fi oyún náà bí àfi tí ọkọ fúnra rẹ̀ bá padà sọ pé òun kọ́ l’òun ni oyún náà. Bákan náà, tí ẹni tí kò sí nílé ọkọ bá ṣe zinā, tí ó bá doyún, ọmọ náà kò níí jẹ́ ọmọ fún arákùnrin t’ó ṣe zinā pẹ̀lú arábìnrin náà, kò sì níí jẹ́ orúkọ rẹ̀ àyàfi tí ó bá fi rinlẹ̀ pé òun l’òun ni oyún, tí ó sì bèèrè fún ọmọ. Ọmọ rẹ̀ ni ọmọ náà, àmọ́ ó bí i nípasẹ̀ zinā. Ìkíní kejì bàbá àti ìyá ọmọ náà sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjìyà zinā láti rí àforíjìn Ọlọ́hun.
Síwájú sí i, lásìkò oyún zinā, wọn kò níí fún wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí oorun ìfẹ́ mìíràn mọ́ torí pé kò sí ìtakókó yìgì láààrin wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn t’ó ní wọ́n lè ṣe ìtakókó yìgì obìnrin náà fún arákùnrin t’ó ṣe zinā pẹ̀lú rẹ̀ lórí oyún zinā náà nítorí kí wọ́n lè máa jẹ ìgbádùn ara wọn lọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́, èyí tí ó dára jùlọ ni pé, kí wọ́n má ṣe ta kókó yìgì lórí oyún zinā nítorí kí àtọ̀ àìtọ́ má baà ròpọ̀ mọ́ àtọ̀ ẹ̀tọ́. Àtọ̀ zinā ni àìtọ́. Àtọ̀ yìgì ni ẹ̀tọ́. Bákan náà, waliyyu ọmọbìnrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ láti ta kókó yìgì fún arákùnrin náà lẹ́yìn ìbímọ tí kò bá yọ́nú sí ẹ̀sìn àti ìwà arákùnrin náà. Àmọ́ lábẹ́ àìmọ̀kan, tọkọ tìyàwó t’ó bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn lórí zinā, waliyyu obìnrin lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìtakókó yìgì fún arákùnrin náà, wọn ìbáà ti bi ọmọ púpọ̀ fúnra wọn ṣíwájú. Èyí sì ni àtúnṣe ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì.
Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin. A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
N̄ǹkan mẹ́ta ni kalmọh “nikāh” dúró fún. Ìkíní, “ ‘aƙdu-nnikāh”; ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ìtakókó yìgì”. Èyí ni kí waliyyu (aláṣẹ) obìnrin sọ fún ọkùnrin kan pé, “Mo fi ọmọbìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ lágbájá fún ọ, kí o fi ṣe ìyàwó.” Gbólóhùn yìí lè wáyé yálà nípasẹ̀ kí ọkùnrin náà bèèrè fún un pé, “Ẹ fún mi ní ọmọbìnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ lágbájá kí n̄g fi ṣe ìyàwó.” (ìyẹn síwájú gbólóhùn waliyyu obìnrin náà) tàbí kí ọkùnrin náà sọ pé, “Mo tẹ́wọ́ gbà á láti fi ṣe ìyàwó” (ìyẹn lẹ́yìn gbólóhùn waliyyu). Gbólóhùn ti waliyyu àti gbólóhùn ti ọkùnrin náà ni a mọ̀ sí “gbólóhùn ìtakókó yìgì. Ìkejì, “nikāh” tún túmọ̀ sí “jimọ̄‘”; ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “oorun ìfẹ́” èyí tí ó (ń) wáyé lẹ́yìn “ ‘aƙdu-nnikāh” – ìtakókó yìgì. Ìkẹta, “nikāh” tún túmọ̀ sí àdàpè àgbèrè “zinā”. Oríkì “zina” nìyí: “Kí ọkùnrin kan ṣe jimọ̄’ (oorun ìfẹ́ lójú ara) obìnrin kan ṣíwájú “aƙdu-nnikāh” láì sí nínú ìrújú lórí irú ẹni tí obìnrin náà jẹ́.” Zina yìí l’ó ń bí ìjìyà kòbókò ọgọ́rùn-ún fún ẹni tí kò ì ṣe “ ‘aƙdu-nnikāh” pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Ó sì ń bí lílẹ̀ lókòpa fún ẹni tí ó bá ti ṣe “ ‘akd-nnikāh pẹ̀lú ẹnì kan rí ṣíwájú. Nikāh tí ó ń túmọ̀ sí “zinā” yìi sì ni ìtúmọ̀ t’ó wà fún kalmọh “nikāh” t’ó jẹyọ nínú āyah yìí. Nípa èyí, àgbọ́yé āyah náà ni pé, alágbèrè lọ́kùnrin kò lè rí obìnrin kan mú ní ọ̀rẹ́ oníṣekúṣe bí kò ṣe alágbèrè ẹgbẹ́ rẹ̀ lóbìnrin tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin tí kò mọ zinā sí èèwọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni pé, alágbèrè lóbìnrin kò lè rí ọkùnrin kan mú ní ọ̀rẹ́ alágbèrè, bí kò ṣe alágbèrè ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin tí kò mọ zinā sí èèwọ̀. Āyah yìí kò ṣe ní èèwọ̀ fún onígbàgbọ́ òdodo láti ṣe ‘aƙdu-nikāh (ìtakókó yìgì), lẹ́yìn náà jimọ̄‘ (oorun ìfẹ́) pẹ̀lú ẹni tí ó ti ronú pìwàdà lórí zinā. Zinā ni Allāhu sì ń tọ́ka sí pé Òun ṣe ní èèwọ̀ ní ìparí āyah náà, kì í ṣe ṣíṣe ‘aƙdu-nikāh pẹ̀lú ẹni t’ó ti ronú pìwàdà lórí zinā.
Àwọn t’ó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Àwọn t’ó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ìyàwó wọn, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí fún wọn àfi àwọn fúnra wọn, ẹ̀rí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú òun wà nínú àwọn olódodo.
Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ibi dandan Allāhu máa bá òun, tí òun bá wà nínú àwọn òpùrọ́.
Ohun tí ó máa yẹ ìyà fún ìyàwó ni pé kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú ọkọ òun wà nínú àwọn òpùrọ́.
Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ìbínú Allāhu máa bá òun, tí ọkọ òun bá wà nínú àwọn olódodo.
____________________
Tí abilékọ bá bí ọmọ, àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ sọ pé òun kọ́ ni òun ni ọmọ náà, tí ìyàwó sì takú pé ọkọ òun l’ó ni ọmọ náà, ìgbéyàwó náà máa túká pẹ̀lú ìṣẹ́bi láààrin tọkọ tìyàwo náà lórí ìlànà t’ó wà nínú āyah 6 sí āyah 9. Lẹ́yìn ìṣẹ́bi náà, ọmọ náà yóò máa bá ìyá rẹ̀ lọ. Ìkíní kejì kò sì lè di tọkọ tìyàwó mọ́. Nítorí náà, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ṣọ́ abẹ́ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ níbi fífi ẹ̀sùn zinā kan ẹnì kejì rẹ̀.
Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá máa tú àṣírí yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú àwọn t’ó mú àdápa irọ́ wá jẹ́ ìjọ kan nínú yín. Ẹ má ṣe lérò pé aburú ni fun yín. Rárá o, oore ni fun yín. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ti ní ohun tí ó dá ní ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ẹni tí ó dá (ẹ̀ṣẹ̀) jùlọ nínú wọn, ìyà ńlá ni tirẹ̀.
Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin ro dáadáa rora wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni àdápa irọ́ pọ́nńbélé.”
Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ní ilé ayé àti ní ọ̀run ni, dájúdájú ìyà ńlá ìbá fọwọ́ bà yín nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ kiri ní ìsọkúsọ.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gbà á (láààrin ara yín) pẹ̀lú ahọ́n yín, tí ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀; ẹ lérò pé n̄ǹkan t’ó fúyẹ́ ni, n̄ǹkan ńlá sì ni lọ́dọ̀ Allāhu.
Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni t’ó tóbi.”
Allāhu ń ṣe wáàsí fun yín pé kí ẹ má ṣe padà síbi irú rẹ̀ mọ́ láéláé tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu ń ṣàlàyé àwọn āyah náà. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú àwọn t’ó nífẹ̀ẹ́ sí kí (ọ̀rọ̀) ìbàjẹ́ máa tàn kálẹ̀ nípa àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá tètè fìyà jẹ yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù, dájúdájú (Èṣù) yóò pàṣẹ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú (fún un). Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni, ẹnì kan ìbá tí mọ́ nínú yín láéláé. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Kí àwọn t’ó ní ọlá àti ìgbàláàyè nínú yín má ṣe búra pé àwọn kò níí ṣe dáadáa sí àwọn ìbátan, àwọn mẹ̀kúnnù àti àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Kí wọ́n ṣàforíjìn, kí wọ́n sì ṣàmójúkúrò. Ṣé ẹ ò fẹ́ kí Allāhu foríjìn yín ni? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn t’ó ń parọ́ sìná mọ́ àwọn ọmọlúàbí l’óbìnrin, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, A ti ṣẹ́bi lé wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Ní ọjọ́ tí àwọn ahọ́n wọn, ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn yóò máa jẹ́rìí takò wọ́n nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́,
ní ọjọ́ yẹn ni Allāhu yóò san wọ́n ní ẹ̀san wọn tí ó tọ́ sí wọn. Wọn yó sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo pọ́nńbélé.
Àwọn obìnrin burúkú wà fún àwọn ọkùnrin burúkú. Àwọn ọkùnrin burúkú sì wà fún àwọn obìnrin burúkú. Àwọn obìnrin rere wà fún àwọn ọkùnrin rere. Àwọn ọkùnrin rere sì wà fún àwọn obìnrin rere. Àwọn (ẹni rere) wọ̀nyí mọ́wọ́-mọ́sẹ̀ nínú (àìdaa) tí wọ́n ń sọ sí wọn. Àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
____________________
Ẹ wo bí gbólóhùn yìí ti ṣe rẹ́gí sí sūrah al-Baƙọrah; 2:221.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn ilé kan yàtọ̀ sí àwọn ilé yín títí ẹ máa fi tọrọ ìyọ̀ǹda àti (títí) ẹ máa fi sálámọ̀ sí àwọn ará inú ilé náà. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Tí ẹ ò bá sì bá ẹnì kan kan nínú ilé náà, ẹ má ṣe wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi yọ̀ǹda fun yín. Tí wọ́n bá sì sọ fun yín pé kí ẹ padà, nítorí náà ẹ padà. Òhun l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti wọ inú àwọn ilé kan tí kì í ṣe ibùgbé, tí àǹfààní wà nínú rẹ̀ fun yín. Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
____________________
Àpẹẹrẹ èyí ni àwọn ilé èrò fun èrò ọkọ̀ àti onírìn-àjò, ilé ìtajà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Ìyẹn fọ̀ wọ́n mọ́ jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Kí wọ́n má ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.1 Kí wọ́n fi ìbòrí wọn bo igbá-àyà wọn.2 Àti pé kí wọ́n má ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn tàbí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn bàbá ọkọ wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin ọkọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn tàbí àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn tàbí àwọn ẹrúkùnrin wọn tàbí àwọn t’ó ń tẹ̀lé obìnrin fún iṣẹ́ rírán, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin akúra tàbí àwọn ọmọdé tí kò tí ì dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀ (sí n̄ǹkan kan). Kí wọ́n má ṣe fi ẹsẹ̀ wọn rin ìrìn-kokokà nítorí kí àwọn (ènìyàn) lè mọ ohun tí wọ́n fi pamọ́ (sára) nínú ọ̀ṣọ́ wọn. Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè.3
____________________
1. Ìyapa-ẹnu wà lórí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” nítorí pé àgbọ́yé méjì ni àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn mú wá lórí rẹ̀. Àgbọ́yé kìíní ni pé, ojú àti ọwọ́ obìnrin ni ìtúmọ̀ “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.” Ojú ni iwájú orí. Ọwọ́ sì ni ọmọníka àti àtẹlẹwọ́. Àgbọ́yé kejì ni pé, ohun tí wọ́n bá rí lára obìnrin lẹ́yìn tí ó ti fi aṣọ jilbāb bo gbogbo ara rẹ̀ tán bámúbámú láì yọ ojú àti ọwọ́ sílẹ̀ ni ìtúmọ̀ “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.” Pẹ̀lú àgbọ́yé kejì yìí, èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀ kò lè tayọ rírí aṣọ jilbāb tí obìnrin wọ̀ jáde àti rírí ọ̀wọ́ abala ara tí ó bá ṣèèsì ṣí sílẹ̀ nípasẹ̀ atẹ́gùn. Àgbọ́yé méjèèjì wọ̀nyí l’ó kúkú wọlé, àmọ́ àyè tí àgbọ́yé kìíní kejì ti wúlò l’ó yàtọ̀ síra wọn. Tí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” bá túmọ̀ sí ojú àti ọwọ́ obìnrin, ìyẹn ní àsìkò tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá wà nínú yàrá pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn ìsọ̀rí àwọn ènìyàn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kà kalẹ̀ nínú āyah yìí. Àgbọ́yé yìí l’ó sì tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ nítorí pé, nínú āyah yìí kan náà ni a ti rí ojútùú ọ̀rọ̀ náà. Irúfẹ́ ìmúra náà sì ni obìnrin gbọ́dọ̀ lò lórí ìrun kíkí nínú yàrá rẹ̀. Àmọ́ tí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” bá túmọ̀ sí ohun tí wọ́n bá rí lára obìnrin lẹ́yìn tí ó ti fi aṣọ jilbāb bo gbogbo ara rẹ̀ tán bámúbámú láì yọ ojú àti ọwọ́ sílẹ̀, ìyẹn ní àsìkò tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá wà ní ìta ilé, òde ayẹyẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i, tí āyah yìí kò bá dárúkọ jilbāb, sūrah al-’Ahzāb; 33:59 ti dárúkọ rẹ̀. Àlòpọ̀ mọ́ra wọn sì ni àwọn āyah, a ò gbọdọ̀ lòkan dákan sí. Bákan náà, tí āyah yìí kò bá dárúkọ ojú àti ọwọ́ fún bíbò ní òde tàbí bíbò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn yàtọ̀ sí àwọn ìsọ̀rí ènìyàn tí āyah yìí kà sílẹ̀, sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti fi rinlẹ̀ pé ẹ̀há híhá kó ojú àti ọwọ́ bíbò sínú. Ibi tí ọ̀rọ̀ fífi jilbāb bo ojú àti ọwọ́ mọ́ra wọn bámúbámú lè ṣẹ́kù sí báyìí ni ipò tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú ìdájọ́ ẹ̀sìn. Ṣé dandan ni tàbí sunnah? Ìyẹn ni pé, ṣe àìbojú bọwọ́ mọ́ jilbāb lè já sí ìyà ní ọ̀run tàbí àìṣe rẹ̀ kò la ìyà kan kan lọ tayọ pípàdánù ẹ̀san rẹ̀ ní ọ̀run? Dandan ni fífi jilbāb bo ojú àti ọwọ́ mọ́ra wọn bámúbámú nítorí pé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ni fún àwọn obìnrin tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ àfi àwọn arúgbó lóbìnrin nìkan, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú āyah 60 níwájú nínú sūrah yìí. Àmọ́ àì lo jilbāb kò sọ ni di kèfèrí, àfi tí onítọ̀ún bá takò ó. 2.Ní ìbámu sí āyah yìí ìbòrí obìnrin gbọdọ̀ bó gbogbo orí, ọrùn, èjìká àti igbá àyà obìnrin dáadáa. Èyí tún kó ojú bíbò sínú. Èyí sì ni àgbọ́yé àwọn obìnrin àkọ́kọ́ níkété tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀. (kitāb at-Tafsīr, al-Bukọ̄riy). 3.Kíyè sí i, nínú àwọn tí ẹlẹ́hàá lè ṣíjú fún ni irú àwọn ìsọ̀rí ènìyàn t’ó jẹyọ nínú āyah yìí àmọ́ tí àwọn ènìyàn náà jẹ́ ẹbí ìyá t’ó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já lẹ́nu ọyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà gbígbé ọmọ fún obìnrin mìíràn láti fún un lọ́yàn mu kò wọ́ pọ̀ láààrin àwa ọmọ Yorùbá, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìdájọ́ t’ó jẹmọ́ ọn bí ó bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹlẹ́hàá lè ṣíjú fún ọmọkùnrin tí ìyá t’ó fún un lọ́yàn mu bí nítorí pé, arákùnrin rẹ̀ ni nípasẹ̀ ọyàn.
Ẹ fi ìyàwó fún àwọn àpọ́n nínú yín àti àwọn ẹni ire nínú àwọn ẹrúkùnrin yín. (Kí ẹ sì wá ọkọ rere fún) àwọn ẹrúbìnrin yín. Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Allāhu sì ni Olùgbààye, Onímọ̀.
Kí àwọn tí kò rí (owó láti fẹ́) ìyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.1 Àwọn t’ó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fun yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.3
____________________
1. Kò sí ìtakora láààrin gbólóhùn yìí “Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” àti gbólóhùn yìí. “Kí àwọn tí kò rí (owó láti fẹ́) ìyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” Gbólóhùn kìíní ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífí ọmọ fún olówó nìkan. Gbólóhùn kejì sì ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífi ìyàwó fún ẹni tí kò ní ọ̀nà kan kan láti máa fi bọ́ ìyàwó. 2. Awẹ́ gbólóhùn “tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.” kì í ṣe májẹ̀mu fún awẹ́ gbólóhùn t’ó ṣíwájú. Ìyẹn ni pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé bí ẹrúbìnrin kò bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ rẹ̀, olówó rẹ̀ lè rán an lọ ṣe sìná wá. Rárá o. Àfijọ ọ̀rọ̀ yìí dà bí awẹ́ gbólóhùn “èyí t’ó ń bẹ nínú ilé yín…” - sūrah an-Nisā; 4:23 -. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah náà. 3. Ìyẹn fún ẹrúbìnrin tí olówó rẹ̀ jẹ nípá láti lọ ṣe sìná.
Dájúdájú A ti sọ àwọn àmì t’ó yanjú, ìtàn àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú yín àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) kalẹ̀ fun yín.
Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan t’ó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn. Kì í gba ìmọ́lẹ̀ nígbà tí òòrùn bá ń yọ jáde tàbí nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀. Epo (ìmọ́lẹ̀) rẹ̀ fẹ́ẹ̀ dá mú ìmọ́lẹ̀ wá, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni. Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
(Àwọn àtùpà ìbùkún náà wà) nínú àwọn ilé kan (ìyẹn àwọn mọ́sálásí) èyí tí Allāhu yọ̀ǹda pé kí wọ́n gbéga,1 kí wọ́n sì máa dárúkọ Rẹ̀ nínú rẹ̀. (Àwọn ènìyàn) yó sì máa ṣàfọ̀mọ́ fún Un nínú rẹ̀ ní àárọ̀ àti àṣálẹ́;2
____________________
1. Ṣíṣe àgbéga mọ́sálásí kò tayọ kíkọ́ mọ́sálásì ní ilé gíga, ṣíṣe sunnah nínú rẹ̀, jíjìnnà sí fífi bidi‘ah lọ́lẹ̀ nínú rẹ̀ àti bíbu ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ fún un. 2. Ṣíṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní àsálẹ́ nínú mọ́sálásí kò túmọ̀ sí ṣíṣe é ní àpapọ̀ pẹ̀lú ariwo bí tàwọn onisūfī. Ẹ ka sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:205.
Àwọn ọkùnrin tí òwò àti kárà-kátà kò dí lọ́wọ́ níbi ìrántí Allāhu, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ, àwọn t’ó ń páyà ọjọ́ kan tí àwọn ọkàn àti ojú yóò máa yí sí ọ̀tún yí sí òsì.
(Wọ́n ṣe rere wọ̀nyí) nítorí kí Allāhu lè fi èyí t’ó dára nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san rere àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Àti pé Allāhu ń pèsè arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì la ìṣírò lọ.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ wọn dà bí ahúnpeéná t’ó wà ní pápá, tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ sì lérò pé omi ni títí di ìgbà tí ó dé síbẹ̀, kò sì bá kiní kan níbẹ̀. Ó sì bá Allāhu níbi (iṣẹ́) rẹ̀ (ní ọ̀run). (Allāhu) sì ṣe àṣepé ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Tàbí (iṣẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí àwọn òkùnkùn kan nínú ibúdò jíjìn, tí ìgbì omi ń bò ó mọ́lẹ̀, tí ìgbì omi mìíràn tún wà ní òkè rẹ̀, tí ẹ̀ṣújò sì wà ní òkè rẹ̀; àwọn òkùnkùn biribiri tí apá kan wọ́n wà lórí apá kan (nìyí). Nígbà tí ó bá nawọ́ ara rẹ̀ jáde, kò ní fẹ́ẹ̀ rí i. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu kò bá fún ní ìmọ́lẹ̀, kò lè sí ìmọ́lẹ̀ kan fún un.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni gbogbo ẹni t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún? Àwọn ẹyẹ náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n bá ń na ìyẹ́ apá wọn? Ìkọ̀ọ̀kan wọn kúkú ti mọ bí ó ṣe máa kírun rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ (fún Un). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń da ẹ̀ṣújò káàkiri ni? Lẹ́yìn náà Ó ń kó o jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbé wọn gun ara wọn, nígbà náà ni o máa rí òjò tí ó máa jáde láti ààrin rẹ̀. Láti inú sánmọ̀, Ó sì ń sọ àwọn yìyín kan (t’ó dà bí) àwọn àpáta kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Ó ń mú un kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Kíkọ yànrànyànràn mọ̀nàmọ́ná inú ẹ̀ṣújò sì fẹ́ẹ̀ lè fọ́ àwọn ojú.
Allāhu ń mú òru àti ọ̀sán tẹ̀lé ara wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn t’ó ní ojú ìríran.
Allāhu ṣẹ̀dá gbogbo abẹ̀mí láti inú omi. Ó wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi àyà rẹ̀ wọ́. Ó wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi ẹsẹ̀ méjì rìn. Ó sì wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi mẹ́rin rìn. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Allāhu sì ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
Wọ́n ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì tẹ̀lé (àṣẹ Wọn).” Lẹ́yìn náà, igun kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa gbúnrí.
Tí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ni wọ́n ni ẹ̀tọ́ (àre) ni, wọn yóò wá bá ọ ní tọkàn-tara.
Ṣé àrùn wà nínú ọkàn wọn ni tàbí wọ́n ṣeyèméjì? Tàbí wọ́n ń páyà pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yóò fi ẹjọ́ wọn ṣègbè ni? Rárá o. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
Ohun tí ó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, ni pé wọ́n á sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ).” Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó ń páyà Allāhu, tí ó sì ń bẹ̀rù Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbura wọn sì ní agbára pé: "Dájúdájú tí o bá pàṣẹ fún àwọn, dájúdájú àwọn yóò jáde." Sọ pé: “Ẹ má ṣe búra mọ́. Títẹ̀lé àṣẹ (pẹ̀lú ìbúra irọ́ ẹnu yín) ti di ohun mímọ̀ (fún wa).” Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Sọ pé: "Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́ náà. Tí wọ́n bá pẹ̀yìn dà, ohun tí A gbé kà á lọ́rùn l’ó ń bẹ lọ́rùn rẹ̀, ohun tí A sì gbé kà yín lọ́rùn l’ó ń bẹ lọ́rùn yín. Tí ẹ bá sì tẹ̀lé e, ẹ máa mọ̀nà tààrà. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé."
Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe àrólé. Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà nítorí kí A lè kẹ yín.
Má ṣe lérò pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mórí bọ́ nínú ìyà lórí ilẹ̀. Iná ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí àwọn ẹrú yín àti àwọn tí kò tí ì bàlágà nínú yín máa gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ yín nígbà mẹ́ta (wọ̀nyí): ṣíwájú ìrun Subh, nígbà tí ẹ bá ń bọ́ aṣọ yín sílẹ̀ fún òòrùn ọ̀sán àti lẹ́yìn ìrun alẹ́. (Ìgbà) mẹ́ta fún ìbọ́rasílẹ̀ yín (nìyí). Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn lẹ́yìn (àsìkò) náà pé kí wọ́n wọlé tọ̀ yín; kí apá kan yín wọlé tọ apá kan. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah náà fun yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Nígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà, kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Àwọn t’ó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n sì máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀ lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà láti jẹun nínú ilé yín, tàbí ilé àwọn bàbá yín, tàbí ilé àwọn ìyá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin ìyá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin ìyá yín, tàbí (ilé) tí ẹ ní ìkápá lórí kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, tàbí (ilé) ọ̀rẹ́ yín. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti jẹun papọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, tí ẹ bá wọ àwọn inú ilé kan, ẹ sálámọ̀ síra yín. (Èyí jẹ́) ìkíni ìbùkún t’ó dára láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Àwọn onígbàgbọ́ ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tí ó kan gbogbogbò, wọn kò níí lọ títí wọn yóò fi gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú àwọn t’ó ń gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ fún apá kan ọ̀rọ̀ ara wọn, fún ẹni tí o bá fẹ́ ní ìyọ̀ǹda nínú wọn, kí o sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ má ṣe ládìsọ́kàn pé ìpè Òjíṣẹ́ láààrin yín dà bí ìpè apá kan fún apá kan. Allāhu kúkú ti mọ àwọn t’ó ń yọ́ sá lọ nínú yín. Nítorí náà, kí àwọn t’ó ń yapa àṣẹ rẹ̀ ṣọ́ra nítorí kí ìdààmú má baà dé bá wọn, tàbí nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baá jẹ wọ́n.
Gbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.