ترجمة سورة الضحى

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الضحى باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

(Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta.
Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú.
Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ.
Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.
Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.
Icon