ترجمة سورة النساء

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة النساء باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.
Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn. Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan burúkú pààrọ̀ n̄ǹkan dáadáa. Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn, ẹ fẹ́ ẹni t’ó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
____________________
Kíyè sí i, àgbọ́yé “méjì” ni pé “fẹ́ méjì”, àgbọ́yé “mẹ́ta” ni pé “fẹ́ mẹ́ta”, àgbọ́yé “mẹ́rin” sì ni pé, “fẹ́ mẹ́rin”. Àgbọ́yé ọ̀rọ̀ àsọpọ̀ “wa” t’ó sì jẹyọ láààrin “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” ni “tàbí”. Ìyẹn ni pé, “fẹ́ méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin”. Níwọ̀n ìgbà tí o ò bá gbọ́ “méjì” yé sí “fẹ́ méjì papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò gbọ́ “mẹ́ta” yé sí “fẹ́ mẹ́ta papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, tí o ò sí gbọ́ “mẹ́rin” yé sí “fẹ́ mẹ́rin papọ̀ ní ọjọ́ kan náà”, o ò gbọ́dọ̀ gbọ́ “mọthnā wa thulātha wa rubā‘” yé sí “fẹ́ mẹ́sàn-án” ìyẹn, nípasẹ̀ lílo ọ̀rọ̀-àsopọ̀ “àti” fún ṣíṣírò méjì, mẹ́ta àti mẹ́rin papọ̀ mọ́ra wọn. Má sì ṣe sọ̀rọ̀ ní ìsọ̀rọ̀ àwọn aláìmọ̀kan nípa sísọ pé, “mẹ́ ni Ọlọ́hun wí”. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu ni. Allāhu kò sọ “mẹ́”. Àwọn ni ìyà “mẹ́” ń wù ú jẹ. Bákan náà, má ṣe korò ojú sí fífẹ́ ìyàwó dé orí méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Ìyẹn kì í ṣe dandan. Àti pé, mẹ́rin yẹ ọkùnrin ju ṣíṣe zinā pẹ̀lú “mẹ́” lọ. Kò sì dìgbà tí ọkọ bá tó ṣe mọthnā kí ó tó lè jẹ̀bi ẹ̀sùn àìṣe déédé lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni! Ọkọ lè jẹ̀bi ẹ̀sùn àìṣe déédé, kódà kó jẹ́ oníyàwó kan péré, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ahun, aláìbìkátà tàbí alápámáṣiṣẹ́ ọkùnrin. Wòóore! Pẹ̀lú āyah yìí, mẹ́rin lòpin òǹkà àpapọ̀ ìyàwó t’ó lè wà nípò ìyàwó fún mùsùlùmí ẹyọ kan. Òfin t’ó rọ̀ mọ́ òǹkà àpapọ̀ ìyàwó Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yàtọ̀ sí èyí. Āyah tiwa ni èyí, sūrah al-’Ahazāb; 33:50-52 ni ti Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Kò dojú rú rárá. Al-hamdu lillāh.
Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fun yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.
Ẹ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fun yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Ẹ máa ṣàgbéyẹ̀wò (òye) àwọn ọmọ òrukàn títí wọn yóò fi tó ìgbéyàwó ṣe. Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.
Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun t’ó kéré nínú rẹ̀ tàbí t’ó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (fún wọn).
Nígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Àwọn (olùpíngún àti alágbàwò ọmọ òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn).
Dájúdájú àwọn t’ó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò.
Allāhu ń pàṣẹ fun yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan) méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, (gbogbo rẹ̀) lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Òfin kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Ìyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un.
____________________
Kíyè sí i, kò bá òfin ’Islām mu láti pín ogún ara ẹni sílẹ̀. Àti pé bí ènìyàn kò bá tí ì kú, dúkìá rẹ̀ kò ì di ogún fún ẹnì kan kan. Bákan náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé tí òun bá ti ka àwọn āyah ogún pípín, òun ti nímọ̀ nípa ogún pípín nìyẹn. Rárá o. Ènìyàn gbọ́dọ̀ ka àwọn tírà tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām fi ṣàlàyé nípa ogún pípín. Fómúlà nìkan ni àwọn āyah ogún pípín jẹ́, bí a ṣe máa lo àwọn fọ́múlà náà wà nínú àwọn tírà ogún pípín.
Àwọn t’ó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi fún wọn ní ọ̀nà (mìíràn).
____________________
Èyí ni òfin àkọ́kọ́ lórí ìdíyàjẹ onísìná obìnrin. Lẹ́yìn náà, òfin lílẹ onísìná lókò pa dé lórí ẹni tí ó bá ṣe sìná lẹ́yìn tí ó ti ṣe nikāh rí. Èyí sì ni ọ̀nà mìíràn tí Allāhu fún wọn láti fi bá abilékọ t’ó ṣe sìná wí. Òfin àkọ́kọ́ yẹn ni àwọn kògbédè-ó-gbékèé ń lò fún ẹ̀há (hijāb) àwọn obìnrin mùsùlùmí, tí ó sì jẹ́ pé ọ̀tọ̀ ni āyah ìdíyàjẹ onísìná bí tinú sūrah an-Nūr; 24:2, ọ̀tọ̀ sì ni āyah ẹ̀há (hijāb) bí tinú sūrah an-Nūr; 24:31 àti sūrah al-’Ahzāb; 33:59.
Àwọn méjì tí wọ́n ṣe (sìná) nínú yín, kí ẹ (fẹnu) bá wọn wí. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́. Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn t’ó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísinsìn yìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn t’ó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má sì dí wọn lọ́wọ́ láti kó apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn lọ àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ pọ́nńbélé. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.
Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn (tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?
____________________
Pípa irọ́ mọ́ ìyàwó ẹni àti fífi ìnira kàn án nítorí kí ó lè sọ pé òun kò ṣe mọ́, - ṣebí ọkọ kúkú ti mọ̀ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé láti ọ̀dọ̀ obìnrin, èyí tí a mọ̀ sí kul‘u, ó máa dá sọ̀daàkí rẹ̀ padà fún ọkọ - ó jẹ́ ìṣesí burúkú tí āyah yìí ń ṣe ní harām.
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn t’ó nípọn lọ́wọ́ yín!
Ẹ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà.
A ṣe é ní èèwọ̀ fun yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fun yín ní ọyàn mu àti arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí t’ó wà nínú ilé yín, tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Awẹ́ gbólóhùn “èyí t’ó wà nínú ilé yín” kì í ṣe májẹ̀mu. Àmọ́ ó ń fún wa ní ìtọ́ka sí pé, kì í ṣe èèwọ̀ fún ọmọ tí obìnrin ti bí fún ọkùnrin kan láti gbé lọ́dọ̀ ọkọ ìyá rẹ̀.
(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni t’ó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀tọ́ fun yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn fún ìgbà díẹ̀ (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn. Ọ̀ran-anyàn ni. Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ jọ yọ́nú sí (láti fojú fò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (t’ó jẹ́ ọ̀ran-anyàn). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Gbólóhùn yìí jẹmọ́ sūrah al-Baƙọrah; 2:236-237.
Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín, onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà (sì) ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn. Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà t’ó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn aṣẹ́wó àti ọ̀dọ́kọ. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira ni ìyà tí ń bẹ fún wọn. (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni t’ó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fun yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ìyẹn ni pé, ẹrúbìnrin, tí ó bá ṣe sìná, kòbókò àádọ́ta ni ìjìyà rẹ̀, kì í ṣe lílẹ̀-lókò-pa nítorí pé, lílẹ̀-lókò-pa kò ṣe é pín sí méjì.
Allāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fun yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn t’ó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Àti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn t’ó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ayé sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ t’ó tóbi.
Allāhu fẹ́ ṣe ìrọ̀rùn fun yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-àlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.
Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá tí A kọ̀ fun yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fun yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé.
Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan. Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Āyah yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí bí àwọn obìnrin kan ṣe ń jẹ̀rankàn pé kí àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin dìjọ wà ní ipò orí-ò-jorí nínú ètò ilé ayé yìí, bí ogún pípín, lílọ-bíbọ̀, iṣẹ́ ṣíṣe láààrin àwọn ọkùnrin, dídi ipò àṣẹ mú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì jẹ́ kí ó yé wa pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá àfi níbi iṣẹ́ ìjọ́sìn àti ẹ̀san rẹ̀.
Ìkọ̀ọ̀kan (àwọn dúkìá) ni A ti ṣe àdáyanrí rẹ̀ fún àwọn tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró (aláṣẹ) fún àwọn obìnrin nítorí pé Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn. Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n. Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan wá wọn níjà. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.
Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòńgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán.
Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò t’ó súnmọ́ àti aládùúgbò t’ó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti ẹni tí agara dá lórí ìrìn-àjò àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga, afọ́nnu.
Àwọn t’ó ń ṣahun, (àwọn) t’ó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) t’ó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn t’ó ń ná owó wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí Èṣù bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́.
Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.
Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Báwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí.
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ọ̀kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ t’ó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
____________________
Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà.
Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà.
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe.
Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn t’ó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́, a ò gba tìrẹ. Òmùgọ̀ wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
Ẹ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ.
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
____________________
Èyí wà fún ẹni tí ó kú sórí ẹbọ ṣíṣe sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ẹni tí ó bá túúbá kúrò níbi ẹbọ ṣíṣe ṣíwájú ìpọ́kàkà ikú, tí ó sì ṣe ’Islām rẹ̀ dáradára, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yóò ṣe àforíjìn fún un. Ẹbọ ṣíṣe ni bíbá Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wá akẹgbẹ́ bíi pípe Jésù Kristi lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Ṣé o ò rí àwọn t’ó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Kò sì níí ṣàbòsí bín-íntín sí wọn.
Wo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo.”?
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un.
Tàbí ìpín kan ń bẹ fún wọn nínú ìjọba (Wa) ni? Ti ó bá rí bẹ́ẹ̀ wọn kò níí fún àwọn ẹ̀nìyàn ní èékán kóró dàbínú.
Tàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba t’ó tóbi.
Nítorí náà, ó ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀. Jahanamọ sì tó ní iná t’ó ń jò.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, láìpẹ́ A máa mú wọn wọ inú Iná. Ìgbàkígbà tí awọ ara wọn bá jóná, A óò máa pààrọ̀ awọ ara mìíràn fún wọn kí wọ́n lè máa tọ́ ìyà wò lọ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji t’ó máa ṣíji bò wọ́n dáradára.
Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan t’ó dára ṣe wáàsí fun yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa ẹnu sí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀.
____________________
Kíyè sí i, ṣíṣẹ́rí ìyapa-ẹnu padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò túmọ̀ sí gbígbé ìyapa-ẹnu lọ pàdé Allāhu l’ọ́jọ́ Àjíǹde tàbí gbígbé ìyapa-ẹnu lọ síbi sàréè Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bí kò ṣe pé fífi al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ yanjú àwọn ìyapa-ẹnu pátápátá. Gbólóhùn yìí jọ sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:10. Ìyẹn nígbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti lọ bá a nídìí sàréè rẹ̀ fún lílo àṣẹ yẹn. Tí ènìyàn kan bá dán an wò pẹ́rẹ́, ó máa kó sínú ẹbọ ńlá. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:101.
Ṣé o ò rí àwọn t’ó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Èṣù sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà t’ó jìnnà.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ẹ wá bá Òjíṣẹ́.”, o máa rí àwọn mùnááfìkí tí wọn yóò máa ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ rẹ tààrà.
Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbà lérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣe wáàsí fún wọn, kí o sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ t’ó lágbára nípa ara wọn.
A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ, wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ìyẹn nígbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti lọ bá a nídìí sàréè rẹ̀ fún lílo àṣẹ yẹn. Tí ènìyàn kan bá dán an wò pẹ́rẹ́, ó máa kó sínú ẹbọ ńlá. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:101.
Rárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá.
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún wọn pé: "Ẹ para yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn.
Nígbà náà, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Wa.
Àti pé dájúdájú Àwa ìbá tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, àwọn olódodo, àwọn t’ó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn àti àwọn ẹni rere. Àwọn wọ̀nyẹn sì dára ní alábàárìn.
Oore àjùlọ yẹn máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu; Allāhu sì tó ní Onímọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú ohun ìṣọ́ra yín lọ́wọ́, kí ẹ sì tú jáde s’ójú ogun ẹ̀sìn níkọ̀níkọ̀ tàbí kí ẹ tú jáde ní àpapọ̀.
Dájúdájú ó ń bẹ nínú yín ẹni t’ó ń fà sẹ́yìn. Tí àdánwó kan bá kàn yín, ó máa wí pé: "Allāhu kúkú ti ṣe ìdẹ̀ra fún mi nítorí pé èmi kò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn."
Dájúdájú tí oore àjùlọ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá sì tẹ̀ yín lọ́wọ́, dájúdájú ó máa sọ̀rọ̀ - bí ẹni pé kò sí ìfẹ́ láààrin ẹ̀yin àti òun (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) - pé: “Yéè! Èmi ìbá wà pẹ̀lú wọn, èmi ìbá jẹ èrè ńlá.”
Nítorí náà, kí àwọn t’ó ń fi ayé ra ọ̀run máa jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jagun nítorí ẹ̀sìn Allāhu, yálà wọ́n pa á tàbí ó ṣẹ́gun, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.
Kí l’ó ṣe yín tí ẹ ò níí jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, nígbà tí àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé (sì ń bẹ lórí ilẹ̀), àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”
____________________
Āyah yìí ń jẹ́ kí á mọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé ogun ẹ̀sìn wà fún ààbò ẹ̀sìn wa, kí ó fi lè wà ní òmìnira, ó tún wà fún ìgbàlà àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé tí wọ́n wà lábẹ́ ìmúnisìn ìjọba kèfèrí. Lóde òní yìí, ìbá jẹ́ pé a rí ikọ̀ ogun ’Islām t’ó dúró déédé lórí sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àwọn mùsùlùmí aláìlágbára ìbá ti kúrò nínú ìnira tí ìjọba kèfèrí ń fi kàn wọ́n lójoojúmọ́. Allāhu, ṣàrànṣe Rẹ fún wa lórí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn Rẹ àti ọ̀tá àwọn ẹrúsìn Rẹ.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun fún ẹ̀sìn òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ Èṣù lógun. Dájúdájú ète Èṣù, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ.
Ṣé ó ò rí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ dá’wọ́ ogun ẹ̀sìn dúró, ẹ máa kírun (lọ ná), kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn jíjà ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: "Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn jíjà ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i." Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá bẹ̀rù Allāhu. A ò sì níí ṣàbòsí bín-íntín si yín.”
____________________
“Fatīl” ni èpó kóró dàbínù.
Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí l’ó ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan.
Ohunkóhun t’ó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.
____________________
Èbùbù, àyànmọ́ àti kádàrá ń túmọ̀ ara wọn. Rere tí ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ àti aburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá ni kìkìdá kádàrá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó pébùbù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Òun l’Ó yan àyànmọ́ fún wa. Láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni orísun gbogbo rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá pẹ̀lú déédé àti ọlá Rẹ̀ lórí wa nítorí pé, kì í ṣe Ọba alábòsí. Kò sì ṣe é pè lẹ́jọ́. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń tọ́ka sí nínú āyah 78. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún ní ẹ̀ṣà bá ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ rere, ó máa dúpẹ́ fún Allāhu ni. Nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu fún ní ẹ̀ṣà bá sì ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ aburú, òun fúnra rẹ̀ l’ó fọwọ́ ara rẹ̀ fa aburú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ dídá t’ó ṣà lẹ́ṣà. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń tọ́ka sí nínú āyah 79 àti nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:30. Bákan náà, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lè ṣẹ̀ṣà láti nawọ́ aburú sí ènìyàn, ìyẹn sì ni ogun Èṣù. Èyí ni Allāhu ń tọ́ka sí nínú sūrah Sọ̄d; 38:41. Àmọ́ sá, kì í ṣe Èṣù ni a máa bẹ̀, kì í ṣe ìyọ́nú ayé tàbí ẹ̀bẹ̀ àwọn àgbà l’a máa ṣe bí kò ṣe wíwá ìyọ́nú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nípa ìṣẹ̀ṣà ìtẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, ìdojú àdúà kọ Ọ́ àti wíwá ààbò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ní ṣókí, gbogbo aburú tí ó máa kan ẹ̀dá ti wà nínú kádàrá rẹ̀, àmọ́ aburú kan máa ṣẹlẹ̀ tààrà láti ọ̀dọ̀ Allāhu sí ọ̀dọ̀ ẹ̀dá, aburú mìíràn máa jẹ́ àfọwọ́fà, nígbà tí aburú mìíràn máa jẹ́ àkóbá. W-Allāhu-l-musta‘ān.
Ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì pẹ̀yìndà, A ò rán ọ níṣẹ́ olùṣọ́ lórí wọn.
Wọ́n ń wí pé: “A tẹ̀lé àṣẹ rẹ.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, igun kan nínú wọn máa gbìmọ̀ n̄ǹkan tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ń sọ (lọ́sàn-án). Allāhu sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ń gbìmọ̀ lóru. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó Aláàbò.
Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀.
____________________
Kò sí āyah kan t’ó tako āyah mìíràn nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Àmọ́ tí ẹnì kan bá rí āyah kan tí ó fẹ́ tako āyah mìíràn lójú tirẹ̀, kó lọ tẹ́tí gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀ lọ́dọ̀ onímọ̀ ẹ̀sìn t’ó nímọ̀ nípa àwọn ìsọ̀rí àti àtúnpín ìsọ̀rí tí àwọn āyah pín sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé pẹ̀lú ohun t’ó rọ̀ mọ́ wọn.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ ìfàyàbalẹ̀ tàbí ìpáyà kan bá dé bá wọn, wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ (ìyẹn, àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn) nínú wọn, àwọn t’ó ń yọ òdodo jáde nínú ọ̀rọ̀ nínú wọn ìbá mọ̀ ọ́n. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín ni, ẹ̀yin ìbá tẹ̀lé Èṣù àfi ìba díẹ̀ (nínú yín).
Nítorí náà, jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò là á bọ ẹnì kan lọ́rùn àfi ìwọ. Kí o sì gbẹ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóǹgbẹ ogun ẹ̀sìn jíjà. Ó ṣeé ṣe kí Allāhu ká ọwọ́jà àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ dúró. Àti pé Allāhu le jùlọ (níbi) ìjà. Ó sì le jùlọ níbi ìjẹni-níyà.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ rere, ó máa rí ìpín ẹ̀san nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ aburú, ó máa rí ìpín ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀. Allāhu sì jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí t’ó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan.
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu lọ?
Kí ni ó máa mu yín pín sí ìjọ méjì nípa àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí! Allāhu l’Ó dá wọn padà sẹ́yìn nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ fi ẹni tí Allāhu ṣì lọ́nà mọ̀nà ni? Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí ọ̀nà kan fún un.
Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa ṣí kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ṣíṣe hijrah náà), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti rí wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn.
Àyàfi àwọn t’ó bá dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (akin-ọkàn) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fun yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, nígbà náà Allāhu kò fun yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Ẹ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n fẹ́ fi yín lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì fẹ́ fi àwọn ènìyàn wọn lọ́kàn balẹ̀ (pé) nígbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) ni wọ́n ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fun yín, tí wọn kò juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fun yín ní agbára t’ó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó sì máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fun yín, onígbàgbọ́ òdodo sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn, ó máa san owó ẹ̀mí fún wọn. Ó sì máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí ẹrú onígbàgbọ́ òdodo, ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa onígbàgbọ́ òdodo kan, iná Jahanamọ ni ẹ̀san rẹ̀. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Allāhu yóò bínú sí i. Ó máa fi ṣẹ́bi lé e. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó tóbi sílẹ̀ dè é.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ogun ẹ̀sìn Allāhu, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo nítorí pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fun yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn olùjókòó sínú ilé nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, yàtọ̀ sí àwọn aláìlera, àti àwọn olùjagun fún ẹ̀sìn Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn, wọn kò dọ́gba. Allāhu fi ipò kan ṣoore àjùlọ fún àwọn olùjagun fún ẹ̀sìn Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé. Olúkùlùkù (wọn) ni Allāhu ṣe àdéhùn ohun rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) fún. Allāhu gbọ́lá fún àwọn olùjagun ẹ̀sìn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé pẹ̀lú ẹ̀san ńlá;
àwọn ipò kan, àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fun yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.
Àyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, tí wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀ (dé ìlú Mọdīnah).
Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn, ó súnmọ́ kí Allāhu ṣàmójúkúrò fún wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ìlú rẹ̀ jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, ó máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ibùsásí àti ìgbàláàyè lórí ilẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ (tí ó jẹ́) olùfìlú-sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ikú bá a (lójú ọ̀nà), ẹ̀san rẹ̀ kúkú ti wà lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Gbígbé ìlú ẹni jù sílẹ̀ láti tẹ̀dó sínú ìlú mìíràn yóò di dandan fún mùsùlùmí nígbà tí wíwà nínú ìlú rẹ̀ kò bá rọgbọ fún ẹ̀sìn ṣíṣe, bákan náà tí mùsùlùmí kò sì ní ìkápá láti ja àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn lógun. Èyí ni a mọ̀ sí Hijrah nínú èdè Lárúbáwá.
Nígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti dín ìrun kù, tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò fòòró yín. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.
Nígbà tí o bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n mú n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì forí kanlẹ̀ (tí wọ́n parí ìrun), kí wọn bọ́ sẹ́yìn yín, kí igun mìíràn tí kò tí ì kírun wá kírun pẹ̀lú rẹ. Kí wọ́n mú ìṣọ́ra wọn àti n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ kí ẹ gbàgbé àwọn n̄ǹkan ìjagun yín àti n̄ǹkan ìgbádùn yín, kí wọ́n lè kọlù yín ní ẹ̀ẹ̀ kan náà. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín tí ó bá jẹ́ pé ìpalára kan ń bẹ fun yín látara òjò tàbí (pé) ẹ jẹ́ aláìsàn, pé kí ẹ fi n̄ǹkan ìjagun yín sílẹ̀ (lórí ìrun). Ẹ mú n̄ǹkan ìṣọ́ra yín lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Nígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀ (ìyẹn nígbà tí ẹ bá wọnú ìlú), kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ẹ má ṣe káàárẹ̀ nípa wíwá àwọn ènìyàn náà (láti jà wọ́n lógun). Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè baà ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá.
Tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Gọ̄fir; 40:55.
Má ṣe bá àwọn t’ó ń jàǹbá ẹ̀mí ara wọn wá àwíjàre. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníjàǹbá, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Wọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń gbìmọ̀ ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn?
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan tàbí tí ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, ó máa bá Allāhu ní Aláforíjìn, Aláàánú.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe kan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, ó dì í ru aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, ó ti dá ọ̀ràn ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti fẹ́ ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́; oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun t’ó tóbi.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.
Kò sí oore nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san t’ó tóbi.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí Òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú han sí i kedere, tí ó tún tẹ̀lé ọ̀nà t’ó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, A óò dojú rẹ̀ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ̀ kọ (nínú ìṣìnà), A ó sì mú un wọ inú iná Jahanamọ. Ó sì burú ní ìkángun.
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 48.
Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà. Wọn kò sì pe kiní kan bí kò ṣe Èṣù olùyapa.
____________________
Nínú āyah yìí, “abo òrìṣà” túmọ̀ sí àwọn n̄ǹkan ọ̀bọrọgidi tí orúkọ wọn wá pẹ̀lú jẹ́ńdà abo tàbí àwọn orúkọ òrìṣà kan tí wọ́n wá pẹ̀lú jẹ́ńdà abo gẹ́gẹ́ bí òrìṣà Lāt, òrìṣà ‘Uzzā àti òrìṣà Mọnāt, tàbí àwọn mọlāika tí wọ́n kàkún abo, tí wọ́n sì sọ wọ́n di òrìṣà. Nítorí náà, abo òrìṣà kò túmọ̀ sí pé abo ni gbogbo àwọn òrìṣà ayé.
Allāhu ṣẹ́bi lé Èṣù. Ó sì wí pé: "Dájúdájú mo máa mú ìpín tí wọ́n pín fún mi nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ.
Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Mo máa fi èròkerò sínú ọkàn wọn. Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀dá Allāhu padà." Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé.
Èṣù ń ṣàdéhùn fún wọn, ó sì ń fi ìfẹ́-irọ́ sínú ọkàn wọn. Èṣù kò sì ṣàdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.
Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; wọn kò sì níí rí ibùsásí kan.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, A máa mú wọn wọ inu àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀ títí láéláé. (Ó jẹ́) àdéhùn tí Allāhu ṣe ní ti òdodo. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu lọ?
Kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn ahlu-l-kitāb (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:62.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn l’ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí èékán kóró dàbínù fún wọn.
Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa gbogbo n̄ǹkan.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fun yín. Ohun tí wọ́n ń ké fun yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fun yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò láti fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.
Tí obìnrin kan bá páyà ìṣe oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára jú lọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ ò lè ṣe déédé (nínú ìfẹ́) láààrin àwọn obìnrin, ẹ ò báà jẹ̀rankàn rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fì síbì kan tán ráúráú, kí ẹ má lọ pa (ẹnì kan) tì bí ohun àgbékọ́. Tí ẹ bá ṣàtúnṣe, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Tí àwọn méjèèjì bá sì pínyà, Allāhu yóò rọ ìkíní kejì lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ t’ó gbòòrò. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbòòrò (nínú ọrọ̀), Ọlọ́gbọ́n.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú A ti pa á láṣẹ fún àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti ẹ̀yin náa pé kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.
Tí (Allāhu) bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò lórí ilẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn. Ó sì máa mú àwọn mìíràn wá. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí ìyẹn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san nílé ayé, ṣebí lọ́dọ̀ Allāhu ní ẹ̀san ayé àti ọ̀run wà. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí nítorí ti Allāhu, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní. Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì lọ. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n sì lékún sí i nínú àìgbàgbọ́, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fí ọ̀nà mọ̀ wọ́n.
____________________
Āyah yìí àti āyah 48 àti 116 fi rinlẹ̀ fún wa pé, kò sí àforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá kú sínú àìgbàgbọ́ ńlá àti ìṣẹbọ ńlá sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìró pé dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ṣé ẹ̀ ń wá agbára lọ́dọ̀ wọn ni? Dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo agbára pátápátá.
(Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fun yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú ẹ̀yin yóò dà bí irú wọn. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ.
(Àwọn ni) àwọn t’ó fẹ́ yọ̀ yín; tí ìṣẹ́gun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá jẹ́ tiyín, wọ́n á wí pé: “Ṣé àwa kò wà pẹ̀lú yín bí?” Tí ìpín kan bá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, (àwọn mùnááfìkí) á wí pé: “Ṣé àwa kò ti ní ìkápá láti jẹ gàba le yín lórí (àmọ́ tí àwa kò ṣe bẹ́ẹ̀), ṣé àwa kò sì dáàbò bò yín tó lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (títí ọwọ́ yín fi ba ọrọ̀-ogun, nítorí náà kí ni ìpín tiwa tí ẹ fẹ́ fún wa?)” Nítorí náà, Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde. Allāhu kò sì níí fún àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀nà (ìṣẹ́gun) kan lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
Ìyẹn ni pé, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí yóò máa wá àǹfàní sọ́dọ̀ àwa mùsùlùmí àti àwọn aláìgbàgbọ́.
Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀.
Wọ́n ń ṣe bàlàbàlà síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọn kò jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí, wọn kò sì jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí ọ̀nà kan fún un.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ yín). Ṣé ẹ fẹ́ ṣe n̄ǹkan tí Allāhu yóò fi ní ẹ̀rí pọ́nńbélé lọ́wọ́ láti jẹ yín níyà ni?
Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn.
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá.
Kí ni Allāhu máa fi ìyà yín ṣe, tí ẹ bá dúpẹ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ ní òdodo? Allāhu sì ń jẹ́ Olùmoore, Onímọ̀.
Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ sí ariwo èpè ṣíṣẹ́ (láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni) àyàfi ẹni tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Onímọ̀.
Tí ẹ bá ṣàfi hàn rere tàbí ẹ fi pamọ́ tàbí ẹ ṣàmójú kúrò níbi aburú, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Alágbára.
Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n fẹ́ ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan,” wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn.
Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọn kò sì ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn, láìpẹ́ àwọn wọ̀nyẹn, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Àwọn ahlul-kitāb ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní gban̄gba.” Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gbá wọn mú nípasẹ̀ àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.
A gbé àpáta sókè orí wọn nítorí májẹ̀mu wọn. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba.” A tún sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà ní ọjọ́ Sabt.” A sì gba àdéhùn t’ó nípọn lọ́wọ́ wọn.
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” – rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. – Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
Àti nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀rọ̀ wọn lórí Mọryam ní ti ìbànilórúkọjẹ́ t’ó tóbi (Allāhu tún fi èdídí dí ọkàn wọn).
Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh, ‘Īsā ọmọ Mọryam, Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni. Dájúdájú àwọn t’ó yapa-ẹnu nípa rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì nínú rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé èròkérò. Wọn kò pa á ní àmọ̀dájú.
____________________
Kíyè sí ìyàtọ̀ pàtàkì t’ó wà láààrin awẹ́ gbólóhùn méjì yìí: ìkíní “وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْۚ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنْ أُلْقِيَ شَبَهُهُ عَلَى غَيْرِهِ” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” Òye ìdí èyí sì ni pé, nítorí kí àwọn ọ̀tá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), tí wọ́n déte láti kàn án mọ́ igi àgbélébùú lè mú ẹni tí àwòrán rẹ̀ jọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Onítọ̀ún ni wọ́n sì kàn mọ́ igi àgbélébùú, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí sì ni ète ti Allāhu tí Ó fi gba Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìdí sì nìyí tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi wà nínú iyèméjì nípa ta gan-an ni wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú nítorí pé, ẹni tí wọ́n kàn mọ́ igi àgbélébùú jọ àwòrán Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni, kò jọ ọ́ ní ohùn rárá. Síwájú sí i, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (ìyẹn ‘ilmu-ssọrf) fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” t’ó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “lām” nínú awẹ́ gbólóhùn
“وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْ ۚ” jẹ́ “شَبَهٌ” (ṣabahun / ṣabah) tàbí “شِبْهٌ” (ṣibhun / ṣibh) – ìtúmọ̀ “ìjọra / àfijọ / àwòrán kan náà”. Àti pé àkòónú “شَبَهٌ”/ “شِبْهٌ” (ṣabahun / ṣibhun) nígbà náà ni pé, wọ́n ń lò ó fún n̄ǹkan méjì t’ó jẹ́ oríṣìí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí wọ́n jọra wọn ní àwòrán. Ìtúmọ̀ yìí sì ni gbogbo ọ̀rọ̀ t’ó pilẹ̀ lórí àwọn háràfí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí “ش ب ه” ní nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ẹ wo àwọn àyè náà; sūrah al-Baƙọrah; 2:25, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7, sūrah al-’Ani‘ām; 6: 99 àti 141, àti sūrah as-Zumọr; 39:23. Bákàn náà, awẹ́ gbólóhùn kejì “وَلَكِنْ شُبِّهَ عَلَيْهِمْ” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “وَلَكِنِ اشْتُبِهَ عَلَيْهِمْ ” “ṣùgbọ́n a fi rú wọn lójú / ṣùgbọ́n a dà á rú mọ́ wọn lójú”. Ìyẹn sì kọ́ ni al-Ƙur’ān sọ. Wòóore, ẹ̀kọ́ nípa mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá (‘ilmu-ssọrf) tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọ̀rọ̀-orúkọ fún “شُبِّهَ” t'ó jẹyọ pẹ̀lú háràfí “ ‘alā” nínú gbólóhùn yìí jẹ́ “شُبْهَةٌ” (ṣubhatun / ṣubhah) – ìtúmọ̀: “ìrújú / rújúrújú”. Àmọ́ sá, “ìjọra” máa ń yọrí sí “ìrújú” nígbà tí kò bá sí “àmọ̀dájú”. Àkíyèsí kejì: Gbogbo tírà tafsīr t’ó sọ̀rọ̀ lórí
“وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمْ” “ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.” l’ó mú ọ̀rọ̀ wá lórí bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe gbé àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wọ ẹnì kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kódà wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà wá ni láti ọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (r.ahmọ), gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí i kà nínú tafsīr Zādu-l-Mọsīr. Ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ nípa ipò Ọmọ ‘Abbās (r.ahmọ) nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ al-Ƙur’ān tàbí ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ hadīth l’ó lè pe ìtàn náà ní ìtàn ’Isrọ̄’īliyāt.
Rárá o, Allāhu gbé e wá sókè lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Āyah 157 àti 158 yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tí ó sọ ìjọ Ahmadiyyah Ƙọ̄diyaniyyah tàbí Lahọ̄riyyah) di ìjọ kèfèrí. Ìdí ni pé, ìgbàgbọ́ ìjọ Ahmadiyyah ni pé, wọn kan ‘Īsā ọmọ Mọryam mọ́ igi àgbélébùú ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kò kú sí orí rẹ̀. Ìjọ Ahmadiyyah sì tún gbà pé ‘Īsā ọmọ Mọryam sá àsálà wá sí ilẹ̀ India. Ó fẹ́ ìyàwó níbẹ̀. Ó kú síbẹ̀. Wọ́n sì sin ín síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìjọ Ahmadiyyah ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gbà pé ẹni tí ó padà wá sáyé lábẹ́ ìpadàbọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam kò jẹ́ ẹnì kan bí kò ṣe mirza Ghulam Ahmad, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah. Ọ̀nà tí èyí sì gbà ṣẹlẹ̀ nìyí nínú ìtọ́kasí wọn: “The word of God which I set out at some places in my book, the Baraheen Ahmadiyya explains how God Almighty made me Isa Son of Mary. In that book God first named me Mary and then disclosed that God had breathed His spirit into this Mary and said that after the breathing of this spirit my status as Mary was converted into my status as Isa, and thus Isa having been born of Mary was called Son of Mary.” Ìtúmọ̀: Mirza Ghulam Ahmad wí pé “Ọ̀rọ̀ Allāhu tí mo mú jáde láti inú ìwé mi, Baraheen Ahmadiyya, ó ń ṣe àlàyé ọ̀nà tí Allāhu gbà sọ mí di ‘Īsā ọmọ Mọryam. Nínú ìwé yẹn, Allāhu kọ́ sọ mí ní Mọryam. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi hàn mí pé Allāhu ti fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sí Mọryam yìí lára. Ó sì sọ pé lẹ́yìn tí Òun ti fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ sí mi lára, ipò mi gẹ́gẹ́ bí Mọryam ti paradà báyìí, mo sì ti di ‘Īsā. Èyí rí bẹ́ẹ̀ fún wí pé bíbí tí Mọryam bí ‘Īsā ni wọ́n fi ń pè é ní ‘Īsā ọmọ Mọryam. [Ìwé Tadhkirah, òǹkọ̀wé: (Ahmadi) Muhammad Zafrullah Khan; ojú ewé: 369.] Ibi dandan Allāhu kí ó máa bá òpùrọ́ yìí.
Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn ahlul-kitāb (láyé nígbà tí ‘Īsā bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn.
____________________
Àgbọ́yé méjì ni àwọn tafsīr mú wá lórí àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ t’ó jẹyọ nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “قَبْلَ مَوْتِهِۦۖ”. Àgbọ́yé kìíní ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nípa bẹ́ẹ̀ ìtúmọ̀ āyah náà máa lọ báyìí pé: “Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn ahlul-kitāb (láyé nígbà tí ‘Īsā bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gba ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām).” Èyí sì máa jẹ́ oore ìronúpìwàdà àti ìpadà sínú ẹ̀sìn ’Islām fún ọ̀wọ́ àwọn tí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá padà bá láyé nínú àwọn t’ó ti sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa àti olùgbàlà wọn. Àgbọ́yé kejì ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ikú ahlul-kitāb t’ó ń pọ́kàkà ikú. Nípa bẹ́ẹ̀ ìtúmọ̀ āyah náà máa lọ báyìí pé: “Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn ahlul-kitāb àfi kí ó gba ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú ahlul-kitāb náà lásìkò ìpọ́kàkà ikú.” Pẹ̀lú àgbọ́yé kejì yìí, àwọn onímọ̀ fi rinlẹ̀ pé, àwọn mọlāika máa gbé àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá fún ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ kú láti fojú rí àṣìṣe rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ó máa ronú pìwàdà lásìkò náà, àmọ́ kò sí ìronúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ òdodo t’ó wúlò lásìkò ìpọ́kàkà ikú. Àgbọ́yé méjèèjì wọ̀nyí kúkú ni òdodo ọ̀rọ̀ nítorí pé kò sí èyí tí kò ní ẹ̀rí ìkúnlọ́wọ́ láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tàbí láti ọ̀dọ̀ àwọn Asíwájú rere fún wa (r.ahm). Kò sì sí ọ̀kan nínú àwọn àgbọ́yé méjèèjì tí ẹ̀rí àtakò wà fún láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ nígbà tí pọ́n-na bá jẹyọ nínú āyah al-Ƙur’ān, ọ̀nà kan pàtàkì nínú ìyọnípọ́n-na ni lílo hadīth Ànábì. Àmọ́, ṣíwájú kí á tó lè lo hadīth kan kan fún ìyọnípọ́n-na, al-Ƙur’ān fúnra rẹ̀ ni ohun àkọ́kọ́ tí a máa lò. Èyí máa ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wíwo sàkánì tí ọ̀rọ̀ onípọ́n-na náa ti jẹyọ. A máa wòye sí ọ̀rọ̀ tí ń bá á bọ̀ níwájú (tàbí) àti ọ̀rọ̀ tí ó tún mú wá lẹ́yìn rẹ̀ (bí ó bá wà). Kódà ìwòye yìí lè ṣẹlẹ̀ nígbà mìíràn nínú āyah kan náà. Nítorí náà, lórí āyah yìí, àgbọ́yé t’ó gbéwọ̀n jùlọ ni àgbọ́yé kìíní. Èyí tí ó ń fi rinlẹ̀ pé ikú ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé ni àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, ọ̀rọ̀ t’ó jẹyọ nínú āyah 157 ń sọ nípa pé àwọn kan ń sọ pé àwọn pa ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àwọn kàn án mọ́ igi àgbélébùú. Ó sì ti kú. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì sọ pé ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀ rárá bí kò ṣe pé Òun gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá sókè lọ́dọ̀ Òun ni. Òkodoro ọ̀rọ̀ náà sì máa hàn sí gbogbo ayé ní àsìkò ìpadà-sọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀. Ìyẹn sì ni àlàyé t’ó jẹyọ nínú àwọn āyah 158 àti 159.
Síwájú sí i, kalmọh “رفع” (rọfa‘a) lè túmọ̀ sí àgbéga tẹ̀mí (ìyẹn, àgbéga ipò gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:176 àti sūrah Mọryam; 19:57) tàbí kí ó túmọ̀ sí àgbéga tara (ìyẹn gbígbé ara kúrò láti àyè ìsàlẹ̀ sí àyè òkè gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Fātir; 35:10). Àmọ́ kò ní tàbí-ṣùgbọ́n nínú mọ́ pé, nígbàkígbà tí harafi “إلى” bá ti tẹ̀lé “رفع”, àgbéga tara l’ó máa jẹ́ ìtúmọ̀ rẹ̀. Wàyí, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ pé òkè sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà, ìdí nìyí tí “بَل رَّفَعَهُ ٱللَّهُ إِلَيْهِۚ” fi túmọ̀ sí “Rárá o, Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam wá sókè sínú sánmọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni.” Bí ẹnì kan bá wá ń retí kalmọh “السماء” (sánmọ̀) nínú āyah náà ṣíwájú kí ó tó lè gbàgbọ́ pé nínú sánmọ̀ ni Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam wá ní ẹ̀mí àti ara, bóyá ni onítọ̀ún gbàgbọ́ pé sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu gan-an wà. Lórí èyí, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:18.
Nítorí náà, gbogbo Mùsùlùmí onisunnah l’ó mọ̀ ní àmọ̀dájú pé, òkè sánmọ̀ keje ni Allahu wà nítorí pé inú sánmọ̀ yìí náà ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gùn lọ láti lọ gba ìrun wákàtí márùn-ún wá lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lásìkò ìrìn òru àti ìgun-sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi rinlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sūrah al-’Isrọ̄’. Kódà tòhun ti bí àìgbàgbọ́ Fir‘aon ṣe gbópọn tó, ó kúkú gbà pé sánmọ̀ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà. Ó sì bẹ Hāmọ̄n ní ilé gíga fíofío kọ́. Ó fẹ́ yọjú wo Allāhu! (sūrah al-Ƙọsọs; 28:38). Nítorí náà, inú sánmọ̀ ni Allāhu gbé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá. Ó sì wà níbẹ̀, kì í ṣe ní ti ìgbésí ayé tilé ayé, àmọ́ ní ti ìgbésí ayé t’ó bá inú sánmọ̀ mu, ìyẹn irú ìgbésí ayé tàwọn mọlāika, tí wọn kì í jẹun, tí wọn kì í mu, tí wọn kì í ṣẹ̀gbin, tí wọn kì í dàgbà sí i, tí wọn kì í gbó lára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àti pé nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ tí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) máa ṣe nígbà tí ó bá padà dé láti ojú sánmọ̀ níbi rírún àgbélébùú, pípa ẹlẹ́dẹ̀, kíkọ gbogbo ẹ̀sìn àfi ẹ̀sìn ’Islām nìkan ṣoṣo, pípa Mọsīh Dajjāl àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ l’ó máa mú kí àwọn ahlul-kitāb àsìkò náà ronú pìwàdà sínú ẹ̀sìn ’Islām. Kíyè sí i, ìpadàbọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé kì í ṣe ní àwòrán ipò Ànábì, bí kò ṣe ní àwòrán ọmọlẹ́yìn Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti adájọ́ onídéédé nítorí pé, kò níí sí Ànábì titun kan kan mọ́ lẹ́yìn Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àti pé, ìjọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan l’ó wà láyé báyìí, nítorí náà Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí kádàrá rẹ̀ jẹmọ́ ìpadàbọ̀ sáyé kò níí wà nípò Ànábì lásìkò náà bí kò ṣe pé, ó máa wà nípò ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì àsìkò yìí. Ìdí sì nìyí tí kò fi níí fi tírà kan dájọ́ lẹ́yìn al-Ƙur’ān. Pẹ̀lú àlàyé yìí, àgbọ́yé kejì kò lè rọ́nà lọ. Àmọ́ sá, tí ẹnì kan bá bá àgbọ́yé kejì yìí lọ, kò la àtakò lọ níwọ̀n ìgbà tí onítọ̀ún kò bá ti tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ l’ópin ayé nítorí pé níwọ̀n ìgbà tí hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ti fi rinlẹ̀, aláìgbàgbọ́ tí ó máa jẹ̀bi ikú lábẹ́ òfin ’Islām ni ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí t’ó bá tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ l’ópin ayé. Wòóore! Gbogbo òǹkà àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ “ẹyọ ẹnì kẹta” ìyẹn “هـُ” t’ó jẹyọ láti inú āyah 157 títí dé 159 nínú sūrah yìí jẹ́ méjìlá. Àyè kan péré l’ó ti ń tọ́ka sí Allāhu, ìyẹn sì ni kalmọh “إِلَيْهِ”, ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni mọ́kànlá yòókù ń tọ́ka sí nítorí pé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan ni kókó nínú àwọn āyah náà. Ìwòyesí yìí tún jẹ́ àtìlẹ́yìn fún àgbọ́yé kìíní láti fi rinlẹ̀ pé “قَبْلَ مَوْتِهِۦۖ” ń túmọ̀ sí “ṣíwájú ikú ‘Isā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé.
Nítorí àbòsí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n di yẹhudi, A ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa kan ní èèwọ̀ fún wọn, èyí tí wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn (tẹ́lẹ̀. A ṣe é ní èèwọ̀ fún wọn sẹ́) nípa bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu.
Àti gbígbà tí wọ́n ń gba owó èlé, tí A sì ti kọ̀ ọ́ fún wọn, àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ dúkìá àwọn ènìyàn lọ́nà èrú. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Ṣùgbọ́n àwọn àgbà nínú ìmọ̀ nínú wọn àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, wọ́n gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, (wọ́n tún gbàgbọ́ nínú àwọn mọlāika) t’ó ń kírun. (Àwọn wọ̀nyẹn) àtí àwọn t’ó ń yọ Zakāh àti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní ẹ̀san ńlá.
Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr.
Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà.
(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà mọ̀ wọ́n.
Àyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.
____________________
Èyí wà fún ẹni tí ó bá kú sínú àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ìkéde ẹ̀sìn ’Islām ti dé etí ìgbọ́ rẹ̀. Bákan náà, ẹ wo āyah 48 àti āyah 116.
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fun yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fun yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo (tí ìjọ́sìn tọ́ sí). Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.
____________________
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní orúkọ mẹ́rin wọ̀nyí nínú āyah yìí: “mọsīh”, “rọsūlullāh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llāh”. Àwọn kristiẹni sì ń tìràn mọ́ “mọsīh”, “kalmọtu-llāh” àti “rūhu-llah” bí ẹni pé orúkọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni olùgbàlà, ọlọ́run, ẹlẹ́dàá àti olúwa. Èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní àkọ́kọ́ náà, nínú èdè Lárúbáwá kò sí èyí tí ó túmọ̀ sí olùgbàlà tàbí ọlọ́run tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olúwa nínú àwọn orúkọ àti ìròyìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tí al-Ƙur’ān fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ìtúmọ̀ “mọsīh” nínú èdè Lárúbáwá nìwọ̀nyí: ẹni tí kò ní kòjẹ̀gbin, alárìnká tí kò ní ibùgbé kan ní pàtó, ẹni tí wọ́n fi òróró pa lára, ẹni tí ó máa ń fọwọ́ àdúà pa aláìlera láti tọrọ ìwòsàn fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́hun, olódodo, ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́. Ní ti “kalmọtu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ọ̀rọ̀ Allāhu / ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Ọ̀rọ̀ Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣẹ̀dá rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn “kun fayakūn”. Nígbà tí Allāhu ń sọ nípa ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ìtúmọ̀ yìí sì ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rinlẹ̀ fúnra Rẹ̀ nínú sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:45, 47 àti 59 pẹ̀lú sūrah Mọryam; 19:35. Kódà pípè tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní “kalmọtu-llāh” jẹ́ àpọ́nlé fún un ni nítorí pé, kò wúlẹ̀ sí ẹ̀dá kan, yálà ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, àfi kí ó jẹ́ “kalmọtu-llāh”. Ìyẹn ni pé, gbogbo ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ l’Ó sọ “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” fún ṣíwájú kí irú ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ tó máa bẹ. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó sì ni “Jẹ́ bẹ́ẹ̀”, kì í ṣe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tàbí ẹlòmíìràn. Bákan náà, ní ti “rūhu-llāh”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “ẹ̀mí Allāhu / ẹ̀mí Ọlọ́hun ”. Ẹ̀mí Allāhu ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀ sínú ikùn ìyá rẹ̀, Ó sì ní kí mọlāika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ sára ìyá rẹ̀ nítorí kí ‘Īsā lè di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Àti ẹ̀mí mímọ́ àti ẹ̀mí àìmọ́ tàbí ẹ̀mí òkùnkùn, Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá ìkíní kejì wọn. Kì í ṣe Èṣù. Èṣù kò dá ohun kan kan. Èṣù gan-an fúnra rẹ̀, ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá tí Allāhu ṣẹ̀dá l’ó wà. Wòóore, fúnra Allāhu l’Ó kúkú fẹ́ atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ kan sára Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nígbà tí Ó mọ ọ́n kalẹ̀ tán ní ọ̀bọrọgidi gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah Sọ̄d; 38:72 àti sūrah al-Hijr; 15:29. Ìyẹn kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa lẹ́yìn Allāhu. Báwo ni ‘Īsā ọmọ Mọryam tí wọ́n fi atẹ́gùn ẹ̀mí rẹ̀ rán mọlāika Jibril ṣe máa wá di olúwa? Rárá, kò lè di olúwa. Tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá wá pe ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní “rūhu-llāh” àpọ́nlé ni fún un nítorí pé, kò sí ẹ̀dá ẹlẹ́mìí kan níbikíbi àfi kí ó jẹ́ pé “rūhu-llāh” ni òun náà. Síwájú sí i, lílo “Ọlọ́hun” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán fún ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Ọlọ́hun kò sọ ohun náà di ọlọ́hun tàbí olúwa tàbí ẹlẹ́dàá tàbí olùgbàlà, àmọ́ àpọ́nlé ni fún ẹ̀dá náà. Wòye sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kí ó tún lè yé ọ yékéyéké: Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Mọryam di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Ẹ̀mí wo ni Ọlọ́hun fi sọ Èṣù di n̄ǹkan ẹlẹ́mìí? Èsì kan náà ni gbogbo wọn ní. Èsì náà sì ni pé, “Ẹ̀mí Ọlọ́hun “rūhu-llāh” ni.” Èyí tí ó túmọ̀ sí pé Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá ẹ̀mí t’ó wà lára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Síwájú sí i, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ràkúnmí kan ní “nọ̄ƙọtu-llāh”, ìtúmọ̀ “ràkúnmí Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé, “ràkúnmí ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ràkúnmí ìyanu tí ó jáde tòhun ti ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti inú àpáta. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ràkúnmí náà ni. Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu pe ilé kan ní “Baetu-llāh”, ìtúmọ̀ “ilé Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ilé ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ilé tí àwọn ẹ̀dá ti ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, ìyẹn sì ni mọ́sálásí. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún orúkọ ilé náà ni. Bákan náà, nínú al-Ƙur’ān, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pe ẹ̀dá kan ní “’abdullāh”, ìtúmọ̀ “ẹrú Ọlọ́hun”. Èyí kò sì túmọ̀ sí pé “ẹrú ni Ọlọ́hun” bí kò ṣe pé ẹ̀dá tí ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun, tí ó sì wà lábẹ́ òfin Ọlọ́hun pẹ̀lú ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ pátápátá fún Ọlọ́hun. Àti pé Allāhu fi ṣe àpọ́nlé fún ẹ̀dá náà ni ni nítorí pé gbogbo wa ni ẹrú Ọlọ́hun, a fẹ́ tàbí a kọ̀. Báwo wá ni “kalmọtu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “kalmọh ni Ọlọ́hun / ọ̀rọ̀ ni Ọlọ́hun”? Àní sẹ́ báwo ni “rūhu-llāh” ṣe máa túmọ̀ sí “rūhu ni Ọlọ́hun / ẹ̀mí ni Ọlọ́hun”? Ìròrí àwọn kristiẹni lásán ni ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ náà, tí wọ́n ti mú wọ inú bíbélì wọn pé “Láti ìṣẹ̀ṣẹ̀kọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ ti wà. Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run sì ni ọ̀rọ̀ náà.” Láéláé, Ọlọ́hun àwa mùsùlùmí kì í ṣe ọ̀rọ̀. Ọlọ́hun wa kì í ṣe ẹ̀mí. Nítorí náà, kò sí ẹ̀dá kan àfi kí ó di bíbẹ nígbà tí Allāhu bá sọ pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, mọ̀ dájú pé àpọ́nlé ni Mọ́là, Haúsá l’a Haúsá ń jẹ́. Nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ (noun phrase), ìgbàkígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ẹ̀yán-ajórúkọ (nominal modifier) fún ọ̀rọ̀-orúkọ kan ìyẹn ni pé, ìgbàkígbà tí Allāhu bá ṣe àfitì ẹ̀dá kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tì sọ́dọ̀ ara Rẹ̀, bí irú èyí “kalmọtu-llāh, rūhu-llāh, nāƙọtu-llāh, baetu-llāh, kitābu-llāh, ‘abdu-llāh, nabiyyu-llāh, rọsūlu-llāh” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣe àpọ́nlé fún ọ̀rọ̀-orúkọ agbẹ̀yán náà, kò tún ní ìtúmọ̀ mìíràn bí kò ṣe láti fi “ìbátan ìní” hàn (possessive genitive). Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, ẹ̀hun oníbàátan ìní (possessive genitive construction) ni ìtúmọ̀ t’ó máa ń wà níbikíbi tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ti lo orúkọ ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán-ajórúkọ nínú àpólà orúkọ, kì í sì ní ìtúmọ̀ alálàjẹ́ (appositive). Pẹ̀lú èyí ìtúmọ̀ “kalmọtu-llāh” ni “kalmọh ti Allāhu / kalmọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ kalmọh nítorí pé, kalmọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; rūhu-llāh, “rūhu ti Allāhu / rūhu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ rūhu nítorí pé, rūhu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; nāƙọtu-llāh “nāƙọh ti Allāhu / nāƙọh tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ nāƙọh nítorí pé nāƙọh kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu”; baetu-llāh, “baeutu ti Allāhu / baetu tí ó jẹ́ ohun ìní Allāhu, kì í ṣe Allāhu tí ó ń jẹ́ baetu nítorí pé, baetu kò sí nínú àlàjẹ́ fún Allāhu” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí a sì ti sọ síwájú pé àpọ́nlé láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó jẹ́ fún ẹ̀dá kan nígbàkígbà tí Allāhu bá fi orúkọ ara Rẹ̀ (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ẹ̀yán ajórúkọ fún un. Nítorí náà, kò wúlẹ̀ sí kiní kan láyé àti lọ́run, yálà ipò ọlá tàbí ipò ìjọba, àfi kí ó jẹ́ ohun ìní fún Allāhu nítorí pé, ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ gbogbo wọn. Báwo wá ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá ṣe lè jẹ́ ohun ìní, tí ohun ìní sì máa tún jẹ́ Allāhu, Ọlọ́hun Olúwa? Kò lè ṣẹlẹ̀ láéláé. Nítorí náà, èyíkéyìí orúkọ ipò tí Allāhu bá lò fún ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), kò fi ibì kan kan túmọ̀ sí pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni olúwa tàbí olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu. Ṣebí àràkárà tí alágbẹ̀dẹ bá fi irin dá, kò lè sọ irin di alágbẹ̀dẹ.
Mọsīh kò kọ̀ láti jẹ́ ẹrú fún Allāhu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mọlāika tí wọ́n súnmọ́ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti jọ́sìn fún Un, tí ó tún ṣègbéraga, (Allāhu) yóò kó wọn jọ papọ̀ pátápátá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn. Ó sì máa ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Ní ti àwọn t’ó bá sì kọ̀ (láti jọ́sìn fún Allāhu), tí wọ́n sì ṣègbéraga, (Allāhu) yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro. Wọn kò sì níí rí alátìlẹ́yìn tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ t’ó yanjú kalẹ̀ fun yín.
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fun yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ arákùnrin (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fun yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Icon