ﰋ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
Ṣé A ò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò ṣẹbọ rí ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Allāhu, ọ̀kan nínú ohun tí ó máa ń kọ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lóminú, tí ó sì máa ń bà á nínú jẹ́ ni àìdá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ àti àìní ìlànà ìjọ́sìn kan lọ́wọ́ ṣíwájú ogójì ọdún tí ó kọ́kọ́ lò. Ní òdodo ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní orúkọ rere gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ àti olùfọkàntán láààrin àwọn Lárúbáwá ṣíwájú kí Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tó gbé e dìde ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àmọ́ ńṣe ni ìṣẹ̀mí ayé ìgbà-àìmọ̀kan àkọ́kọ́ t’ó fi lògbà pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìlú Mọkkah máa ń bà á nínú jẹ́ gan-an. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń fún un ní ìró ìdùnnú pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà-àìmọ̀kan ní ọrùn rẹ̀ mọ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
Àti pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kàn wulẹ̀ ń banújẹ́ lórí ìgbà-àìmọ̀kan, èyí tí ìdàjọ́ rẹ̀ jẹ́ pé tí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, àmọ́ tí onítọ̀ún padà gba ’Islām, ìbáà jẹ́ pé ó gbà á ní òwúrọ̀, ó sì jáde kúrò láyé ní ọ̀sán ọjọ́ náà, bí ó tilẹ̀ wù kí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wúwo tó, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ náà ti di ohun tí wọ́n ti ṣàforíjìn rẹ̀ fún un pátápátá. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:17-18.

A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ọ̀kan), gbìyànjú (òmíràn).
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.