ﰡ
’Alif Lām Rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà ọgbọ́n.
Ṣé ó jẹ́ kàyéfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn, pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.”
Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́.
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀.
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu).
Dájúdájú àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run), tí wọ́n yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ dódó sí (ìṣẹ̀mí ayé yìí) àti àwọn afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa,
àwọn wọ̀nyẹn, ibùgbé wọn ni Iná nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
____________________
“Ìgbàgbọ́ òdodo” t’ó jẹyọ nínú gbólóhùn “àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo” àti gbólóhùn “Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà.” jẹ́ n̄ǹkan kan náà. Ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni ìwọ̀nyí: (Ìkíní); Ìgbàgbọ́ òdodo yóò máa ṣe atọ́nà onígbàgbọ́ òdodo lọ síbi àlékún iṣẹ́ rere títí ọjọ́ ikú rẹ̀. (Ìkejì); Ìgbàgbọ́ òdodo yóò yọ sí onígbàgbọ́ òdodo ní àwòrán ẹ̀dá t’ó rẹwà jùlọ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ t’ó lágbára jùlọ lọ́jọ́ tí onígbàgbọ́ òdodo náà bá jíǹde nínú sàréè rẹ̀ lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwòrán iṣẹ́ rere yìí yó sì máa darí rẹ̀ lọ títí olówó rẹ̀ máa fi wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Àdúà wọn nínú rẹ̀ ni “mímọ́ ni fún Ọ, Allāhu”. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ìparí àdúà wọn sì ni pé “gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá”.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń kánjú mú aburú bá àwọn ènìyàn (nípasẹ̀ èpè ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ń) tètè mú oore bá wọn (nípasẹ̀ àdúà), A ìbá ti mú òpin ba ìṣẹ́mí wọn. Nítorí náà, A máa fi àwọn tí kò retí ìpàdé Wa sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
Nígbà tí ìnira bá kan ènìyàn, ó máa pè Wá lórí ìdùbúlẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ìjókòó tàbí ní ìnàró. Nígbà tí A bá mú ìnira rẹ̀ kúrò fún un, ó máa tẹ̀ síwájú (nínú àìgbàgbọ́) bí ẹni pé kò pè Wá sí ìnira tí ó mú un. Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn alákọyọ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
A kúkú ti pa àwọn ìran kan rẹ́ ṣíwájú yín nígbà tí wọ́n ṣe àbòsí. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Wọn kò sì gbàgbọ́. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
Lẹ́yìn náà, A ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn nítorí kí Á lè wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa, t’ó yanjú fún wọn, àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) yóò máa wí pé: “Mú Ƙur’ān kan wá yàtọ̀ sí èyí tàbí kí o yí i padà.” Sọ pé: “Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún mi láti yí i padà láti ọ̀dọ̀ ara mi. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni, èmi ìbá tí lè ké al-Ƙur’ān fun yín, àti pé Allāhu ìbá tí fi ìmọ̀ rẹ̀ mọ̀ yín. Mo kúkú ti lo àwọn ọdún kan láààrin yín ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?”
Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn ọ̀daràn kò níí jèrè.
Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Kí ni àwọn ènìyàn jẹ́ (ní ìpìlẹ̀) bí kò ṣe ìjọ ẹyọ kan (ìjọ ’Islām). Lẹ́yìn náà ni wọ́n yapa ẹnu. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan t’ó ti ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, Àwa ìbá ti yanjú ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí láààrin ara wọn.
Wọ́n ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí àmì kan sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Nítorí náà, sọ pé: “Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”
Nígbà tí A bá fún àwọn ènìyàn ní ìdẹ̀ra kan tọ́wò lẹ́yìn tí ìnira ti fọwọ́ bà wọ́n, nígbà náà ni wọ́n máa dète sí àwọn āyah Wa. Sọ pé: “Allāhu yára jùlọ níbi ète. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń dá léte.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí atẹ́gùn t’ó dára sì ń tukọ̀ wọn lọ, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì lérò pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n sì pe Allāhu pẹ̀lú ṣíṣe àfọ̀mọ́-àdúà fún Un pé: “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”
____________________
Ṣíṣe àfọ̀mọ́ àdúà fún Allāhu ni pípe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó gbà wọ́n là tán ìgbà náà ni wọ́n tún ń ṣe ìbàjẹ́ kiri lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ìbàjẹ́ yín ń bẹ lórí yín. (Ìbàjẹ́ yín sì jẹ́) ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí yín. A sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àpèjúwe ìṣẹ̀mí ayé dà bí omi kan tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí àwọn irúgbìn nínú ohun tí ènìyàn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn ń jẹ sì gbà á sára, títí di ìgbà tí ilẹ̀ yóò fi lọ́ràá. Ó sì mú ọ̀ṣọ́ (ara) rẹ̀ jáde. Àwọn t’ó ni í sì lérò pé àwọn ni alágbára lórí rẹ̀, (nígbà náà ni) àṣẹ Wa dé bá a ní òru tàbí ní ọ̀sán. A sì sọ ọ́ di oko tí wọ́n fà tu dànù bí ẹni pé kò sí níbẹ̀ rárá rí ní àná. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ aláròjinlẹ̀.
Allāhu ń pèpè sí ilé Àlàáfíà. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).
Rere àti àlékún (oore) wà fún àwọn t’ó ṣe rere. Eruku tàbí ìyẹpẹrẹ kan kò níí bò wọ́n lójú mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn t’ó sì ṣ’iṣẹ́ aburú, ẹ̀san aburú bí irú rẹ̀ (ni ẹ̀san wọn). Ìyẹpẹrẹ sì máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kò sí aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (Wọ́n máa dà bí) ẹni pé wọ́n fi apá kan òru t’ó ṣókùnkùn bò wọ́n lójú pa. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pé: “Ẹ dúró pa sí àyè yín, ẹ̀yin àti àwọn òrìṣà yín.” Nítorí náà, A yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn òrìṣà wọn sì wí pé: “Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Nítorí náà, Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin àwa àti ẹ̀yin pé àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa ìjọ́sìn yín (tí ẹ̀ ṣe fún wa).”
Níbẹ̀ yẹn, ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan máa dá ohun t’ó ṣe síwájú mọ̀. Wọn yó sì da wọ́n padà sọ́dọ̀ Allāhu, Olúwa wọn, Òdodo. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì máa dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́.
Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?"
Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?
Báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe wá sí ìmúṣẹ lórí àwọn t’ó ṣèbàjẹ́ pé dájúdájú wọn kò níí gbàgbọ́.
Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè pilẹ̀ dídá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú)?" Sọ pé: "Allāhu l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú). Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?
Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni t’ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo?" Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo. Nígbà náà, ṣé Ẹni t’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí pé kí wọ́n máa tẹ̀lé ni tàbí ẹni tí kò lè dá ọ̀nà mọ̀ fúnra rẹ̀ àfi tí A bá fi mọ̀nà?” Nítorí náà, kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò sì rí kiní kan tẹ̀lé bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì lè rọrọ̀ kiní kan níwájú òdodo. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni? Sọ pé: "Ẹ mú sūrah kan bí irú rẹ̀ wá. Kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè pè lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
Kò rí bẹ́è, wọ́n pe ohun tí wọn kò ní ìmọ̀ rẹ̀ nírọ́ ni. Àti pé ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò tí ì dé bá wọn (ni wọ́n fi pè é nírọ́). Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ṣe rí.
Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo. Ó tún ń bẹ́ nínú wọn ẹni tí kò gbà á gbọ́. Olúwa rẹ sì ni Onímọ̀-jùlọ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ pé: “Tèmi ni iṣẹ́ mi. Tiyín ni iṣẹ́ yín. Ẹ̀yin yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí mò ń ṣe níṣẹ́. Èmi náà sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Ó sì wà nínú wọn, àwọn t’ó ń tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ l’o máa mú adití gbọ́rọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe làákàyè?
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Rūm; 30:53.
Ó tún ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ń wò ọ́. Ṣé ìwọ l’o máa fi afọ́jú mọ̀nà ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ríran?
Dájúdájú Allāhu kò níí fí kiní kan ṣàbòsí sí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ènìyàn ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.
Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó wọn jọ àfi bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé ju àkókò kan nínú ọ̀sán. Wọn yó sì dára wọn mọ̀. Dájúdájú àwọn t’ó pe ìpàdé Allāhu nírọ́ ti ṣòfò; wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, Allāhu ni Arínú-róde ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Òjíṣẹ́ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí Òjíṣẹ́ wọn bá dé, A óò ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Sọ pé: “Èmi kò ní ìkápá ìnira tàbí oore kan fún ẹ̀mí ara mi àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Gbèdéke àkókò ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.”
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Rẹ̀ bá dé ba yín ní òru tàbí ní ọ̀sán? Èwo nínú rẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú?”
Ṣé lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán ni ẹ máa gbà á gbọ́? Ṣé nísinsìn yìí (ni ẹ óò gbà á gbọ́), tí ẹ sì kúkú ti ń wá a pẹ̀lú ìkánjú?
Lẹ́yìn náà, A óò sọ fún àwọn t’ó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà gbére wò.” Ṣé A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
Wọ́n sì ń bèèrè fún ìró rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “ṣé òdodo ni?” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo fi Olúwa mi búra. Dájúdájú òdodo ni. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.”
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan t’ó ṣàbòsí, ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi ìyà). Wọn yóò fi igbe àbámọ̀ pamọ́ nígbà tí wọ́n bá rí Ìyà. A ó ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Gbọ́! Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò nímọ̀.
Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Èyin ènìyàn, ìṣítí kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ti dé ba yín. Ìwòsàn ni fún n̄ǹkan t’ó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Sọ pé: “Pẹ̀lú àjùlọ oore Allāhu (ìyẹn, al-Ƙur’ān) àti àánú Rẹ̀ (ìyẹn, ’Islām), nítorí ìyẹn ni kí wọ́n máa fi dunnú; ó sì lóore jùlọ sí ohun tí àwọn (aláìgbàgbọ́) ń kó jọ (nínú oore ayé).”
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú arísìkí, tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe àwọn kan ní èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́. Ṣé Allāhu l’Ó yọ̀ǹda fun yín ni tàbí ẹ̀ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”
Kí ni èrò-ọkàn àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde ná? Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kì í dúpẹ́ (fún Un).
Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; tí ó mọ ní òdiwọ̀n iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, kí ó tún kéré jú ìyẹn lọ tàbí kí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.
Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé).
____________________
Nínú èdè Lárúbáwá, ìtúmọ̀ “waliyyu” pọ̀. Nínú rẹ̀ ni ìwọ̀nyí; ọ̀rẹ́, alásùn-únmọ́, ọ̀rẹ́ àyò, alámòójútó, aláṣẹ-ẹni, aláàbò, aláfẹ̀yìntì, alárànṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo àwọn ìtúmọ̀ wọ̀nyí l’ó so pọ̀ mọ́ra wọn. Ẹyọ ni “waliyyu”, ọ̀pọ̀ ni “’aoliyā’u”. Nínú āyah yìí “’aoliyā’u-llāh” túmọ̀ sí “àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu” tàbí “àwọn alásùn-únmọ́ Allāhu”. Ọ̀rọ̀ ìdà kejì rẹ̀ ni “ ‘aduwwu-llāh” (ìtúmọ̀: àwọn ọ̀tá Allāhu tàbí àwọn olùjìnnà sí Allāhu). “‘Aduwwu-llāh” ni ẹyọ, “ ‘a‘dā’u-llāh” ni ọ̀pọ̀. Nínú āyah 63 ní al-Ƙur’ān fúnra rẹ̀ ti mú oríkì wá fún “waliyyu-llāh”. Oríkì méjì tí ọ̀kan kò rọrọ̀ tayọ ìkejì rẹ̀ ni āyah náà sí mú wá. Àwọn ni “al-’Īmọ̄n” ìgbàgbọ́ òdodo àti “tẹƙwa-llāh” ìbẹ̀rù Allāhu. Ìyẹn ni pé, ẹnì kan kò níí jẹ́ “waliyyu-llāh” àfi kí ó jẹ́ mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo àti olùbẹ̀rù Ọlọ́hun. ’Islām ní orígun márùn-ún, ’Īmọn ni orígun mẹ́fà, ìbẹ̀rù Ọlọ́hun sì ní orígun méjì. Ní ti àwọn orígun ’Islām márààrún; (ìkíní) ìjẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu àti ìjẹ́rìí pé dájúdájú Muhammad, Òjíṣẹ́ Allāhu ni, (ìkejì) kíkí ìrun wákàtí márààrún, (ìkẹta) gbígba ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, (ìkẹrin) yíyọ Zakāh, (ìkarùn-ún) ṣíṣe àbẹ̀wò sí Ilé Ọlọ́hun fún ẹni t’ó bá lágbára ọ̀nà láti dé ibẹ̀. Ní ti àwọn orígun ’Īmọ̄n mẹ́fẹ̀ẹ̀fà; (ìkíní) ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, (ìkejì) ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn mọlāika, (ìkẹta) ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn Tírà sánmọ̀, (ìkẹrin) ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu, (ìkarùn-ún) ìgbàgbọ́ òdodo nínú kádàrá, oore rẹ̀ àti aburú rẹ̀, (ìkẹfà) ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ní ti àwọn orígun takwa-llāh méjèèjì; (ìkíní) títẹ̀lé ohun tí Allāhu pa láṣẹ tàbí ohun tí Ó ṣe ní halāl, (ìkejì) jíjìnnà sí ohun tí Allāhu kọ̀ tàbí tí Ó ṣe ní harām, yálà ó jẹ́ n̄ǹkan abẹ̀sìnjẹ́ tàbí aláìbẹ̀sìnjẹ́. Ẹnikẹ́ni nínú ènìyàn àti àlùjànnú tí ó bá gba ìròyìn pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyẹn ní àpapọ̀ ni a mọ̀ sí ““waliyyu-llāh”. Irú ẹni náà kò níí yé máa ní àgbéga ipò “waliyyu-llāh” níwọ̀n ìgbà tí ó bá ń lékún sí i nínú gbogbo ìwọ̀nyẹn ní àpapọ̀. Àmọ́ kò sí bí onítọ̀ún ṣe lè wọ ipò “Ànábì Ọlọ́hun” tàbí ipò “Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Èyí fi hàn kedere pé, ipò aṣíwájú pátápátá ni àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ wà sí gbogbo àwa ’aoliyā’u-llāh”. Kíyè sí i, “waliyyu-llāh” ni àwọn kristiẹni ń pè ní “wòlíì Ọlọ́hun”, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí “waliyyu-llāh” kan kan láààrin wọn nítorí pé kò sí ẹnì kan nínú wọn t’ó gba ìròyìn pẹ̀lú àwọn oríkì “waliyyu-llāh” gẹ́gẹ́ bí kò ṣe sí “waliyyu-llāh” kan kan nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ ní ìbámu sí sūrah al-’Anfāl; 8:34. Bákan náà, àwọn onisūfī sọ àwọn ògbólógbòó aládàádáálẹ̀ aṣíwájú wọn di “ ’aoliyā’u-llāh” dípò “ ’aoliyā’u-ṣṣaetọ̄n”. Ìdí ni pé, ojú ọ̀nà sunnah Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan ṣoṣo ni ojú ọ̀nà tí ẹnikẹ́ni lè gba di “waliyyu-llāh” ní ìbámu si sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:31 àti sūrah an-Nisā’; 4:115. Ẹni tí ó bá ń tọ ojú ọ̀nà bíi Tijāniyyah, Ƙọ̄diriyyah, Ahmadiyyah, Ṣī’ah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kò lè rọ́nà wọ inú agbo àwọn “ ’aoliyā’u-llāh” láéláé àyàfi tí ó bá padà sínú sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
(Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu).
Ti wọn ni ìró ìdùnnú nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kò sí ìyípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.
Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú gbogbo agbára pátápátá ń jẹ́ ti Allāhu. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀. Kí ni àwọn t’ó ń pe àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu ń tẹ̀lé ná? Wọn kò tẹ̀lé (kiní kan) bí kò ṣe àròsọ. Wọn kò sì ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
Òun ni Ẹni t’Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó ṣe) ọ̀sán ní (àsìkò) tí ẹ óò ríran (kedere). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).
Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹ̀dá di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Olùrọrọ̀. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. – Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín fún èyí. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?
Sọ pé: “Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.”
Ìgbádùn bín-íntín (lè wà fún wọn) nílé ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, A óò fún wọn ní ìyà líle tọ́ wò nítorí pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́.
Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fun yín bá lágbara lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́.
Tí ẹ bá sì kọ̀yìn (sí ìrántí), èmi kò kúkú tọrọ owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín. Kò sí ẹ̀san kan fún mi (níbì kan) bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì ti pa mí láṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí.”
Nígbà náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, A gbà á là, òun àti àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omí. A sì ṣe wọ́n ní àrólé (lórí ilẹ̀). A sì tẹ àwọn t’ó pe āyah Wa nírọ́ rì sínú agbami. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ṣe rí.
Lẹ́yìn náà, A gbé àwọn Òjíṣẹ́ kan dìde sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn náà kò kúkú gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ Ànábì Nūh) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn, ìyẹn ni pé, irú kan-ùn ni wọ́n). Báyẹn ni A ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn alákọyọ.
____________________
Ẹ tún wo sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:101.
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn wọn A fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā àti Hārūn níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n ṣègbéraga. Wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Dájúdájú èyí ni idán pọ́nńbélé.”
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan tí ẹ̀yin yóò máa wí nípa òdodo ni pé idán ni nígbà tí ó dé ba yín? Ṣé idán sì ni èyí bí? Àwọn òpìdán kò sì níí jèrè."
Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè ṣẹ́rí wa kúrò níbi ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ (nínú ìbọ̀rìṣà) àti nítorí kí títóbi sì lè jẹ́ tẹ̀yin méjèèjì lórí ilẹ̀? Àwa kò sì níí gba ẹ̀yin méjèèjì gbọ́.”
Fir‘aon wí pé: “Ẹ lọ mú gbogbo àwọn onímọ̀ nípa idán pípa wá fún mi.”
Nígbà tí àwọn òpìdán sì dé, (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ máa jù sílẹ̀.”
Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Idán ni ohun tí ẹ mú wá. Dájúdájú Allāhu sì máa bà á jẹ́. Dájúdájú Allāhu kò sì níí ṣàtúnṣe iṣẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Allāhu sì máa mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ìbáà kórira rẹ̀.
Nítorí náà, kò sí ẹni t’ó gba (Ànábì) Mūsā gbọ́ àfi àwọn àrọ́mọdọ́mọ kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo (wọn) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè wọn pé ó máa fòòró àwọn. Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ.
(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun náà ni kí ẹ gbáralé tí ẹ bá jẹ́ mùsùlùmí.”
Nítorí náà, wọ́n sọ pé: "Allāhu la gbáralé. Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún ìjọ alábòsí.
____________________
Ìyẹn ni pé, kí Allāhu má ṣe fi ọ̀tá ẹ̀sìn wa borí wa. Tàbí àdánwò t’ó máa kàn wá tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn wa yóò fi lérò pé a kì í ṣe ẹni Allāhu, kí Allāhu má ṣe fi kàn wá. Ìdí ni pé, àdánwò tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi kan ẹ̀dá nílé ayé, kò níí ṣe pọ̀ pẹ̀lú jíjẹ́ ẹni Ọlọ́hun tàbí àìjẹ́ ẹni Ọlọ́hun nítorí pé, Aṣèyí-Ó-wùú ni Allāhu. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àdánwò àìlera tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi kan Ànábì ’Ayyūb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), tòhun ti bí ó ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Ànábì Yūsuf ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹni tí wọ́n fi sínú ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìparọ́-sìná-mọ́ni, tòhun ti bí ó ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Nítorí náà, mùsùlùmí bùkátà sí ìrawọ́rasẹ̀ sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Kí Ó sì fi àánú Rẹ gbà wá là lọ́wọ́ ìjọ aláìgbàgbọ́."
A sì ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn ibùgbé fún àwọn ènìyàn yín sí ìlú Misrọ. Kí ẹ sì sọ ibùgbé yín di ibùkírun. Kí ẹ sì máa kírun. Àti pé, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.”
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O fún Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ àti dúkìá nínú ìṣẹ̀mí ayé. Olúwa wa, (O fún wọn) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ. Olúwa wa, pa dúkìá wọn rẹ́, kí O sì mú ọkàn wọn le, kí wọ́n má gbàgbọ́ mọ́ títí wọn fi máa rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro."
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀."
A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami odò já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti àbòsí àti ìtayọ ẹnu-àlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”
____________________
Àkíyèsí mẹ́ta l’ó wà nínú gbólóhùn tí Fir‘aon sọ yìí. Ìkíní: Fir‘aon sọ pé, “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.”, dípò kí Fir‘aon sọ pé, “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.” Ìgbéraga rẹ̀ l’ó mú “àfi Allāhu.”wúwo lẹ́nu rẹ̀, tí ó fi wí pé “àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.” Ìkéjì: Nínú ẹ̀gbàwá Imām ’Ahmọd, nínú hadīth mọrfū‘ Sa‘īd bun Jubaer (rọdiyallāhu 'anhu) àti Ibn ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu), Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Dájúdájú Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń rọ́ erùpẹ̀ sí ẹnu Fir‘aon ní ti ìpáyà pé kí ó má sọ pé, “kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.”. Èyí fi hàn pé, Fir‘aon kò rí kalmọh wí bí ó ṣe yẹ kí ó wí i. Wọ́n ní kí ó sọ́ tó, ó ní òun kò lè sọ tótòtòó. Dípò kí ó sọ pé, “kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.”, ó wí pé, “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.” Ṣé Ọlọ́hun tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́ kò lórúkọ ni?. Ìkẹta: Ẹ̀sìn ’Islām ni ẹ̀sìn àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lójú ayé Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Mùsùlùmí sì ni wọ́n. Èyí l’ó hàn sí Fir‘aon l’òun náà fi sọ pé, “Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.” Àmọ́ lẹ́yìn ikú Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pa ẹ̀sìn ’Islām tì pátápátá, wọ́n sì gbé ẹ̀sìn mìíràn kalẹ̀ fúnra wọn. Orúkọ ẹ̀sìn àdádáálẹ̀ wọn sì ni Yẹhūdiyyah. Irú àdánwò yìí kan náà l’ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lẹ́yìn tí Allāhu gbé e gun sánmọ̀ lọ láàyè. Ìjọ tirẹ̀ náà pa ẹ̀sìn ’Islām tì pátápátá, wọ́n sì gbé ẹ̀sìn mìíràn kalẹ̀ fúnra wọn. Orúkọ ẹ̀sìn àdádáálẹ̀ wọn sì ni Nasrọ̄niyyah.
Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́?
Nítorí náà, ní òní ní A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa.
A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé alápọ̀n-ọ́nlé. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa ẹnu (sí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí.
Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú Taorāt àti ’Injīl), bi àwọn t’ó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò. Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò.
Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́,
gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
____________________
Ẹ wo sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:138.
Kò kúkú sí ìlú kàn, t’ó gbàgbọ́ (lásìkò ìyà), tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus. Nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀.
Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ìbá gbàgbọ́, gbogbo wọn pátápátá. Nítorí náà, ṣé ìwọ l’o máa jẹ wọ́n nípá ni títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo?
Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah at-Taobah; 9:13.
Sọ pé: "Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀."
Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ìgbà àwọn t’ó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”
Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
(Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
____________________
“Hanīf”; olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Òun ni ẹni tí ó yàgò fún gbogbo ìṣìnà àti ẹ̀sìnkẹ́sìn, tí ó wá dúró déédé sínú ìmọ̀nà ’Islām nìkan ṣoṣo. Ipò tí gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (a.s.w.) wà nìyẹn nínú ’Islām.
Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.”
Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú òdodo ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Èmi sì kọ́ ni olùṣọ́ fun yín."
Tẹ̀lé ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Kí o sì ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́. Òun sì lóore julọ nínú àwọn olùdájọ́.