ترجمة سورة الرّوم

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الرّوم باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

’Alif lām mīm.
Wọ́n ṣẹ́gun Rōmu
____________________
Àwọn ará ilẹ̀ Fārisi (ìyẹn ̓Irān)
ní àwọn ilẹ̀ t’ó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn
____________________
Ìyẹn ní ilẹ̀ Siria, ‘Irāƙ, Jọdan àti Palẹstin
ní ọdún mẹ́wàá (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣaájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú
sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣaburú nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.
Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù.
Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn.
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí wọn yó sì máa dunnú.
Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò kó wá sínú Iná.
Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní alẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀.
TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán.
(Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde.
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé).
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fun yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó láròjinlẹ̀.
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè.
Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀.
TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.
____________________
Āyah yìí jọ sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 nítorí pé, wọ́n dì jọ jẹ́ oní-pọ́nna. Ní ti āyah òkè yìí, pọ́n-na inú rẹ̀ ni pé, kò sí ẹni tí kò tẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Irú àṣẹ tí wọ́n ń tọ́ka sí nínú āyah yìí l’ó mú pọ́n-na lọ́wọ́. Àṣẹ méjì l’ó wà lórí ẹ̀dá. Àṣẹ àdámọ́ àti àṣẹ ìjọ́sìn. Àṣẹ àdámọ́ l’ó jẹmọ́ wíwá sáyé, lílọ sọ́run àti gbogbo ohun tí ọmọnìyàn kò lè ríbi yẹ̀ ẹ́ sí bí ebi, òǹgbẹ, oorun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwọ̀nyẹn ni àṣẹ Allāhu lára ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà onígbàgbọ́ òdodo tàbí aláìgbàgbọ́. Nítorí náà, gbogbo wa ni à ń tẹ̀lé àṣẹ Allāhu t’ó jẹmọ́ àdámọ́ nígbàkígbà tí àṣẹ náà bá dé sí wá lára. Kódà tí ìdíwọ́ kan bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láti tẹ̀lé àṣẹ náà, ìnira máa gbá a mú títí ó máa fi tẹ̀lé àṣẹ náà. Àmọ́ ní ti àṣẹ ìjọ́sìn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan l’ó ń tẹ̀lé àṣẹ Allāhu lórí rẹ̀. Ní ti àwọn aláìgbàgbọ́, àṣẹ Èṣù àti àṣẹ ìfẹ́-inú wọn ni wọ́n ń tẹ̀lé. Irú āyah òkè yìí tún wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:116, Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ t’ó ṣíwájú nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
____________________
Ìròyìn t’ó ga jùlọ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ròyìn ara Rẹ̀ ni gbolóhùn “Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.” Àti gbólóhùn yìí :“Kò sí kiní kan t’ó dà bí Rẹ̀…” (at-Tọbariy)
(Allāhu) ṣàkàwé kan fun yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fun yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gbadọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè.
____________________
Èsì sí àkàwé yìí ni pé, kò sí olówó ẹrú tí ó máa sọ ẹrú rẹ̀ di ẹgbẹ́ rẹ̀ lórí dúkìá rẹ̀. Ṣebí dúkìá náà ni ẹrú jẹ́ fún olówó ẹrú. Nítorí náà, kò lè sí ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa sọ di ẹgbẹ́ Rẹ̀ láààrin gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Ẹrú Rẹ̀ sì ni gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀.
Ńṣe ni àwọn t’ó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn.
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yūnus; 10:105.
(Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kírun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
(Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn t’ó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?
Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù.
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́.
Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀bùn, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san.
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fun yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú).
Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún
nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fun yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Allāhu ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀.
Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yìí ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀.
Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.
Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé, níwọ̀n ìgbà tí āyah 52 àti 53 òkè yìí ti fi rinlẹ̀ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè bá òkú sọ̀rọ̀ kí ó gbọ́, kí ó sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jí òkú dìde; níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la etí adití kí ó gbọ́rọ̀ àti níwọ̀n ìgbà tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè la ojú afọ́jú kí ó ríran gẹ́gẹ́ bí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe la ojú afọ́jú, wọ́n ní nígbà náà kí l’ó fẹ́ sọ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) di aṣíwájú bíi ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti pé, kò lè sí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nítorí pé, kò lè jí òkú dìde, kò lè la etí adití, kò sì lè la ojú afọ́jú. Wọ́n ní nítorí náà, ọ̀dọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nìkan ni ìgbàlà wà nítorí pé, ó ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn àti òmíràn fún ará ayé!
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, iṣẹ́ ìyanu kọ́ ni òṣùwọ̀n fún ta ni ó lè jẹ́ aṣíwájú àwọn ènìyàn. Ẹnì kan kan kò sì lè rọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan lóyè nípasẹ̀ àìṣe iṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan t’ó dá iṣẹ́ ìyanu ṣe láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ bí kò ṣe èyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá yọ̀ǹda fún un láti ṣe nítorí pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run. Nítorí náà, fún àlékún lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ̄’idah; 5:110.
Lẹ́yìn náà, kì í ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ní agbára láti fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu òkè wọ̀nyẹn ṣe, tí Allāhu bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ àwọn kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn, ńṣe ni wọ́n gbé àwọn āyah náà ka ibùgbékà òdì nítorí pé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ṣíṣe ni àkòrí àwọn āyah náà bí kò ṣe pé àpẹẹrẹ àti àpèjúwe àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ni kókó nínú àwọn āyah náà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà wé òkú, adití àti afọ́jú ni. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń fi yé Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, lẹ́yìn tí ó bá ti ké àwọn āyah fún àwọn ènìyàn nípa òdodo ’Islām, ẹni tí ó bá tún takú sórí àìgbàgbọ́, kì í ṣe ènìyàn t’ó pé níye mọ́, onítọ̀ún ti wà nípò òkú, ẹni tí kò lè ṣe àtúnṣe kan kan mọ́ sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò adití nítorí pé, adití kì í gbọ́rọ̀. Bákan náà, aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ti wà nípò afọ́jú nítorí pé, afọ́jú kì í ríran, kò sì lè dárìn láì níí máa já sí kòtò àti gelemọ. Nítorí náà, àfiwé àwọn aláìgbàgbọ́ agbọ́mágbà ní kókó àti àkòrí àwọn āyah náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu.
Lẹ́yìn náà, irúfẹ́ àwọn āyah náà ń pa ìbànújẹ́ rẹ́ nínú ọkàn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni nítorí pé, bí ó ṣe ń wù ú tó àti bí ó ṣe ń jẹ̀rankàn tó ni pé, kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ gbàgbọ́ nínú Allāhu. Àmọ́ wọn kò gbàgbọ́, Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń pàrọwà fún un pé, ọwọ́ Òun ni ìyẹn wà. Kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má wulẹ̀ fi ìrònú ìyẹn han ara rẹ̀ léèmọ̀.
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára.
Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń f’irọ́ tanra wọn jẹ.
Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”
Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (mùsùlùmí) kò jẹ́ kiní kan tayọ òpùrọ́.”
Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀.
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ dòpè.
Icon