ترجمة سورة الأنعام

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الأنعام باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó tún dá òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.
Òun ni Ẹni tí Ó da yín láti inú erùpẹ̀ amọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó fi gbèdéke ìgbà kan sí (ìṣẹ̀mí ayé yín). Àti pé gbèdéké àkókò kan (tún wà fún ayé) lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣeyèméjì.
Òun ni Allāhu nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ó mọ ìkọ̀kọ̀ yín àti gban̄gba yín. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò sí àmì kan tí ó máa dé bá wọn nínú àwọn àmì Olúwa wọn, àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.
Wọ́n kúkú pe òdodo nírọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, láìpẹ́ àwọn ìró ohun tí wọ́n máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.
Ṣé wọn kò rí i pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?” Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́.
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú.
____________________
Ìyẹn ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn ti da bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ṣa ọkùnrin kan lẹ́ṣà láààrin wọn rú mọ́ra wọn lójú, ìyẹn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ẹni tí àwọn náà jẹ́rìí sí jíjẹ́ olódodo àti olùfọkàntán rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, tí wọ́n sì ń sọ ìsọkúsọ sí i lóríṣiríṣi lọ́nà àìtọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe máa dojú ọ̀rọ̀ rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ tí ó bá jẹ́ pé mọlāika kan ni Allāhu ní kí ó jẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ láààrin wọn nítorí pé, àwọn tí wọn kò gbàgbọ́ nínú ènìyàn tí wọ́n mọ ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀ sí òdodo àti ìfọkàntán, wọn kò níí wulẹ̀ gbàgbọ́ pàápàá nínú mọlāika tí wọn kò mọ n̄ǹkan kan nípa ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀.
Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí àwọn t’ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.
Sọ pé: “Ẹ rin orí ilẹ̀ lọ, lẹ́yìn náà kí ẹ wo báwo ni àtubọ̀tán àwọn t’ó ń pe òdodo nírọ́ ṣe rí.”
Sọ pé: “Ti ta ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni.” Ó ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò níí gbàgbọ́.
____________________
Irú àánú wo? Èsì rẹ̀ wá níwájú nínú āyah 54. Lẹ́yìn náà, bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ṣe fi apá kan mọ̀nà, kò túmọ̀ sí pé kì í ṣe Aláàánú, kò sì túmọ̀ sí pé àánú Rẹ̀ kò lè kárí gbogbo wa ní ayé àti ní ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé bí Allāhu ṣe fi ọ̀nà tààrà Rẹ̀, ’Islām, mọ apá kan kò túmọ̀ sí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) jẹ́ alábòsí. Àmọ́ ẹ̀kọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ wa nínú ìwọ̀nyẹn pọ̀ púpọ̀. Nínú rẹ̀ ni pé, gbogbo ìròyìn ara Rẹ̀ l’ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ. Lára ìròyìn Rẹ̀ ni ìfinimọ̀nà àti ìṣinilọ́nà, àánú àti ìyà. Kò sí èyí t’ó máa ṣe àlékún ọlá Rẹ̀ nínú wọn, kò sì sí èyí tí ó máa tàbùkù ipò Rẹ̀ nínú wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni kó wòye sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú ọpọlọ t’ó mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì nítorí pé, kò sí ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò ní àwíjàre lórí rẹ̀.
TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó ń bẹ nínú òru àti ọ̀sán. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).” Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
____________________
Irú āyah yìí wà níwájú ní āyah 163. Ó tún wà nínú sūrah az-Zumọr; 39:12. Kíyè sí i, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bá ’Islām láyé ni, kì í ṣe òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe ’Islām nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn tí gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (alaehim sọlātu wa salām) t’ó ṣíwájú rẹ̀ ṣe. Àmọ́ nínú ìjọ tirẹ̀, òun ni ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo. Bákan náà, bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Allāhu (alaehim sọlātu wa salām) ṣe máa ń sọ nìyẹn nínú ìjọ kóówá wọn ní ìgbà kóówá wọn gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-‘A‘rọ̄f; 7: 143. Nítorí náà, Ànábì kọ̀ọ̀kan ní ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo nínú ìjọ rẹ̀. Kódà fún wí pé nínú ìjọ Fir‘aon, àwọn òpìdán rẹ̀ ni àwọn t’ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní òdodo, l’ó mú àwọn náà pe ara wọn ní ẹni àkọ́kọ́ onígbàgbọ́ òdodo, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:51. Síwájú sí i, nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́, ìyẹn nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:41, wọ́n sì kúkú di aláìgbàgbọ́ ní gbogbo ọ̀nà lẹ́yìn Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì ni àwọn ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́ bí? Rárá. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ìjọ ìjọ t’ó ṣíwájú wọn di aláìgbàgbọ́ ṣíwájú wọn bí ìjọ Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ nígbà tàwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, àwọn ni wọ́n tún wà nípò àwọn ẹni àkọ́kọ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìjọ tiwọn. Nítorí náà, kò sí “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ ’Islām ni ìjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Èyí ni àwọn kan mọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun”. Èwo nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni kò juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀? Èwo nínú wọn sẹ́ ni kò ṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun? Kò sí. Ìdí nìyí ti gbogbo wọn fi jẹ́ mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:128-141.
Kíyè sí i! Kristiẹniti kò túmọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́hun”. Kristiẹniti kò sì túmọ̀ sí ìjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Ọlọ́hun, òfin Ọlọ́hun àti ìlànà Rẹ̀. Kódà àwọn kristiẹni wulẹ̀ ti kó ara wọn kúrò lábẹ́ òfin Ọlọ́hun, wọ́n ti wà lábẹ́ òfin “ìfẹ́-àwọn wòlíì” ní orúkọ “oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kristi”. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Taobah; 9:31 àti sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:64.
Nítorí náà, Ànábì Muhammad kì í ṣe ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu, òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Àmọ́ nínú ìjọ rẹ̀, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ Ńlá, tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”
Ẹnikẹ́ni tí A bá darí rẹ̀ kúrò níbi (ìyà) ní Ọjọ́ yẹn, (Allāhu) ti ṣàánú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé.
Tí Allāhu bá fi ìnira kan kàn ọ́, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun náà. Tí Ó bá sì mú oore kan bá ọ, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Òun sì ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀.
____________________
Āyah yìí àti āyah 61 nínú sūrah yìí ti fi rinlẹ̀ pé, òkè lókè àwọn sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà pẹ̀lú títóbi Rẹ̀. Àmọ́ sūrah az-Zukruf; 43:84, sūrah al-Hadīd; 57:4 àti sūrah al-Mujādilah; 58:7 èyí tí àwọn kan fi lérò pé kò sí ibi tí pàápàá bíbẹ Allāhu kò sí, lókè àti nílẹ̀ ní kọ̀rọ̀ àti ní gban̄gba, ó jẹ́ ìtúmọ̀ òdì tí kò wà ní ìbámu sí èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí àwọn āyah náà. Ìdí ni pé, àwọn āyah 18 àti 61 nínú sūrah al-’Ani‘ām àti sūrah an-Nahl; 16:50 ń sọ nípa ibi tí pàápàá bíbẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà, ìyẹn sì ni òkè sánmọ̀ keje. Àmọ́ àwọn sūrah az-Zukruf; 43: 84, sūrah al-Hadīd; 57:4 àti sūrah al-Mujādilah; 58:7 sì ń sọ nípa ìmọ̀ Allāhu àti nípa bí ìmọ̀ Rẹ̀ ṣe gbòòrò, t’ó sì fi ìmọ̀ Rẹ̀ yípo gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ pátápátá, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi sí ẹ̀dá kan kan tí Allāhu kò nímọ̀ nípa ibi tí ó wà. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi sūrah al-’Ani‘ām; 6:80, sūrah Tọ̄hā; 20:98 àti sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 yanjú ìrújú tí àwọn aláṣìtú wọ̀nyẹn ní. Kíyè sí i, tòhun ti bí Fir‘aon ṣe ṣàì gbàgbọ́ tó nínú pàápàá bíbẹ Allāhu, kò kúkú wá Allāhu lọ sí àyè kan kan lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe inú òkè ayé, ìyẹn sánmọ̀, bí ó tilẹ̀ já sí pé kò lè rí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Èyí wà nínú sūrah Gọ̄fir; 40:36-37. Ọ̀kan pàtàkì t’ó sì burú nínú àwọn àdìsọ́kàn àwọn aláìgbàgbọ́ ni pé, “ibi gbogbo ni Ọlọ́hun wà”. Má ṣe bá wọn sọ bẹ́ẹ̀ nítorí kí o má baà dà bí tiwọn. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Sọ pé: “Kí ni ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀rí?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin.” Ó sì fi ìmísí al-Ƙur’ān yìí ránṣẹ́ sí mi, nítorí kí n̄g lè fi ṣe ìkìlọ̀ fun ẹ̀yin àti ẹnikẹ́ni tí (al-Ƙur’ān) bá dé etí ìgbọ́ rẹ̀. Ṣé dájúdájú ẹ̀yin ń jẹ́rìí pé àwọn ọlọ́hun mìíràn tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.” Sọ pé: “Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Àti pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).”
Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́.
____________________
Gbólóhùn yìí “Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n” ń túmọ̀ sí pé, àwọn t’ó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl mọ̀ pé nínú tírà méjèèjì, ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá àti pé Òjíṣẹ́ tí wọ́n ń retí ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àmọ́ wọ́n daṣọ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀. Ìdí nìyí tí āyah 21 fi pè wọ́n ní alábòsí.
Ta l’ó sì ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí (ẹni tí) ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.
Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn t’ó bá (Allāhu) wá akẹgbẹ́ pé: “Níbo ni àwọn òrìṣà yín wà, àwọn tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Allāhu?”
Lẹ́yìn náà, ìfòòró wọn (lórí ìbéèrè náà) kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n á wí pé: “A fi Allāhu, Olúwa wa búra, àwa kì í ṣe ọ̀ṣẹbọ.”
Wo bí wọ́n ṣe parọ́ mọ́ra wọn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ ń bẹ nínú wọn. A sì fi èbìbò bo ọkàn wọn kí wọ́n má baà gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Tí wọ́n bá rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́ débi pé nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ, wọn yó sì máa bá ọ jiyàn; àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì máa wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Àwọn ni wọ́n ń kọ̀ (fún àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé Ànábì s.a.w.), àwọn náà sì ń takété sí i. Wọn kò sì kó ìparun bá ẹnikẹ́ni bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.
Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí A bá dá wọn dúró síbi Iná, wọ́n sì máa wí pé: “Yéè! Kí wọ́n sì dá wa padà (sílé ayé), àwa kò sì níí pe àwọn āyah Olúwa wa nírọ́ (mọ́), a sì máa wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Kò rí bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ ṣíwájú ti hàn sí wọn ni. Tí ó bá jẹ́ pé A bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
Wọ́n wí pé: "Kí ni (ó tún jẹ́ ìṣẹ̀mí ọ̀run) bí kò ṣe ìṣẹ̀mí wa nílé ayé; Wọn kò sì níí gbé wa dìde (ní ọ̀run)."
Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, Ó sì máa sọ pé: “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọ́n á sì wí pé: “Rárá (òdodo ni), Olúwa wa.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ máa ń ṣàì gbàgbọ́.”
Dájúdájú àwọn t’ó pe pípàdé Allāhu (lọ́run) nírọ́ ti ṣòfò débi pé nígbà tí Àkókò náà bá dé bá wọn lójijì, wọ́n á wí pé: “A ká àbámọ̀ lórí ohun tí a fi jáfira.” Wọ́n sì máa ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn sẹ́yìn wọn. Kíyè sí i, ohun tí wọn yóò rù lẹ́ṣẹ̀ sì burú.
Ìṣẹ̀mí ayé kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe eré àti ìranù. Ọgbà Ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
A kúkú ti mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń wí yóò bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú wọn kò lè pè ọ́ ní òpùrọ́, ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ń tako àwọn āyah Allāhu ni.
Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ.
Tí ó bá sì jẹ́ pé gbígbúnrí wọn lágbára lára rẹ, nígbà náà tí o bá lágbára láti wá ihò kan sínú (àjà) ilẹ̀, tàbí àkàbà kan sínú sánmọ̀ (ṣe bẹ́ẹ̀) kí o lè mú àmì kan wá fún wọn. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá kó wọn jọ sínú ìmọ̀nà (’Islām). Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn aláìmọ̀kan.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 12 nínú sūrah yìí.
Àwọn t’ó ń gbọ́rọ̀ ni àwọn t’ó ń jẹ́pè. Àwọn òkú, Allāhu yó sì gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí.
Wọ́n tún wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.”
Kò sí ohun abẹ̀mí kan (t’ó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan t’ó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí.
Àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, adití àti ayaya t’ó wà nínú àwọn òkùnkùn ni wọ́n. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa ṣì í lọ́nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fi sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín tàbí tí Àkókò náà bá dé ba yín, ṣe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni ẹ̀yin máa pè, tí ẹ bá jẹ́ olódodo!"
Rárá, Òun (nìkan) l’ẹ̀ ń pè. Ó sì máa mú (ìnira) tí ẹ̀ ń pè É sí kúrò (fun yín), tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin yó sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ sí I.
Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi ìpọ́njú àti àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).
Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn ti le koko. Èṣù sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn.
Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù.
Nítorí náà, A pa ìjọ t’ó ṣàbòsí run pátápátá. Gbogbo ọpẹ́ sì ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá gba ìgbọ́rọ̀ yín àti ìríran yín, tí Ó sì di ọkàn yín pa, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu ni ó máa mú un wá fun yín? Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì ń gbúnrí!
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín ní òjijì tàbí ní ojúkojú, ṣé wọ́n máa pa ẹnì kan run bí kò ṣe ìjọ alábòsí!”
A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí wọ́n jẹ́) oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ rẹ̀), kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, ọwọ́ ìyà yóò tẹ̀ wọ́n nítorí pé wọ́n máa ń ṣèbàjẹ́.
Sọ pé: “Èmi kò sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fun yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí.” Sọ pé: "Ǹjẹ́ afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Ṣé ẹ ò ronú jinlẹ̀ ni?"
Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn t’ó ń páyà pé Wọ́n máa kó àwọn jọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, kò sì níí sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. (Kìlọ̀ fún wọn) kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Má ṣe lé àwọn t’ó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.
____________________
Āyah yìí ń sọ nípa àwọn Sọhābah (r.ahm.) tí wọ́n jẹ́ tálíkà pọ́nńbélé, gẹ́gẹ́ bí āyah 53 tí ó tẹ̀lé āyah yìí ṣe fi hàn. Àwọn Sọhābah wọ̀nyí kò sì ní ibi iṣẹ́ kan kan tí wọ́n lè máa rí lọ. Gbàgede mọ́sálásí Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni ibùgbé àti ibùsùn wọn. Gbàgede mọ́sálásí yìí ni à ń pè ní suffah. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe àwọn Sọhābah wọ̀nyí ní ahlu-ssuffah "ará gbàgede". Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu nínú oúnjẹ ọrẹ tí àwọn t’ó ríbi lọ bá gbé wá fún Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Wọn a sì máa gbé sàárà fún wọn pẹ̀lú. Fún wí pé wọn kì í lọ sí ibì kan kan ló fi jẹ́ pé ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ ṣíṣe tilāwa al-Ƙur’ān àti ṣíṣe gbólóhùn athikir tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kọ́ wọn ni àwọn Sọhābah wọ̀nyí dúnnímọ́ jùlọ. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì pa Ànábì Rẹ̀ ní àṣẹ láti máa wà pẹ̀lú wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń wà pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n ń ríbi lọ fún ọ̀nà ìjẹ-ìmu wọn. Nítorí náà, àwọn Sọhābah wọ̀nyí kì í ṣe sūfi. Wọn kì í sì ṣe onitọrīkọ kan kan. Irúfẹ́ āyah yìí tún wà nínú sūrah al-Kahf; 18:28.
Báyẹn ni A ṣe fi apá kan wọn ṣe àdánwò fún apá kan nítorí kí (àwọn aláìgbàgbọ́) lè wí pé: “Ṣé àwọn (mùsùlùmí aláìní) wọ̀nyí náà ni Allāhu ṣe ìdẹ̀ra (ìmọ̀nà) fún láààrin wa!?” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùdúpẹ́ ni?
Nígbà tí àwọn t’ó gba àwọn āyah Wa gbọ́ bá wá bá ọ, sọ (fún wọn) pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Olúwa yín ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí ó ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
55. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah nítorí kí ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fojú hàn kedere.
Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi láti jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu.” Sọ pé: “Èmi kò níí tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, mo ti ṣìnà (tí mo bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín). Èmi kò sì sí nínú àwọn olùmọ̀nà.”
Sọ pé: “Dájúdájú mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, ẹ̀yin sì pè é nírọ́. Kò sí ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ní ọ̀dọ̀ mi. Kò sí ìdájọ́ náà (fún ẹnikẹ́ni) àyàfi fún Allāhu, Ẹni tí ń sọ (ìdájọ́) òdodo. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi ni, Wọn ìbá ti ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà láààrin èmi àti ẹ̀yin. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn alábòsí.”
Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.
Òun ni Ẹni t’Ó ń kùn yín ní oorun ní alẹ́. Ó sì nímọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́ ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbe yín dìde (fún ìjẹ-ìmu) ní (ọ̀sán) nítorí kí wọ́n lè parí gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí yín. Lẹ́yìn náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Ismul-mọsdar “yatawaffākum” ni “wafāt”. Ní àyè yìí “wafāt” kò sì túmọ̀ sí ikú bí kò ṣe oorun. Bákan náà, “wafāt” ni ismul-mọsdar “tawaffathu” nínú āyah 61 níwájú. Òhun sì túmọ̀ sí ikú. Fún àlàyé kíkún, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:55.
Òun ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Ó sì ń rán àwọn ẹ̀ṣọ́ kan si yín títí di ìgbà tí ikú yóò fi dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Àwọn Òjíṣẹ́ wa yó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, wọn kò sì níí jáfira.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Lẹ́yìn náà, wọ́n yóò dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, Olúwa wọn, Òdodo. Kíyè sí i, tiRẹ̀ ni ìdájọ́. Òun sì yára jùlọ nínú àwọn olùṣírò.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Sọ pé: “Ta ni ẹni t’ó ń gbà yín là nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò, Ẹni tí ẹ̀ ń pè pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ní ìkọ̀kọ̀ pé: "Dájúdájú tí Ó bá gbà wá là nínú èyí, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un)?"
Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń gbà yín là nínú rẹ̀ àti nínú gbogbo ìbànújẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣẹbọ.”
Sọ pé: “Ó lágbára láti fi ìyà ránṣẹ́ si yín láti òkè yín tàbí láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ yín, tàbí kí Ó dà yín pọ̀ mọ́ onírúurú ìjọ, nítorí kí Ó lè mu apá kan yín fìnira kan apá kan. Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè gbọ́ àgbọ́yé.”
Àwọn ènìyàn rẹ pe al-Ƙur’ān nírọ́! (Àmọ́) òdodo ni. Sọ pé: “Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.”
Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ l’ó ní àkókò (ìṣẹ̀lẹ̀). Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Nígbà tí o bá rí àwọn t’ó ń sọ ìsọkúsọ nípa àwọn āyah Wa, nígbà náà ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn. Tí Èṣù bá ń mú ọ gbàgbé (tẹ́lẹ̀), ní báyìí lẹ́yìn ìrántí má ṣe jókòó ti ìjọ alábòsí.
Kiní kan nínú ìṣírò-iṣẹ́ wọn kò sí lọ́rùn àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ìṣítí ni nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún Iná).
Pa àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Sọ pé: “Ṣé a óò máa pè lẹ́yìn Allāhu, ohun tí kò lè ṣe wá ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wa; (ṣé) kí wọ́n tún dá wa padà sí ẹsẹ̀-àárọ̀ wa lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti fi ọ̀nà mọ̀ wá (kí á lè dà) bí ẹni tí Èṣù mú tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí ìdààmú dé bá? Ó (sì) ní àwọn ọ̀rẹ́ kan tí wọ́n ń pè é síbi ìmọ̀nà (pé), “Máa bọ̀ ní ọ̀dọ̀ wa.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà ti Allāhu (’Islām), òhun ni ìmọ̀nà. Wọ́n sì pa wá láṣẹ pé kí á gba ẹ̀sìn ’Islām nítorí ti Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
Àti pé kí ẹ kírun, kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Òun ni Ẹni tí wọ́n yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Òun sì ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu máa yí ilẹ̀ àti sánmọ̀ padà sí n̄ǹkan mìíràn), Ó sì máa sọ pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Òdodo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀. TiRẹ̀ sì ni ìjọba ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba ni. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.
(Rántí) nígbà tí ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀, Āzar, (pé): “Ṣé o máa sọ àwọn ère òrìṣà di ọlọ́hun ni? Dájúdájú èmi rí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú.
Nígbà tí òkùnkùn alẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó rí ìràwọ̀ kan, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn (olúwa) t’ó ń wọ̀ọ̀kùn.”
Nígbà tí ó rí òṣùpá t’ó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Dájúdájú tí Olúwa mi kò bá tọ́ mi sọ́nà, dájúdájú mo máa wà nínú àwọn olùṣìnà ènìyàn.”
Nígbà tí ó rí òòrùn t’ó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà t’ó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).
____________________
Nínú àwọn āyah 76, 77 àti 78, ní tẹ̀léǹtẹ̀lé ni Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pe ìràwọ̀, òṣùpá àti òòrùn ní olúwà rẹ̀ lẹ́yìn Allāhu! Èèwọ̀ sì ni sísọ bẹ́ẹ̀. Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tún wọ́gi lé ìkọ̀ọ̀kan wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé àti lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Ǹjẹ́ pípè tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pe ìràwọ̀, òṣùpá àti òòrùn ní olúwà rẹ̀ sọ ọ́ di ọ̀ṣẹbọ bí? Rárá. Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò jọ́sìn fún ìràwọ̀, òṣùpá, òòrùn àti òrìṣà kan kan rí nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí ọjọ́ ikú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù nínú àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (alaehim sọlāt wa salām) kò ṣe ṣẹbọ rí. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ti ṣe àfọ̀mọ́ Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pé kò ṣẹbọ rí, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:135, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:67 àti 95, sūrah al-’Ani‘ām; 6:161 àti sūrah an-Nahl; 16:120 àti 123. Àwọn onímọ̀ sì ṣe àlàyé lórí àwọn āyah 76, 77 àti 78 nínú sūrah al-’Ani‘ām yìí púpọ̀ pẹ̀lú èròǹgbà láti ṣọ́ ẹnu wa níbi sísọ ìsọkúsọ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm, àyò Allāhu (kọlīlu-llāh alaehi sọlātu wa salām). Èyí tí àwọn onímọ̀ ṣe yìí láti máa ṣọ́ ẹnu wa níbi sísọ ìsọkúsọ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 90:50. Lẹ́yìn náà, èyí tí ó tẹ́rùn jùlọ gẹ́gẹ́ bí ibùgbékà ọ̀rọ̀ náà ni àlàyé tí àwọn àfáà mú wá pé, “Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mú ọ̀rọ̀ náà wá lójú pọ̀n-nà ìgbémọ́ra àti ìjẹ́nilẹ́gọ̀ọ́ láti sọ àròjàre ìjọ rẹ̀ dàròjẹ̀bi wọn, kì í ṣe lójú pọ̀n-nà ìṣeyèméjì nípa Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn – w-Allahu ’a‘lam – nítorí pé ohun tí ọ̀rọ̀ náà jọ ni kí a sọ pé, Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sọ pé, “Ṣé èyí “ìràwọ̀” ni olúwa mi? Rárá. Ṣé èyí “òṣùpá” ni olúwá mi? Rárá… Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn n̄ǹkan tí ìjọ rẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ìjọ rẹ̀ l’ó ń pe ìwọ̀nyẹn ní olúwa wọn. Àmọ́ Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń wá ọ̀nà tí ó máa gbà fi yé wọn pé ìràwọ̀, òṣùpá, òòrùn tàbí òrìṣà kan kò lè jẹ́ olúwa kí ó máa sá lọ sá bọ̀. A kúkú tún rí ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn lọ́dọ̀ Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lójú pọ̀n-nà ẹ̀lọ́. Ìyẹn nígbà tí àwọn abọ̀rìṣà bi í léèrè pé, “Ṣé ìwọ l’o ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?” Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí l’ó ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀).” Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó sì yọ àáké ti àwọn òrìṣà wọn, tí ó sì rún wọn wómúwómú. Àmọ́ ó kúkú sọ òye t’ó fẹ́ kí àwọn ọ̀ṣẹbọ mú jáde nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Òye náà ni pé, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.” (sūrah al-’Anbiyā’; 21:62-63). Èyí kò kúkú sọ Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di òpùrọ́, ìyẹn kò sì sọ Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ọ̀ṣẹbọ, àmọ́ ìkíní kejì wà lábẹ́ fífi òye ṣàyẹ̀wò òye wọn wò bóyá òye wọn ti rí ìmọ́lẹ̀ tàbí ó sì wà nínú òkùnkùn. Òye tí ó bá rí ìmọ́lẹ̀ l’ó máa rí ìdáláre fún ohun tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe wọ̀nyí. Àmọ́ tí òye bá wà nínú òkùnkùn kò níí rí ìdáláre náà, gẹ́gẹ́ bí òye àwọn ọ̀ṣẹbọ ọjọ́ náà kò ṣe rí ìdáláre fún Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām).
Dájúdájú èmi dojú mi kọ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (mo) dúró déédé (sínú ’Islām fún Un). Èmi kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
Àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jà á níyàn. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò jà mí níyàn nípa Allāhu, Ó sì ti fi ọ̀nà mọ̀ mí? Èmi kò sì páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Un, àfi bí Allāhu bá fẹ́ kiní kan (pé kó ṣẹlẹ̀). Olúwa mi fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Báwo ni èmi yóò ṣe páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Allāhu, tí ẹ̀yin kò sì páyà pé ẹ̀ ń bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pẹ̀lú ohun tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fun yín lórí rẹ̀? Èwo nínú ikọ̀ méjèèjì l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ẹ bá nímọ̀?
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọn kò sì da ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ mọ́ àbòsí (ìbọ̀rìṣà), àwọn wọ̀nyẹn ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ń bẹ fún. Àwọn sì ni olùmọ̀nà."
Ìyẹn ni àwíjàre Wa tí A fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. À ń ṣe àgbéga ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
Ati pé A ta á lọ́rẹ (Ànábì) ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (tí ó jẹ́ ọmọ ’Ishāƙ). Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fi mọ̀nà. A sì fi (Ànábì) Nūh mọ̀nà ṣíwájú. Àti pé nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì ’Ibrọ̄hīm tí A fi mọ̀nà ni àwọn Ànábì) Dāwūd, Sulaemọ̄n, ’Ayyūb, Yūsuf, Mūsā àti Hārūn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Àti (Ànábì) Zakariyyā, Yahyā, ‘Īsā àti ’Ilyās; gbogbo wọn wà nínú àwọn ẹni rere.
Àti ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘, Yūnus àti Lūt; ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A ṣoore àjùlọ fún lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn).
Àti pé nínú àwọn bàbá wọn, àrọ́mọdọ́mọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn, A ṣà wọ́n lẹ́ṣà. A sì fi wọ́n mọ̀nà tààrà (’Islām).
Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà nínú àwọn ẹrú Rẹ̀. Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A fún ní Tírà, ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah) àti (ipò) Ànábì. Nítorí náà, tí àwọn wọ̀nyí bá ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú A ti gbé e lé àwọn ènìyàn kan lọ́wọ́, tí wọn kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Nítorí náà, ọ̀nà wọn ni kí o tẹ̀lé. Sọ pé: “Èmi kò bi yín ní owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.”
Wọn kò fún Allāhu ní iyì tí ó tọ́ sí I, nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀ fún abara kan.” Sọ pé: "Ta ni Ó sọ tírà tí (Ànábì) Mūsā mú wá kalẹ̀, (èyí t’ó jẹ́) ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn, èyí tí ẹ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé àjákọ, tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀, tí ẹ sì ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ rẹ̀ pamọ́, A sì fi ohun tí ẹ ò mọ̀ mọ̀ yín, ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín?" Sọ pé: "Allāhu ni." Lẹ́yìn náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìsọkúsọ wọn, kí wọ́n máa ṣeré.
Èyí (al-Ƙur’ān) tún ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀; ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti pé nítorí kí o lè ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù). Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, wọ́n gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn sì ni wọ́n ń ṣọ́ ìrun wọn.
Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí ẹni tí ó wí pé wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi - A ò sì fi kiní kan ránṣẹ́ sí i - àti ẹni tí ó wí pé "Èmi náà yóò sọ irú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ kalẹ̀."? Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé) “Ẹ mú ẹ̀mí yín jáde wá. Lónìí ni Wọn yóò san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí ohun tí ẹ̀ máa ń sọ nípa Allāhu ní àìtọ́. Ẹ sì máa ń ṣe ìgbéraga sí àwọn āyah Rẹ̀.”
Dájúdájú ẹ ti wá bá wa ní ìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ẹ sì ti fi ohun tí A fun yín sílẹ̀ sí ẹ̀yìn yín. A ò mà rí àwọn olùṣìpẹ̀ yín pẹ̀lú yín, àwọn tí ẹ sọ láì ní ẹ̀rí pé dájúdájú láààrin yín àwọn ni akẹgbẹ́ (fún Allāhu). Dájúdájú àṣepọ̀ ààrin yín ti já pátápátá. Àti pé ohun tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn (láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí ìṣìpẹ̀ yín) ti dòfo mọ yín lọ́wọ́.
Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú kóró èso irúgbìn àti kóró èso dàbínù hù jáde. Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú. Ó sì ń mú òkú jáde láti ara alààyè. Ìyẹn ni Allāhu. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Ó ń mú ojúmọ́ mọ́. Ó ṣe òru ní ìsinmi. (Ó ń mú) òòrùn àti òṣùpá (rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.
Òun ni Ẹni tí Ó fi àwọn ìràwọ̀ ṣe (ìmọ́lẹ̀) fun yín kí ẹ lè fi ríran nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn t’ó nímọ̀.
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Nítorí náà, ibùgbé (nílé ayé) àti ibùpadàsí (ní ọ̀run wà fun yín). A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn t’ó ní àgbọ́yé.
Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A fi mú gbogbo n̄ǹkan ọ̀gbìn jáde. A tún mú ewéko t’ó ń dán lọ̀gbọ́lọ̀gbọ́ jáde láti inú rẹ̀. A tún ń mú ṣiri èso jáde nínú rẹ̀. (A sì ń mú jáde) láti ara igi dàbínù, láti ara èso àkọ́yọ rẹ̀, èso t’ó ṣùjọ mọ́ra wọn t’ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ wálẹ̀. (À ń ṣe) àwọn ọgbà oko èso àjàrà, èso zaetūn àti èso rummọ̄n (ní àwọn èso t’ó) jọra àti (àwọn èyí tí) kò jọra. Ẹ wo èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so àti (nígbà tí ó bá) pọ́n. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
Wọ́n sì fi àwọn àlùjànnú ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dàá wọn! Wọ́n tún parọ́ mọ́ Ọn (pé) Ó bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, láì nímọ̀ kan (nípa Rẹ̀). Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni. Báwo ni Ó ṣe ní ọmọ nígbà tí kò ní aya. Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àwọn ojú (ẹ̀dá) kò lè ká Allāhu. Òun sì ká àwọn ojú. Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
Àwọn ẹ̀rí t’ó dájú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni t’ó bá ríran, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì fọ́jú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.
Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè wí pé: "O kẹ́kọ̀ọ́ (rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ni." Dípò kí wọ́n wí pé: "Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ ni." àti nítorí kí A lè ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn t’ó nímọ̀.
____________________
Èsì ọ̀rọ̀ fún àwọn t’ó sọ bẹ́ẹ̀ ni sūrah an-Nahl; 16:103.
Tẹ̀lé ohun tí wọ́n fi rán ọ́ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ìmọ̀nà fún wọn), wọn ìbá tí ṣẹbọ. A ò sì fi ọ́ ṣe olùṣọ́ lórí wọn. Àti pé ìwọ kọ́ ni alámòjúútó wọn.
Ẹ má ṣe bú àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kí àwọn (abọ̀rìṣà) má baà bú Allāhu ní ti àbòsí àti àìnímọ̀. Báyẹn ni A ti ṣe iṣẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni ibùpadàsí wọn. Nítorí náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n máa ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú tí àmì (ìyanu) kan bá dé bá àwọn, àwọn gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́. Sọ pé: "Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà." Kí sì ni ó máa mu yín fura mọ̀ pé dájúdájú nígbà tí ó bá dé (bá wọn) wọn máa gbà á gbọ́?
A máa yí ọkàn wọn àti ojú wọn sódì ni; (wọn kò níí gbà á gbọ́) gẹ́gẹ́ bí wọn kò ṣe gbàgbọ́ nínú (èyí t’ó ṣíwájú nínú àwọn àmì ìyanu) nígbà àkọ́kọ́. A ó sì fí wọn sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.
Dájúdájú tí A bá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wọn, tí àwọn òkú ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí A tún kó gbogbo n̄ǹkan jọ síwájú wọn, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi tí Allāhu bá fẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni aláìmọ̀kan.
Báyẹn ni A ti ṣe àwọn èṣù ènìyàn àti èṣù àlùjànnú ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan; apá kan wọn ń fi odù irọ́ ránṣẹ́ sí apá kan ní ti ẹ̀tàn. Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́ (láti tọ́ wọn sọ́nà ni) wọn ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, fi wọn sílẹ̀ tòhun ti àdápa irọ́ tí wọ́n ń dá.
Kí àwọn ọkàn tí wọn kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí (odù irọ́ Èṣù), kí wọ́n máa yọ́nú sí i, kí wọ́n sì máa dá ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀ ǹ só.
Ṣé n̄ǹkan mìíràn ni kí n̄g wá ní olùdájọ́ lẹ́yìn Allāhu ni? Òun sì ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fun yín tí wọ́n fi ṣàlàyé ìdájọ́. Àwọn tí A sì fún ní tírà mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
____________________
Irú gbólóhùn yìí wà nínú sūrah Yūsuf; 12:111 àti sūrah an-Nahl; 16:89. Wàyí, àwọn n̄nkan titun titun àti àwọn n̄ǹkan ìgbàlódé t’ó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn al-Ƙur’ān, tí Allāhu kò sì sọ̀rọ̀ nípa wọn ńkọ́? Kíyè sí i, al-Ƙur’ān dúró fún òṣùwọ̀n (fọ́múlà) àti ìdájọ́ tí a ó fi máa ṣe ìyàtọ̀ láààrin ìmọ̀ àti ìròrí, ohun rere àti aburú, ẹ̀tọ́ àti èèwọ̀, ìjọ́sìn àti ìranù, ìtẹ̀lé àṣẹ àti ìyapa àṣẹ, iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra àti iṣẹ́ Iná. Sunnah Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì dúró fún àlàyé al-Ƙur’ān.
Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ pé ní òdodo àti ní déédé. Kò sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Tí o bá tẹ̀lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀, wọ́n máa ṣì ọ́ lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọn kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Kí sì ni wọn (ń ṣe) bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Àti pé, Òun sì l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá fi orúkọ Allāhu pa, tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Rẹ̀.
Kí ni ó máa kọ̀ fun yín láti jẹ nínú ohun tí wọ́n fi orúkọ Allāhu pa! Ó kúkú ti ṣàlàyé fun yín ohun tí Ó ṣe ní èèwọ̀ fun yín àyàfi èyí tí ìnira (ebi) bá tì yín débẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni wọ́n ń fi ìfẹ́-inú wọn pẹ̀lú àìnímọ̀ (wọn) ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà.
Ẹ fi èyí t’ó hàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀.
Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Dájúdájú ìbàjẹ́ ni. Àti pé dájúdájú àwọn èṣù, wọn yóò máa fi ìránde odù irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.
Ǹjẹ́ ẹni tí (àfiwé rẹ̀) jẹ́ òkú (ìyẹn, aláìgbàgbọ́), tí A sọ di alààyè (nípa pé ó gba ’Islām), tí A sì fún un ní ìmọ́lẹ̀ (ìyẹn, ìmọ̀ ẹ̀sìn), tí ó sì ń lò ó láààrin àwọn ènìyàn, (ǹjẹ́) ó dà bí ẹni tí àfiwé tirẹ̀ jẹ́ (ẹni tí) ń bẹ nínú àwọn òkùnkùn (àìgbàgbọ́), tí kò sì jáde kúrò nínú rẹ̀? Báyẹn ni wọ́n ti ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Báyẹn ni A ṣe sọ àwọn àgbà kan di ọ̀daràn ìlú nínú ìlú kọ̀ọ̀kan, nítorí kí wọ́n lè máa dète níbẹ̀. Wọn kò sì dète sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí ara wọn, wọn kò sì fura.
Nígbà tí āyah kan bá sì dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Àwa kò níí gbà á gbọ́ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fún àwa náà ní irú ohun tí wọ́n fún àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu.” Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí. Láìpẹ́ ìyẹpẹrẹ àti ìyà líle láti ọ̀dọ̀ Allāhu yóò dé bá àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n ń dá léte.
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fọ̀nà mọ̀, Ó máa ṣí igbá-àyà rẹ̀ payá fún ’Islām. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́ ṣì lọ́nà, Ó máa fún igbá-àyà rẹ̀ pa gádígádí bí ẹni pé ó ń gùnkè lọ sínú sánmọ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe dẹ wàhálà asán sí àwọn tí kò gbàgbọ́.
Èyí ni ojú ọ̀nà Olúwa rẹ (t’ó jẹ́) ọ̀nà tààrà. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń lo ìrántí.
Ilé àlàáfíà ń bẹ fun wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Òun sì ni Alátìlẹ́yìn wọn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
(Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
____________________
Kíyè sí i, āyah yìí kò sọ pé "tí Allāhu bá fẹ́." Ohun tí ó sọ ni pé “àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.” Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ìtúmọ̀ fún “àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́” :(Ìkíní) àfi tí Allāhu bá fẹ́ so ìyà wọn rọ̀ fún ọ̀wọ́ àsìkò Àjíǹde láti inú sàréè àti ní àsìkò Ìdájọ́. (Ìkejì) àfi tí Allāhu bá fẹ́ fi ìran ìyà mìíràn jẹ wọ́n pẹ̀lú ìyà Iná. (Ìkẹta) àfi tí Allāhu bá fẹ́ gba ìṣìpẹ̀ fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn kò bà jẹ́, ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n, tí wọ́n sì ti ipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ wà nínú Iná pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. (Ìkẹrin) àfi tí Allāhu bá fẹ́ fi àánú Rẹ̀ nìkan la àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn kò bà jẹ́, ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n, tí wọ́n sì ti ipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ wà nínú Iná pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Èyí wà ní ìbámu sí hadīth ’Anas, láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu (s.a.w), ó sọ pé: “Ọwọ́jà Iná yóò ba àwọn ènìyàn kan nípasẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tí wọ́n dá, (Iná yó sì jẹ́) ìyà (fún wọn). Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò fi ìkẹ́ àjùlọ Rẹ̀ mú wọn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n á sì máa pè wọ́n ni Jahanamiyyūn.” (al-Bukāriy;7012, Tafsīr al-Ƙurtubiy). Nítorí náà, Tí ó bá jẹ́ pé ohun tí āyah náà sọ ni pé "tí Allāhu bá fẹ́", a ò bá sọ pé kò dájú pé gbére ni Iná ọ̀run. Àmọ́ āyah náà kò sọ pé "tí Allāhu bá fẹ́." Bákan náà, “àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́” kò túmọ̀ sí pé kò níí sí olùṣegbére nínú Iná. Nítorí pé, o ti rinlẹ̀ nínú àwọn āyah mìíràn pé kò sí àforíjìn Allāhu fún ẹni tí ó bá kú sórí ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu, yálà nípasẹ̀ àṣepọ̀ láààrin ènìyàn àti àlùjànnú tàbí ní ọ̀nà mìíràn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olùṣegbére nínú Iná. Ẹ ka àlàyé yìí síwájú sí i nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Hūd 11; 108.
Báyẹn ni A ṣe fi apá kan àwọn alábòsí ṣọ̀rẹ́ apá kan (wọn) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, ṣé àwọn Òjíṣẹ́ kan láààrin yín kò wá ba yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Mi fun yín, tí wọ́n sì ń fi ìpàdé yín Òní yìí ṣèkìlọ̀ fun yín? Wọ́n wí pé: “A jẹ́rìí léra wa lórí (pé wọ́n wá).” Ìṣẹ́mí ayé tàn wọ́n jẹ. Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.
Ìyẹn nítorí pé Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run nípasẹ̀ àbòsí (ọwọ́ wọn), lásìkò tí àwọn ara ìlú náà jẹ́ aláìmọ̀ (títí Òjíṣẹ́ yóò fi dé bá wọn).
Àwọn ipò (ìkẹ́ àti ipò ìyà) ń bẹ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ohun tí wọ́n bá ṣe níṣẹ́. Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Olúwa rẹ ni Ọlọ́rọ̀, Aláàánú. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò (lórí ilẹ̀). Ó sì máa fi ohun tí Ó bá fẹ́ rọ́pò (yín) lẹ́yìn (ìparun) yín gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe mu yín jáde lẹ́yìn (ìparun) àrọ́mọdọ́mọ àwọn ìjọ mìíràn.
Dájúdájú ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín, ó kúkú ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀; ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ dúró sórí ọ̀nà yín, dájúdájú èmi náà yóò dúró (sórí ọ̀nà mi), láìpẹ́ ẹ̀ máa mọ ẹni tí Ọgbà (Ìdẹ̀ra) yóò jẹ́ ìkángun tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
Wọ́n sì fi ìpín kan fún Allāhu nínú ohun tí Ó dá nínú n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn; wọ́n wí pé: "Èyí ni ti Allāhu – pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, - èyí sì ni ti àwọn òrìṣà wa." Nítorí náà, ohun tí ó bá jẹ́ ti àwọn òrìṣà kò níí dàpọ̀ mọ́ ti Allāhu. Ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Allāhu, ó ń dàpọ̀ mọ́ ti àwọn òrìṣà wọn; ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.
Báyẹn ni àwọn òrìṣà wọn ṣe pípa àwọn ọmọ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ nítorí kí wọ́n lè pa wọ́n run àti nítorí kí wọ́n lè d’ojú ẹ̀sìn wọn rú mọ́ wọn lọ́wọ́. Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí ṣe (bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ tòhun ti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
Wọ́n tún wí pé: "Èèwọ̀ ni àwọn ẹran-ọ̀sìn àti n̄ǹkan oko wọ̀nyí. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi ẹni tí a bá fẹ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́." - Àwọn ẹran-ọ̀sìn kan tún ń bẹ tí wọ́n ṣe ẹ̀yìn wọn ní èèwọ̀ (fún gígùn àti ẹrù rírù), àwọn ẹran kan tún ń bẹ tí wọn kì í fi orúkọ Allāhu pa. (Wọ́n fi àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí) dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
Wọ́n tún wí pé: "Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan ṣoṣo, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa." Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀. (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
Àwọn t’ó fi agọ̀ àti àìmọ̀ pa àwọn ọmọ wọn kúkú ti ṣòfò; wọ́n tún ṣe ohun tí Allāhu pa lésè fún wọn ní èèwọ̀, ní ti dídá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Wọ́n kúkú ti ṣìnà, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn n̄ǹkan ọgbà oko èyí tí ẹ̀ ń fọwọ́ ara yín gbìn àti èyí t’ó ń lalẹ̀ hù àti dàbínù àti irúgbìn tí (adùn) jíjẹ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àti èso zaetūn àti èso rummọ̄n t’ó jọra wọn àti èyí tí kò jọra wọn. Ẹ jẹ nínú èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so, kí ẹ sì yọ Zakāh rẹ̀ ní ọjọ́ ìkórè rẹ̀. Kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn, èyí t’ó lè ru ẹrù àti èyí tí kò lè ru ẹrù. Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù; dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.
(Allāhu dá ẹran) mẹ́jọ ní takọ-tabo; méjì nínú àgùtàn (takọ-tabo), méjì nínú ewúrẹ́ (takọ-tabo). Sọ pé: "Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Ẹ fún mi ní ìró pẹ̀lú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
Méjì nínú ràkúnmí (takọ-tabo) àti méjì nínú màálù (takọ-tabo). Sọ pé: "Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Tàbí ṣé ẹ̀yin wà níbẹ̀ nígbà tí Allāhu pa yín láṣẹ èyí ni?" Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí t’ó tún tayọ ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Sọ pé: "Èmi kò rí nínú ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi tí Wọ́n ṣe jíjẹ rẹ̀ ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ ṣíṣàn,1 tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ t’ó yàtọ̀ sí Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ìnira (ebi) bá mú jẹ ẹ́, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.2
____________________
1 Láti ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Umọr, láti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ó sọ pé: "A ṣe òkúǹbete méjì àti ẹ̀jẹ̀ méjì ní ẹ̀tọ́ fún wa; òkúǹbete méjì náà ni ẹja àti tata. Ẹ̀jẹ̀ méjì náà –mo rò ó sí pé Ànábì sọ pé- ẹ̀dọ̀ àti àwọ́n" (Sunanul-Baehaƙiy al-Kubrọ̄; 18776) 2 Āyah yìí kò kó gbogbo ohun jíjẹ àti ohun mímu t’ó jẹ́ harām sínú tán nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kàn fi fọ èsì sí èrò-ọkàn àwọn ọ̀ṣẹbọ ni, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ ṣíwájú nínú āyah 138-139.
A ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn t’ó di yẹhudi gbogbo ẹran eléèékánná (tàbí onípátákò t’ó ṣùpọ̀ mọ́ra wọn). Nínú ẹran màálù àti àgùtàn, A tún ṣe ọ̀rá àwọn méjèèjì ní èèwọ̀ fún wọn àfi èyí tí ó bá lẹ̀ mọ́ ẹ̀yìn wọn tàbí ìfun tàbí èyí tí ó bá ròpọ̀ mọ́ eegun. Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Dájúdájú Àwa sì ni Olódodo.
Tí wọ́n bá sì pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ nígbà náà pé: "Olúwa yín ni Oníkẹ̀ẹ́ tó gbòòrò. Kò sì sí ẹni t’ó lè gbé ìyà Rẹ̀ kúrò lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀."
Àwọn t’ó ń ṣẹbọ yóò wí pé: "Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni àwa àti àwọn bàbá wa ìbá tí ṣẹbọ, àti pé àwa ìbá tí ṣe n̄ǹkan kan léèwọ̀." Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́ títí wọ́n fi tọ́ ìyà Wa wò. Sọ pé: "Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan ń bẹ ní ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ mú un jáde fún wa?" Ẹ̀yin kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Kí sì ni ẹ̀ ń sọ bí kò ṣe pé ẹ̀ ń parọ́.
Sọ pé: "Ti Allāhu ni ẹ̀rí t’ó pé pérépéré." Nítorí náà, tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá fi gbogbo yín mọ̀nà pátápátá."
Sọ pé: "Ẹ mú àwọn ẹlẹ́rìí yín jáde, àwọn t’ó máa jẹ́rìí pé dájúdájú Allāhu l’ó ṣe èyí léèwọ̀." Tí wọ́n bá jẹ́rìí (sírọ́), ìwọ má ṣe bá wọn jẹ́rìí (sí i). Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́. Àwọn sì ni wọ́n ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.
Sọ pé: "Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fun yín; pé kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, – Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn – kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ – èyí t’ó hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n pé dáadáa. A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.
Àti pé dájúdájú èyí ni ọ̀nà Mi (tí ó jẹ́ ọ̀nà) tààrà. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú ọ̀nà (mìíràn) nítorí kí ó má baà mu yín yapa ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Rẹ̀)."
Lẹ́yìn náà, A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà ní pípé pérépéré fún ẹni tí ó máa ṣe dáadáa. (Ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan. (Ó tún jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.
Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín.
Nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Ọ̀wọ́ ìjọ méjì tí ó ṣíwájú wa ni Wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún. A sì jẹ́ aláìnímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ wọn.”
Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Dájúdájú Wọn ìbá sọ Tírà kalẹ̀ fún wa ni, àwa ìbá mọ̀nà jù wọ́n lọ.” Ẹ̀rí t’ó yanjú, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, t’ó tún gbúnrí kúrò níbẹ̀? A máa san àwọn t’ó ń gbúnrí kúrò níbi àwọn āyah Wa ní (ẹ̀san) ìyà burúkú nítorí pé wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbẹ̀).
Ṣé wọ́n ń retí n̄ǹkan (mìíràn) bí kò ṣe pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí Olúwa rẹ wá bá wọn tàbí kí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ wá bá wọn? Ní ọjọ́ tí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ bá wá bá wọn, ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà). Sọ pé: “Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí (Ọjọ́ náà).
Dájúdájú àwọn t’ó ya ẹ̀sìn wọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ, ìwọ kò ní n̄ǹkan kan ṣe pọ̀ pẹ̀lú wọn. Ọ̀rọ̀ wọn sì ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú iṣẹ́ dáadáa wá, (ẹ̀san) mẹ́wàá irú rẹ̀ l’ó máa wà fún un. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wa, A ò níí san án ní ẹ̀san àyàfi irú rẹ̀. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi ti fi ọ̀nà tààrà (’Islām) mọ̀ mí, ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
Sọ pé: "Dájúdájú ìrun mi, ẹran (pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Kò sí akẹgbẹ́ fún Un. Ìyẹn ni Wọ́n pa láṣẹ fún mi. Èmi sì ni ẹni-àkọ́kọ́ àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)."
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.
Sọ pé: "Ṣé èmi yóò tún wá olúwa kan yàtọ̀ sí Allāhu ni, nígbà tí ó jẹ́ pé Òun ni Olúwa gbogbo n̄ǹkan. Ẹ̀mí kan kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”
Òun ni Ẹni tí Ó ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀. Ó sì fi àwọn ipò gbe yín ga ju ara yín lọ nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
Icon