ﰡ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá.
Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ Taorāh àti ’Injīl kalẹ̀
ní ìṣaájú. Ìmọ̀nà sì ni fún àwọn ènìyàn.1 Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.2 Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà t’ó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
____________________
1 Gbólóhùn yìí níí ṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọ àti àsìkò. Ìyẹn ni pé, ìjọ ’Isrọ’īl nìkan ni tírà Taorāh àti ’Injīl jẹ́ ìmọ̀nà fún. Ìjọ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó ni Taorāh. Ìjọ Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó sì ni ’Injīl. Àmọ́ lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ẹni tí Allāhu ṣe gbogbo ayé ní ìjọ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ Ànábì ìkẹ́yìn (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti tẹ̀lé Taorāh àti ’Injīl kan kan mọ́ àyàfi al-Ƙur’ān, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti tẹ̀lé Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā lásìkò yìí àfi Ànábì ìgbà yìí, Ànábì Muhammad. Kò wulẹ̀ sí ojúlówọ́ Taorāh àti ’Injīl ní àsìkò yìí mọ́ ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:75, 79 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Nínú Sọhīh Muslim, láti ọ̀dọ̀ ’Abū Huraerah, láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam), dájúdájú ó sọ pé: “Èmí fi Ẹni tí ẹ̀mí mi wà ní ọwọ́ Rẹ̀ búra; ẹnì kan nínú ìjọ yìí, yẹ̀húdí àti kristiẹni, kò níí gbọ́ nípa mi, lẹ́yìn náà kí ó kú láì gba ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ gbọ́, àfi kí ó wà nínú èrò Iná.” Bákàn náà, nínú tírà musnad ’Ahmọd àti musọnnaf ‘Abdur-Razāƙ, láti ọ̀dọ̀ ‘Abdullāh bun Thābit (rọdiyallāhu 'anhu), Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ẹni tí ó máa wà láàrin yín, lẹ́yìn náà tí ẹ bá tẹ̀lé e, tí ẹ sì pa mí tì, ẹ̀yin ìbá ṣìnà.”
2 Fún àlàyé lórí Furƙọ̄n, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:53.
Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan t’ó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀.
Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n.
Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè.
____________________
Pọ́n-na ni kí ìsọ tàbí ọ̀rọ̀ ṣe é túmọ̀ sí ọ̀pọ̀ ọ̀nà, yálà ìtúmọ̀ tí wọ́n gbà lérò tàbí ìtúmọ̀ tí wọn kò gbà lérò. Nítorí náà, àwọn āyah onípọ́n-na yóò máa kọlura wọn tààrà nínú ìtúmọ̀ wọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí yóò fi máa yọrí sí ìtakora lójú aláìnímọ̀. Ìyẹn ni pé, àwọn āyah onípọ́n-na máa dà bí ẹni pé ìtakora kan wà láààrin ìtúmọ̀ āyah kan àti ìtúmọ̀ āyah mìíràn ṣùgbọ́n ìtakora náà jọ bẹ́ẹ̀ ni lójú aláìnímọ̀ kíkún nípa ọ̀nà ìdàpọ̀ àwọn āyah “tọrīƙọtul-jam‘”, ìtakora náà kò sì rí bẹ́ẹ̀ ní ti pàápàá.
Síwájú sí i, rírí àwọn āyah tí ìtúmọ̀ wọn ní “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀” (at-ta‘ārudu aṭḥ-ṭḥọ̄hiriy) nínú al-Ƙur’ān, òhun náà l’ó sì mú kí á rí irúfẹ́ wọn nínú àwọn hadīth Ànábì tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Dandan sì ni fún wa láti gbàgbọ́ nínú wọn pátápátá ní àpapọ̀.
Kíyè sí i, irúfẹ́ àwọn āyah onípọ́n-na wọ̀nyí ni àwọn kan máa ń tọ́ka sí nígbà tí wọ́n bá ṣàì mọ̀kan sí ọ̀nà ìdàpọ̀ àwọn āyah tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ láti máa rí n̄ǹkan jẹ ní ìjẹkújẹ tàbí láti lè fi tako òdodo ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí āyah tàbí hadith kan tí ó ní pọ́n-na, tí ìtakora wọn wá wọ ipò “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” (at-ta‘ārudu al-haƙīƙiy). Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:82.
Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ ni Ọlọ́rẹ.
Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.
(Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà.
Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ sínú iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú."
Àmì kúkú wà fun yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Ìkejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìjọ kejì ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú. Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùrìran.
Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà.
Sọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan t’ó dára ju ìyẹn lọ fun yín?” Àwọn t’ó bá bẹ̀rù (Allāhu), àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn,
àwọn t’ó ń sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná."
(Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì.
Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti kristiẹni) kò yapa ẹnu (sí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Ẹni t’ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí ’Islām), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.
Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, tí wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́.
Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè síbi Tírà Allāhu, kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà, tí wọ́n sì ń gbúnrí?
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ t’ó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn.
Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Sọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán. Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru. Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń ṣe arísìkí fún ẹni tí O bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.”
Kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Àfi (tí ẹ bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ lórí ahọ́n) láti fi ṣọ́ra fún wọn ní ti wíwá ààbò (fún ìgbàgbọ́ yín). Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Sọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò t’ó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn olùjọ́sìn.
Sọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.
Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).
Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀."
Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.”
Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà náà ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: "Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀."
Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́ àdúà."
Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): "Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu. (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò sì níí súnmọ́ obìnrin. (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere."
____________________
"Ọ̀rọ̀ kan” láti ọ̀dọ̀ Allāhu" ni “Jẹ́ bẹ́ẹ̀” tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣẹ̀dá ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah yìí kan náà, āyah 59. Ẹ tún wo sūrah an-Nisā’; 4:171.
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù."
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ).
Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́ tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò. Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfan̄fà (lórí rẹ̀).
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Abiyì ni ní ayé àti ní ọ̀run. Ó sì wà lára alásùn-únmọ́ (Allāhu).
____________________
Àwọn kristiẹni lèrò pé sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:45 tako sūrah Mọryam; 19:17 nípa pé “mọlā’ikah” jẹ́ “ọ̀pọ̀” nínú āyah àkọ́kọ́, ó sì jẹ́ ẹyọ “mọlak” nínú āyah kejì.
Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀”. Àlàyé rẹ̀ nìyí, nínú āyah ti āli ‘Imrọ̄n, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa bí àwọn mọlā’ikah ṣe wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbi ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àwọn mọlāika t’ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà ju ẹyọ kan lọ. Ìdí nìyí tí “mọlā’ikah” fi jẹ́ ọ̀pọ̀ nínú āyah yẹn. Àmọ́ nínú āyah ti Mọryam, ẹyọ mọlāika kan péré ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi “ẹ̀mí” ‘Īsā rán níṣẹ́ sí Mọryam. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ “mọlak” ẹyọ fún mọlā’ikah. Pẹ̀lú àlàyé yìí, ọ̀tọ̀ ni àsìkò àsọtẹ́lẹ̀ fún Mọryam nípa bíbí ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ọ̀tọ̀ sì ni àsìkò tí àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sí ìmúṣẹ.
Bákan náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:171 lórí àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀”.
Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà t’ó bá dàgbà. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere."
(Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
(Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, ìjìnlẹ̀ òye, Taorāh àti ’Injīl.
(Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) "Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fun yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fun yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
____________________
Àlàyé lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nínú ìtọsȩ̣̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ̄’idah; 5:110.
Mo sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe ní ẹ̀tọ́ fun yín apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fun yín. Mo ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà."
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.
Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí."
Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte.
____________________
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe adéte. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ (kúrò lọ́wọ́ wọn).1 Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́.2 Mo sì máa fi àwọn t’ó tẹ̀lé ọ borí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ yapa ẹnu sí.
____________________
1 Wọ́n ṣẹ̀dá "mutawaffi" láti ara "wafāt/wafāh." Ìtúmọ̀ mẹ́ta ni wafāt/wafāh ní nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: "maot" ikú, "naom" oorun àti "ƙọbd" gbígba n̄ǹkan tàbí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan. Wafāt/wafāh túmọ̀ sí "maot" ikú nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Wafāt/wafāh túmọ̀ sí "naom" oorun nínú sūrah al-’Ani‘ām; 6:60. Wafāt/wafāh sì túmọ̀ sí "ƙọbd" gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:55 ati sūrah al-Mọ̄’dah; 5:117. Ìdí tí wafāt/wafāh ti ‘Īsā fi túmọ̀ sí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan (ìyẹn, gbígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gba Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kúrò lọ́wọ́ àwọn yẹhudi tí wọ́n pète pèrò láti kàn án mọ́ orí igi àgbélébùú, òhun ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé, àwọn yẹhudi kò rí ‘Īsā ọmọ Mọryam pa, wọn kò sì rí i kàn mọ́ igi àgbélébùú, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Nisā’; 4:157-159.
Bákan náà, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ hadīth Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó ní àlàáfíà l’ó fi rinlẹ̀ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam yóò padà sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé láti wá ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá kan. Kò sì níí sí rújúrújú kan kan nínú ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam àti àwọn iṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣe ní òpin ayé. Àmọ́ ìjọ Ahmadiyyah àti irú wọn mìíràn kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì túmọ̀ wafāt/wafāh ti ‘Īsā ọmọ Mọryam sí ikú nítorí pé olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ti sọra rẹ̀ di ‘Īsā ọmọ Mọryam. Àwọn ìjọ Ahmadiyyah sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ digbí. Èyí sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú ìdí pàtàkì tí ìjọ Ahmadiyyah fi yapa ’Islām. Wọ́n sì di kèfèrí. Ẹ kà á síwájú sí i nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nisā’; 4:158.
2 Lára àṣìṣe àwọn kristiẹni ni bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn gan-an ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí pẹ̀lú gbólóhùn “àwọn t’ó tẹ̀lé ọ”, ìyẹn àwọn t’ó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní àkọ́kọ́ náà, ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn t’ó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọ̀wọ́ àwọn t’ó tẹ̀lé e lójú ayé rẹ̀, mùsùlùmí ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pera wọn bẹ́ẹ̀ nínú sūrah yìí, āyah 52. Ó tún wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’dah; 5:111. Àmọ́ nípa àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ìsọ̀rí mẹ́ta ni wọ́n. Ìsọ̀rí kìíní ni ìjọ yẹhudi. Àwọn di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọn kò ṣe gba ‘Īsā gbọ́ ní Òjíṣẹ́ àti bí wọ́n ṣe pète pèrò láti kàn án mọ́ igi àgbélébùú àti láti pa á, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kó o yọ nínú ète wọn. Ìsọ̀rí yìí gan-an ló sì jẹyọ nínú sūrah yìí láààrin āyah 52 sí 56. (Síwájú sí i, àwọn t’ó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), tí wọ́n pera wọn ní mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì fẹ́ kan ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mọ́gi àgbélébùú; àwọn igun méjèèjì náà l’ó tún jẹyọ nínú sūrah as-Sọff; 61:14.) Lórí àwọn ìjọ mẹ́ta t’ó di aláìgbàgbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), nasara ni ìjọ kejì. Wọ́n di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam kì í ṣe olúwa àti olùgbàlà fún ẹnì kan kan, kò sì pera rẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí. Àwọn nasara wọ̀nyí ni Allāhu sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:17, 72 àti 73. Ìjọ kẹta ni ìjọ Ahmadiyyah. Wọ́n di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé àwọn yẹhudi rí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kàn mọ́gi àgbélébùú, àmọ́ kò kú sórí rẹ̀. Ìgbàgbọ́ Ahmadiyyah yìí sì tako sūrah an-Nisā’; 4:157-159.
Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí.
Ìyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān).
Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Ìjọra mélòó gan-an l’ó wà láààrin Jésù Kristi àti Adam t’ó fi to sọ pé, ‘Dájúdájú irú ‘Īsā ní ọ̀dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam’!”
Èsì: Tí ìyàtọ̀ púpọ̀ bá wà láààrin Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), ṣebí àwọn méjèèjì dìjọ jẹ́ irú kan náà ni ní abala jíjẹ́ ẹ̀dá Ọlọ́hun, ẹrú Ọlọ́hun àti Ànábì Ọlọ́hun. Àmọ́ sísọ tí àwọn kristiẹni sọ Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa wọn, olùgbàlà wọn, ọmọ Ọlọ́hun àti ọlọ́hun ọmọ ní ti irọ́ àti ìparọ́mọ́ni ni wọ́n fi ń lérò pé irú Ànábì ‘Īsā kọ́ ni irú Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kò wa tán bí!
Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì.
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣe àdúà taratara, kí á sì tọrọ ègún Allāhu lé àwọn òpùrọ́ lórí.”
Dájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Tí wọ́n bá sì pẹ̀yìn dà (níbi òdodo náà), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t’ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.”
____________________
"Ahlul-kitāb" túmọ̀ sí àwọn oní-tírà. Ìyẹn ni pé, àwọn ìjọ tí wọ́n fira wọn tì sí ọ̀dọ̀ àwọn Ànábì méjì kan tí Allāhu fún ní tírà. Àwọn wọ̀nyí ni ìjọ yẹhudi àti ìjọ nasara. Nítorí náà, ahlul-kitāb ni àlàjẹ́ fún ìjọ méjèèjì.
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni?
Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀? Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
____________________
Ìyẹn ni pé, ’Islām tí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ’Islām tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mú wá, ó ti dojúrú mọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́, tòhun ti bí wọ́n ṣe bá àwọn Ànábì méjèèjì lògbà pọ̀. Nítorí náà, kí ni wọ́n fẹ́ rí sọ nípa ’Islām tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mú wá, ẹni tí wọn kò bá láyé, bí kò ṣe ìsọkúsọ irú èyí tí wọ́n ń sọ nípa àwọn Ànábì wọn, Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā ('alaehim sọlātu wa salām).
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe kristiẹni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Dájúdájú àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jùlọ ni àwọn t’ó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí (Ànábì Muhammad s.a.w.) àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura.
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)!
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)?
Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām).
____________________
Èyí jẹ́ ète kan nínú àwọn ète tí àwọn ahlul-kitāb ń lò. Ète náà ni pé, àwọn kan nínú wọn máa kó sínú ẹ̀sìn ’Islām ní àsìkò kan. Wọn kò sì níí ’Islām í ṣe nítorí pé àìgbàgbọ́ kò yé bá wọn fínra nínú ọkàn wọn, gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fìdí èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:61. Àmọ́ tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà wọ́n kó sínú ’Islām ní àsìkò náà nítorí kí wọ́n lè padà kéde pé àwọn kò ṣe ’Islām mọ́. Irú àwọn wọ̀nyí ni wọ́n sọra wọn di "akéúgbajésù". Ìjàǹbá kan nínú àwọn ìjàǹbá tí ahlul-kitāb ń ṣe fún àwa Mùsùlùmí ni èyí. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi ṣẹ́rí àwọn tí ìgbàgbọ́ òdodo wọn nínú Allāhu kò tí ì rinlẹ̀ àti àwọn t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gba ẹ̀sìn ’Islām. Kí irú àwọn wọ̀nyí lè máa wí pé: "Tí kò bá jẹ́ pé irọ́ wà nínú ’Islām ni, lágbájá àti tàmẹ̀dò kò níí di akéúgbajésù." Kò sì sí lágbájá àti tàmẹ̀dò kan t’ó sọra wọn di akéúgbajésù bí kò ṣe àwọn oníjàǹbá. Àti pé, èdè ni kéú, ìmọ̀ ẹ̀sìn ni al-Ƙur’ān àti hadīth. Àwọn oníjàǹbá wọ̀nyí kì í sì ṣe onímọ̀ ẹ̀sìn. Ìdí nìyí tí ẹ̀yin kò fi lè rí akéúgbajésù kan tí ó lè ko mùsùlùmí onímọ̀ ẹ̀sìn lójú. Nítorí náà, ẹ má ṣe gbẹ̀tàn. ’Islām nìkan ṣoṣo ni òdodo. Ìṣìnà pọ́nńbélé ni gbogbo ẹ̀sìn yòókù pátápátá.
(Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí Wọ́n fun yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”
(Allāhu) ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá.
Ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
Rárá (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Dájúdájú àwọn t’ó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹyìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde. Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn.
Dájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn t’ó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, ìjìnlẹ̀ òye àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, "ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu." Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) "ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn)."
(Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni?
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: “(Ẹ lo) èyí tí Mo bá fun yín nínú Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) yóò dé ba yín; ó máa fi èyí t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí."
Nítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad s.a.w.) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.
Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa pẹ̀lú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
Báwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni olùṣìnà.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
Ọwọ́ yin kò lè ba oore àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.
Gbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àyàfi èyí tí ’Isrọ̄’īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo.”
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí.
Sọ pé: "Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ."
Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah. (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.
____________________
Bakkah jẹ́ orúkọ kejì fún Mọkkah. Ìtúmọ̀ Bakkah ni ìdìfúnǹfún. Ìdìfúnǹfún yìí kò sì lè má ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe tawāf lọ́wọ́ nínú Haram Mọkkah.
Àwọn àmì t’ó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ kó wọ́, ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo ’Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́.
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.
____________________
Kíyè sí i, gbólóhùn yìí, “Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín!” Ìyẹn ṣíwájú kí ó tó kú (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò sí láààrin wa mọ́. Irú āyah yìí wà nínú sūrah at-Taobah; 9:94 àti 105 àti sūrah an-Nisā’; 4:64. Àwọn onibidia nìkan ni wọ́n tún gbà pé títí dí àsìkò yìí ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ń bẹ láààrin wa, tí ó ń rí iṣẹ́ ọwọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ Ahmadiyyah gbà pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) padà wá sáyé, ó sì ń bá mirza Ghulam Ahmad, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ṣe ìpàdé ojú ayé. Bákan náà, ìjọ Tijāniyyah náà gbà pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) padà wá sáyé láti fún ṣeeu Ahmada Tijāni lọ́wọ́ wírìdí. Kódà wọ́n gbà pé lójoojúmọ́ àti níbi gbogbo ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn àrólé rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin (r.ahm) máa wá jókòó sórí aṣọ funfun, èyí tí wọ́n máa ń tẹ́ sáààrin lásìkò tí wọ́n bá ń ka Jaoharatul-kamāl lọ́wọ́. Irọ́ ńlá ni gbogbo àdìsọ́kàn burúkú wọ̀nyí. Àwọn āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ kò sì jẹmọ́ “lẹ́yìn ikú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam)” bí kò ṣe “ṣíwájú ikú rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam)”. Kí á lè mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àmọ̀dájú, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Kíyè sí i, dájúdájú wọn máa mú àwọn ọkùnrin kan wá nínú ìjọ mi (ìyẹn l’ọ́jọ́ Ìdájọ́), wọ́n sì máa mú wọn lọ sí apá òṣì, n̄g ó sì sọ pé; “Olúwa mi, àwọn ènìyàn mi (nìyí).” Wọ́n sì máa sọ pé: “Dájúdájú ìwọ kò mọ ohun tí wọ́n dáálẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ.” (Bukọ̄riy àti Muslim)
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí.
Ẹ dúró ṣinṣin ti okùn Allāhu (’Islām) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú ’Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà (’Islām).
Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun t’ó lóore jùlọ, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé t’ó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún.
Ní ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́.
Ní ti àwọn tí ojú wọn funfun (ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Ẹ jẹ́ ìjọ t’ó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn , ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
____________________
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dé bá, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì gba ’Islām. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Mọ̄’idah; 5:82-86 àti sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:113 àti 115.
Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fun yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bá wọn àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu àlà.
(Àwọn ahlul-kitāb) kò rí bákan náà. Ìjọ kan t’ó dúró déédé wà nínú àwọn ahlul-kitāb, tí ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun).
Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 110 t’ó ṣíwájú.
Ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí wọ́n pàdánù ẹ̀san rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn t’ó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú aláfinúhàn kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fun yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fun yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè.
Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú àwọn tírà, gbogbo rẹ̀ (pátápátá). Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.
Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ si yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì ṣọ́ra (fún wọn), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
(Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò sì ń fi àyè ibùjagun han àwọn onígbàgbọ́ òdodo, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(Rántí) nígbà tí ìjọ méjì nínú yín fẹ́ ṣojo. Allāhu sì ni Aláfẹ̀yìntì àwọn méjèèjì. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Allāhu kúkú fun yín ní ìṣẹ́gun ní ogun Badr, nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìlágbára. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
Rántí nígbà tí ò ń sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo pé: “Ṣé kò níí to yín tí Olúwa yín bá ṣe ìrànlọ́wọ́ fun yín pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú àwọn mọlāika, tí Wọ́n máa sọ̀kalẹ̀?”
Rárá (ó máa tó wa.). Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrú, tí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, tí àwọn (ọ̀tá) bá dé ba yín lójijì, Olúwa yín yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún máàrún nínú àwọn mọlāika pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ lára wọn.
Allāhu kò ṣe é lásán bí kò ṣe kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú fun yín àtí nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe lórí ọ̀tá (láti ibì kan kan) bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
(Allāhu ṣe àrànṣe náà fun yín) nítorí kí Ó lè gé apá kan dànù nínú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tàbí nítorí kí Ó lè dójú tì wọ́n, tí wọ́n sì máa padà wálé lófo.
Kò sí ohun t’ó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n.
____________________
Ẹ̀kọ́ tí āyah yìí fẹ́ kọ́ wa ni pé, mùsùlùmí kan kò gbọdọ̀ ro kèfèrí kan pin pé kó níí gba ’Islām títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí kèfèrí náà parí ìrìn-àjò ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀ sínú ’Islām, tí Allāhu bá fẹ́ foríjìn ín. Ó sì ṣe é ṣe kí ó bá àìgbàgbọ́ rẹ̀ kú, tí Allāhu bá fẹ́ jẹ ẹ́ níyà.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ó ń foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́, Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe jẹ èlé, àdìpèlé lórí àdìpèlé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.
Kí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí Wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín.
Ẹ yára wá àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí ìbú rẹ̀ tó àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Àwọn t’ó ń ná owó wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni). -
Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn ni àforíjìn àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san olùṣe-iṣẹ́ rere sì dára.
Àwọn orípa kan kúkú ti lọ ṣíwájú yín. Nítorí náà, ẹ rin ilẹ̀ lọ, kí ẹ wòye sí bí ìgbẹ̀yìn àwọn t’ó pe òdodo nírọ́ ṣe rí.
Èyí ni àlàyé fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti wáàsí sì ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹ má ṣe kọ́lẹ, ẹ sì má ṣe banújẹ́; ẹ̀yin l’ẹ máa lékè tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ kèfèrí. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè (tẹ́wọ́) gba àwọn t’ó máa kú fún Un nínú yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
Àti pé (ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè ṣàfọ̀mọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè run àwọn aláìgbàgbọ́.
Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí Allāhu kò tí ì ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun (ẹ̀sìn) nínú yín, tí kò sì tí ì ṣàfi hàn àwọn onísùúrù.
Dájúdájú ẹ ti ń fẹ́ ikú (ogun ẹ̀sìn) ṣíwájú kí ẹ tó pàdé rẹ̀. Ẹ kúkú ti rí i (báyìí), ẹ sì ń wòran.
Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.
____________________
Āyah yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀rí àtamọ́-àtọmọ̀ lọ́dọ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú. Wọ́n ní ikú rẹ̀ ti jẹyọ nínú “Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀” Èsì: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa ikú àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ('alaehim sọlātu wa salām) t’ó ṣíwájú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), kò pọn dandan kí āyah náà yà lọ síbi ọ̀rọ̀ nípa àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ kíyè sí i, bí ọ̀rọ̀ bá wá ní àwòrán gbogbogbò nínú al-Ƙur’ān, kò túmọ̀ sí pé kò lè ní àyàfi nínú nínú āyah mìíràn tàbí nínú hadīth Ànábì t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú sūrah an-Nisā’; 4:117, Allāhu ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ pé, “Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà.” Nínú ohun tí àwọn kan sì sọ di òrìṣà ni Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ṣé abo sì ni òun náà ni tàbí akọ? Ìsọkúsọ l’ó sì máa jẹ́ láti pe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní abo. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé, Allāhu kò ṣe “àyàfi” nínú āyah “abo lòrìṣà”, àmọ́ ó yé wa nínú àwọn āyah mìíràn pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kì í ṣe abo. Akọ ni.
Àpẹẹrẹ mìíràn fún mímú “àyàfi” fún āyah al-Ƙur’ān wá nínú hadīth, òhun ni pé nínú al-Ƙur’ān èèwọ̀ ni òkúǹbete ẹran. Nínú hadith Ànábì láti rí “àyàfi” sí èèwọ̀ náà. Àyàfi kìíní ni pé, awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè kì í ṣe èèwọ̀ fún lílò fún ọ̀ṣọ́ ilé tàbí ọ̀ṣọ́ ara. Irú awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè bẹ́ẹ̀ sì di ẹ̀tọ́ láti fi ṣe bàtà, bẹ́lítì, àpò aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àyàfi kejì: nínú hadīth l’a ti rí i kà pé ẹ̀tọ́ ni òkúǹbete gbogbo ẹran inú omi àti àwọn òkúǹbete ẹja. Bí kò ṣe sí ohun t’ó sọ ọ́ di dandan láti rí àwọn àyàfi wọ̀nyí nínú āyah náà, ohun náà l’ó jẹ́ kí á mọ̀ pé kò sí ohun t’ó sọ ọ́ di dandan nínú āyah òkè yìí láti sọ pé “Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀ (àyàfi ‘Īsā ọmọ Mọryam). Níwọ̀n ìgbà tí a sì ti rí àwọn hadīth tààrà kà lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), èyí ti fi rinlẹ̀ pé “àyàfi” wà fún òun nìkan ṣoṣo láààrin gbogbo àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù nípa pé òun nìkan ni kò ì kú.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹ̀mí kan láti kú àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ikú jẹ́) àkọsílẹ̀ onígbèdéke. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ayé, A máa fún un ní ayé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ọ̀run, A máa fún un ní ọ̀run. A ó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere.
Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí wọ́n ti jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ-ẹ̀yìn (wọn). Wọn kò ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú ogun ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò kọ́lẹ, wọn kò sì jura wọn sílẹ̀ fún ọ̀tá ẹ̀sìn. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù.
Kò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: "Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́."
Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ẹ̀san ayé àti dáadáa ẹ̀san ọ̀run. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe rere.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa yi yín lẹ́sẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Nígbà náà, ẹ máa padà di ẹni òfò (sínú àìgbàgbọ́).
Allāhu sì ni Alárànṣe yín. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọffāt; 37:125.
A máa fi ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sínú ọkàn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́, èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún. Iná sì ni ibùgbé wọn; ilé àwọn alábòsí sì burú.
Dájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fun yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa (àṣẹ Ànábì) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fun yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gùnkè sá lọ, tí ẹ̀yin kò sì bojú wo ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn, Òjíṣẹ́ sì ń pè yín láti ẹ̀yìn yín. Nítorí náà, (Allāhu) fi ìbànújẹ́ (pípa tí àwọn ọ̀ṣẹbọ pa àwọn kan láààrin yín) san yín ní ẹ̀san ìbànújẹ́ (tí ẹ fi kan Ànábì nípasẹ̀ àìtẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ lójú ogun ’Uhd. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ẹ má baà banújẹ́ lórí ohun tí ó bọ́ fun yín àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fun yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó ìrònú bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí." Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.” (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
____________________
Ìyẹn ni pé, bí ikú kò ṣe ní ibùyẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọjọ́ ikú, àyè ikú (ibùkú) àti ọ̀nà ikú kò lè yí padà.
Dájúdájú àwọn t’ó pẹ̀yìn dà nínú yín ní ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé, dájúdájú Èṣù l’ó yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ nítorí apá kan ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì kúkú ti ṣàmójú kúrò fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀ tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Dájúdájú tí wọ́n bá pa yín s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ kú (sínú ilé), dájúdájú àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Allāhu lóore ju ohun tí ẹ̀ ń kójọ (nílé ayé).
Dájúdájú tí ẹ bá kú (sínú ilé) tàbí wọ́n pa yín (s’ójú ogun ẹ̀sìn), dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni wọn máa ko yín jọ sí.
Ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú rọ̀ ọ́ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E.
Tí Allāhu bá ṣe àrànṣe fun yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fun yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá jí ọrọ̀ ogun mú ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.
Ṣé ẹni tí ó (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu dà bí ẹni tí ó padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, ibùgbé rẹ̀ sì ni iná Jahanamọ? Ìkángun náà sì burú.
(Èkínní kejì èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná ni) wọ́n ní ipò (ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Allāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
Ṣé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ tí ikọ̀ ogun méjèèjì pàdé (ṣẹlẹ̀) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni.
(Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀lé yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn ju ìgbàgbọ́ lọ. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́.
Àwọn t’ó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá wọn (t’ó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn) pé – tí àwọn sì jòkóò kalẹ̀ sílé (ní tiwọn), "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n tẹ̀lé tiwa ni, wọn ìbá tí pa wọ́n." Sọ pé: “Ẹ yẹkú dànù fún ẹ̀mí yín tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Ẹ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu, àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:154.
Wọ́n ń dunnú nítorí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀. Wọ́n sì ń yọ̀ fún àwọn tí kò tí ì pàdé wọn nínú àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ pé: “Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.”
Wọ́n ń bá wọn yọ̀ fún ìkẹ́ àti oore-àjùlọ (tí ń dúró dè wọ́n) lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn onígbàgbọ́ òdodo ráre.
(Àwọn ni) àwọn t’ó jẹ́pè Allāhu àti Òjíṣẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti f’ara gbọgbẹ́. Ẹ̀san ńlá wà fún àwọn t’ó ṣe rere, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu) nínú wọn.
(Àwọn ni) àwọn tí àwọn ènìyàn wí fún pé: “Wọ́n mà ti kóra jọ dè yín, nítorí náà ẹ bẹ̀rù wọn.” (Èyí) lékún ìgbàgbọ́ òdodo wọn. Wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó fún wa. Ó sì dára ni Alámòójútó.”
Nítorí náà, wọ́n padà délé pẹ̀lú ìkẹ́ àti oore-àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Aburú kan kò sì kàn wọ́n. Àti pé wọ́n (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
Dájúdájú ìyẹn ni Èṣù, tí ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dẹ́rù bà yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń sáré kó sínú àìgbàgbọ́ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Dájúdájú wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Allāhu kò fẹ́ kí ìpín kan nínú oore wà fún wọn ní ọ̀run (ni); ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn.
Dájúdájú àwọn t’ó fi ìgbàgbọ́ òdodo ra àìgbàgbọ́, wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn.
Allāhu kò níí gbé àwọn onígbàgbọ́ òdodo jù sílẹ̀ lórí ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀ (níbi àìmọ onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ṣọ̀bẹ-ṣèlu) títí Ó máa fi ya ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára ẹni dáadáa. Allāhu kò sì níí fi ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ mọ̀ yín, ṣùgbọ́n Allāhu yóò ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Tí ẹ bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ẹ̀san ńlá yó sì wà fun yín.
____________________
Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun. Kò sì sí Òjíṣẹ́ Allāhu mọ́ lẹ́yìn òpin àwọn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Bí ẹnì kan bá tún pe ara rẹ̀ ní “òjíṣẹ́ Ọlọ́hun” ní àsìkò yìí, òpùrọ́ asọ̀ọ̀kùn sẹ́sìn ni. Ẹ tún wo sūrah al-Jinn; 72:26-28.
Kí àwọn t’ó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn. Rárá, aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun dì wọ́n lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Allāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì síwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀).
Àwọn t’ó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.
____________________
Àpẹẹrẹ fún ìpín-ìpín Tírà ni suhf ’Ibrọ̄hīm àti suhf Mūsā. Àpẹẹrẹ fún Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni az-Zabūr, at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé.
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.
Dájúdájú A ó máa dan yín wò nínú dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìpalára láti ọ̀dọ̀ àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan.
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́. Wọ́n sì jù ú sẹ́yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n sì tà á ní owó kékeré. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń tà mà sì burú (níyà).
Ẹ má ṣe lérò pé àwọn t’ó ń dunnú sí ohun tí wọ́n ṣe (ní àìdáa máa là nínú ìyà). Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn (ènìyàn) máa yìn wọ́n fún ohun tí wọn kò ṣe (níṣẹ́ rere). Nítorí náà, ẹ má ṣe rò wọ́n ro ìgbàlà níbi Ìyà. Ìyà ẹlẹ́ta eléro sì wà fún wọn.
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán; (àmì wà nínú wọn) fún àwọn onílàákàyè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:164.
Àwọn t’ó ń rántí Allāhu ní ìnàró, ìjókòó àti ní ìdùbúlẹ̀; tí wọ́n ń ronú sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (wọ́n sì ń sọ pé:) "Olúwa wa, Ìwọ kò ṣẹ̀dàá èyí pẹ̀lú irọ́. Mímọ́ ni fún Ọ. Nítorí náà, ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.
Olúwa wa, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún àwọn alábòsí.
Olúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan t’ó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: "Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere.
Olúwa wa, fún wa ní ohun tí O ṣàdéhùn rẹ̀ fún wa lórí (ahọ́n) àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ. Má sì ṣe dójú tì wá ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Ìwọ kì í yapa àdéhùn."
Olúwa wọn sì jẹ́pè wọn pé: “Dájúdájú Èmi kò níí fi iṣẹ́ oníṣẹ́ kan nínú yín ráre; ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ara kan náà ni yín (níbi ẹ̀san). Nítorí náà, àwọn t’ó gbé (ìlú wọn) jù sílẹ̀, tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn, tí wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n nítorí ẹ̀sìn Mi, wọ́n jagun ẹ̀sìn, wọ́n sì pa wọ́n. Dájúdájú Èmi yóò bá wọn pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Èmi yó sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ẹ̀san dáadáa wà.
Má ṣe gba ẹ̀tàn pẹ̀lú ìgbòkè-gbodò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìlú.
Ìgbádùn díẹ̀ (lè wà fún wọn), lẹ́yìn náà iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ibùgbé náà sì burú.
Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ibùdésí kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì lóore jùlọ fún àwọn ẹni rere.
Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn; wọ́n ń páyà Allāhu, wọn kì í ta àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu ní owó kékeré. Àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún āyah 110 fún àgbọ́yé āyah yìí.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣe sùúrù, ẹ pàrọwà sùúrù, ẹ ṣọ́ bodè ìlú yín (láti lè dènà àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá ẹ̀sìn). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.