ترجمة سورة القيامة

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة القيامة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú Ọjọ́ Àjíǹde.
Mo tún ń búra pẹ̀lú ẹ̀mí t’ó máa dára rẹ̀ lẹ́bi.
Ṣé ènìyàn lérò pé A ò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?
Rárá o. A lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba.
Ṣùgbọ́n ènìyàn gbèrò láti pe (Ọjọ́ Àjíǹde) t’ó ń bẹ níwájú rẹ̀ nírọ́.
Ó ń bèèrè pé: "Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?"
Nígbà tí ojú bá kọ mọ̀nà,
àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,
àti (nígbà) tí A bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn,
ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: "Níbo ni ibùsásí wà?"
Rárá, kò sí ibùsásí.
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.
Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun t’ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun t’ó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,
ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.
Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.
Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.
Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.
Ẹ gbọ́! Ńṣe l’ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé.
Ẹ sì ń pa ọ̀run tì.
Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).
Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.
Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.
(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé Wọ́n máa fi aburú kan òhun.
Ẹ gbọ́! Nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.
A sì máa sọ pé: "Ǹjẹ́ ọlọ́fọ̀ pípè kan wà bí (tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?
Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.
Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.
Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.
Ṣùgbọ́n ó pe òdodo nírọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.
Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.
Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́.
Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì sẹ́.
Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?
Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?
Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.
(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti inú rẹ̀, akọ àti abo.
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?
Icon