ترجمة سورة فاطر

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة فاطر باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Àgbọ́yé òǹkà tí ó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 ni àgbọ́yé òǹkà t’ó tún jẹyọ nínú āyah yìí. Èyí túmọ̀ sí pé, alápá méjì wà nínú àwọn mọlāika, alápá mẹ́ta wà nínú wọn, alápá mẹ́rin sì wà nínú wọn. Alápá púpọ̀, tí apá rẹ̀ lé ní mẹ́rin, tún wà nínú wọn.
Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dá a dúró. Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ.
Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fun yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná t’ó ń jò fòfò.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi ń bẹ fún wọn.
Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l’o fẹ́ banújẹ́ lé lórí?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe.
Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí).
Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun.
Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A ò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A ò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín lọ́fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ t’ó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l’ẹ ti ń jẹ ẹran (ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí ki ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
(Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù.
Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn).
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́.
Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò nílẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá.
Ìyẹn kò sì kágara kan bá Allāhu.
Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan. Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nahl; 16:25.
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba.
Àwọn òòkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba).
Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba).
Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Naml; 27:81.
Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀.
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn.
____________________
Āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀nà tí ìjọ Ahmadiyyah gbà di kèfèrí. Ìdí ni pé, nítorí āyah yìí ni ìjọ náà fi pe gbogbo òrìṣà ní ànábì tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán níṣẹ́ sí ayé. Ìtọ́kasí wọn nìyí: “In pursuance of this doctrine, he (mirza Ghulam Ahmad al-Ƙadiyyaanii) testified to the truth of Krishna, Ram Chandra and Buddha, the prophets of India, and Zoroaster, the prophet of Persia, and described the rejection of their claims as, in a sense, amounting to a denial of the universal Providence of God.” Ìtúmọ̀ “Láti lè tẹ̀lé ìgbàgbọ́ yìí l’ó mú kí mirza Ghulam Ahmad jẹ́rìí pé òdodo ni òrìṣà Krishna, òrìṣà Ram Chandra àti òrìṣà Buda, tí wọ́n jẹ́ àwọn ànábì ilẹ̀ India. Àti òrìṣà Zoroaster, tí ó jẹ́ ànábì ilẹ̀ Persia. Mirza Ghulam Ahmad sì gbà pé ẹni tí ó bá tako àwọn òrìṣà náà, ó ti tako oore tí Allāhu ṣe fún àgbáyé.” Ahmadiyyah Movement, láti ọwọ́ Bashirud-din Mahmud Ahmad, ojú ewé: 69. Bákàn náà, ìjọ Ahmadiyyah tún gbàgbọ́ lábẹ́ āyah yìí pé kò sí ìlú tí Allāhu kò ti gbé Òjíṣẹ́ kan dìde. Èyí kì í ṣe àgbọ́yé āyah yìí. Àti pé ìgbàgbọ́ wọn yìí tako sūrah al-Furƙọ̄n; 25:51. Lẹ́yìn náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọsọs; 28:46.
Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn t’ó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.
Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn pẹ̀lú aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta.
Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn t’ó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn.
____________________
Àìmọ̀kan kò ṣeé lò láti fi páyà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Aláìmọ̀kan yóò máa ṣe àwọn kiní kàn tí ó máa lérò pé òun ń fi páyà Allāhu ni, àmọ́ t’ó jẹ́ pé ńṣe l’ó ń da ara rẹ̀ láàmú. Ìmọ̀ nípa Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ènìyàn lè fi páyà Allāhu ní ọ̀nà òtítọ́ àti ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìmọ̀ náà ní àsìkò yìí ni ìmọ̀ al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Méjèèjì l’ó máa jogún ìpáyà Allāhu fún olówó rẹ̀. Kíyè sí i! Tí a bá rí onímímọ̀ ẹ̀sìn tí kì í páyà Allāhu, ó wù ú bẹ́ẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni. Kì í ṣe pé ìmọ̀ nípa Allāhu l’ó sọ ọ́ di bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn onibidiah. Nítorí náà, tí ẹ̀dá bá kéú tán, t’ó sọ bidiah di iṣẹ́, t’ó kúndùn bidiah ju sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti yọ barka “ìbùkún” kúrò nínú ìmọ̀ rẹ̀ nìyẹn. Ẹ ka sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:175 àti 176 kí ẹ rí àpẹẹrẹ irú wọn.
Dájúdájú àwọn t’ó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun.
(Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.
Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur’ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí t’ó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ t’ó tóbi.
____________________
Nínú āyah yìí, alábòsí t’ó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí ni ẹni tí ó géwọ́ kúrú níbi àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn nínú ẹ̀sìn. Olùṣe-déédé ni ẹni t’ó ń ṣe ọ̀wọ́ àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn nínú ẹ̀sìn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere ni ẹni t’ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan ọ̀ran-anyàn àti àwọn n̄ǹkan àṣegbọrẹ papọ̀ nínú ẹ̀sìn.
Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
Wọ́n yóò sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́,
Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀.
Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahnamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò sì níí gbé ìyà rẹ̀ fúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san.
Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe.” Ṣé A ò fun yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Òun ní Ẹni t’Ó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò.
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí t’ó yanjú nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.”
Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn.
Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: "Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (t’ó ti ṣíwájú) lọ." Nígbà tí olùkìlọ̀ sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)
ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ìpète aburú. Ìyà ìpète aburú kò sì níí kò lé ẹnì kan lórí àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́? Nítorí náà, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hijr; 15:13.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Icon