ترجمة سورة الصافات

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الصافات باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

(Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà;
àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà;
àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí.
Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni;
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun.
(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e.
Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn.
Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ."
Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san."
Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́?
Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
(Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)."
____________________
Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo. Àpẹẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn àáfà tí wọ́n bá àwọn àlùjọ̀nnú dòwò pọ̀ tán, tí wọ́n sọra wọn di oníṣẹ́-ìyanu àti àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ Tijāniyyah.
(Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà.
Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà."
Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà.
Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga.
Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?"
Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún.
Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
Wọ́n dà bí tinú ẹyin.
____________________
Àwọn kristiẹni, nínú ọ̀rọ̀ wọn kan tí wọ́n ń fi tàbùkù àwọn ìkẹ́ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, wọ́n sọ pé, “Nítorí ọ̀wọ́n èso ní erúkùsù ilẹ̀ Lárúbáwá ni Allāhu fi ṣàdéhùn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso fún àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn ọtí àmupara ni Allāhu fi bá wọn pèsè ọtí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ dè wọ́n nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn àgbèrè ṣíṣe ni Allāhu fi bá wọn pèsè obìnrin ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀!”
Èsì: Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn kristiẹni wọ̀nyí, yàtọ̀ sí pé ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí aláwàdà kẹríkẹrì, ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run, irú ìkẹ́ wo gan-an ni wọ́n ń retí nígbà náà? Síwájú sí i, kì í kúkú ṣe Lárúbáwá nìkan ni mùsùlùmí. Gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni mùsùlùmí. Àwọn kristiẹni ṣe wá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé nítorí Lárúbáwá nìkan ni Allāhu fi dá Ọgbà Ìdẹ̀ra! Ìgbádùn inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wulẹ̀ pọ̀ tayọ èso, ọtí tí kìí pani àti obìnrin. Àmọ́ sá, kò wulẹ̀ sí ìgbádùn kan kan fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́run bí kò ṣe Iná gbére.
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?"
Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá."
Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù.
Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá.
A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.
____________________
Ìyẹn ni pé, ẹ̀sìn Ànábì Nūh ni ẹ̀sìn Ànábì ’Ibrọ̄hīm (aleehimọ sọlātu wa salām), ẹ̀sìn ’Islām.
(Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an.
Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí."
Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni?
Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀?"
Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná."
Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).
____________________
Ìyẹn ìlú Ṣām.
Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere."
A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà.
Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́."
Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
____________________
Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí.
A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.
____________________
Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām); (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun t’ó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún. Àmọ́, àwọn kristiẹni, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àṣà wọn, orúkọ burúkú ni wọ́n ń fún Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Hūd; 11:71.
Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá.
A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú.
A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀,
____________________
Ṣé ẹlẹ́dàá mìíràn wà lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni? Ẹ yiri àwọn gbólóhùn wọ̀nyí wò: أَحْسَنَ ٱلْخَٰلِقِينَ Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá. (Ó tún wà nínú sūrah al-Mu’minūn; 23:14)
Irúfẹ́ gbólóhùn yìí nìwọ̀nyí: وَأَنتَ خَيْرُ ٱلرَّٰزِقِينَ Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè. (sūrah al-Mọ̄’idah; 5:114); وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:87);
وَأَنتَ أَرْحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú. (sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:151); وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām; 6:62); àti وَٱللَّهُ خَيْرُ ٱلْمَٰكِرِينَ Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte. (āl-‘Imrọ̄n; 3:54).
Àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń jẹ́ Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́dàá, olùpèsè, olùdájọ́, aláàánú, oníṣirò àti eléte. Kíyè sí i, nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń ṣe fún àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, àmọ́ tí a tún ń rí àwọn kan nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tí àwọn náà máa ń ṣe wọ́n ni dídá ẹ̀dá, ìpèsè, ẹjọ́ dídá, àánú ṣíṣe, ìṣírò iṣẹ́ àti ète dídá. Ṣùgbọ́n ìkọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ náà bùkátà sí àlàyé.
Dídá ẹ̀dá: Ní òdodo ni pé, kò sí ẹ̀dá kan láyé àti lọ́run, ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún, àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́, ẹ̀dá kan nínú ẹ̀dá Allahu ni. Àmọ́ ohun tí a gbà lérò pẹ̀lú fífi dídá ẹ̀dá tì sọ́dọ̀ ẹ̀dá ni ṣíṣe iṣẹ́-ọnà bíi ère gbígbẹ́ àti yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí. Èdè abunikù fún agbẹ́gilére ni “ẹlẹ́dàá”. Tí agbẹ́gilére bá mọ súná burúkú tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún òun, tí ó sì mọ̀ pé dájúdájú òun kò lè fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀ t’ó ń gbẹ́ kalẹ̀, bóyá ó máa mọ̀ ọ́n ní ọ̀ràn. Ìdí nìyí tí hadīth kan fi sọ pé, lára ìyà tí ń bẹ nílẹ̀ ní ọ̀run nínú Iná de agbẹ́gi-lére ni pé, wọ́n máa sọ fún un pé kí ó fi ẹ̀mí sára ère rẹ̀. Kò sì níí lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wàyí, wọ́n ń pé agbẹ́gilére ní “ẹlẹ́dàá” nítorí pé, wọ́n ń fi iṣẹ́-ọnà wọn jọ ẹ̀dá tí Allāhu dá. Tí a bá wá lo orúkọ “ẹlẹ́dàá” fún wọn, dípò oníṣẹ́-ọnà, tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì ń jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ta ni Ẹlẹ́dàá t’ó dára jùlọ tí ẹ̀dá tirẹ̀ jẹ́ ojúlówó? Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ pé, “Òun ni Ẹni t’ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá.” Pípe “oníṣẹ́-ọnà” ni “ẹlẹ́dàá” kò sì túmọ̀ sí pé ẹ̀dá kan wà t’ó ṣẹ̀dá ara rẹ̀ tàbí pé ẹ̀dá kan wà t’ó ń dá ẹ̀dá mìíràn bí kò ṣe ṣíṣe iṣẹ́-ọnà. Nítorí náà, ìtúmọ̀ àwọn ẹlẹ́dàá nínú āyah yìí ni “àwọn oníṣẹ́-ọnà tàbí àwọn agbẹ́gilére”.
Ìpèsè: Àwọn ẹ̀dá kan gbàgbọ́ pé àwọn òrìṣà kan ń pèsè ìjẹ-ìmu àti owó fún àwọn. Bí àpẹẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ pé òrìṣà Ajé ń ṣe ìjẹ-ìmu, owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n, ó máa hàn sí wọn kedere pé, ìpèsè ti Allāhu pọ̀ jùlọ, kò sì ṣe é kà. Àti pé nínú ìpèsè Rẹ̀ ni wọ́n ti fún àwọn òrìṣà.
Ẹjọ́ dídá; A kúkú ní àwọn adájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, yálà nílé ẹjọ́ tàbí ní àyè mìíràn. Àmọ́ kò sí adájọ́ tí ó jẹ́ arínú-róde. Àti pé ó wà nínú àwọn adájọ́ t’ó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti fi ẹjọ́ ṣègbè. Allāhu nìkan ṣoṣo ni kì í fí ẹjọ́ ṣègbè. Àti pé ìdájọ́ Rẹ̀ dúró sórí mímọ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba olùrojọ́. Nítorí náà, ìdí nìyí tí Allāhu fi mọ ẹjọ́ da jùlọ nínú àwọn adájọ́. Ìdájọ́ Rẹ̀ sì ni òpin.
Àánú Ṣíṣe: Ojú àánú àti ọkàn àánú ń bẹ lára àwọn ẹ̀dá kan, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ẹlẹ́yinjú-àánú. Àmọ́ Allāhu ní àánú ẹ̀dá Rẹ̀ púpọ̀ jùlọ. Àti pé, nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà, Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.
Bí àlàyé ṣe máa lọ nìyẹn lórí irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ nínú al-Ƙur’ān, gẹ́gẹ́ bíi gbólóhùn “Olùyára jùlọ nínú àwọn olùṣírò-iṣẹ́”. Àmọ́ ní ti ète dídá, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171.
Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.
Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí.
____________________
Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi takú sórí omi, wọ́n jọ fẹnu kò pé kí àwọn kọ orúkọ àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi sí ara fọ́nrán ọ̀pá kọ̀ọ̀kan. Wọ́n sì jọ fẹnu kò pé ẹni tí wọ́n bá yọ fọ́nrán orúkọ rẹ̀ jáde nínú koto fọ́nrán ni wọn yóò jù sínú odò nítorí kí ọkọ t’ó takú lè lágbára láti rìn. Fọ́nrán orúkọ ti Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni wọ́n rí mú jáde. Wọ́n sì jù ú sínú odò. Ó sì ṣe wẹ́kú ẹnu ẹja.
Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.
____________________
Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Wàyí, àwọn kristiẹni lérò pé Allāhu kò nímọ̀ nípa pàtó òǹkà ìjọ Ànábì Yūnus ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’Ó fi mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá pẹ̀lú “ ’ao” - “tàbí”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:74 fún àlàyé lórí rẹ̀.
Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?"
Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
"Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni?
Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà.
Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.
Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
Wọ́n kúkú ń wí pé:
"Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà."
Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Icon